Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Ẹ̀ka Ọ́fíìsì Tó Ń Bójú Tó Iṣẹ́ Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Rọ́ṣíà

APRIL 27, 2016
RỌ́ṢÍÀ

Àwọn Aláṣẹ Kìlọ̀ Fáwọn Ẹlẹ́rìí Pé Àwọ́n Máa Ti Ẹ̀ka Ọ́fíìsì Wọn Pa ní Rọ́ṣíà, Èyí Ò sì Ní Jẹ́ Kí Wọ́n Lómìnira Ẹ̀sìn

Àwọn Aláṣẹ Kìlọ̀ Fáwọn Ẹlẹ́rìí Pé Àwọ́n Máa Ti Ẹ̀ka Ọ́fíìsì Wọn Pa ní Rọ́ṣíà, Èyí Ò sì Ní Jẹ́ Kí Wọ́n Lómìnira Ẹ̀sìn

Àwọn aláṣẹ orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà ti gbé ìgbésẹ̀ míì láti fòfin de àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ìgbésẹ̀ ọ̀hún le gan-an, ìjọba sì ń tì wọ́n lẹ́yìn. Agbẹjọ́rò Àgbà ń halẹ̀ mọ́ wọn pé ìjọba máa ti Ẹ̀ka Ọ́fíìsì Tó Ń Bójú Tó Iṣẹ́ Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Rọ́ṣíà pa torí ẹ̀sùn “agbawèrèmẹ́sìn” tí wọ́n fi kàn wọ́n. Nínú lẹ́tà tí wọ́n kọ sí wọn ní March 2, 2016 láti kìlọ̀ fún wọn, Igbákejì Agbẹjọ́rò Àgbà, V. Ya. Grin pàṣẹ pé láàárín oṣù méjì, kí Ẹ̀ka Ọ́fíìsì náà wá nǹkan ṣe sí gbogbo “ẹrù òfin” tó wà lọ́wọ́ wọn.

Ìjọba orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà ti ń gbìyànjú láti ká àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lọ́wọ́ kò kí wọ́n má bàa lómìnira láti ṣe ẹ̀sìn wọn, àmọ́ lẹ́tà yìí tún wá jẹ́ kọ́rọ̀ náà burú sí i. Tí wọ́n bá ti Ẹ̀ka Ọ́fíìsì náà pa, wọ́n á dáwọ́ iṣẹ́ dúró níbẹ̀, wọ́n á kà á mọ́ àwọn iléeṣẹ́ tí ìjọba kà sí agbawèrèmẹ́sìn, ilé náà á sì di ti ìjọba. Gbogbo ilé ìsìn àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, tí iye rẹ̀ jẹ́ ọgọ́rùn-ún mẹ́rin ó lé mẹ́fà [406] tí wọ́n forúkọ wọn sílẹ̀ lábẹ́ òfin àtàwọn ìjọ tó lé ní ẹgbẹ̀rún méjì ààbọ̀ [2,500] ló ṣeé ṣe kí wọ́n tì pa torí wọ́n ń bá Ẹ̀ka Ọ́fíìsì náà ṣiṣẹ́ pọ̀. Èyí lè mú kí ìjọba gbẹ́sẹ̀ lé àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba (ilé ìjọsìn) àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà jákèjádò Rọ́ṣíà. Torí náà, tí wọ́n bá ti Ẹ̀ka Ọ́fíìsì náà pa, ohun tó máa yọrí sí ni pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ò ní lẹ́tọ̀ọ́ láti ṣe ẹ̀sìn wọn mọ́.

Ohun tí kò ṣẹlẹ̀ táwọn kan hùmọ̀ ni ìjọba ilẹ̀ Rọ́ṣíà fi ń gbéjà ko àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, wọ́n sì ń mọ̀ọ́mọ̀ ṣi òfin orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà lò, èyí tó dá lórí Bí Wọ́n Ṣe Lè Gbéjà Ko Àwọn Agbawèrèmẹ́sìn, láti fìyà jẹ wọ́n. Lọ́dún 2015, Ìgbìmọ̀ Tó Ń Rí sí Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn lábẹ́ ìdarí Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-èdè sọ pé inú àwọn ò dùn sí “ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìròyìn tó ń wọlé, tó ń fi hàn pé ìjọba túbọ̀ ń lo òfin [nípa Àwọn Agbawèrèmẹ́sìn] láti ṣèdíwọ́ fún òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ . . . àti òmìnira ẹ̀sìn, pàápàá jù lọ fáwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà.” *

