Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìfẹ́ Kì Í Yẹ̀

Ìfẹ́ Kì Í Yẹ̀

(1 Kọ́ríńtì 13:⁠8)

Wà á jáde:

  1. 1. Nínú ayé yìí;

    Ìfẹ́ ṣọ̀wọ́n púpọ̀,

    Àmọ́ ìfẹ́ tiwa jinlẹ̀!

    Àwọn olóòótọ́

    Èèyàn ló yí wa ká,

    A kì í fara wé ayé yìí.

    (ṢÁÁJÚ ÈGBÈ)

    Ìfẹ́ kò ní yẹ̀ rárá.

    Jèhófà ló sọ bẹ́ẹ̀.

    (ÈGBÈ)

    Ìfẹ́ kì í yẹ̀ láé!

    Ọ̀dọ̀ Jèhófà ni

    Ìfẹ́ ti ń wá.

    Ìfẹ́ kì í yẹ̀ láé

    Ó ń mú káyé wa dùn.

    Ìfẹ́ wa tó jinlẹ̀,

    Kó má ṣe yẹ̀ rárá.

    Ìfẹ́ kì í yẹ̀.

  2. 2. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé

    Ìṣòro pọ̀ láyé

    Ó sì lè mú ká rẹ̀wẹ̀sì,

    A máa láyọ̀ gan-an

    Tí a bá ń ṣe oore

    Tá a sì ń tu àwọn míì nínú.

    (ṢÁÁJÚ ÈGBÈ)

    Ìfẹ́ kò ní yẹ̀ rárá.

    Jèhófà ló sọ bẹ́ẹ̀.

    (ÈGBÈ)

    Ìfẹ́ kì í yẹ̀ láé!

    Ọ̀dọ̀ Jèhófà ni

    Ìfẹ́ ti ń wá.

    Ìfẹ́ kì í yẹ̀ láé

    Ó ń mú káyé wa dùn.

    Ìfẹ́ wa tó jinlẹ̀,

    Kó má ṣe yẹ̀ rárá.

    (ÈGBÈ)

    Ìfẹ́ kì í yẹ̀ láé!

    Ọ̀dọ̀ Jèhófà ni

    Ìfẹ́ ti ń wá.

    Ìfẹ́ kì í yẹ̀ láé

    Ó ń mú káyé wa dùn.

    Ìfẹ́ wa tó jinlẹ̀,

    Kó má ṣe yẹ̀ rá-rá.

    Ìfẹ́ kì í yẹ̀,

    Ìfẹ́ kì í yẹ̀,

    Ìfẹ́ kì í yẹ̀.