Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìwé Àìsáyà

Orí

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Yìí

  • 1

    • Bàbá kan àti àwọn ọmọ rẹ̀ tó ya ọlọ̀tẹ̀ (1-9)

    • Jèhófà kórìíra ìjọsìn ojú lásán (10-17)

    • “Ẹ jẹ́ ká yanjú ọ̀rọ̀” (18-20)

    • Síónì máa pa dà di ìlú olóòótọ́ (21-31)

  • 2

    • A gbé òkè Jèhófà ga (1-5)

      • Wọ́n á fi idà rọ ohun ìtúlẹ̀ (4)

    • Ọjọ́ Jèhófà máa tẹ àwọn agbéraga lórí ba (6-22)

  • 3

    • Àwọn olórí Júdà kó àwọn èèyàn ṣìnà (1-15)

    • A dá àwọn ọmọbìnrin Síónì oníṣekúṣe lẹ́jọ́ (16-26)

  • 4

    • Obìnrin méje máa di ọkùnrin kan mú (1)

    • Ohun tí Jèhófà mú kó rú jáde máa ní ògo (2-6)

  • 5

    • Orin nípa ọgbà àjàrà Jèhófà (1-7)

    • Ó mà ṣe fún ọgbà àjàrà Jèhófà o (8-24)

    • Ọlọ́run bínú sí àwọn èèyàn rẹ̀ (25-30)

  • 6

    • Ìran nípa Jèhófà nínú tẹ́ńpìlì rẹ̀ (1-4)

      • “Mímọ́, mímọ́, mímọ́ ni Jèhófà” (3)

    • A wẹ ètè Àìsáyà mọ́ (5-7)

    • Àìsáyà gba iṣẹ́ (8-10)

      • “Èmi nìyí! Rán mi!” (8)

    • “Títí dìgbà wo, Jèhófà?” (11-13)

  • 7

    • A ránṣẹ́ sí Ọba Áhásì (1-9)

      • Ṣeari-jáṣúbù (3)

    • Ohun tí a fi máa dá Ìmánúẹ́lì mọ̀ (10-17)

    • Ohun tó máa gbẹ̀yìn ìwà àìṣòótọ́ (18-25)

  • 8

    • Ásíríà máa gbé ogun wá (1-8)

      • Maheri-ṣalali-háṣí-básì (1-4)

    • Ẹ má bẹ̀rù⁠—“Ọlọ́run wà pẹ̀lú wa!” (9-17)

    • Àìsáyà àti àwọn ọmọ rẹ̀ máa jẹ́ àmì (18)

    • Ẹ yíjú sí òfin, kì í ṣe sí àwọn ẹ̀mí èṣù (19-22)

  • 9

    • Ìmọ́lẹ̀ tó tàn yòò fún ilẹ̀ Gálílì (1-7)

      • A bí “Ọmọ Aládé Àlàáfíà” (6-7)

    • Ọwọ́ Ọlọ́run máa kọ lu Ísírẹ́lì (8-21)

  • 10

    • Ọwọ́ Ọlọ́run máa kọ lu Ísírẹ́lì (1-4)

    • Ásíríà⁠—​Ọ̀pá ìbínú Ọlọ́run (5-11)

    • Ìyà tó máa jẹ Ásíríà (12-19)

    • Àṣẹ́kù Jékọ́bù máa pa dà (20-27)

    • Ọlọ́run máa dá Ásíríà lẹ́jọ́ (28-34)

  • 11

    • Èéhù Jésè máa fi òdodo ṣàkóso (1-10)

      • Ìkookò máa bá ọmọ àgùntàn gbé (6)

      • Ìmọ̀ Jèhófà máa bo ayé (9)

    • Àṣẹ́kù pa dà (11-16)

  • 12

    • Orin ìdúpẹ́ (1-6)

      • “Jáà Jèhófà ni okun mi” (2)

  • 13

    • Ọ̀rọ̀ ìkéde sí Bábílónì (1-22)

      • Ọjọ́ Jèhófà sún mọ́lé! (6)

      • Àwọn ará Mídíà máa ṣẹ́gun Bábílónì (17)

