Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ọmọbìnrin Mi Ọ̀wọ́n

Ọmọbìnrin Mi Ọ̀wọ́n

Wà á jáde:

  1. 1. Lát’ọmọ jòjòló,

    Ó ń tọ́jú rẹ̀.

    Bó sì ṣe ń dàgbà sí i

    Ló máa ń tọ́ ọ sọ́nà.

    Ó wá bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe

    Ohun tó dára;

    Ó múnú bàbá rẹ̀ dùn.

    (ÈGBÈ)

    Ọmọbìnrin, Ó fẹ́ràn rẹ gan-an.

    Fọkàn balẹ̀, Ó nífẹ̀ẹ́ rẹ.

  2. 2. Ó máa ń hùwà rere

    Lójoojúmọ́.

    Ó máa ń rántí ohun

    Tí bàbá rẹ̀ kọ́ ọ.

    Ọkàn rẹ̀ máa ń balẹ̀,

    Inú rẹ̀ máa ń dùn,

    Tí bàbá rẹ̀ bá sọ fún un pé:

    (ÈGBÈ)

    “Mo fẹ́ràn rẹ, ọmọbìnrin mi.

    Fọkàn balẹ̀, mo nífẹ̀ẹ́ rẹ.”

    (ÀSOPỌ̀)

    Jèhófà máa ń rí

    Gbogbo iṣẹ́ rẹ,

    Ó sì tún máa ń rí

    Bó o ṣe nífẹ̀ẹ́ Rẹ̀.

    Kò ní jẹ́ gbàgbé

    Bó o ṣe ń fayé rẹ

    Ṣe ìfẹ́ Rẹ̀.

    (ÈGBÈ)

    Ọmọbìnrin, Ó fẹ́ràn rẹ gan-an.

    Fọkàn balẹ̀, yóò dúró tì ọ́.

    Ọmọbìnrin, yóò máa ṣìkẹ́ rẹ.

    Fọkàn balẹ̀, Ó fẹ́ ọ.