Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

ERITREA

Wọ́n Fi Wọ́n Sẹ́wọ̀n Torí Ohun Tí Wọ́n Gbà Gbọ́​—Eritrea

Wọ́n Fi Wọ́n Sẹ́wọ̀n Torí Ohun Tí Wọ́n Gbà Gbọ́​—Eritrea

Ọjọ́ pẹ́ tí ìjọba orílẹ̀-èdè Eritrea ti ń fàṣẹ ọba mú àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà, títí kan àwọn obìnrin àtàwọn àgbàlagbà, tí wọ́n sì ń fi wa sẹ́wọ̀n láì fẹ̀sùn kàn wa tàbí gbọ́ ẹjọ́ wa. Torí pé à ń ṣe ẹ̀sìn wa ni wọ́n ṣe mú wa, nígbà míì sì rèé, wọn kì í sọ ohun tó fà á tí wọ́n fi mú wa. Nínú àṣẹ kan tí ààrẹ orílẹ̀-èdè Eritrea, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Afwerki pa ní October 25, 1994, ó gbẹ́sẹ̀ lé ẹ̀tọ́ táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní gẹ́gẹ́ bí ọmọ ilẹ̀ Eritrea torí pé àwa Ẹlẹ́rìí ò lọ́wọ́ sí ìdìbò tó wáyé lọ́dún 1993 nígbà tí orílẹ̀-èdè náà fẹ́ gba òmìnira, a sì tún kọ̀ láti ṣiṣẹ́ ológun torí ẹ̀rí ọkàn wa ò gbà wa láyè. Káwọn aláṣẹ orílẹ̀-èdè Eritrea tó sọ ọ́ di dandan pé káwọn èèyàn ṣe iṣẹ́ ológun, wọ́n ti ṣètò iṣẹ́ àṣesìnlú míì fáwọn tí kò lè ṣe iṣẹ́ ológun. Ọ̀pọ̀ Ẹlẹ́rìí Jèhófà ló ti kópa nínú iṣẹ́ àṣesìnlú yìí lábẹ́ oríṣiríṣi ìjọba. Ìjọba máa ń fáwọn tó bá parí iṣẹ́ àṣesìnlú wọn ní ìwé ẹ̀rí Certificates of Completed National Service, kódà wọ́n máa yìn wọ́n fún iṣẹ́ tí wọ́n ṣe. Àmọ́ nítorí àṣẹ tí ààrẹ pa, ńṣe làwọn aláàbò ìlú wá ń ju àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà sẹ́wọ̀n, tí wọ́n ń fìyà jẹ wa, tí wọ́n sì ń halẹ̀ mọ́ wa, kí wọ́n lè fipá mú wa sẹ́ ìgbàgbọ́ wa.

Ẹlẹ́rìí Jèhófà méjìdínlógójì (38) ló ṣì wà lẹ́wọ̀n títí di báyìí (ọkùnrin mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n (27) àti obìnrin mọ́kànlá (11)). Ní December 4, 2020, wọ́n dá àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà méjìdínlọ́gbọ̀n sílẹ̀ lẹ́wọ̀n (ọkùnrin mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n (26) àti obìnrin méjì), lẹ́yìn tí ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn ti lo nǹkan bí ọdún márùn-ún sí mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n (26) lẹ́wọ̀n. Ní January 29, 2021, wọ́n dá ọkùnrin kan tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà sílẹ̀, lẹ́yìn tó ti lo ohun tó ju ọdún méjìlá (12) lẹ́wọ̀n, wọ́n tún dá àwọn mẹ́ta míì sílẹ̀ ní February 1, 2021 (ọkùnrin kan àti obìnrin méjì), lẹ́yìn tí wọ́n ti lo nǹkan bí ọdún mẹ́rin sí mẹ́sàn-án lẹ́wọ̀n.

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Kan Tó Wà Lẹ́wọ̀n Ń Kú Torí Nǹkan Ò Rọrùn fún Wọn Rárá

Ẹlẹ́rìí mẹ́rin ló ti kú sẹ́wọ̀n ní Eritrea, àwọn mẹ́ta tó ti dàgbà sì kú lẹ́yìn tí wọ́n dá wọn sílẹ̀ torí ìyà tí wọ́n fi jẹ wọ́n nígbà tí wọ́n wà lẹ́wọ̀n.

