Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìwé Sekaráyà

Orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Yìí

  • 1

    • Jèhófà ní kí wọ́n pa dà sọ́dọ̀ òun (1-6)

      • ‘Ẹ pa dà sọ́dọ̀ mi, èmi yóò sì pa dà sọ́dọ̀ yín’ (3)

    • Ìran 1: Àwọn tó ń gun ẹṣin láàárín àwọn igi mátílì (7-17)

      • ‘Jèhófà yóò pa dà tu Síónì nínú’ (17)

    • Ìran 2: Ìwo mẹ́rin àti oníṣẹ́ ọnà mẹ́rin (18-21)

  • 2

    • Ìran 3: Ọkùnrin kan mú okùn ìdíwọ̀n dání (1-13)

      • Wọ́n máa wọn Jerúsálẹ́mù (2)

      • Jèhófà, ‘di ògiri iná yí i ká’ (5)

      • Bí wọ́n ṣe fọwọ́ kan ẹyinjú Ọlọ́run (8)

      • Ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè yóò fara mọ́ Jèhófà (11)

  • 3

    • Ìran 4: Wọ́n fún àlùfáà àgbà ní aṣọ míì (1-10)

      • Sátánì ta ko Àlùfáà Àgbà Jóṣúà (1)

      • ‘Màá mú ìránṣẹ́ mi tó ń jẹ́ Èéhù wá!’ (8)

  • 4

    • Ìran 5: Ọ̀pá fìtílà kan àti igi ólífì méjì (1-14)

      • ‘Kì í ṣe nípasẹ̀ agbára, bí kò ṣe nípasẹ̀ ẹ̀mí mi’ (6)

      • Má ṣe pẹ̀gàn ọjọ́ tí nǹkan bẹ̀rẹ̀ wẹ́rẹ́ (10)

  • 5

    • Ìran 6: Àkájọ ìwé tó ń fò (1-4)

    • Ìran 7: Agbọ̀n tó dà bí òṣùwọ̀n eéfà (5-11)

      • Obìnrin tó wà nínú rẹ̀ ń jẹ́ Ìwà Burúkú (8)

      • Wọ́n gbé agbọ̀n náà lọ sí ilẹ̀ Ṣínárì (9-11)

  • 6

    • Ìran 8: Kẹ̀kẹ́ ẹṣin mẹ́rin (1-8)

    • Èéhù yóò di ọba àti àlùfáà (9-15)

  • 7

    • Jèhófà dẹ́bi fún àwọn tó ń gbààwẹ̀ tí kò dénú (1-14)

      • “Ṣé torí mi lẹ ṣe gbààwẹ̀ lóòótọ́?” (5)

      • ‘Ẹ dá ẹjọ́ òdodo, kí ìfẹ́ tí ẹ ní má yẹ̀, kí ẹ sì máa ṣàánú ara yín’ (9)

  • 8

    • Jèhófà fún Síónì ní àlàáfíà àti òtítọ́ (1-23)

      • Jerúsálẹ́mù, “ìlú òtítọ́” (3)

      • “Ẹ máa bá ara yín sọ òtítọ́” (16)

      • Àsìkò ààwẹ̀ yóò di àsìkò àjọ̀dún (18, 19)

      • ‘Ẹ jẹ́ ká tètè wá Jèhófà’ (21)

      • Ọkùnrin mẹ́wàá di aṣọ Júù kan mú (23)

  • 9

    • Ọlọ́run dá àwọn orílẹ̀-èdè tó wà yí ká lẹ́jọ́ (1-8)

    • Ọba Síónì ń bọ̀ (9, 10)

      • Ọba tó jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ ń gun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ (9)

    • Wọ́n á tú àwọn èèyàn Jèhófà sílẹ̀ (11-17)

  • 10

    • Jèhófà ni kí ẹ bẹ̀ pé kó rọ̀jò, kì í ṣe àwọn ọlọ́run èké (1, 2)

    • Jèhófà mú kí àwọn èèyàn rẹ̀ wà níṣọ̀kan (3-12)

      • Olórí tó wá láti ilé Júdà (3, 4)

  • 11

    • Ohun tó ṣẹlẹ̀ torí wọ́n kọ olùṣọ́ àgùntàn tí Ọlọ́run yàn (1-17)

      • “Bójú tó agbo ẹran tí wọ́n fẹ́ pa” (4)

      • Ọ̀pá méjì: Adùn àti Ìṣọ̀kan (7)

      • Owó iṣẹ́ olùṣọ́ àgùntàn: ọgbọ̀n (30) owó fàdákà (12)

      • Ó sọ owó náà sí ibi ìṣúra (13)

  • 12

    • Jèhófà yóò dáàbò bo Júdà àti Jerúsálẹ́mù (1-9)

      • Jerúsálẹ́mù yóò di “òkúta tó wúwo” (3)

    • Wọ́n ń pohùn réré ẹkún torí ẹni tí wọ́n gún (10-14)

  • 13

    • Ọlọ́run yóò mú àwọn òrìṣà àtàwọn wòlíì èké kúrò (1-6)

      • Ojú yóò ti àwọn wòlíì èké (4-6)

    • Wọ́n á kọ lu olùṣọ́ àgùntàn (7-9)

      • Ọlọ́run yóò yọ́ ìdá kẹta mọ́ (9)

  • 14

    • Ìjọsìn tòótọ́ borí, ó sì fìdí múlẹ̀ (1-21)

      • Òkè Ólífì yóò là sí méjì (4)

      • Jèhófà yóò jẹ́ ọ̀kan, orúkọ rẹ̀ yóò sì jẹ́ ọ̀kan (9)

      • Àjàkálẹ̀ àrùn yóò kọ lu àwọn tó ń gbéjà ko Jerúsálẹ́mù (12-15)

      • Wọn yóò ṣe Àjọyọ̀ Àtíbàbà (16-19)

      • Gbogbo ìkòkò yóò di mímọ́ fún Jèhófà (20, 21)