      • Wọn ò ní gbé inú Bábílónì mọ́ láé (20)

  • 14

    • Ísírẹ́lì máa gbé ní ilẹ̀ tirẹ̀ (1, 2)

    • Wọ́n fi ọba Bábílónì ṣe ẹlẹ́yà (3-23)

      • Ẹni tó ń tàn máa já bọ́ láti ọ̀run (12)

    • Ọwọ́ Jèhófà máa fọ́ ará Ásíríà túútúú (24-27)

    • Ọ̀rọ̀ ìkéde sí Filísíà (28-32)

  • 15

    • Ọ̀rọ̀ ìkéde sí Móábù (1-9)

  • 16

    • Ọ̀rọ̀ ìkéde sí Móábù ń bá a lọ (1-14)

  • 17

    • Ọ̀rọ̀ ìkéde sí Damásíkù (1-11)

    • Jèhófà máa bá àwọn orílẹ̀-èdè wí (12-14)

  • 18

    • Ọ̀rọ̀ ìkéde sí Etiópíà (1-7)

  • 19

    • Ọ̀rọ̀ ìkéde sí Íjíbítì (1-15)

    • Íjíbítì máa mọ Jèhófà (16-25)

      • Pẹpẹ kan máa wà fún Jèhófà ní Íjíbítì (19)

  • 20

    • Àmì àti àpẹẹrẹ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí Íjíbítì àti Etiópíà (1-6)

  • 21

    • Ọ̀rọ̀ ìkéde sí aginjù òkun (1-10)

      • Ó ń ṣọ́nà láti orí ilé ìṣọ́ (8)

      • “Bábílónì ti ṣubú!” (9)

    • Ìkéde lòdì sí Dúmà àti aṣálẹ̀ tó tẹ́jú (11-17)

      • “Olùṣọ́, báwo ni òru ṣe rí?” (11)

  • 22

    • Ìkéde nípa Àfonífojì Ìran (1-14)

    • Wọ́n fi Élíákímù rọ́pò Ṣébínà tó jẹ́ ìríjú (15-25)

      • Èèkàn tó ṣàpẹẹrẹ ohun kan (23-25)

  • 23

    • Ọ̀rọ̀ ìkéde sí Tírè (1-18)

  • 24

    • Jèhófà máa sọ ilẹ̀ náà di òfìfo (1-23)

      • Jèhófà di Ọba ní Síónì (23)

  • 25

    • Ọlọ́run máa bù kún àwọn èèyàn rẹ̀ lọ́pọ̀ yanturu (1-12)

      • Àkànṣe àsè Jèhófà tó ní wáìnì tó dáa (6)

      • Kò ní sí ikú mọ́ (8)

  • 26

    • Orin ìgbẹ́kẹ̀lé àti ìgbàlà (1-21)

      • Jáà Jèhófà, Àpáta ayérayé (4)

      • Àwọn tó ń gbé ayé máa kọ́ òdodo (9)

      • “Àwọn òkú rẹ máa wà láàyè” (19)

      • Ẹ wọ àwọn yàrá inú, kí ẹ sì fara pa mọ́ (20)

  • 27

    • Jèhófà pa Léfíátánì (1)

    • Orin tó fi Ísírẹ́lì wé ọgbà àjàrà (2-13)

  • 28

    • Ó mà ṣe fún àwọn ọ̀mùtípara Éfúrémù o! (1-6)

    • Àwọn àlùfáà àti wòlíì Júdà ń ta gọ̀ọ́gọ̀ọ́ (7-13)

    • Wọ́n “bá Ikú dá májẹ̀mú” (14-22)

      • Òkúta igun tó ṣeyebíye ní Síónì (16)

      • Iṣẹ́ Jèhófà tó ṣàjèjì (21)

    • Bí Jèhófà ṣe ń fi ọgbọ́n báni wí (23-29)

  • 29

    • O gbé, ìwọ Áríélì! (1-16)

      • Ọlọ́run dẹ́bi fún àwọn tó ń fi ẹnu lásán sìn ín (13)

    • Adití máa gbọ́rọ̀; afọ́jú sì máa ríran (17-24)