Kárí ayé làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà wà, wọ́n sì ti forúkọ ẹ̀sìn wọn sílẹ̀ lábẹ́ òfin. Wọ́n lómìnira láti ṣe ẹ̀sìn wọn láwọn orílẹ̀-èdè tó ti dòmìnira káàkiri ayé àti ní gbogbo orílẹ̀-èdè tó wà lábẹ́ Àwùjọ Àwọn Orílẹ̀-Èdè Ilẹ̀ Yúróòpù. Àmọ́ ọ̀rọ̀ ò rí bẹ́ẹ̀ ní Rọ́ṣíà. Láàárín ọdún 1990 sí 1999 ni wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ sí í gbé ìgbésẹ̀ lóríṣiríṣi kí wọ́n lè ṣèdíwọ́ fún ẹ̀sìn táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣe ní ìrọwọ́rọsẹ̀, wọn ò sì dáwọ́ dúró látìgbà náà. Ọ̀rọ̀ ọ̀hún tún wá burú sí i lẹ́yìn tí ìjọba ilẹ̀ Rọ́ṣíà ṣòfin láti gbéjà ko àwọn agbawèrèmẹ́sìn, wọ́n sì ti ń ṣi òfin yẹn lò láti fìyà jẹ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà.

Òfin Ò Ṣàlàyé Kedere Nípa Àwọn Tó Ń Jẹ́ Agbawèrèmẹ́sìn, Àwọn Aláṣẹ Wá Ń Ṣì í Lò

Lọ́dún 2002, ìjọba ilẹ̀ Rọ́ṣíà ṣe òfin tó dá lórí Bí Wọ́n Ṣe Lè Gbéjà Ko Àwọn Agbawèrèmẹ́sìn torí ọ̀rọ̀ àwọn apániláyà. Látìgbà tí wọ́n ti ṣe òfin náà ni àwọn èèyàn ti ń rò ó pé ó ṣeé ṣe káwọn aláṣẹ ilẹ̀ Rọ́ṣíà ṣi òfin náà lò láti fìyà jẹ wọ́n, torí òfin náà ò ṣàlàyé délẹ̀délẹ̀ nípa àwọn tí wọ́n ń pè ní agbawèrèmẹ́sìn. Lọ́dún 2003, Ìgbìmọ̀ Tó Ń Rí sí Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn lábẹ́ ìdarí Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-èdè rọ ìjọba ilẹ̀ Rọ́ṣíà láti ṣàtúnṣe sí òfin náà, kí wọ́n sì ṣàlàyé délẹ̀délẹ̀ nípa ohun tí wọ́n ń pè ní agbawèrèmẹ́sìn, “kó má bàa sáyè fún ẹnikẹ́ni láti ṣì í lò.” *

Wọ́n ṣàtúnṣe sí òfin náà, àmọ́ dípò kí wọ́n ṣàlàyé rẹ̀ dáadáa, ṣe ni àtúnṣe náà jẹ́ kí ìtumọ̀ rẹ̀ gbòòrò. Lọ́dún 2012, Ilé Ìgbìmọ̀ Aṣòfin ti Ìgbìmọ̀ Ilẹ̀ Yúróòpù kíyè sí i pé: “Òfin ti tẹ́lẹ̀ sọ pé agbawèrèmẹ́sìn làwọn tó ń ‘ṣe ohun tó ń da àwùjọ rú, tó ń rúná sí kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà, tó ń da orílẹ̀-èdè rú tàbí tó ń dá wàhálà sílẹ̀ láàárín àwọn ẹlẹ́sìn, ohun tí wọ́n ń ṣe sì máa ń mú ìwà ipá dá ní tàbí kí wọ́n sún àwọn èèyàn hùwà ipá.’ Nígbà tí wọ́n tún òfin náà ṣe lọ́dún 2006, wọ́n yọ gbólóhùn náà, ‘ohun tí wọ́n ń ṣe sì máa ń mú ìwà ipá dá ní tàbí kí wọ́n sún àwọn èèyàn hùwà ipá.’ . . . Èyí ti wá mú kí ọ̀rọ̀ náà ‘agbawèrèmẹ́sìn’ nítumọ̀ tó pọ̀, àwọn agbófinró sì lè ṣì í lò.”

