Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Máa Dárí Jini Látọkàn

Máa Dárí Jini Látọkàn

Wà á jáde:

  1. 1. Ìgbà kan wà tẹ́nì kan ṣẹ̀ mí.

    Tí mo bá rántí, ó máa ń dùn mí.

    Ó máa ń bà mí nínú jẹ́ gan-an.

    Mi ò gbàgbé ẹ̀ṣẹ̀ tó ṣẹ̀ mí.

    Mo mọ̀ pé ó yẹ kí n ti dárí jì í.

    Àmọ́ kò rọrùn fún mi rárá.

    (ṢÁÁJÚ ÈGBÈ)

    Ohun tó ṣẹlẹ̀ kì í ṣe ẹ̀bi mi.

    Jèhófà náà rí i pé ọ̀rọ̀ yẹn dùn mí.

    Mo wá bẹ Jèhófà pé:

    (ÈGBÈ)

    “Jọ̀ọ́, ràn mí lọ́wọ́.

    Jẹ́ kọ́rọ̀ yìí tán nínú mi.

    Baba, jẹ́ kí n lè dárí jì í.

    Jẹ́ kí n ṣohun tó o fẹ́.

    Jèhófà mo mọ̀ pé

    Tí mo bá ṣẹ̀ ọ́, ò ń dárí jì mí.

    Baba, jẹ́ kí n lè dárí jì í.

    Jẹ́ kí n ṣohun tó o fẹ́;

    Kí n dárí jì í.”

  2. 2. Mò ń gbìyànjú kí n má bàa rántí,

    Àmọ́ ó ṣì wà lọ́kàn mi.

    Ó yẹ kí n gbàgbé ọ̀rọ̀ àná.

    Mo wá rí i pé inú mi kì í dùn.

    Tí mo bá ń di àwọn èèyàn sínú,

    Ìṣòro mi á máa pọ̀ sí i.

    (ṢÁÁJÚ ÈGBÈ)

    Ohun tó ṣẹlẹ̀ kì í ṣe ẹ̀bi mi.

    Jèhófà náà rí i pé ọ̀rọ̀ yẹn dùn mí.

    Mo wá bẹ Jèhófà pé:

    (ÈGBÈ)

    “Jọ̀ọ́, ràn mí lọ́wọ́.

    Jẹ́ kọ́rọ̀ yìí tán nínú mi.

    Baba, jẹ́ kí n lè dárí jì í.

    Jẹ́ kí n ṣohun tó o fẹ́.

    Jèhófà mo mọ̀ pé

    Tí mo bá ṣẹ̀ ọ́, ò ń dárí jì mí.

    Baba, jẹ́ kí n lè dárí jì í.

    Jẹ́ kí n ṣohun tó o fẹ́;

    Kí n dárí jì í.

    Ràn mí lọ́wọ́

    Kí n dárí jì í;

    Kí n dárí jì í.”