  • 30

    • Íjíbítì ò lè ṣèrànwọ́ kankan (1-7)

    • Àwọn èèyàn ò fetí sí àsọtẹ́lẹ̀ (8-14)

    • Ìgbẹ́kẹ̀lé máa fi hàn pé wọ́n lágbára (15-17)

    • Jèhófà ṣojúure sí àwọn èèyàn rẹ̀ (18-26)

      • Jèhófà, Olùkọ́ni Atóbilọ́lá (20)

      • “Èyí ni ọ̀nà” (21)

    • Jèhófà máa dá Ásíríà lẹ́jọ́ (27-33)

  • 31

    • Ìrànlọ́wọ́ Ọlọ́run ló dájú, kì í ṣe ti èèyàn (1-9)

      • Ẹran ara ni àwọn ẹṣin Íjíbítì (3)

  • 32

    • Ọba kan àti àwọn ìjòyè máa ṣàkóso fún ìdájọ́ òdodo (1-8)

    • A kìlọ̀ fún àwọn obìnrin tí ara tù (9-14)

    • Tí a bá tú ẹ̀mí jáde, ó máa mú ìbùkún wá (15-20)

  • 33

    • Ìdájọ́ àti ìrètí fún àwọn olódodo (1-24)

      • Jèhófà ni Onídàájọ́, Afúnnilófin àti Ọba (22)

      • Kò sẹ́ni tó máa sọ pé: “Ara mi ò yá” (24)

  • 34

    • Jèhófà máa gbẹ̀san lára àwọn orílẹ̀-èdè (1-4)

    • Édómù máa di ahoro (5-17)

  • 35

    • Ayé pa dà di Párádísè (1-7)

      • Afọ́jú máa ríran; adití máa gbọ́ràn (5)

    • Ọ̀nà Ìjẹ́mímọ́ fún àwọn tí a tún rà (8-10)

  • 36

    • Senakérúbù gbéjà ko Júdà (1-3)

    • Rábúṣákè pẹ̀gàn Jèhófà (4-22)

  • 37

    • Hẹsikáyà ní kí Àìsáyà bá òun bẹ Ọlọ́run fún ìrànlọ́wọ́ (1-7)

    • Senakérúbù halẹ̀ mọ́ Jerúsálẹ́mù (8-13)

    • Àdúrà tí Hẹsikáyà gbà (14-20)

    • Àìsáyà sọ ohun tí Ọlọ́run sọ (21-35)

    • Áńgẹ́lì kan pa 185,000 àwọn ọmọ Ásíríà (36-38)

  • 38

    • Hẹsikáyà ṣàìsàn, ara rẹ̀ sì yá (1-22)

      • Orin ìdúpẹ́ (10-20)

  • 39

    • Àwọn ìránṣẹ́ láti Bábílónì (1-8)

  • 40

    • A tu àwọn èèyàn Ọlọ́run nínú (1-11)

      • Ohùn kan nínú aginjù (3-5)

    • Ọlọ́run tóbi (12-31)

      • Àwọn orílẹ̀-èdè dà bí ẹ̀kán omi kan látinú korobá (15)

      • Ọlọ́run ń gbé orí “òbìrìkìtì ayé” (22)

      • Ó ń fi orúkọ pe gbogbo ìràwọ̀ (26)

      • Kì í rẹ Ọlọ́run (28)

      • Ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Jèhófà ń mú kéèyàn jèrè okun pa dà (29-31)

  • 41

    • Aṣẹ́gun kan láti ìlà oòrùn (1-7)

    • Ọlọ́run yan Ísírẹ́lì pé kó jẹ́ ìránṣẹ́ òun (8-20)

      • “Ábúráhámù ọ̀rẹ́ mi” (8)

    • Ó pe àwọn ọlọ́run míì níjà (21-29)

  • 42

    • Ìránṣẹ́ Ọlọ́run àti ohun tó máa ṣe (1-9)

      • ‘Jèhófà ni orúkọ mi’ (8)

    • Orin ìyìn tuntun sí Jèhófà (10-17)

    • Ísírẹ́lì fọ́jú, ó sì dití (18-25)

