Isinsìnyí Ló Yẹ Ká Túbọ̀ Wàásù
Wà á Jáde:
1. Ó ti wá ṣe kedere sí wa
Pé ayé yìí ń bàjẹ́ sí i,
Ó yẹ ká tẹra mọ́ṣẹ́ ‘wàásù
Bí òpin ti ń sún mọ́lé.
Àǹfààní ńlá léyìí jẹ́ fún wa
Láti sọ̀rọ̀ Jèhófà,
Àtàwọn ‘bùkún ‘jọba rẹ̀
Èyí la ń wàásù fáyé.
(ÈGBÈ)
Ó yẹ ká fi
Ìtara wàásù.
A kò ní bẹ̀rù, kò sì ní rẹ̀ wá.
Ìsínyi ló yẹ
Ká túbọ̀ wàásù,
Àkókò òpin la wà báyìí.
2. Àkókò tó dára jù nìyí
Láti wàásù ‘jọba náà.
Torí náà ká sa gbogbo ‘pa wa
Ká sọ fún gbogbo èèyàn.
Tá a bá ń rántí ohun tá a ti ṣe
Lẹ́nu ‘ṣẹ́ náà láyé yìí,
A mọ̀ pé a ti ṣèfẹ́ Jáà
Gbogbo ipá wa la sà.
(ÈGBÈ)
Ó yẹ ká fi
Ìtara wàásù.
A kò ní bẹ̀rù, kò sì ní rẹ̀ wá.
Ìsínyi ló yẹ
Ká túbọ̀ wàásù,
Àkókò òpin la wà báyìí.
(ÀSOPỌ̀)
Gbogbo wa pátá là ń ṣiṣẹ́ yìí
A ó máa lo gbogbo okun wa.
Láìpẹ́ ayé yìí máa dópin,
Ayé tuntun ti dé tán.
(ÈGBÈ)
Ó yẹ ká fi
Ìtara wàásù.
A kò ní bẹ̀rù, kò sì ní rẹ̀ wá.
Ìsínyi ló yẹ
Ká túbọ̀ wàásù,
Àkókò òpin la wà báyìí.