Ohun táwọn èèyàn rò pé àwọn aláṣẹ máa ṣi òfin náà lò wá dòótọ́. Lọ́dún 2007, Agbẹjọ́rò Àgbà lo òfin yìí láti fẹ̀sùn kan àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, kí wọ́n sì tọ pinpin ọ̀rọ̀ wọn. Igbákejì Agbẹjọ́rò Àgbà, Ọ̀gbẹ́ni V. Ya. Grin, tóun náà fọwọ́ sí lẹ́tà tí ìjọba kọ lẹ́nu àìpẹ́ yìí sí Ẹ̀ka Ọ́fíìsì wa, kọ lẹ́tà láti pàṣẹ fáwọn agbẹjọ́rò pé kí wọ́n bẹ̀rẹ̀ ìwádìí nípa àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Lẹ́tà yìí ló kọ́kọ́ fi hàn pé káàkiri orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà ni wọ́n ti fẹ́ fòfin de àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, àwọn aláṣẹ sì ń tì wọ́n lẹ́yìn.

Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn Ẹlẹ́rìí kì í hùwà ọ̀daràn, jákèjádò orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà làwọn agbẹjọ́rò ti ń fẹ̀sùn kàn wọ́n, ẹjọ́ tó lé ní ọgọ́rùn-ún márùn-ún [500] ló ti wà lọ́rùn wọn látọdún 2007. Ilé Ìgbìmọ̀ Aṣòfin ti Ìgbìmọ̀ Ilẹ̀ Yúróòpù tún kíyè sí i pé: “Ìjọba ilẹ̀ Rọ́ṣíà ti ṣi Òfin tí ìjọba àpapọ̀ orílẹ̀-èdè náà ṣe lò, èyí ‘tó dá lórí bí wọ́n ṣe lè gbéjà ko àwọn agbawèrèmẹ́sìn,’ (ìyẹn Òfin Agbawèrèmẹ́sìn), tí wọ́n ṣe lọ́dún 2002. Wọ́n ti lò ó láti fòfin de àwọn ẹ̀sìn kan, pàápàá àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lórílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà, tí iye wọn jẹ́ 162,000. Látọdún 2006 tí wọ́n ti tún òfin náà ṣe ni wọ́n ti wá ń ṣì í lò ju tìgbàkigbà rí lọ.” *

“Ìjọba ilẹ̀ Rọ́ṣíà ti ṣi Òfin tí ìjọba àpapọ̀ orílẹ̀-èdè náà ṣe lò, èyí ‘tó dá lórí bí wọ́n ṣe lè gbéjà ko àwọn agbawèrèmẹ́sìn’ . . . Wọ́n ti lò ó láti fòfin de àwọn ẹ̀sìn kan, pàápàá àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lórílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà.”—Ilé Ìgbìmọ̀ Aṣòfin ti Ìgbìmọ̀ Ilẹ̀ Yúróòpù

Wọ́n Fòfin De Àwọn Ìtẹ̀jáde Ẹ̀sìn, Wọ́n Tún Fìyẹn Ká Àwọn Ẹlẹ́rìí Wọn Lọ́wọ́ Kò

Kó tó di pé àwọn agbófinró rí sí Ẹ̀ka Ọ́fíìsì náà, tó wà ní tòsí ìlú St. Petersburg, wọ́n ti dájú sọ àwọn ìtẹ̀jáde àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Àwọn agbẹjọ́rò nílùú Taganrog àti Gorno-Altaysk pe ẹjọ́, wọ́n ní kí ìjọba fòfin de ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìtẹ̀jáde àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà pé wọ́n jẹ́ “agbawèrèmẹ́sìn,” kí wọ́n sì kà wọ́n mọ́ àwọn ohun tí ìjọba kà sí Ẹrù Àwọn Agbawèrèmẹ́sìn.

