‘Ẹ Máa Kéde Ìhìn Rere!’
Àpéjọ Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti Ọdún 2024
A kì í gba owó ìwọlé • A kì í gbégbá ọrẹ
Àwọn Nǹkan Tá A Máa Gbádùn
Friday: A máa sọ̀rọ̀ nípa àwọn ẹ̀rí tó fi hàn pé òótọ́ làwọn nǹkan tí ìwé Ìhìn Rere sọ nípa Jésù. Wàá rí bí àwọn ìtàn tó wà nínú ẹ̀ ṣe lè ṣe ẹ́ láǹfààní lónìí. —Kól. 1:20.
Saturday: Kí ni Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ nípa ibi tí wọ́n máa bí Jésù sí àtàwọn nǹkan tó máa ṣẹlẹ̀ nígbà tó bá wà lọ́mọdé? Ṣé àwọn àsọtẹ́lẹ̀ yẹn sì ṣẹ lóòótọ́?
Sunday: Nínú àsọyé tó dá lórí Bíbélì tí àkòrí ẹ̀ ní “Ìdí tí Ìròyìn Burúkú Ò Fi Bà Wá Lẹ́rù,” wàá mọ ohun tó mú kí ọkàn ọ̀pọ̀ èèyàn balẹ̀ lónìí, bó tiẹ̀ jẹ́ pé nǹkan túbọ̀ ń burú sí i láyé.
Fídíò Ìtàn Bíbélì
Ìhìnrere Látọ̀dọ̀ Jésù: Abala 1
Ìmọ́lẹ̀ Tòótọ́ fún Aráyé
Ọ̀nà àrà tí wọ́n gbà bí Jésù jẹ́ ọ̀kan lára àwọn nǹkan àgbàyanu tó ṣẹlẹ̀ nígbà tó wà lọ́mọdé. Àwọn òbí ẹ̀ gbé e lọ sí Íjíbítì torí pé ọba burúkú kan fẹ́ pa á. Nígbà tó yá, ọ̀nà tó gbà ń sọ̀rọ̀ wú àwọn aṣáájú ẹ̀sìn ìgbà yẹn lórí gan-an. Nínú fídíò alápá méjì tá a máa wò lọ́jọ́ Friday àti Saturday, wàá rí báwọn nǹkan yìí àtàwọn nǹkan míì ṣe ṣẹlẹ̀.
Wo àwọn fídíò yìí kó o lè mọ bá a ṣe máa ṣe àpéjọ tọdún yìí
Kí La Máa Ń Ṣe Láwọn Àpéjọ Wa?
Wàá rí bí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe máa ń ṣe àwọn àpéjọ wa.
‘Ẹ Máa Kéde Ìhìn Rere!’ Àpéjọ Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti Ọdún 2024
Wo díẹ̀ lára àwọn nǹkan tá a máa gbádùn ní àpéjọ tọdún yìí.
Ìtọ́wò Fídíò: Ìhìnrere Látọ̀dọ̀ Jésù
Ọ̀pọ̀ èèyàn ló mọ̀ nípa ọ̀nà àrà tí wọ́n gbà bí Jésù. Àmọ́ àwọn nǹkan wo ló ṣẹlẹ̀ ṣáájú àkókò yẹn àti lẹ́yìn náà?