Kí Ló Ń Ṣẹlẹ̀ Nígbà Téèyàn Bá Kú?
Ohun tí Bíbélì sọ
Bíbélì sọ pé: “Àwọn alààyè mọ̀ pé àwọn yóò kú; ṣùgbọ́n ní ti àwọn òkú, wọn kò mọ nǹkan kan rárá.” (Oníwàásù 9:5; Sáàmù 146:4) Torí náà, téèyàn bá ti kú, ó ti di aláìsí nìyẹn. Àwọn òkú kò lè ronú, wọn ò lè ṣe ohunkóhun, bẹ́ẹ̀ sì ni wọn ò ní ìmọ̀lára ohunkóhun.
“Ìwọ ó sì padà di erùpẹ̀”
Nígbà tí Ọlọ́run ń bá Ádámù, ọkùnrin àkọ́kọ́ sọ̀rọ̀, ó ṣàlàyé ohun tó máa ń ṣẹlẹ̀ téèyàn bá kú. Torí pé Ádámù ṣàìgbọràn, Ọlọ́run sọ fún un pé: “Erùpẹ̀ . . . ni ìwọ, ìwọ ó sì padà di erùpẹ̀.” (Jẹ́nẹ́sísì 3:19, Bíbélì Mímọ́) Ádámù kò sí níbì kankan kí Ọlọ́run tó “fi erùpẹ̀ ilẹ̀” dá a. (Jẹ́nẹ́sísì 2:7, Bíbélì Mímọ́) Bákan náà, nígbà tí Ádámù kú, ó padà di erùpẹ̀, ó sì di aláìsí.
Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Ádámù náà ló ṣì ń ṣẹlẹ̀ sí àwọn tó bá kú. Bíbélì sọ ohun tó máa ń ṣẹlẹ̀ sí àwọn èèyàn àtàwọn ẹranko, ó ní: “Láti inú erùpẹ̀ ni gbogbo wọn ti wá, gbogbo wọn ó sì padà di erùpẹ̀.”—Oníwàásù 3:19, 20, Bíbélì Mímọ́.
Ikú kọ́ ni òpin ohun gbogbo
Bíbélì sábà máa ń fi ikú wé oorun. (Sáàmù 13:3; Jòhánù 11:11-14; Ìṣe 7:60) Ẹni tó sùn wọra gan-an kì í mọ ohun tó ń lọ láyìíká rẹ̀. Bákan náà, àwọn òkú kò mọ ohunkóhun mọ́. Àmọ́, Bíbélì kọ́ wa pé Ọlọ́run máa jí àwọn òkú dìde bí ẹni pé ńṣe ló jí wọn lójú oorun, tí yóò sì tún jẹ́ kí wọ́n wà láàyè lẹ́ẹ̀kan sí i. (Jóòbù 14:13-15) Ikú kì í ṣe òpin ohun gbogbo fún àwọn tí Ọlọ́run bá jí dìde.