Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Mo Gbẹ́kẹ̀ Lé Ọ

Mo Gbẹ́kẹ̀ Lé Ọ

Wà á jáde:

  1. 1. Bí igi tó fìdí múlẹ̀,

    Ọ̀rọ̀ rẹ wọkàn mi

    Ó wọkàn mi, ara tù mí, ara tù mí pẹ̀sẹ̀.

    Ìṣòro yòówù kó dé,

    Màá lo ọgbọ́n Ọlọ́run,

    Ìgbà gbogbo lọ̀rọ̀ rẹ̀ máa ń kì mí láyà pé:

    (ṢÁÁJÚ ÈGBÈ)

    Ọmọ, má ṣe bẹ̀rù.

    Ti Jèhófà ni kí o máa gbọ́.

    (ÈGBÈ)

    Nígbà ‘ṣòro, ọ̀rọ̀ rẹ

    Ló jẹ́ kí nlè fara dà á.

    Títí ayé mi, èmi yóò máa gbẹ́kẹ̀ lé ọ

  2. 2. Ọ̀pọ̀ nǹkan ló ń ṣẹlẹ̀ láyé,

    Tó lè mú kí n rẹ̀wẹ̀sì,

    Ìwọ lalátìlẹyìn mi; má fi mí lẹ̀.

    Mo gbọ́dọ̀ máa ṣàṣàrò

    Lórí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run

    Kí n lè máa gbọ́ ohùn Baba, bó ṣe ń sọ pé:

    (ṢÁÁJÚ ÈGBÈ)

    Ọmọ, má ṣe bẹ̀rù.

    Ti Jèhófà ni kí o máa gbọ́

    Má jẹ́ kí ‘ṣòro bò ẹ́ mọ́lẹ̀.

    Máa ronú nípa ohun rere.

    (ÈGBÈ)

    Nígbà ‘ṣòro, ọ̀rọ̀ rẹ

    Ló jẹ́ kí nlè fara dà á.

    Títí ayé mi, èmi yóò máa gbẹ́kẹ̀ lé ọ.

    Lé ọ.

    (ṢÁÁJÚ ÈGBÈ)

    Ọmọ, má ṣe bẹ̀rù.

    Ti Jèhófà ni kí o máa gbọ́

    Má jẹ́ kí ‘ṣòro bò ẹ́ mọ́lẹ̀.

    Máa ronú nípa ohun rere.

    (ÈGBÈ)

    Nígbà ‘ṣòro, ọ̀rọ̀ rẹ

    Ló jẹ́ kí n lè fara dà á.

    Títí ayé mi, èmi yóò máa gbẹ́kẹ̀ lé ọ.