Lọ́dún 2009 àti 2010, àwọn ilé ẹjọ́ nílùú Taganrog àti Gorno-Altaysk dá àwọn agbẹjọ́rò náà láre, wọ́n tẹ̀ lé ohun táwọn kan tó pe ara wọn ní ọ̀jọ̀gbọ́n sọ. Látìgbà yẹn, ìdájọ́ méjèèjì yìí, tó mú kí wọ́n fòfin de ìtẹ̀jáde méjìléláàádọ́ta [52] tó jẹ́ ti ẹ̀sìn, ni wọ́n ń lò láti fi oríṣiríṣi ẹ̀sùn kan àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ohun tí àwọn ilé ẹjọ́ ìlú Taganrog àti Gorno-Altaysk ṣe yìí náà làwọn aláṣẹ tó wà láwọn àgbègbè míì lórílẹ̀-èdè náà ń tẹ̀ lé. Títí dòní, ìtẹ̀jáde mẹ́tàdínláàádọ́rùn-ún [87] tó jẹ́ tàwọn Ẹlẹ́rìí ni àwọn ilé ẹjọ́ ti kéde pé wọ́n jẹ́ Ẹrù Àwọn Agbawèrèmẹ́sìn.

Àwọn Ẹlẹ́rìí ò gbà pẹ̀lú ẹjọ́ táwọn ilé ẹjọ́ ìlú Taganrog àti Gorno-Altaysk dá àtèyí táwọn ilé ẹjọ́ míì dá lórílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà pé ẹrù agbawèrèmẹ́sìn làwọn ìtẹ̀jáde wa. Wọ́n ti kọ̀wé pe ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn méjìdínlọ́gbọ̀n [28] sí Ilé Ẹjọ́ Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn ti Ilẹ̀ Yúróòpù kí wọ́n lè bá wọn wá nǹkan ṣe sí ẹ̀sùn agbawèrèmẹ́sìn tí àwọn ilé ẹjọ́ fi ń kàn wọ́n àtàwọn ìyà míì tí wọ́n fi ń jẹ wọ́n. Ó yẹ kí Ilé Ẹjọ́ náà dá méjìlélógún [22] lára ẹjọ́ náà láìpẹ́. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ìjọba ilẹ̀ Rọ́ṣíà ń gbèjà ara wọn lọ́dọ̀ Ilé Ẹjọ́ Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn náà, wọ́n gbà pé ọ̀pọ̀ ìtẹ̀jáde àwọn Ẹlẹ́rìí tí wọ́n kà sí Ẹrù Àwọn Agbawèrèmẹ́sìn kò “mú ìwà ipá dá ní tàbí sún àwọn èèyàn hùwà ipá.”

Wọn Ò Jẹ́ Kí Wọ́n Lómìnira Ọ̀rọ̀ Sísọ

Àtìgbà táwọn aláṣẹ ilẹ̀ Rọ́ṣíà ti mú káwọn ilé ẹjọ́ kéde pé ẹrù “àwọn agbawèrèmẹ́sìn” ni ìtẹ̀jáde àwọn Ẹlẹ́rìí ni wọ́n ti rí ọ̀rọ̀ sọ, wọ́n sì ń gùn lé ìyẹn láti gbéjà ko àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, kí wọ́n sì túbọ̀ ká wọn lọ́wọ́ kò, kí wọ́n má bàa lómìnira ọ̀rọ̀ sísọ.

  • Lọ́dún 2010, àwọn aláṣẹ gbẹ́sẹ̀ lé ìwé àṣẹ táwọn Ẹlẹ́rìí fi ń kó ìwé Ilé Ìṣọ́ àti Jí! wọ orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà, kí wọ́n sì máa pín in. Àtọdún 1879 la ti ń tẹ ìwé Ilé Ìṣọ́. Nínú gbogbo ìwé ìròyìn táwọn èèyàn ń tẹ̀ jáde, ìwé méjèèjì yìí làwọn èèyàn mọ̀ jù kárí ayé.

  • Láti March 2015 ni àwọn aláṣẹ ò ti jẹ́ kí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kó ìtẹ̀jáde ẹ̀sìn èyíkéyìí wọ orílẹ̀-èdè náà.

  • Láti July 2015 ni ìjọba ilẹ̀ Rọ́ṣíà ti fòfin de ìkànnì àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ìyẹn jw.org, ó sì ti mú kó nira fún gbogbo àwọn tó ń gbé ní Rọ́ṣíà láti rí ìtẹ̀jáde wà jáde lórí ìkànnì. Ṣe ni ìjọba máa gbé ẹnikẹ́ni tó bá ń polongo ìkànnì náà.