Lọ́dún 2018, àwọn Ẹlẹ́rìí méjì kú lẹ́yìn tí wọ́n mú wọn lọ sí Ọgbà Ẹ̀wọ̀n Mai Serwa. Ẹni àkọ́kọ́ ni Habtemichael Tesfamariam tó kú ní January 3 lẹ́ni ọdún mẹ́rìndínlọ́gọ́rin (76). Èkejì sí ni Habtemichael Mekonen tó kú ní March 6 lẹ́ni ọdún mẹ́tàdínlọ́gọ́rin (77). Ọdún 2008 làwọn aláṣẹ ní Eritrea ju àwọn méjèèjì sẹ́wọ̀n láìnídìí.

Lọ́dún 2011 àti 2012, àwọn Ẹlẹ́rìí méjì kú nítorí ohun tó burú jáì tí wọ́n ṣe sí wọn ní Ọgbà Ẹ̀wọ̀n Meitir. Ọ̀gbẹ́ni Misghina Gebretinsae, ẹni ọdún 62 tí wọ́n tì mọ́ “àjà ilẹ̀” tí wọ́n ti ń fìyà jẹni, kú ní July 2011 torí ooru burúkú tó mú un nígbà tó wà níbẹ̀. Yohannes Haile, ẹni ọdún 68 kú ní August 16, 2012, lẹ́yìn tí wọ́n fi irú ìyà kan náà jẹ ẹ́ fún nǹkan bí ọdún mẹ́rin. Àwọn àgbàlagbà mẹ́ta míì tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà kú lẹ́yìn tí wọ́n dá wọn sílẹ̀ lẹ́wọ̀n, ràbọ̀ràbọ̀ ìyà tí wọ́n jẹ lẹ́wọ̀n ló sì pa wọ́n. Orúkọ wọn ni Kahsai Mekonnen, Goitom Gebrekristos àti Tsehaye Tesfariam.

Wọn Ò Kọbi Ara sí Ọ̀rọ̀ Àwọn Àjọ Tó Ń Rí Sọ́rọ̀ Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn

Orílẹ̀-èdè Eritrea kọ̀ láti tẹ̀ lé ìlànà tó wà fún ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn lágbàáyé. Àwọn àjọ tó lórúkọ tó ń rí sí ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn ti bẹnu àtẹ́ lu bí orílẹ̀-èdè Eritrea ṣe ń fojú àwọn èèyàn gbolẹ̀ lórí ẹ̀tọ́ wọn, wọ́n sì ti ní kó ṣàtúnṣe sọ́rọ̀ náà.

Lọ́dún 2014, Àjọ Tó Ń Rí sí Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn gba ìròyìn látọ̀dọ̀ ẹni tó ń jábọ̀ fún wọn lórí bí ọ̀rọ̀ ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn ṣe ń lọ sí lórílẹ̀-èdè Eritrea, wọ́n sì rọ àwọn aláṣẹ pé kí wọ́n fara mọ́ ẹ̀tọ́ táwọn èèyàn ní láti má ṣe ohun tí ẹ̀rí ọkàn wọn ò gbà, “èyí tó bára mu pẹ̀lú ohun táwọn orílẹ̀-èdè fara mọ́,” àti pé “kí wọ́n ṣe àbójútó tó péye fún gbogbo àwọn ẹlẹ́wọ̀n; kí wọ́n rí i dájú pé wọ́n ń rí ìtọ́jú tí wọ́n nílò . . . kí wọ́n sì mú káwọn ibi tí wọ́n ń ti àwọn èèyàn mọ́ sunwọ̀n sí i gẹ́gẹ́ bí ìlànà tó wà kárí ayé ṣe sọ.” Nínú ìpinnu tí àjọ náà ṣe lọ́dún 2015, wọ́n ní kí ìjọba Eritrea “ṣètò láti fàyè gba àwọn tí ẹ̀rí ọkàn wọn ò bá lè jẹ́ kí wọ́n ṣiṣẹ́ ológun.”

Lọ́dún 2016, Àjọ Tó Ń Ṣèwádìí Lórí Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn ní Eritrea sọ pé àwọn aláṣẹ ní Eritrea “ti hùwà ìkà gbáà” torí ‘bí wọ́n ṣe ń ṣe inúnibíni sáwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà àtàwọn míì torí ẹ̀sìn wọn àti nítorí ẹ̀yà wọn.’

Lọ́dun 2017, Àjọ Àwọn Akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ Tó Ń Rí sí Ẹ̀tọ́ àti Àbójútó Àwọn Ọmọ sọ ohun tó kíyè sí pé bó tiẹ̀ jẹ́ pé òfin wà, wọn ò jẹ́ kí “àwọn ọmọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà” rí ẹ̀tọ́ yìí lò, wọ́n sì ń fìyà burúkú jẹ wọ́n. Àjọ náà dábàá pé kí orílẹ̀-èdè Eritrea “gbà, kí wọ́n sì fara mọ́ ọn láìsì ojúsàájú kankan pé ọmọ kọ̀ọ̀kan ló ní Ẹ̀tọ́ Láti Ní Èrò Tó Wuni, Láti Ṣe Ohun Tí Ẹ̀rí Ọkàn Ẹni Bá Gbà Láyè àti Ẹ̀sìn Tó Wuni.”

