Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìwé Òwe

Orí

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Yìí

  • 1

    • Ohun tí òwe wà fún (1-7)

    • Ewu tó wà nínú ẹgbẹ́ búburú (8-19)

    • Ọgbọ́n tòótọ́ ń ké jáde ní gbangba (20-33)

  • 2

    • Ìwúlò ọgbọ́n (1-22)

      • Máa wá ọgbọ́n bí ìṣúra tó fara sin (4)

      • Làákàyè ń dáàbò boni (11)

      • Ìṣekúṣe máa ń fa àjálù (16-19)

  • 3

    • Jẹ́ ọlọ́gbọ́n, kí o sì gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà (1-12)

      • Fi àwọn ohun ìní rẹ tó níye lórí bọlá fún Jèhófà (9)

    • Ọgbọ́n ń fúnni láyọ̀ (13-18)

    • Ọgbọ́n ń dáàbò boni (19-26)

    • Ìwà tó yẹ ká máa hù sáwọn èèyàn (27-35)

      • Máa ṣe rere fún àwọn èèyàn nígbà tí o bá lè ṣe é (27)

  • 4

    • Ẹ̀kọ́ ọlọgbọ́n tí bàbá kan kọ́ni (1-27)

      • Ju ohun gbogbo, ní ọgbọ́n (7)

      • Yẹra fún ọ̀nà burúkú (14, 15)

      • Ipa ọ̀nà àwọn olódodo ń mọ́lẹ̀ sí i (18)

      • “Dáàbò bo ọkàn rẹ” (23)

  • 5

    • Ìkìlọ̀ nítorí obìnrin oníṣekúṣe (1-14)

    • Máa yọ̀ pẹ̀lú aya rẹ (15-23)

  • 6

    • Ṣọ́ra fún ṣíṣe onídùúró ẹni tó fẹ́ yá owó (1-5)

    • “Tọ èèrà lọ, ìwọ ọ̀lẹ” (6-11)

    • Ìkà àti aláìwúlò ẹ̀dá (12-15)

    • Ohun méje tí Jèhófà kórìíra (16-19)

    • Ṣọ́ra fún obìnrin burúkú (20-35)

  • 7

    • Rọ̀ mọ́ àwọn àṣẹ Ọlọ́run, kí o sì wà láàyè (1-5)

    • Ó fa ojú ọ̀dọ́kùnrin aláìmọ̀kan mọ́ra (6-27)

      • “Bí akọ màlúù tí wọ́n ń mú lọ síbi tí wọ́n ti fẹ́ pa á” (22)

  • 8

    • Ọgbọ́n sọ̀rọ̀ bí èèyàn (1-36)

      • ‘Èmi ni àkọ́bẹ̀rẹ̀ àwọn iṣẹ́ Ọlọ́run’ (22)

      • ‘Gẹ́gẹ́ bí àgbà òṣìṣẹ́ lẹ́gbẹ̀ẹ́ Ọlọ́run’ (30)

      • ‘Mo fẹ́ràn àwọn ọmọ èèyàn’ (31)

  • 9

    • Ọgbọ́n tòótọ́ ń pe àwọn èèyàn (1-12)

      • “Ọgbọ́n yóò jẹ́ kí ọjọ́ ayé rẹ di púpọ̀” (11)

    • Òmùgọ̀ obìnrin ń pe àwọn èèyàn (13-18)

      • “Omi tí a jí gbé máa ń dùn” (17)

  • ÀWỌN ÒWE SÓLÓMỌ́NÌ (10:1–24:34)

    • 10

      • Ọlọ́gbọ́n ọmọ ń mú inú bàbá rẹ̀ dùn (1)

      • Ọwọ́ tó ń ṣiṣẹ́ kára ń sọni di ọlọ́rọ̀ (4)

      • Tí ọ̀rọ̀ bá ti pọ̀, àṣìṣe kò ní ṣàì wáyé (19)

      • Ìbùkún Jèhófà ló ń sọni di ọlọ́rọ̀ (22)

      • Ìbẹ̀rù Jèhófà ń mú kí ẹ̀mí ẹni gùn (27)

    • 11

      • Ọgbọ́n wà lọ́dọ̀ àwọn tó mọ̀wọ̀n ara wọn (2)

      • Apẹ̀yìndà máa ń fa ìparun bá àwọn ẹlòmíì (9)

      • “Nípasẹ̀ ọ̀pọ̀ agbani-nímọ̀ràn, àṣeyọrí á wà” (14)

      • Ẹni tó bá láwọ máa láásìkí (25)

      • Ẹni tó bá gbẹ́kẹ̀ lé ọrọ̀ rẹ̀ máa ṣubú (28)

    • 12

      • Ẹni tó kórìíra ìbáwí kò ní ọgbọ́n (1)