  • Níbẹ̀rẹ̀ ọdún 2016, agbẹjọ́rò kan nílùú Vyborg gbé ẹ̀sùn kan dìde pé kí ìjọba kéde pé ìwé “àwọn agbawèrèmẹ́sìn” ni Bíbélì Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń tẹ̀ jáde.

Yàtọ̀ sí pé àwọn aláṣẹ ò jẹ́ kí wọ́n lómìnira ọ̀rọ̀ sísọ, wọ́n ti ń fi àwọn ìtẹ̀jáde tí wọ́n kà sí Ẹrù Àwọn Agbawèrèmẹ́sìn ta ko àwọn Ẹlẹ́rìí, wọ́n fẹ́ lò ó láti fòfin de àwọn ibi ìjọsìn wọn tí wọ́n ti forúkọ wọn sílẹ̀ lábẹ́ òfin, wọ́n sì ń lò ó láti fẹ̀sùn kan àwọn Ẹlẹ́rìí tó ń ṣe ìsìn wọn.

Wọ́n Ń Túlé Àwọn Ẹlẹ́rìí, Wọ́n sì Ń Fẹ̀sùn Kàn Wọ́n

Tí ìjọba bá ti ka ìtẹ̀jáde kan mọ́ Ẹrù Àwọn Agbawèrèmẹ́sìn, wọ́n máa fòfin dè é kí ẹnikẹ́ni má bàa pín in kiri, tẹ̀ ẹ́ jáde tàbí kó o pamọ́ torí àti máa pín in. Àwọn aláṣẹ láwọn ìlú tó wà nílẹ̀ Rọ́ṣíà ti gùn lé ìyẹn láti gbàṣẹ nílé ẹjọ́ kí wọ́n lè máa túlé ọgọ́rọ̀ọ̀rún àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà àtàwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba wọn bóyá wọ́n máa rí ìtẹ̀jáde èyíkéyìí tó dá lórí ẹ̀sìn tí ìjọba fòfin dè.

Lọ́pọ̀ ìgbà, ọwọ́ tó le làwọn aláṣẹ máa ń gbé wá tí wọ́n bá ń túlé, ohun tí wọ́n sì máa ń gbẹ́sẹ̀ lé máa ń kọjá ohun tí òfin gbà láyè. Ṣe ni wọ́n máa ń gba ohun ìní wọn àti gbogbo ìtẹ̀jáde ẹ̀sìn tí wọ́n bá rí níbẹ̀, yálà ó wà lára àwọn tí òfin kà sí Ẹrù Àwọn Agbawèrèmẹ́sìn tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́.

  • Ní August 2010, nílùú Yoshkar-Ola, nǹkan bíi ọgbọ̀n [30] ọlọ́pàá láti Iléeṣẹ́ Ààbò Ìjọba àti àwọn ológun ya wọ ibì kan táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ń ṣe ìsìn. Àwọn ọlọ́pàá náà mú àwọn Ẹlẹ́rìí kan, wọ́n fún wọn lọ́rùn, wọ́n sì lọ́ ọwọ́ wọn sẹ́yìn. Wọ́n tú ibi tí wọ́n ti ń ṣèsìn, wọ́n sì gba àwọn ohun ìní wọn, àwọn ìwé kan àtàwọn ìtẹ̀jáde.

  • Ní July 2012, lórílẹ̀-èdè Karelia, àwọn ọlọ́pàá láti Iléeṣẹ́ Ààbò Ìjọba tó gbé ìbọn arọ̀jò ọta dá ní, tí wọ́n sì fi nǹkan bojú mú Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan níta gbangba, wọ́n lù ú, wọ́n fipá mú un dojú bolẹ̀ sórí mọ́tò rẹ̀, wọ́n sì lọ́ ọwọ́ rẹ̀ sẹ́yìn. Àwọn ọlọ́pàá náà ya wọ ilé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan, wọ́n gba àwọn ohun ìní wọn àtàwọn ìtẹ̀jáde ẹ̀sìn wọn. Wọn ò tiẹ̀ fẹ́ mọ̀ bóyá àwọn ìtẹ̀jáde náà wà lára àwọn tí òfin kà sí Ẹrù Àwọn Agbawèrèmẹ́sìn tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́.