Lọ́dún 2018, Àjọ Ilẹ̀ Áfíríkà Tó Ń Rí Sọ́rọ̀ Ẹ̀tọ́ Àwọn Èèyàn dábàá pé kí orílẹ̀-èdè Eritrea “tètè wá nǹkan ṣe sí bí wọ́n ṣe ń fi ẹ̀tọ́ gbogbo àwọn tó wà látìmọ́lé dù wọ́n, títí kan . . . àwọn tó ń ṣe ẹ̀sìn Ẹlẹ́rìí Jèhófà,” ó sì ní kí wọ́n ṣèwádìí ohun tó fa ikú àwọn Ẹlẹ́rìí tó wà látìmọ́lé. Àjọ náà tẹnu mọ́ ọn pé kí orílẹ̀-èdè Eritrea rí i dájú pé “wọn ò fi ẹ̀tọ́ ọmọ ìlú du” àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà.”

Lọ́dún May 2019, Ìgbìmọ̀ Tó Ń Rí sí Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn lábẹ́ ìdarí àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè rọ orílẹ̀-èdè Eritrea pé kó fara mọ́ ẹ̀tọ́ táwọn èèyàn ní láti ṣe ẹ̀sìn tó wù wọ́n kí wọ́n sì gba ohun tó wù wọ́n gbọ́ àti pé kó “tú gbogbo àwọn tó tì mọ́lé torí pé wọ́n ń ṣe ẹ̀sìn tó wù wọ́n sílẹ̀, títí kan àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà.” Àjọ náà tún sọ pé kí orílẹ̀-èdè Eritrea “rí sí i pé òfin fàyè gba ẹni tí ẹ̀rí ọkàn rẹ̀ ò bá gbà láyè láti ṣiṣẹ́ ológun, kí wọ́n sì tún ṣètò iṣẹ́ àṣesìnlú tí kò sí lábẹ́ àwọn ológun táwọn tí kò lè ṣiṣẹ́ ológun máa ṣe.”

Nínú ìròyìn kan tí ìgbìmọ̀ tó ń ṣèwádìí nínú àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè (UN Special Rapporteur) gbé jáde ní May 12, 2021, wọ́n sọ fún ìjọba orílẹ̀-èdè Eritrea pé “gbogbo àwọn tí wọ́n fi sẹ́wọ̀n nítorí ìgbàgbọ́ wọn láì fẹ̀sùn kàn wọ́n tàbí gbọ́ ẹjọ́ wọn ni wọ́n gbọ́dọ̀ dá sílẹ̀ lójú ẹsẹ̀, títí kan àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí iye wọ́n jẹ́ ogún (20),” bákan náà “wọ́n gbọ́dọ̀ ṣàtúnṣe ìpinnu tí wọ́n ṣe pé àwọn máa fi ẹ̀tọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà dù wọ́n torí ẹ̀sìn wọn, wọ́n gbọ́dọ̀ ṣe ohun tí àjọ tó ń rí sí ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn nílẹ̀ Áfíríkà (African Commission on Human and Peoples’ Rights) sọ pé kò yẹ kí wọ́n fi ẹ̀tọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà dù wọ́n, wọ́n sì gbọ́dọ̀ ṣèwádìí lórí ìròyìn kan tó sọ pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan kú sínú àtìmọ́lé.”

Wọ́n Rán Wọn Lọ Sẹ́wọ̀n Gbére

Ẹ̀wọ̀n tí ò lọ́jọ́ ni wọ́n fi èyí tó pọ̀ jù lára àwọn ọkùnrin Ẹlẹ́rìí yìí sí, kò sì jọ pé wọ́n á dá wọn sílẹ̀ títí wọ́n á fi kú tàbí tó bá kù díẹ̀ kí wọ́n kú. Nígbà tí kò ti sí bá a ṣe lè fi ẹsẹ̀ òfin tọ ọ̀rọ̀ tó wà nílẹ̀ yìí, ńṣe ni ká kúkú gbà pé ẹ̀wọ̀n gbére làwọn arákùnrin yìí wà.

Déètì Ìṣẹ̀lẹ̀

  1. April 16, 2024

    Iye àwọn Ẹlẹ́rìí tó wà lẹ́wọ̀n di méjìdínlógójì (38).

  2. February 1, 2021

    Wọ́n dá àwọn Ẹlẹ́rìí mẹ́ta sílẹ̀ lẹ́wọ̀n.

