Ẹ̀KỌ́ 1
Kí Ni Ìròyìn Ayọ̀ Náà?
1. Ìròyìn wo ló wá látọ̀dọ̀ Ọlọ́run?
Ọlọ́run fẹ́ kí àwa èèyàn máa gbádùn ayé wa lórí ilẹ̀ ayé. Ó dá ayé àti gbogbo ohun tó wà nínú rẹ̀ torí pé ó nífẹ̀ẹ́ àwa èèyàn. Láìpẹ́, Ọlọ́run máa mú kí nǹkan túbọ̀ dáa fún àwa èèyàn níbi gbogbo. Ó máa mú gbogbo ohun tó ń fa ìyà tó ń jẹ aráyé kúrò.—Ka Jeremáyà 29:11.
Kò sí ìjọba kankan tó ti ṣàṣeyọrí láti mú ìwà ipá, àìsàn àti ikú kúrò. Àmọ́, ìròyìn ayọ̀ kan wà o. Láìpẹ́, Ọlọ́run máa mú gbogbo ìjọba èèyàn kúrò, á sì fi ìjọba tirẹ̀ rọ́pò wọn. Àwọn tó bá wà lábẹ́ Ìjọba Ọlọ́run máa gbádùn àlàáfíà àti ìlera tó jí pépé.—Ka Àìsáyà 25:8; 33:24; Dáníẹ́lì 2:44.
2. Kí nìdí tó fi yẹ ká tètè sọ ìròyìn ayọ̀ yìí fún àwọn èèyàn?
Ìgbà tí Ọlọ́run bá pa àwọn èèyàn búburú run ni ìyà tó ń jẹ aráyé máa tó dópin. (Sefanáyà 2:3) Ìgbà wo nìyẹn máa ṣẹlẹ̀? Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ti sọ tẹ́lẹ̀ nípa àwọn ìṣòro tó ń bá aráyé fínra lákòókò wa yìí. Àwọn nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ láyé báyìí fi hàn pé kò ní pẹ́ mọ́ tí Ọlọ́run máa dá sí ọ̀rọ̀ ayé yìí.—Ka 2 Tímótì 3:1-5.
3. Kí ló yẹ ká ṣe?
Ó yẹ ká kẹ́kọ̀ọ́ nípa Ọlọ́run látinú Bíbélì, Ọ̀rọ̀ rẹ̀. Bíbélì dà bíi lẹ́tà látọ̀dọ̀ Bàbá kan tó nífẹ̀ẹ́ àwọn ọmọ rẹ̀. Ó sọ bá a ṣe lè gbádùn ìgbésí ayé wa báyìí àti bá a ṣe lè ní ìyè àìnípẹ̀kun lórí ilẹ̀ ayé lọ́jọ́ iwájú. Òótọ́ ni pé inú àwọn kan lè má dùn sí bó o ṣe fẹ́ mọ ohun tó wà nínú Bíbélì. Àmọ́, tó o bá ń ronú nípa àwọn nǹkan rere tí Ọlọ́run ṣèlérí fún ọ lọ́jọ́ iwájú, o ò ní jẹ́ kí ẹnikẹ́ni dí ẹ lọ́wọ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.—Ka Òwe 29:25; Ìfihàn 14:6, 7.