Ẹ̀KỌ́ 8
Kí Nìdí Tí Ọlọ́run Fi Fàyè Gba Ìwà Ibi àti Ìyà?
1. Báwo ni ìwà ibi ṣe bẹ̀rẹ̀?
Ìwà ibi bẹ̀rẹ̀ nígbà tí Sátánì pa irọ́ àkọ́kọ́. Áńgẹ́lì pípé ni Sátánì nígbà tí Ọlọ́run dá a, àmọ́ ‘kò dúró ṣinṣin nínú òtítọ́.’ (Jòhánù 8:44) Ó jẹ́ kí ohun tí kò lẹ́tọ̀ọ́ sí máa wu òun, ó fẹ́ kí àwọn èèyàn máa jọ́sìn òun dípò Ọlọ́run. Sátánì parọ́ fún Éfà obìnrin àkọ́kọ́, ó sì mú kó ṣègbọràn sí òun dípò Ọlọ́run. Ádámù dara pọ̀ mọ́ Éfà, òun náà sì ṣàìgbọràn sí Ọlọ́run. Ìpinnu tí Ádámù ṣe yọrí sí ìyà àti ikú.—Ka Jẹ́nẹ́sísì 3:1-6, 19.
Nígbà tí Sátánì tan Éfà pé kó ṣàìgbọràn sí Ọlọ́run, ńṣe ni Sátánì fẹ́ kí wọ́n ṣọ̀tẹ̀ sí Ọlọ́run tó jẹ́ Ọba Aláṣẹ ayé àtọ̀run àti Ẹni Gíga Jù Lọ. Ọ̀pọ̀ jù lọ èèyàn ló ti dara pọ̀ mọ́ Sátánì tí wọn ò sì fẹ́ kí Ọlọ́run máa ṣàkóso àwọn. Nípa bẹ́ẹ̀, Sátánì ti di “alákòóso ayé.”—Ka Jòhánù 14:30; 1 Jòhánù 5:19.
2. Ṣé àbùkù wà nínú àwọn ohun tí Ọlọ́run dá?
Gbogbo ohun tí Ọlọ́run ṣe ló jẹ́ pípé. Àtèèyàn àtàwọn áńgẹ́lì tí Ọlọ́run dá ló lè yàn láti ṣègbọràn sí Ọlọ́run láìyẹhùn. (Diutarónómì 32:4, 5) Nígbà tí Ọlọ́run dá wa, ó fún wa lómìnira láti yàn bóyá ká ṣe rere tàbí búburú. Òmìnira yìí fún wa láǹfààní láti fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run.—Ka Jémíìsì 1:13-15; 1 Jòhánù 5:3.
3. Kí nìdí tí Ọlọ́run fi fàyè gba ìyà títí di báyìí?
Látìgbà yẹn wá, Jèhófà ti fàyè gba ọ̀tẹ̀ tí wọ́n ṣe sí òun tó jẹ́ Ọba Aláṣẹ ayé àtọ̀run. Kí nìdí? Ìdí ni pé ó fẹ́ kí àwọn èèyàn mọ̀ pé ìṣàkóso tí òun kò bá lọ́wọ́ sí kò lè ṣe wọ́n láǹfààní. (Oníwàásù 7:29; 8:9) Lẹ́yìn ẹgbẹ̀rún mẹ́fà (6,000) ọdún tí èèyàn ti wà láyé, ọ̀rọ̀ náà ti wá ṣe kedere. Gbogbo bí àwọn èèyàn tó ń ṣàkóso ṣe ń sapá tó, wọn ò lè fòpin sí ogun, ìwà ọ̀daràn, ìrẹ́jẹ àti àìsàn.—Ka Jeremáyà 10:23; Róòmù 9:17.
Àkóso Ọlọ́run yàtọ̀ pátápátá sí ti èèyàn, àwọn tó fara mọ́ Ìjọba Ọlọ́run ń jàǹfààní lọ́pọ̀lọpọ̀. (Àìsáyà 48:17, 18) Láìpẹ́, Jèhófà máa pa gbogbo ìjọba èèyàn run. Àwọn èèyàn tó bá gbà pé kí Ọlọ́run máa ṣàkóso àwọn nìkan ló máa gbé láyé.—Àìsáyà 11:9.—Ka Dáníẹ́lì 2:44.
Wo Fídíò náà Kí Nìdí Tí Ọlọ́run Fi Gbà Pé Ká Máa Jìyà?
4. Kí ni sùúrù Ọlọ́run mú ká lè ṣe?
Sátánì sọ pé kò sí ẹnì kankan tó máa sin Jèhófà torí pé ẹni yẹn dìídì nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, àfi tó bá ń rí nǹkan gbà. Ṣé ó wù ẹ́ láti fi hàn pé irọ́ ni ohun tí Sátánì sọ yìí? O lè fi hàn pé irọ́ ni! Sùúrù Ọlọ́run ń fún gbogbo wa láǹfààní láti fi hàn bóyá àkóso Ọlọ́run la fara mọ́ àbí àkóso èèyàn. Bá a ṣe ń gbé ìgbé ayé wa ló ń fi èyí tá a fara mọ́ hàn.—Ka Jóòbù 1:8-12; Òwe 27:11.
5. Báwo la ṣe lè fi Ọlọ́run ṣe Alákòóso wa?
A lè fi Ọlọ́run ṣe Alákòóso wa tá a bá wá ìsìn tòótọ́ tí ohun tí wọ́n ń ṣe nínú rẹ̀ bá Bíbélì, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run mu, tá a sì dara pọ̀ mọ́ ìsìn náà. (Jòhánù 4:23)A lè fi hàn pé a ò fẹ́ kí Sátánì jẹ́ alákòóso wa, tá a bá ṣe bíi ti Jésù, tí a ò lọ́wọ́ sí ìṣèlú àti ogun.—Ka Jòhánù 17:14.
Sátánì ń fi agbára rẹ̀ mú kí àwọn èèyàn wo ìṣekúṣe àti ìwàkiwà bí ohun tí kò burú. Tí a kò bá lọ́wọ́ nínú irú àwọn ìwà bẹ́ẹ̀, àwọn ọ̀rẹ́ àtàwọn ìbátan wa lè máa fi wá ṣe yẹ̀yẹ́ tàbí kí wọ́n gbógun tì wá. (1 Pétérù 4:3, 4) Torí náà, àwa la máa pinnu ohun tá a máa ṣe. Ṣé àwọn tó nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run la máa dara pọ̀ mọ́? Ṣé òfin rẹ̀ tó mọ́gbọ́n dání, tó sì fi hàn pé ó nífẹ̀ẹ́ wa la máa tẹ̀ lé? Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, ńṣe là ń fi hàn pé òpùrọ́ ni Sátánì tó sọ pé a ò ní ṣe ohun tí Ọlọ́run fẹ́ nígbà tí ìṣòro bá dé.—Ka 1 Kọ́ríńtì 6:9, 10; 15:33.
Ìfẹ́ tí Ọlọ́run ní sí aráyé mú kó dá wa lójú pé ìwà ibi àti ìyà máa dópin. Àwọn tó fi hàn pé àwọn nígbàgbọ́ nínú ọ̀rọ̀ yìí máa wà láàyè títí láé lórí ilẹ̀ ayé.—Ka Jòhánù 3:16.