Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ayé Tuntun

Ayé Tuntun

Wà á jáde:

  1. 1. Ronú nípa báyé ṣe máa rí.

    Nígbà táyé tuntun tá à ń retí bá dé.

    Àwọn ‘mọdé ń ṣeré

    Kò sí ohun tó ń fa ìbẹ̀rù mọ́.

    Àwọn tó máa gbénú ayé tuntun

    Làwọn onígbọràn, èèyàn àlàáfíà.

    Títí ayérayé ni.

    Àlàáfíà tí a ti ń retí dé!

    Jáà yóò ṣìkẹ́ wa

    Lábẹ́ ìjọba Ọmọ rẹ̀,

    Nínú ayé tuntun.

    (ÈGBÈ)

    Ìrètí ń múnú wa dùn.

    Ìrètí máa ń fọkàn wa balẹ̀.

    Ṣe ni ìrètí wa ń tàn bí oòrùn.

    À ń retí ìbùkún

    Nínú ayé tuntun.

  2. 2. Tí a bá dénú ayé tuntun

    Lórí òkè, lórí ilẹ̀, níbi odò.

    Ìtura yóò gbayé.

    Ṣàdédé lo rẹ́nì kan tó ń bọ̀,

    Ọjọ́ pẹ́ tẹ́ ẹ ti ríra.

    Ẹ̀yin méjèèjì wá dì mọ́ra

    Ẹ jọ ń sunkún ayọ̀

    O mọ̀ pé onítọ̀hún ti kú tẹ́lẹ̀.

    Jèhófà ti jí

    Ẹni yẹn dìde!

    Sínú ayé tuntun.

    (ÈGBÈ)

    Ìrètí ń múnú wa dùn.

    Ìrètí máa ń fọkàn wa balẹ̀.

    Ṣe ni ìrètí wa ń tàn bí oòrùn.

    À ń retí ìbùkún

    Nínú ayé tuntun.

    (ÀSOPỌ̀)

    Ọ̀rọ̀ tí Jèhófà sọ

    Kò ní lọ láìṣẹ, ó di dandan.

    Gbogbo ìfẹ́ Jèhófà ni

    Ó máa ṣẹ pátápátá ní ayé.

    (ÈGBÈ)

    Ìrètí ń múnú wa dùn.

    Ìrètí máa ń fọkàn wa balẹ̀

    Ṣe ni ìrètí wa ń tàn bí oòrùn.

    À ń retí ìbùkún

    Nínú ayé tuntun,

    Nínú ayé tuntun,

    Nínú ayé tuntun,

    Nínú ayé tuntun.