      • “Ọ̀rọ̀ téèyàn sọ láìronú dà bí ìgbà tí idà gúnni” (18)

      • Wíwá àlàáfíà ń mú kí ayọ̀ wà (20)

      • Ètè tó ń parọ́ jẹ́ ohun ìríra lójú Jèhófà (22)

      • Àníyàn ń mú kí ọkàn rẹ̀wẹ̀sì (25)

    • 13

      • Àwọn tó ń wá ìmọ̀ràn máa ń gbọ́n (10)

      • Ìrètí pípẹ́ máa ń mú ọkàn ṣàìsàn (12)

      • Aṣojú tó jẹ́ olóòótọ́ ń mú ìwòsàn wá (17)

      • Ẹni tó ń bá ọlọ́gbọ́n rìn yóò gbọ́n (20)

      • Ọ̀nà kan tí a lè gbà fìfẹ́ hàn ni pé ká báni wí (24)

    • 14

      • Ọkàn èèyàn mọ ìbànújẹ́ rẹ̀ (10)

      • Ọ̀nà tó dà bíi pé ó tọ́ lè yọrí sí ikú (12)

      • Aláìmọ̀kan máa ń gba gbogbo ọ̀rọ̀ gbọ́ (15)

      • Ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń bá ọlọ́rọ̀ ṣọ̀rẹ́ (20)

      • Ìbàlẹ̀ ọkàn ń mú kí ara lókun (30)

    • 15

      • Ìdáhùn pẹ̀lẹ́ máa ń mú kí ìbínú rọlẹ̀ (1)

      • Ojú Jèhófà wà níbi gbogbo (3)

      • Àdúrà àwọn adúróṣinṣin máa ń múnú Ọlọ́run dùn (8)

      • Láìsí ìfinúkonú, èrò á dasán (22)

      • Máa ṣe àṣàrò kí o tó dáhùn (28)

    • 16

      • Jèhófà ń ṣàyẹ̀wò èrò ọkàn (2)

      • Fi gbogbo iṣẹ́ rẹ lé Jèhófà lọ́wọ́ (3)

      • Ọ̀dọ̀ Jèhófà ni òṣùwọ̀n pípé ti wá (11)

      • Ìgbéraga ló ń ṣáájú ìparun (18)

      • Ewú orí jẹ́ adé ẹwà (31)

    • 17

      • Má fi búburú san rere (13)

      • Kí ìjà tó bẹ́, fi ibẹ̀ sílẹ̀ (14)

      • Ọ̀rẹ́ tòótọ́ máa ń nífẹ̀ẹ́ ẹni nígbà gbogbo (17)

      • “Ọkàn tó ń yọ̀ jẹ́ oògùn tó dára fún ara” (22)

      • Ẹni tó ní òye máa ń ṣọ́ ọ̀rọ̀ tó ń sọ (27)

    • 18

      • Ẹni tó bá ń ya ara rẹ̀ sọ́tọ̀, ire ara rẹ̀ ló ń wá, kò sì gbọ́n (1)

      • Orúkọ Jèhófà jẹ́ ilé gogoro tó lágbára (10)

      • Ọrọ̀ kì í ṣe ààbò gidi (11)

      • Ọgbọ́n wà nínú fífi etí sí tọ̀túntòsì (17)

      • Ọ̀rẹ́ kan ń fà mọ́ni ju ọmọ ìyá lọ (24)

    • 19

      • Ìjìnlẹ̀ òye tí èèyàn ní máa ń dẹwọ́ ìbínú rẹ̀ (11)

      • Oníjà aya dà bí òrùlé tó ń jò (13)

      • Ọ̀dọ̀ Jèhófà ni aya olóye ti wá (14)

      • Bá ọmọ wí nígbà tí ìrètí ṣì wà (18)

      • Ọgbọ́n tó wà nínú kéèyàn máa gba ìmọ̀ràn (20)

    • 20

      • Afiniṣẹ̀sín ni wáìnì (1)

      • Ọ̀lẹ kì í túlẹ̀ nígbà òtútù (4)

      • Èrò ọkàn èèyàn dà bí omi jíjìn (5)

      • Ìkìlọ̀ lórí kéèyàn kánjú jẹ́ ẹ̀jẹ́ (25)

      • Ògo àwọn ọ̀dọ́kùnrin ni agbára wọn (29)

    • 21

      • Jèhófà ń darí ọkàn ọba (1)

      • Ṣíṣe ohun tí ó tọ́ sàn ju ẹbọ lọ (3)

      • Iṣẹ́ àṣekára máa ń múni ṣàṣeyọrí (5)

      • Ẹni tí kì í fetí sí ẹni rírẹlẹ̀, a ò ní gbọ́ tiẹ̀ (13)

