Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ó Ti Fẹ́rẹ̀ẹ́ Dé Tán

Ó Ti Fẹ́rẹ̀ẹ́ Dé Tán

Wà á jáde:

  1. 1. Ò ń gbọ́ tẹ́yẹ ń kọrin tó dùn,

    Tójú ọjọ́ sì rẹwà.

    Bó o sì ṣe ń lọ lójú ọ̀nà,

    O wá rí i bóòrùn tó yọ ṣe ń tàn.

    Ò ń káwọn òkú káàbọ̀,

    Ó sì ń yà ọ́ lẹ́nu gan-an

    Pó o wà ní Párádísè;

    Ó sì ti fẹ́rẹ̀ẹ́ dé tán.

  2. 2. Ilé kan wà ní ìsàlẹ̀

    Ìkan wà lórí òkè.

    Àwọn kan ń kọrin létídò

    Bí omi tó mọ́ lóló ṣe ń ṣàn.

    Àkókò ìkórè tó.

    Ẹ jẹ́ kí ‘kórè bẹ̀rẹ̀.

    A ti wà láyé tuntun;

    Ó sì ti fẹ́rẹ̀ẹ́ dé tán.

    (ÀSOPỌ̀)

    Ó yẹ ká sọ fáwọn èèyàn

    Nípa ìrètí tá a ní yìí

    Kò sẹ́kún mọ́, kò síkú mọ́.

    Ará dọ̀tun, ayé tuntun.

  3. 3. Inú gbogbo èèyàn ló ń dùn.

    Ò ń gbọ́ òórùn tó tura.

    O wá ń kí àwọn èèyàn rẹ.

    Kò sẹ́ṣẹ̀, èèyàn ti di pípé.

    A dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà

    Torí ‘fẹ tó ní sí wa.

    Ìbùkún ńlá ló sì jẹ́

    Ó sì ti fẹ́rẹ̀ẹ́ dé tán.

    (ÀSOPỌ̀)

    Lójoojúmọ́, mò ń sọ pé:

    “Inú mi dùn pé mo rí ọ!”

    Ṣe ló dà bí àlá sí mi,

    Pé mo lè tún pa dà rí ọ.

  4. 4. Mo ti ń fojú sọ́nà

    Láti rí ayé tuntun.

    Jèhófà ló ṣèlérí yìí.

    Ọ̀rọ̀ rẹ̀ kò ní lọ láìṣẹ.

    Tí n bá rántí ayé tuntun,

    Ó máa ń fọkàn mi balẹ̀.

    Mo ti ń retí ọjọ́ náà,

    Ó sì ti fẹ́rẹ̀ẹ́ dé tán.