Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Fojú Inú Wò Ó

Fojú Inú Wò Ó

Wà á jáde:

  1. 1. Ayé yìí mà le, ó sú wa.

    Ọ̀wọ́n oúnjẹ ti gbòde kan.

    Mo dijú mi, mo sì wá ri

    Gbogbo ‘lérí ti dìmúṣẹ.

    (ÈGBÈ)

    Wògbà tí ìrora kò ní sí mọ́,

    Táyé á dùn tá ò ní darúgbó mọ́.

    Wògbà tígbe ayọ̀ á gbẹnu wa pé,

    “O ṣe, o ṣe fáyé tuntun tó pèsè fún wa!”

  2. 2. Mi ò gbọ́rọ̀ rí láyé mi,

    Ọjọ́ ogbó, ń mójú ṣú.

    Etí mi ṣì máa gbọ́ orin.

    Mo ṣì máa rí ìgbà ọ̀tun.

    (ÈGBÈ)

    Wògbà tí ìrora kò ní sí mọ́,

    Táyé á dùn, tá ò ní darúgbó mọ́.

    Wògbà tígbe ayọ̀ á gbẹnu wa pé,

    “O ṣe, o ṣe, fáyé tuntun tó pèsè fún wa!”

    (ÀSOPỌ̀)

    Nǹkan lè má rí bí mo ṣe fẹ́.

    Àmọ́ láìpẹ́, màá lè máa sáré!

    (ÈGBÈ)

    Wògbà tí ìrora kò ní sí mọ́,

    Táyé á dùn, tá ò ní darúgbó mọ́.

    Wògbà tíjó ayọ̀ máa gba ayé yìí kan!

    Ayé yìí á mà dùn bí oyin.

    (ÈGBÈ)

    Wògbà tí ìrora kò ní sí mọ́,

    Táyé á dùn, tá ò ní darúgbó mọ́.

    Wògbà tígbe ayọ̀ á gbẹnu wa pé,

    “O ṣe, o ṣe fáyé tuntun tó pèsè fún wa!”