Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Màá Fọjọ́ Ọ̀la Mi Sin Jèhófà

Màá Fọjọ́ Ọ̀la Mi Sin Jèhófà

Wà á jáde:

  1. 1. Ó máa ń ṣe mí bíi kí n mọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ ọ̀la,

    Bọ́jọ́ ‘la mi ṣe máa rí, àti bọ́la mi ṣe máa dùn.

    Mo ti pinnu pé ohun yòówù kó ṣẹlẹ̀,

    Ìfẹ́ Jèhófà ni màá ṣe títí láé.

    (ÈGBÈ)

    Nínú gbogbo nǹkan tó wà tí mo lè ṣe láyé,

    Ohun tó dára, tí màá fayé mi ṣe,

    Ni kí n máa ṣèpinnu tó dáa, tó máa múnú Jáà dùn.

    Gbogbo ohun tí mo ní, Jèhófà ló fún mi.

    Ọkàn mi balẹ̀; mi ò kábàámọ̀ rárá.

    Mo túbọ̀ ń sún mọ́ Jèhófà lójoojúmọ́ ayé.

  2. 2. Nígbà míì ó lè dà bíi pé kí n ṣe ìpinnu tí kò tọ́,

    Ìpinnu tó lè mú kí n fi Jèhófà Ọlọ́run sílẹ̀.

    Bí mo ṣe ń rántí ìyàsímímọ́ sí Jáà

    Máa mú kí n túbọ̀ nígbàgbọ́ tó jinlẹ̀.

    (ÈGBÈ)

    Nínú gbogbo nǹkan tó wà tí mo lè ṣe láyé,

    Ohun tó dára, tí màá fayé mi ṣe,

    Ni kí n máa ṣèpinnu tó dáa, tó máa múnú Jáà dùn.

    Gbogbo ohun tí mo ní, Jèhófà ló fún mi.

    Ọkàn mi balẹ̀; mi ò kábàámọ̀ rárá.

    Mo túbọ̀ ń sún mọ́ Jèhófà lójoojúmọ́ ayé.

    (ÀSOPỌ̀)

    Mò ń sún mọ́ Jèhófà, òun lọ̀rẹ́ mi.

    Òun ló jẹ́ káyé mi nítumọ̀, kó sì dáa.

    Ìgbésí ayé yìí ló dára jù lọ.

    Ìyẹn lohun tó dáa jù, tó ń fúnni láyọ̀.