Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

A Ò Ní Wẹ̀yìn

A Ò Ní Wẹ̀yìn

Wà á jáde:

  1. 1. Nígbà tí mo kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́

    Nípa Jèhófà àti ayé tuntun,

    Ó wọ̀ mí lọ́kàn, ó múnú mi dùn.

    Àmọ́ kò rọrùn láti ṣohun tó tọ́.

    (ṢÁÁJÚ ÈGBÈ)

    Mo ti pinnu pé

    Ohun tó tọ́ ni màá ṣe.

    (ÈGBÈ)

    Mo fẹ́ kígbàgbọ́ mi máa lágbára sí i

    Kí n lè máa ṣèfẹ́ Ọlọ́run.

    Màá fi Bíbélì ṣe atọ́nà mi,

    Màá sì tẹra mọ́ àdúrà.

    Mo gbẹ́kẹ̀ lé Bàbá; mi ò ní wẹ̀yìn.

  2. 2. Àwa ti pinnu lọ́kàn wa pé,

    Ìfẹ́ Jèhófà la ó fayé wa ṣe.

    Àmọ́ aráyé ń ṣe bó ṣe wù wọ́n;

    Àfi ká máa ṣọ́ra ká má dà bíi wọn.

    (ṢÁÁJÚ ÈGBÈ)

    A mọ òtítọ́,

    A sì ní ìrètí.

    (ÈGBÈ)

    Ká jẹ́ kígbàgbọ́ wa máa lágbára sí i

    Ká lè máa ṣèfẹ́ Ọlọ́run.

    Ká fi Bíbélì ṣe atọ́nà wa,

    Ká sì tẹra mọ́ àdúrà.

    A gbẹ́kẹ̀ lé Bàbá; a ò ní wẹ̀yìn.

    (ÈGBÈ)

    Ká jẹ́ kígbàgbọ́ wa máa lágbára sí i

    Ká lè máa ṣèfẹ́ Ọlọ́run.

    Ká fi Bíbélì ṣe atọ́nà wa,

    Ká sì tẹra mọ́ àdúrà.

    A gbẹ́kẹ̀ lé Bàbá; a ò ní wẹ̀yìn.

    A ò ní wẹ̀yìn;

    A ò ní wẹ̀yìn!