  3. January 29, 2021

    Wọ́n dá Ẹlẹ́rìí kan sílẹ̀ lẹ́wọ̀n.

  4. December 4, 2020

    Wọ́n dá àwọn Ẹlẹ́rìí méjìdínlọ́gbọ̀n (28) sílẹ̀ lẹ́wọ̀n.

  5. March 6, 2018

    Habtemichael Mekonen kú lẹ́ni ọdún mẹ́tàdínlọ́gọ́rin (77), lẹ́yìn tí wọ́n mú un lọ sí Ọgbà Ẹ̀wọ̀n Mai Serwa.

  6. January 3, 2018

    Habtemichael Tesfamariam kú lẹ́ni ọdún mẹ́rìndínlọ́gọ́rin (76), lẹ́yìn tí wọ́n mú un lọ sí Ọgbà Ẹ̀wọ̀n Mai Serwa.

  7. July 2017

    Wọ́n kó gbogbo àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí wọ́n fi sí ẹ̀wọ̀n Meitir lọ sí Ọgbà Ẹ̀wọ̀n Mai Serwa tó wà lẹ́yìn odi ìlú Asmara.

  8. July 25, 2014

    Wọ́n dá ọ̀pọ̀ lára àwọn tí wọ́n mú ní April 14 sílẹ̀, àmọ́ ogún (20) nínú àwọn tí wọ́n mú ní April 27 ló ṣì wà ní àtìmọ́lé.

  9. April 27, 2014

    Wọ́n mú àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà mọ́kànlélọ́gbọ̀n (31) nígbà tí wọ́n ń pàdé pọ̀ láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.

  10. April 14, 2014

    Wọ́n mú àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó lé ní àádọ́rùn-ún (90) nígbà tí wọ́n ń ṣe Ìrántí Ikú Kristi tí wọ́n máa ń ṣe lọ́dọọdún.

  11. August 16, 2012

    Yohannes Haile, ẹni ọdún méjìdínláàádọ́rin (68) kú sẹ́wọ̀n, torí ìyà tí wọ́n fi jẹ ẹ́ ti pọ̀ jù.

  12. July 2011

    Misghina Gebretinsae, ẹni ọdún méjìlélọ́gọ́ta (62) kú sẹ́wọ̀n, torí ìyà tí wọ́n fi jẹ ẹ́ ti pọ̀ jù.

  13. June 28, 2009

    Àwọn agbófinró ya wọ ilé Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan nígbà tí wọ́n ń ṣe ìsìn lọ́wọ́, wọ́n mú gbogbo àwọn Ẹlẹ́rìí mẹ́tàlélógún (23) tó wà níbẹ̀, látorí ọmọ ọdún méjì dórí ẹni ọgọ́rin (80) ọdún.

  14. April 28, 2009

    Àwọn agbófinró kó gbogbo àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí wọ́n fi sátìmọ́lé ní àgọ́ ọlọ́pàá lọ sí Ọgbà Ẹ̀wọ̀n Meitir, àmọ́ wọ́n ṣì fi ẹnì kan sílẹ̀ sí àgọ́ ọlọ́pàá náà.

  15. July 8, 2008

    Àwọn agbófinró bẹ̀rẹ̀ sí í ya wọ ilé àwa Ẹlẹ́rìí àti ibi tá a ti ń ṣiṣẹ́, wọ́n mú mẹ́rìnlélógún (24) lára wa, ọ̀pọ̀ nínú wọn ló sì jẹ́ pé àwọn ló ń gbọ́ bùkátà ìdílé wọn.

  16. May 2002

    Ìjọba fòfin de gbogbo ẹ̀sìn tí ò sí lábẹ́ àwùjọ ẹ̀sìn mẹ́rin tí ìjọba fọwọ́ sí.

  17. October 25, 1994

    Ààrẹ pàṣẹ pé kí wọ́n gbẹ́sẹ̀ lé ẹ̀tọ́ tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní pé a jẹ́ ọmọ ìbílẹ̀ àti àwọn ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn pàtàkì tá a ní gẹ́gẹ́ bí ọmọ ilẹ̀ Eritrea.

  18. September 17, 1994

    Wọ́n fi Paulos Eyasu, Isaac Mogos àti Negede Teklemariam sẹ́wọ̀n láìfi ẹ̀sùn kàn wọ́n tàbí kí wọ́n fojú ba ilé ẹjọ́.

  19. Láàárín ọdún 1940 sí 1949

    Wọ́n dá àwùjọ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà àkọ́kọ́ sílẹ̀ lórílẹ̀-èdè Eritrea.