  • Ní March 2016, lórílẹ̀-èdè Tatarstan, àwọn ọlọ́pàá ya wọ Gbọ̀ngàn Ìjọba kan àtàwọn ilé kan táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń gbé, wọ́n sì kó wọn lẹ́rù. Wọ́n gba àwọn kọ̀ǹpútà wọn, àwọn tablet wọn àtàwọn ìtẹ̀jáde tó jẹ́ ti ẹ̀sìn wọn.

Fídíò gbé ẹni tó yọ́ lọ fi ìwé kan sínú Gbọ̀ngàn Ìjọba kí wọ́n lè fi ṣe ẹ̀rí láti mú àwọn Ẹlẹ́rìí

Àwọn agbófinró ti dọ́gbọ́n fídíò ohun táwọn Ẹlẹ́rìí ń ṣe nínú ilé wọn àti nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba wọn. Wọ́n ń ṣọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí lọ́wọ́-lẹ́sẹ̀, débi pé wọ́n máa ń fi ìmọ̀ ẹ̀rọ mọ ohun tí àwọn Ẹlẹ́rìí ń sọ lórí fóònù, e-mail tí wọ́n ń fi ránṣẹ́, àwọn agbófinró sì tún ń lo àwọn ọ̀nà èrú míì láti wádìí nípa àwọn Ẹlẹ́rìí. Lórúkọ pé àwọn ọlọ́pàá kan fẹ́ fẹ̀sùn agbawèrèmẹ́sìn kan àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, wọ́n ti bá a débi pé wọ́n mú lára àwọn ìwé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí ìjọba kà sí ẹrù òfin, wọ́n sì lọ dọ́gbọ́n fi sínú àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba wọn lẹ́yìn wọn kí wọ́n lè fìyẹn mú wọn. Àwọn nǹkan yìí tí wá mú kí wọ́n fi ẹ̀sùn ọ̀daràn kan ọ̀pọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí.

Àwọn Aláṣẹ Ń Fòfin De Àwọn Ẹ̀sìn Tó Ti Forúkọ Sílẹ̀ Lábẹ́ Òfin, Wọ́n Wá Ń Fẹ̀sùn Ọ̀daràn Kàn Wọ́n

Yàtọ̀ sí pé àwọn agbófinró ń fẹ̀sùn kan àwọn Ẹlẹ́rìí ní kọ̀ọ̀kan, wọ́n ti fi àwọn ìwé tí ìjọba kà sí ẹrù òfin tí wọ́n lọ ń fi sínú àwọn Gbọ̀ngàn wọn lẹ́yìn wọn ṣe “ẹ̀rí,” kí ìjọba lè fòfin de ẹ̀sìn àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà. * Tí ìjọba bá ti lè kéde pé “agbawèrèmẹ́sìn” ni ẹ̀sìn kan, ṣe ni wọ́n máa gbẹ́sẹ̀ lé àwọn ohun tí ẹ̀sìn náà ní. Irú ẹ̀ ti ṣẹlẹ̀ sáwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nílùú Taganrog àti Samara. Wọ́n ti gbẹ́sẹ̀ lé ilé ìjọsìn àwọn Ẹlẹ́rìí tó wà ládùúgbò yẹn. Ohun kan náà sì làwọn aláṣẹ tó wà láwọn ìlú míì náà rawọ́ lé.

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà wà nílé ẹjọ́ nílùú Taganrog lórílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà

Lẹ́yìn táwọn aláṣẹ fòfin de ẹ̀sìn àwọn Ẹlẹ́rìí nílùú Taganrog, wọ́n tún sọ pé ṣe ni àwọn Ẹlẹ́rìí tó ń pàdé láti gbàdúrà, kí wọ́n sì jọ́sìn “ń ṣe ohun tí ò bófin mu lẹ́yìn tí wọ́n ti fòfin de ẹ̀sìn wọn.” Ọgbọ́nkọ́gbọ́n táwọn aláṣẹ dá nílùú Taganrog yìí ti mú kí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà mẹ́rìndínlógún [16] jẹ̀bi ẹ̀sùn ọ̀daràn torí pé wọ́n ń pàdé ní ìrọwọ́rọsẹ̀ láti jọ́sìn. Bẹ́ẹ̀, ohun táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣe kárí ayé nìyí. Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó bá ti wá ń jọ́sìn nílùú Taganrog báyìí ti di ọ̀daràn, èyí sì ni ìgbà àkọ́kọ́ tírú ẹ̀ máa ṣẹlẹ̀ látìgbà tí ìjọba Soviet Union ti kógbá wọlé.

