Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Mo Gbọ́dọ̀ Ṣe Àyípadà

Mo Gbọ́dọ̀ Ṣe Àyípadà

Wà á jáde:

  1. 1. Ohun kan wà tí mo

    Ti ń rò tipẹ́

    Àwọn àyípadà

    Kan wà tí ó yẹ kí n ṣe

    Ki n túbọ̀ tẹra mọ́ iṣẹ́ Jèhófà.

    Mo gbọ́dọ̀ wá nǹkan ṣe sọ́rọ̀ yìí.

    Kí n lè ṣe púpọ̀ sí i.

    (ÈGBÈ)

    Mo gbọ́dọ̀ ṣàyípadà látòní lọ.

    Lónìí sì ni, kò tún ní dọ̀la mọ́.

    Jèhófà Ọlọ́run, ràn mí lọ́wọ́.

    Mo fẹ́ ṣàyípadà, jọ̀ọ́ ràn mí lọ́wọ́.

  2. 2. Kò ní rọrùn, mo mọ̀,

    Àmọ́ bí mo

    Ṣe ṣe ìpinnu yìí

    Ó jẹ́ k’ọkàn mi balẹ̀.

    Mo fẹ́ gbìyànjú àwọn ohun tuntun.

    Ọ̀pọ̀ nǹkan ló wà tí mo lè ṣe,

    Ṣùgbọ́n mi ò mọ̀ rárá.

    (ÈGBÈ)

    Mo gbọ́dọ̀ ṣàtúnṣe, ó ti di dandan.

    Lójoojúmọ́ ni màá máa sunwọ̀n sí i.

    Jèhófà Ọlọ́run, ràn mí lọ́wọ́.

    Mo fẹ́ ṣàyípadà, jọ̀ọ́ ràn mí lọ́wọ́.

    (ÀSOPỌ̀)

    Mo rántí pé nígbà kan

    Mo rò pé mi ò lè ṣe é

    Tó jẹ́ pé mo máa ń sọ pé,

    Kí ló ń ṣẹlẹ̀ gan-an?

    Ṣùgbọ́n mo ti wá rí i pé

    Tí n bá fẹ́ ṣàṣeyọrí

    Mo gbọ́dọ̀ jẹ́ onígboyà kí n gbẹ́kẹ̀ lé Jáà

    (ÈGBÈ)

    Lójoojúmọ́ ni mo wá ń sunwọ̀n sí i.

    Àyípadà tó dára ní mò ń ṣe.

    Jèhófà, ìwọ lo ràn mí lọ́wọ́,

    Mo sì tún rí ‘bùkún rẹ, mo gbẹ́kẹ̀ lé ọ.

    (ÈGBÈ)

    Mo gbọ́dọ̀ ṣàyípadà látòní lọ.

    Lónìí sì ni kò tún ní dọ̀la mọ́.

    Jèhófà Ọlọ́run, ràn mí lọ́wọ́.

    Mo fẹ́ ṣàyípadà, jọ̀ọ́ ràn mí lọ́wọ́.

    (ÈGBÈ)

    Mo gbọ́dọ̀ ṣàtúnṣe, ó ti di dandan.

    Lójoojúmọ́ ni màá máa sunwọ̀n sí i.

    Jèhófà Ọlọ́run, ràn mí lọ́wọ́.

    Mo fẹ́ ṣàyípadà, jọ̀ọ́ ràn mí lọ́wọ́.

    Mo gbẹ́kẹ̀ lé ọ.