Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìpinnu

Ìpinnu

Wà á jáde:

  1. 1. Nǹkan ti tojú sú mi,

    N ko mọ ohun tí màá ṣe.

    Lọ́kàn mi,

    Mò sì ń tanra mi,

    Mo mọ̀ pé mo ti yófẹ̀ẹ́.

  2. 2. Ó máa ń nira

    Láti ṣohun tó tọ́,

    Mi kò fẹ́ kọ́kàn mi tàn mí.

    Kọ́rọ̀ ‘lọ́run tọ́ mi sọ́nà.

  3. 3. Kì í ṣe ohun tó rọrùn ni

    Kí n bọ́ lọ́wọ́ ara kíkú yìí.

    Ó ń mú kí n máa ro èròkerò,

    Àmọ́ Jáá di ọwọ́ mi mú u.

    (ÈGBÈ)

    Ó ní: ‘Mo nífẹ̀ẹ́ rẹ gan-an, mi ò sì fẹ́ kó o sọnù.

    Rí i pé ò ń gbẹ́kẹ̀ lé mi.

    Má bẹ̀rù, màá ràn ẹ́ lọ́wọ́.’

  4. 4. Ohun tá a bá yàn ṣe pàtàkì.

    Ohun tí a gbìn ni a máa ká.

    Lákọ̀ọ́kọ̀, káwọn yíyàn wa

    Jẹ́ láti inú ọkàn tó tọ́.

    Ká ṣọ́ ọkàn wa ńmú ìyè wa.

  5. 5. Àwọn yíyàn tí mo ṣe,

    Mo ti ṣohun t’Ọ́lọ́run fẹ́.

    Bó ti wù kó nira tó,

    Àmọ́ Jáá di ọwọ́ mi mú.