Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Máa Bá a Lọ

Máa Bá a Lọ

Wà á jáde:

  1. 1. Ìrísí ayé ń yí pa dà;

    Mo gbọ́dọ̀ máa bá a lọ.

    Ràn mí lọ́wọ́ kí ń máa bá a lọ

    Bá a ṣe ń sáré náà.

    Tá a bá pàdé àtakò

    Tí wọn kò fẹ́ gbọ́ wa,

    Ká tẹ̀lọ́nà tuntun tó dáa,

    Ká wẹ́ni tó máa gbọ́.

    (ÈGBÈ)

    Ká máa bá a lọ.

    Di ọwọ́ mi mú.

    Ká lè jọ ṣẹ́gun.

    Ká máa bá a lọ, láìrẹ̀wẹ̀sì.

    Ká rókun gbà

    Ká baa lè ṣáṣeyọrí.

    Máa bá a lọ.

  2. 2. Èrò rere ni mo ní

    Lójoojúmọ́ ayé,

    Kìí fìgbà gbogbo rọrùn

    Láti ṣohun tó yẹ.

    Bíṣòro bá dìde,

    Bí nǹkàn bá fẹ́ yíwọ́.

    A ní ọ̀pọ̀ àrànṣe gan-an ni,

    Kẹ́sẹ̀ wa lè múlẹ̀.

    (ÈGBÈ)

    Ká máa bá a lọ.

    Di ọwọ́ mi mú.

    Ká lè jọ ṣẹ́gun.

    Ká máa bá a lọ, láìrẹ̀wẹ̀sì.

    Ka rókun gbà,

    Ká baa lè ṣáṣeyọrí.

    Máa bá a lọ.

    (ÀSOPỌ̀)

    Ìsapá ń mú ‘bùkún wá

    Bá a bá fi kún ‘sapá wa.

    Gba ìtọ́ni, wàá rí i

    Wàá múnú Ọlọ́run dùn.

    A ní ‘rètí;

    Tó dájú.

    Tá ò lè pá mọ́ra​—

    Párádísè, kò sẹ́kún.

    Mo ń fayọ̀ sapá

    (ÈGBÈ)

    Kí ń máa bá a lọ.

    Di ọwọ́ mi mú.

    Ká lè jọ ṣẹ́gun.

    Ká máa bá a lọ, láìrẹ̀wẹ̀sì.

    Ká rókun gbà,

    Ká baa lè ṣáṣeyọrí.

    Máa bá a lọ.

    Ká máa bá a lọ.

    Di ọwọ́ mi mú.

    Ká lè jọ ṣẹ́gun.

    Ká máa bá a lọ, láìrẹ̀wẹ̀sì.

    Ká rókun gbà,

    Ká baa lè ṣáṣeyọrí.

    Máa bá a lọ.

    Ká máa bá a lọ.