Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìwé Àwọn Onídàájọ́

Orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Yìí

  • 1

    • Àwọn tí Júdà àti Síméónì ṣẹ́gun (1-20)

    • Àwọn ará Jébúsì ò kúrò ní Jerúsálẹ́mù (21)

    • Jósẹ́fù gba Bẹ́tẹ́lì (22-26)

    • Wọn ò lé àwọn ọmọ Kénáánì kúrò tán (27-36)

  • 2

    • Áńgẹ́lì Jèhófà kìlọ̀ fún wọn (1-5)

    • Jóṣúà kú (6-10)

    • Jèhófà yan àwọn onídàájọ́ tó máa gba Ísírẹ́lì sílẹ̀ (11-23)

  • 3

    • Jèhófà dán Ísírẹ́lì wò (1-6)

    • Ótíníẹ́lì, onídàájọ́ àkọ́kọ́ (7-11)

    • Éhúdù onídàájọ́ pa Ẹ́gílónì, ọba tó sanra (12-30)

    • Ṣámúgárì onídàájọ́ (31)

  • 4

    • Jábínì ọba Kénáánì fìyà jẹ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì (1-3)

    • Dèbórà wòlíì obìnrin àti Bárákì onídàájọ́ (4-16)

    • Jáẹ́lì pa Sísérà olórí ogun (17-24)

  • 5

    • Dèbórà àti Bárákì kọrin ìṣẹ́gun (1-31)

      • Àwọn ìràwọ̀ bá Sísérà jà (20)

      • Ọ̀gbàrá Kíṣónì kún àkúnya (21)

      • Àwọn tó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà dà bí oòrùn (31)

  • 6

    • Mídíánì fìyà jẹ Ísírẹ́lì (1-10)

    • Áńgẹ́lì kan fi dá Gídíónì onídàájọ́ lójú pé Jèhófà máa ràn án lọ́wọ́ (11-24)

    • Gídíónì wó pẹpẹ Báálì lulẹ̀ (25-32)

    • Ẹ̀mí Ọlọ́run bà lé Gídíónì (33-35)

    • Ó fi ìṣùpọ̀ irun àgùntàn wádìí ọ̀rọ̀ (36-40)

  • 7

    • Gídíónì àti 300 ọkùnrin rẹ̀ (1-8)

    • Àwọn ọmọ ogun Gídíónì ṣẹ́gun Mídíánì (9-25)

      • “Idà Jèhófà àti ti Gídíónì!” (20)

      • Ibùdó Mídíánì dà rú (21, 22)

  • 8

    • Àwọn èèyàn Éfúrémù bínú sí Gídíónì (1-3)

    • Wọ́n lé àwọn ọba Mídíánì mú, wọ́n sì pa wọ́n (4-21)

    • Gídíónì ò gbà kí wọ́n fi òun jọba (22-27)

    • Àkópọ̀ ìtàn ìgbésí ayé Gídíónì (28-35)

  • 9

    • Ábímélékì jọba ní Ṣékémù (1-6)

    • Jótámù ṣe àkàwé (7-21)

    • Ìjọba Ábímélékì ni àwọn èèyàn lára (22-33)

    • Ábímélékì gbógun ja Ṣékémù (34-49)

    • Obìnrin kan ṣe Ábímélékì léṣe, ó sì kú (50-57)

  • 10

    • Tólà àti Jáírì onídàájọ́ (1-5)

    • Ísírẹ́lì ṣọ̀tẹ̀, ó sì ronú pìwà dà (6-16)

    • Àwọn ọmọ Ámónì halẹ̀ mọ́ Ísírẹ́lì (17, 18)

  • 11

    • Wọ́n lé Jẹ́fútà onídàájọ́ jáde, àmọ́ wọ́n sọ ọ́ di olórí nígbà tó yá (1-11)

    • Jẹ́fútà bá àwọn ọmọ Ámónì sọ̀rọ̀ (12-28)

    • Ẹ̀jẹ́ tí Jẹ́fútà jẹ́ àti ọmọbìnrin rẹ̀ (29-40)

      • Ọmọbìnrin náà ò lọ́kọ rárá (38-40)

  • 12

    • Wọ́n bá àwọn ọmọ Éfúrémù jà (1-7)

      • Wọ́n ní kí wọ́n pe Ṣíbólẹ́tì (6)

    • Íbísánì, Élónì àti Ábídónì di onídàájọ́ (8-15)

  • 13

    • Áńgẹ́lì kan wá sọ́dọ̀ Mánóà àti ìyàwó rẹ̀ (1-23)

    • Wọ́n bí Sámúsìn (24, 25)

  • 14

    • Sámúsìn onídàájọ́ fẹ́ fi ọmọ Filísínì ṣe aya (1-4)

    • Ẹ̀mí Jèhófà mú kí Sámúsìn pa kìnnìún (5-9)

    • Sámúsìn pa àlọ́ níbi ìgbéyàwó (10-19)

    • Wọ́n fún ọkùnrin míì ní ìyàwó Sámúsìn (20)

  • 15

    • Sámúsìn gbẹ̀san lára àwọn Filísínì (1-20)

  • 16

    • Sámúsìn lọ sí Gásà (1-3)

    • Sámúsìn àti Dẹ̀lílà (4-22)

    • Sámúsìn gbẹ̀san, ó sì kú (23-31)

  • 17

    • Àwọn ère Míkà àti àlùfáà rẹ̀ (1-13)

  • 18

    • Àwọn ọmọ Dánì ń wá ilẹ̀ (1-31)

      • Wọ́n kó àwọn ère Míkà, wọ́n sì mú àlùfáà rẹ̀ (14-20)

      • Wọ́n gba Láíṣì, wọ́n sì yí orúkọ rẹ̀ pa dà sí Dánì (27-29)

      • Wọ́n jọ́sìn ère ní Dánì (30, 31)

  • 19

    • Ìṣekúṣe tí àwọn ọmọ Bẹ́ńjámínì ṣe ní Gíbíà (1-30)

  • 20

    • Wọ́n gbógun ja àwọn ọmọ Bẹ́ńjámínì (1-48)

  • 21

    • Wọ́n gba ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì sílẹ̀ (1-25)