Ọjọ́ Kọ̀ọ̀kan Ní Wàhálà Tiẹ̀
Wà á jáde:
1. Mo nígbàgbọ́ pé lọ́jọ́ kan, ayé ṣì máa dáa,
Ó dá mi lójú pé láìpẹ́, Párádísè máa dé.
Àmọ́ tí ìṣòro bá dé,
Kì í rọrùn láti rántí pé,
Ọlọ́run mi nífẹ̀ẹ́ mi gan-an, kò sì ní fi mí sílẹ̀.
Jèhófà wà pẹ̀lú mi.
(ÈGBÈ)
Bí ‘ṣòro bá dé, àdúrà
Àtọkànwá tí mo bá gbà
Ló máa ń fọkàn mi balẹ̀.
Baba ọ̀run wà pẹ̀lú mi.
Ọ̀rọ̀ rẹ̀ ń tù mí nínú
Mo tún ní ọ̀rẹ́ tòótọ́.
Gbogbo ọjọ́ ló ní wàhálà tiẹ̀.
Wàhálà ọjọ́ kan ti tó;
Mi ò kì í da tọ̀la mọ́ tòní.
Ìyẹn máa ń jẹ́ kí
Ọkàn mi balẹ̀.
2. Mo nífẹ̀ẹ́ rẹ gan-an ọ̀rẹ́ mi,
Gba ìmọ̀ràn yìí.
Bíṣòro tiẹ̀ pọ̀ láyé,
Má jẹ́ kó gbà ẹ́ lọ́kàn.
Wo’ore ńlá t’Ọlọ́run ṣe.
Tó fún wa lọ́mọ rẹ̀ ọ̀wọ́n.
Ṣó o rí i pé ó nífẹ̀ẹ́ wa gan-an?
Fọkàn balẹ̀, ṣáà gbẹ́kẹ̀ lé e.
Jọ̀ọ́, má sọ̀rètí nù.
(ÈGBÈ)
Gbàdúrà látọkàn.
T’ánìíyàn bá gbà ẹ́ lọ́kàn,
Ṣáà gbọ́kàn lé Jèhófà.
Kì í dá wa dá ìṣòro wa.
Ọ̀rọ̀ rẹ̀ ń tù wá nínú
A tún ní ọ̀rẹ́ tòótọ́.
Gbogbo ọjọ́ ló ní wàhálà tiẹ̀.
Wàhálà ọjọ́ kan tó;
Ká má ṣe da tọ̀la mọ́ tòní;
Ìyẹn máa jẹ́ kí
Ọkàn wa balẹ̀.
(ÈGBÈ)
Gbàdúrà látọkàn.
Tánìíyàn bá gbà ẹ́ lọ́kàn,
Ṣáà gbọ́kàn lé Jèhófà.
Kì í dá wa dá ìṣòro wa.
Ọ̀rọ̀ rẹ̀ ń tù wá nínú
A tún ní ọ̀rẹ́ tòótọ́.
Gbogbo ọjọ́ ló ní wàhálà tiẹ̀.
Wàhálà ọjọ́ kan tó;
Má ṣe da tọ̀la mọ́ tòní;
Ìyẹn máa jẹ́ kí
Ọkàn wa balẹ̀—
Ọkàn wa balẹ̀.