Tí Wọ́n Bá Ti Ẹ̀ka Ọ́fíìsì náà Pa, Ohun Tó Máa Yọrí sí Ò Ní Dáa

Ẹ̀ka Ọ́fíìsì Tó Ń Bójú Tó Iṣẹ́ Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Rọ́ṣíà

Táwọn aláṣẹ bá fi lè ti Ẹ̀ka Ọ́fíìsì àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà pa, wọ́n máa dáwọ́ iṣẹ́ dúró níbẹ̀, wọ́n á sì fòfin de gbogbo ohun tó ń ṣe jákèjádò Rọ́ṣíà. Wọ́n sì tún lè fẹ̀sùn ọ̀daràn kan àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kárí ayé bíi tàwọn Ẹlẹ́rìí tó wà nílùú Taganrog torí pé wọ́n ń pàdé pọ̀ láti jọ́sìn, wọ́n sì ń sọ ohun tí wọ́n gbà gbọ́ fáwọn míì. Ó ṣeé ṣe kó wá di pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà lórílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà á lómìnira láti gba ohun tó wù wọ́n gbọ́, àmọ́ àwọn àtàwọn míì ò ní lómìnira láti ṣe ẹ̀sìn wọn. *

Ọ̀gbẹ́ni Philip Brumley tó jẹ́ Agbẹjọ́rò Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà sọ pé: “Ìrẹ́jẹ gbáà ni bí wọ́n ṣe ka àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà mọ́ àwọn agbawèrèmẹ́sìn yìí, kò sì bọ́gbọ́n mu rárá bí wọ́n ṣe ka àwọn ìtẹ̀jáde wọn sí ẹrù àwọn apániláyà. Àwọn aláṣẹ orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà ti ṣi òfin lò, bẹ́ẹ̀ ohun tí wọ́n ṣe yìí ta ko òfin tí ìjọba àpapọ̀ fi lélẹ̀ kárí ayé, ìlànà tí Ìgbìmọ̀ Ilẹ̀ Yúróòpù fi lélẹ̀, ó tún ta ko ohun tó wà nínú ìwé UN Declaration of Human Rights àti òfin tí ìjọba orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà fúnra wọn ṣe. Wọ́n ń fi òfin ṣèdíwọ́ fún ìjọsìn tí àwọn Ẹlẹ́rìí ń ṣe ní ìrọwọ́rọsẹ̀, wọ́n sì fẹ́ fòfin de ibi tá a ti ń darí iṣẹ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lórílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà.”

Ọ̀gbẹ́ni Vasiliy Kalin tó jẹ́ aṣojú Ẹ̀ka Ọ́fíìsì náà sọ pé: “Àti ọ̀rúndún kọkàndínlógún làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ń jọ́sìn lórílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà, wọ́n sì fara da inúnibíni tó le gan-an nígbà ìjọba Soviet Union. Nígbà tó yá, ìjọba gbà pé wọ́n fìyà jẹ wá láìnídìí, wọ́n sì wá nǹkan ṣe sí i. A fẹ́ máa ṣe ìjọsìn wa lọ ní ìrọwọ́rọsẹ̀ ní Rọ́ṣíà. Ṣe làwọn tó ń bà wá lórúkọ jẹ́, tí wọ́n sì ń fẹ̀sùn ‘agbawèrèmẹ́sìn’ kàn wá ń fìyẹn bojú, ohun tó ń ṣe wọ́n gan-an ni pé wọn ò gba ti ẹ̀sìn wa àti ohun tá a gbà gbọ́. A kì í ṣe agbawèrèmẹ́sìn.”

