Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

“Tẹ̀ lé Ipa Ọ̀nà Áàjò Àlejò”

“Tẹ̀ lé Ipa Ọ̀nà Áàjò Àlejò”

Wà á jáde:

  1. 1. O lè jẹ́ oúnjẹ tàbóhun mímu,

    Eré ‘nàjú tàbí ‘jíròrò.

    Jèhófà lẹni tó fún wa láǹfààní yìí o.

    Káwa nàá lè ṣe bẹ̀ẹ​—

    (ÈGBÈ)

    “Tẹ̀lé ‘pa ọ̀nà áájò àlejò.”

    Fara wé Ọlọ́run.

    Má yẹnì kankan sọ́tọ̀ tó bá ń ṣe é.

    Ohun tífẹ̀ẹ́ jẹ́ gan-an nìyẹn.

  2. 2. Bàbá wa ọ̀run ló pèsè ibùgbé fún wa o.

    Àmọ́, ṣé a lè ṣàjọpín rẹ̀ pẹ̀láwọn míì?

    Ká lè rí ayọ̀ tó wà nínú ká máa fúnni!

    Ìwà Kristẹni nìyẹn.

    (ÈGBÈ)

    “Tẹ̀lé ‘pa ọ̀nà áájò àlejò.”

    Fara wé Ọlọ́run.

    Má yẹnì kankan sọ́tọ̀ tó bá ń ṣe e.

    Ohun tífẹ̀ẹ́ jẹ́ gan-an nìyẹn.

    (ÀSOPỌ̀)

    Àwọn kan ò lóhun táwa ní.

    Ká fún wọn lára ẹ̀.

    Nígbà àjálù, wọ́n pàdánù.

    Ṣé a ma bìkítà?

    Ṣá a lè gbà wọ́n sílé wa, ká sì bójútó wọn?

    Ká ràn wọ́n lọ́wọ́.

    (ÈGBÈ)

    “Tẹ̀lé ‘pa ọ̀nà áájò àlejò.”

    Fara wé Ọlọ́run.

    Má yẹnì kankan sọ́tọ̀ tó bá ń ṣe e.

    Ohun tífẹ̀ẹ́ jẹ́ gan-an nìyẹn.

    Ohun tífẹ̀ẹ́ jẹ́ gan-an nìyẹn.

    Ohun tífẹ̀ẹ́ jẹ́ gan-an nìyẹn.