  • 43

    • Jèhófà pa dà kó àwọn èèyàn rẹ̀ jọ (1-7)

    • Kí àwọn ọlọ́run gbèjà ara wọn (8-13)

      • “Ẹ̀yin ni ẹlẹ́rìí mi” (10, 12)

    • Wọ́n máa tú wọn sílẹ̀ láti Bábílónì (14-21)

    • “Jẹ́ ká gbé ẹjọ́ wa wá” (22-28)

  • 44

    • Ọlọ́run máa bù kún àwọn àyànfẹ́ rẹ̀ (1-5)

    • Kò sí Ọlọ́run míì àfi Jèhófà (6-8)

    • Àwọn òrìṣà tí èèyàn ṣe kò já mọ́ nǹkan kan (9-20)

    • Jèhófà, Olùtúnrà Ísírẹ́lì (21-23)

    • Ipasẹ̀ Kírúsì ni wọ́n máa pa dà (24-28)

  • 45

    • Ọlọ́run yan Kírúsì pé kó ṣẹ́gun Bábílónì (1-8)

    • Amọ̀ ò lè bá Amọ̀kòkò fà á (9-13)

    • Àwọn orílẹ̀-èdè míì mọ Ísírẹ́lì (14-17)

    • Ọlọ́run ṣeé gbára lé lórí ọ̀rọ̀ ìṣẹ̀dá àti ṣíṣí nǹkan payá (18-25)

      • Ó dá ayé ká lè máa gbé inú rẹ̀ (18)

  • 46

    • Àwọn òrìṣà Bábílónì àti Ọlọ́run Ísírẹ́lì (1-13)

      • Jèhófà ń sọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú (10)

      • Ẹyẹ aṣọdẹ láti ìlà oòrùn (11)

  • 47

    • Ìṣubú Bábílónì (1-15)

      • Àṣírí àwọn awòràwọ̀ tú (13-15)

  • 48

    • Ọlọ́run bá Ísírẹ́lì wí, ó sì wẹ̀ ẹ́ mọ́ (1-11)

    • Jèhófà máa kọ lu Bábílónì (12-16a)

    • Ẹ̀kọ́ Ọlọ́run ṣàǹfààní (16b-19)

    • “Ẹ jáde kúrò ní Bábílónì!” (20-22)

  • 49

    • Iṣẹ́ ìránṣẹ́ Jèhófà (1-12)

      • Ìmọ́lẹ̀ àwọn orílẹ̀-èdè (6)

    • A tu Ísírẹ́lì nínú (13-26)

  • 50

    • Àwọn ẹ̀ṣẹ̀ Ísírẹ́lì fa wàhálà (1-3)

    • Ìránṣẹ́ Jèhófà tó jẹ́ onígbọràn (4-11)

      • Ahọ́n àti etí àwọn tí a kọ́ (4)

  • 51

    • Síónì máa pa dà rí bí ọgbà Édẹ́nì (1-8)

    • Aṣẹ̀dá Síónì tó lágbára tù wọ́n nínú (9-16)

    • Ife ìbínú Jèhófà (17-23)

  • 52

    • Jí, ìwọ Síónì! (1-12)

      • Ẹsẹ̀ àwọn tó ń mú ìhìn rere wá rẹwà (7)

      • Àwọn olùṣọ́ Síónì kígbe níṣọ̀kan (8)

      • Àwọn tó ń gbé àwọn ohun èlò Jèhófà gbọ́dọ̀ mọ́ (11)

    • A máa gbé ìránṣẹ́ Jèhófà ga (13-15)

      • Wọ́n ba ìrísí rẹ̀ jẹ́ (14)

  • 53

    • Ìyà tó máa jẹ ìránṣẹ́ Jèhófà, bó ṣe máa kú àti bí wọ́n ṣe máa sin ín (1-12)

      • Wọ́n kórìíra rẹ̀, wọ́n sì yẹra fún un (3)

      • Ó gbé àìsàn àti ìrora (4)

      • “Bí àgùntàn sí ibi tí wọ́n ti fẹ́ pa á” (7)

      • Ó ru ẹ̀ṣẹ̀ ọ̀pọ̀ èèyàn (12)