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà retí pé kí ìjọba orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà jẹ́ kí wọ́n ní òmìnira ẹ̀sìn bíi tàwọn orílẹ̀-èdè míì. Wọ́n tún fẹ́ kí Agbẹjọ́rò Àgbà dáwọ́ àtakò tí wọ́n ń ṣe sí Ẹ̀ka Ọ́fíìsì wọn dúró, kí ìjọba Rọ́ṣíà má sì fi ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn du àwọn ẹlẹ́sìn kéékèèké. Ìbéèrè kan ni pé, Ṣé ìjọba orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà máa ṣe bẹ́ẹ̀? Àbí ohun tí ìjọba Soviet Union ṣe nígbà yẹn, tí wọ́n ń fìyà jẹ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, làwọn náà fẹ́ pa dà sí?

^ ìpínrọ̀ 4 Ìgbìmọ̀ Tó Ń Rí sí Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn lábẹ́ ìdarí Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-èdè jábọ̀ nípa ìjọba Orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà nínú ìròyìn ẹlẹ́ẹ̀keje irú ẹ̀, CCPR/C/RUS/CO/7, 28 April 2015, ìpínrọ̀ 20.

^ ìpínrọ̀ 7 “Àgbéyẹ̀wò Ìròyìn látọ̀dọ̀ Àwọn Orílẹ̀-èdè Tó Fọwọ́ sí Àpilẹ̀kọ 40 nínú Àdéhùn náà, Ibi tí Ìgbìmọ̀ Tó Ń Rí sí Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn parí èrò sí nípa ìjọba Orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà,” látọ̀dọ̀ Ìgbìmọ̀ Tó Ń Rí sí Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn lábẹ́ ìdarí Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-èdè, CCPR/CO/79/RUS, December 1, 2003, ìpínrọ̀ 20.

^ ìpínrọ̀ 10 “Ìjọba Orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà gbọ́dọ̀ ṣe ohun tó pọn dandan kí wọ́n ṣe, wọn ò sì gbọ́dọ̀ yẹ àdéhùn,” Doc. 13018, látọ̀dọ̀ Ilé Ìgbìmọ̀ Aṣòfin ti Ìgbìmọ̀ Ilẹ̀ Yúróòpù, ní 14 September 2012, ìpínrọ̀ 497.

^ ìpínrọ̀ 30 Lórílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà, àwọn ẹlẹ́sìn ìlú kọ̀ọ̀kan tí òfin bá fọwọ́ sí lè forúkọ ẹ̀sìn wọn sílẹ̀ lábẹ́ òfin ìlú wọn. Òfin yìí kọ́ ló máa jẹ́ kí wọ́n lómìnira láti ṣe ẹ̀sìn wọn jákèjádò Rọ́ṣíà, wọn ò lómìnira kọjá ìlú wọn tàbí àgbègbè wọn. Ọ̀kan lára àǹfààní tó kàn wà níbẹ̀ ni pé àwọn ẹlẹ́sìn náà máa lè kọ́ ibi ìjọsìn wọn tàbí kí wọ́n ya ibì kan tí wọ́n á máa lò láti jọ́sìn.

^ ìpínrọ̀ 33 Èyí ta ko Àpilẹ̀kọ 28 nínú Òfin tí Ìjọba Àpapọ̀ Orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà ṣe, tó sọ pé: “Gbogbo èèyàn ló ní òmìnira ẹ̀rí ọkàn, òmìnira ẹ̀sìn, títí kan òmìnira fún ẹnì kan láti sọ ní gbangba pé òun ní ẹ̀sìn tòun tàbí kí òun àtàwọn kan jọ sọ bẹ́ẹ̀, ẹnikẹ́ni ló sì lómìnira láti sọ pé òun ò ṣe ẹ̀sìn kankan, bẹ́ẹ̀ ni gbogbo èèyàn lómìnira láti yan èrò tó wù wọ́n tó dá lórí ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn tàbí nǹkan míì, kí wọ́n máa sọ ọ́ fáwọn míì, wọ́n sì lómìnira láti máa ṣe ohun tó wà ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí wọ́n yàn, tí wọ́n sì ń sọ.”

^ ìpínrọ̀ 40 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania kì í fi ẹ̀sìn ṣòwò, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń lò ó láti ti iṣẹ́ tá à ń ṣe kárí ayé lẹ́yìn. Àwọn ni wọ́n ń ṣe àwọn ìtẹ̀jáde àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà lábẹ́ òfin.