      • Kò sí ọgbọ́n tó lòdì sí Jèhófà tó lè dúró (30)

    • 22

      • Orúkọ rere sàn ju ọ̀pọ̀ ọrọ̀ (1)

      • Kíkọ́ ọmọ láti kékeré máa ṣe é láǹfààní jálẹ̀ ayé rẹ̀ (6)

      • Ọ̀lẹ ń bẹ̀rù kìnnìún tó wà níta (13)

      • Ìbáwí ń mú ìwà òmùgọ̀ kúrò (15)

      • Òṣìṣẹ́ tó bá já fáfá ló ń bá àwọn ọba ṣiṣẹ́ (29)

    • 23

      • Máa lo làákàyè tí wọ́n bá ń ṣe ọ́ lálejò (2)

      • Má ṣe máa lé ọrọ̀ (4)

      • Ọrọ̀ lè fò lọ kúrò lọ́dọ̀ rẹ (5)

      • Má ṣe wà lára àwọn tó ń mutí lámujù (20)

      • Ọtí máa ń buni ṣán bí ejò (32)

    • 24

      • Má ṣe jowú àwọn ẹni ibi (1)

      • Ọgbọ́n ni a fi ń gbé ilé ró (3)

      • Olódodo lè ṣubú, àmọ́ yóò dìde (16)

      • Má gbẹ̀san (29)

      • Ìtòògbé ń sọni di òtòṣì (33, 34)

  • ÀWỌN ÒWE SÓLÓMỌ́NÌ TÍ ÀWỌNKÙNRINBA HẸSIKÁYÀ DÀ KỌ (25:1–29:27)

    • 25

      • Pípa àṣírí mọ́ (9)

      • Ọ̀rọ̀ téèyàn rò dáadáa kó tó sọ (11)

      • Má tojú bọ ilé onílé (17)

      • Kíkó ẹyin iná lé ọ̀tá lórí (21, 22)

      • Ìròyìn rere dà bí omi tútù (25)

    • 26

      • Ìwà àwọn ọ̀lẹ (13-16)

      • Má ṣe dá sí ìjà tí kì í ṣe tìrẹ (17)

      • Yẹra fún dídá àpárá (18, 19)

      • Kò sígi, kò síná (20, 21)

      • Ọ̀rọ̀ abanijẹ́ dà bí òkèlè dídùn (22)

    • 27

      • Ìbáwí látọ̀dọ̀ ọ̀rẹ́ ń ṣeni láǹfààní (5, 6)

      • Ọmọ mi, mú ọkàn mi yọ̀ (11)

      • Irin ń pọ́n irin (17)

      • Mọ agbo ẹran rẹ (23)

      • Ọrọ̀ kì í wà títí láé (24)

    • 28

      • Àdúrà ẹni tí kò pa òfin mọ́ jẹ́ ohun ìríra (9)

      • Ẹni tó bá jẹ́wọ́ á rí àánú gbà (13)

      • Èèyàn ò lè kánjú di ọlọ́rọ̀ láì jẹ̀bi (20)

      • Ká báni wí sàn ju ká máa pọ́nni (23)

      • Ẹni tó lawọ́ kò ní ṣaláìní (27)

    • 29

      • Ọmọ tí a bá fi sílẹ̀ máa ń kó ìtìjú báni (15)

      • Láìsí ìran, àwọn èèyàn á ya ìyàkuyà (18)

      • Ẹni tó ń bínú máa ń dá wàhálà sílẹ̀ (22)

      • Onírẹ̀lẹ̀ máa ń gba ògo (23)

      • Ìbẹ̀rù èèyàn jẹ́ ìdẹkùn (25)

  • 30

    • ÀWỌN Ọ̀RỌ̀ ÁGÚRÌ (1-33)

      • Má ṣe fún mi ní òṣì tàbí ọrọ̀ (8)

      • Àwọn ohun tí kì í ní ìtẹ́lọ́rùn (15, 16)

      • Àwọn ohun tí èèyàn kò lè tọ ipasẹ̀ rẹ̀ (18, 19)

      • Obìnrin alágbèrè (20)

      • Àwọn ẹranko tó ní ọgbọ́n àdámọ́ni (24)

  • 31

    • ÀWỌN Ọ̀RỌ̀BA LÉMÚẸ́LÌ (1-31)

      • Tá ló ti rí aya tó dáńgájíà? (10)

      • Ẹni tí kì í ṣọ̀lẹ àti òṣìṣẹ́ kára (17)

      • Òfin inú rere wà ní ahọ́n rẹ̀ (26)

      • Ọkọ rẹ̀ àti àwọn ọmọ rẹ̀ yìn ín (28)

      • Òòfà ẹwà àti ẹwà ojú kì í tọ́jọ́ (30)