Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ó Dá Mi Lójú

Ó Dá Mi Lójú

Wà á Jáde:

  1. 1. Bó o ṣe ń gbàdúrà.

    Tó o sì tún ń wàásù,

    Ohun t’Ọlọ́run fẹ́ lò ń ṣe yẹn.

    Torí náà, ìṣòro yòówù tó o bá ní,

    Mọ̀ pé Jèhófà ń rí gbogbo ẹ̀.

    (ṢÁÁJÚ ÈGBÈ)

    Tí àwọn aláṣẹ bá ń fìyà jẹ ọ́,

    Jèhófà ń rí ọ.

    Ìgbàgbọ́ tó o ní ń fún wa lókun,

    A wà lẹ́yìn rẹ.

    (ÈGBÈ)

    ‘Ó dá mi lójú

    Kò síṣòro náà tó lè dènà ìfẹ́ Jèhófà sí wa.

    ‘Ó dá mi lójú

    Pé kò sóhun tó lè yà wá nínú ìfẹ́ Ọlọ́run.’

    Ṣáà fọkàn balẹ̀;

    Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ rẹ.

  2. 2. O ti ń fìgboyà

    Jọ́sìn Jèhófà,

    O sì gbára lé e nígbà ìṣòro.

    Torí náà, tí inúnibíni bá dé,

    Mọ̀ pé Jèhófà yóò dì ọ́ mú.

    (ṢÁÁJÚ ÈGBÈ)

    Tí àwọn aláṣẹ bá ń fìyà jẹ ọ́,

    Jèhófà ń rí ọ.

    Ìgbàgbọ́ tó o ní ń fún wa lókun;

    A wà lẹ́yìn rẹ.

    (ÈGBÈ)

    ‘Ó dá mi lójú

    Kò síṣòro náà tó lè dènà ìfẹ́ Jèhófà sí wa.

    ‘Ó dá mi lójú

    Pé kò sóhun tó lè yà wá nínú ìfẹ́ Ọlọ́run.’

    Ṣáà fọkàn balẹ̀;

    Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ rẹ.

    Ó nífẹ̀ẹ́ rẹ.

    (ÀSOPỌ̀)

    Bó o tiẹ̀ ń jìyà torí pé ò ń ṣèfẹ́ Ọlọ́run​—

    Jọ̀ọ́, má ṣe bẹ̀rù.

    Torí pé níkẹyìn, ‘wàá di aṣẹ́gun’, wàá sì láyọ̀​—

    Óò, wàá láyọ̀ gan-an.

    (ÈGBÈ)

    ‘Ó dá mi lójú

    Kò síṣòro náà tó lè dènà ìfẹ́ Jèhófà sí wa.

    ‘Ó dá mi lójú

    Pé kò sóhun tó lè yà wá nínú ìfẹ́ Ọlọ́run.’

    Ó dá mi lójú

    Kò síṣòro náà tó lè dènà ìfẹ́ Jèhófà sí wa.

    ‘Ó dá mi lójú

    Pé kò sóhun tó lè yà wá nínú ìfẹ́ Ọlọ́run.’

    Ṣáà fọkàn balẹ̀;

    Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ rẹ.