  • 54

    • Síónì tó yàgàn máa ní ọmọ púpọ̀ (1-17)

      • Jèhófà, ọkọ Síónì (5)

      • Jèhófà máa kọ́ àwọn ọmọ Síónì (13)

      • Ohun ìjà tí wọ́n bá ṣe sí Síónì kò ní ṣàṣeyọrí (17)

  • 55

    • Ìkésíni láti jẹ, kí wọ́n sì mu lọ́fẹ̀ẹ́ (1-5)

    • Ẹ wá Jèhófà àti ọ̀rọ̀ rẹ̀ tó ṣeé gbára lé (6-13)

      • Ọ̀nà Ọlọ́run ga ju ti èèyàn lọ (8, 9)

      • Ó dájú pé ọ̀rọ̀ Ọlọ́run máa yọrí sí rere (10, 11)

  • 56

    • Àwọn àjèjì àti àwọn ìwẹ̀fà máa rí ìbùkún (1-8)

      • Ilé àdúrà fún gbogbo èèyàn (7)

    • Àwọn olùṣọ́ tó fọ́jú, ajá tí kò lè fọhùn (9-12)

  • 57

    • Olódodo àti àwọn olóòótọ́ ṣègbé (1, 2)

    • Àgbèrè ẹ̀sìn tí Ísírẹ́lì ń ṣe hàn síta (3-13)

    • A tu àwọn ẹni rírẹlẹ̀ nínú (14-21)

      • Àwọn ẹni burúkú dà bí òkun tó ń ru (20)

      • Kò sí àlàáfíà fún ẹni burúkú (21)

  • 58

    • Ààwẹ̀ tó dénú àti èyí tí kò dénú (1-12)

    • Pípa Sábáàtì mọ́ ń múnú ẹni dùn (13, 14)

  • 59

    • Àwọn ẹ̀ṣẹ̀ Ísírẹ́lì mú kí wọ́n jìnnà sí Ọlọ́run (1-8)

    • Wọ́n jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ (9-15a)

    • Jèhófà dá sí i torí àwọn tó ronú pìwà dà (15b-21)

  • 60

    • Ògo Jèhófà tàn sórí Síónì (1-22)

      • Bí àwọn àdàbà tó ń fò lọ sí ilé wọn (8)

      • Wúrà dípò bàbà (17)

      • Ẹni tó kéré máa di ẹgbẹ̀rún (22)

  • 61

    • A fòróró yàn án láti kéde ìhìn rere (1-11)

      • “Ọdún ìtẹ́wọ́gbà Jèhófà” (2)

      • “Igi ńlá òdodo” (3)

      • Àwọn àjèjì máa ṣèrànwọ́ (5)

      • “Àlùfáà Jèhófà” (6)

  • 62

    • Orúkọ tuntun tí Síónì á máa jẹ́ (1-12)

  • 63

    • Jèhófà máa gbẹ̀san lára àwọn orílẹ̀-èdè (1-6)

    • Bí Jèhófà ṣe fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn nígbà àtijọ́ (7-14)

    • Àdúrà ìrònúpìwàdà (15-19)

  • 64

    • Àdúrà ìrònúpìwàdà ń bá a lọ (1-12)

      • Jèhófà, “Ẹni tó mọ wá” (8)

  • 65

    • Jèhófà máa dá àwọn abọ̀rìṣà lẹ́jọ́ (1-16)

      • Ọlọ́run Oríire àti Àyànmọ́ (11)

      • “Àwọn ìránṣẹ́ mi máa jẹun” (13)

    • Ọ̀run tuntun àti ayé tuntun (17-25)

      • A máa kọ́ ilé; a máa gbin ọgbà àjàrà (21)

      • Kò sẹ́ni tó máa ṣiṣẹ́ àṣedànù (23)

  • 66

    • Ìjọsìn tòótọ́ àti ìjọsìn èké (1-6)

    • Síónì tó jẹ́ ìyá àti àwọn ọmọ rẹ̀ (7-17)

    • Àwọn èèyàn kóra jọ láti jọ́sìn ní Jerúsálẹ́mù (18-24)