Sá Eré Náà Dé Òpin
Wà á jáde:
1. Gbogbo wa
Ni à ń sáré kan.
Eré ìje ìyè;
Má jẹ́ kó sú ẹ.
Kó o lè túbọ̀ lókun,
Máa ka Bíbélì.
Má jẹ́ káyé yìí tàn ẹ́;
Jọ̀ọ́, má ṣe dẹwọ́.
(ÈGBÈ)
Má ṣe wo ọ̀tún
Tàbósì.
Má ṣe wẹ̀yìn wò.
Ṣáà máa sáré, tẹsẹ̀ mọ́rìn.
Ọ̀pọ̀ ìbùkún ló ń
Dúró dè ẹ́,
Tẹra mọ́ ọn,
Torí àkókò ń lọ.
Jọ̀ọ́, má fàkókò ṣòfò.
Ṣáà máa sáré,
Tẹsẹ̀ mọ́rìn.
2. Kò ní pẹ́ mọ́
Tá a máa sáré náà dópin.
A máa ríbùkún gbà
Tá a bá fara dà á.
(ÈGBÈ)
Má ṣe wo ọ̀tún
Tàbósì.
Má ṣe wẹ̀yìn wò.
Ṣáà máa sáré, tẹsẹ̀ mọ́rìn.
Ọ̀pọ̀ ìbùkún ló ń
Dúró dè ẹ́,
Tẹra mọ́ ọn,
Torí àkókò ń lọ.
Jọ̀ọ́, má fàkókò ṣòfò.
Ṣáà máa sáré,
Tẹsẹ̀ mọ́rìn.
Má jẹ́ kó sú ẹ.
(ÀSOPỌ̀)
Ọ̀pọ̀ nǹkan ló wà tó lè dán ẹ wò.
Àmọ́ má ṣe gbà rárá,
Má ṣe jẹ́ kí wọ́n tàn ẹ́.
Jọ̀ọ́, tẹsẹ̀ mọ́rìn;
Má wẹ̀yìn.
Máa sáré; tẹra mọ́ ọn.
(ÈGBÈ)
Má ṣe wo ọ̀tún
Tàbósì.
Má ṣe wẹ̀yìn wò.
Ṣáà máa sáré, tẹsẹ̀ mọ́rìn.
Ọ̀pọ̀ ìbùkún ló ń
Dùró dè ẹ́, tẹra mọ́ ọn,
Torí àkókò ń lọ.
Jọ̀ọ́, má fàkókò ṣòfò.
Ṣáà máa sáré,
Tẹsẹ̀ mọ́rìn.
Má ṣe wẹ̀yìn wò;
Má ṣe wẹ̀yìn wò.
Pọkàn pọ̀, tẹsẹ̀ mọ́rìn.
Má ṣe jẹ́ kó sú ẹ.
Tẹra mọ́ ọn.
Ṣáà máa sáré.
Má wẹ̀yìn;
Sáré náà dópin!