Orísun Ayọ̀ Wa
Wà á jáde:
1. Àwọn ìràwọ̀ lọ salalu lójú ọ̀run.
Bójúmọ́ bá sì ti wá mọ́,
Oòrùn á tún yọ.
O dá ilẹ̀ àti omi,
Gbogbo iṣẹ́ ọwọ́ rẹ ló ń mú inú rẹ dùn.
(ÈGBÈ)
Inú wa ń dùn sí iṣẹ́ rẹ,
A sì ń wàásù ìhìn rere,
Ayé tuntun ti dé tán.
A mọ̀ pé o nífẹ̀ẹ́ wa gan-an,
Èyí ló ń múnú wa dùn jù.
Jèhófà, Ọlọ́run wa
Lorísun ayọ̀ wa.
2. Jèhófà, ọ̀pọ̀ nǹkan lò ń ṣe
Tó ń fún wa láyọ̀.
A lè gbọ́ràn, a lè ríran
A tún lè ronú.
Èrò rere lo ní sí wa,
O fẹ́ ká wà láàyè láéláé,
O fẹ́ ká láyọ̀.
(ÈGBÈ)
Inú wa ń dùn sí iṣẹ́ rẹ,
A sì ń wàásù ìhìn rere,
Ayé tuntun ti dé tán.
A mọ̀ pé o nífẹ̀ẹ́ wa gan-an,
Èyí ló ń múnú wa dùn jù.
Jèhófà, Ọlọ́run wa
Lorísun ayọ̀ wa.
(ÀSOPỌ̀)
Ikú ìrúbọ Ọmọ rẹ
Ló ń jẹ́ ká láyọ̀.
Ẹ̀bùn yìí ló jẹ́ ká ní ìrètí
Ayọ̀ tí kò lópin.
(ÈGBÈ)
Inú wa ń dùn sí iṣẹ́ rẹ
A sì ń wàásù ìhìn rere,
Ayé tuntun ti dé tán.
A mọ̀ pé o nífẹ̀ẹ́ wa gan-an
Èyí ló ń múnú wa dùn jù.
Jèhófà, Ọlọ́run wa
Lorísun ayọ̀ wa.
(ÈGBÈ)
Inú wa ń dùn sí iṣẹ́ rẹ
A sì ń wàásù ìhìn rere,
Ayé tuntun ti dé tán.
A mọ̀ pé o nífẹ̀ẹ́ wa gan-an
Èyí ló ń múnú wa dùn jù.
Jèhófà, Ọlọ́run wa
Lorísun ayọ̀ wa.
(Tún wo Sm. 37:4; 1 Kọ́r. 15:28.)