Máa Ṣọ́ Ohun Tí Ò Ń Rò
Wà á jáde:
1. Ohun tó daa ni mo fẹ́ ṣe;
Èrò tó dáa ló yẹ kí n ní.
Bí mo ṣe ń gbìyànjú tó,
Kò rọrùn fún mi rárá.
Jèhófà jọ̀ọ́, ràn mí lọ́wọ́
Kí n lè máa ṣohun táá múnú rẹ dùn.
Bíbélì sọ fún mi pé
Ohun tó yẹ kí n ṣe ni pé:
(ÈGBÈ)
Kí n ṣọ́ ohun tí mò ń rò lọ́kàn mi;
Kí n yẹra fún èròkerò,
Kí n sì ṣohun táá fún mi láyọ̀.
Yóò jẹ́ kí n lè máa ṣe ohun tó tọ́.
2. Ó wù mí gan-an kí n ṣèfẹ́ rẹ̀.
Àmọ́ nígbà míì, ó máa ń ṣòro.
Nǹkan máa ń tojú sú mi,
Ó sì máa ń tán mi lókun.
Síbẹ̀, mo máa ń sapá láti
Jáde lọ wàásù fún àwọn èèyàn.
Ó ń jẹ́ kínú mi máa dùn,
Ó sì ń jẹ́ kọ́kàn mi balẹ̀.
(ÈGBÈ)
Màá ṣọ́ ohun tí mò ń rò lọ́kàn mi;
Màá yẹra fún èròkerò,
Màá sì ṣohun táá fún mi láyọ̀.
Yóò jẹ́ kí n lè máa ṣe ohun tó tọ́;
Ohun tó tọ́.
(ÀSOPỌ̀)
Téròkerò bá fẹ́ máa wá,
Màá tètè gbé e kúrò lọ́kàn.
Ó dájú pé bí mo ṣe ń sapá,
Jèhófà ń rí mi, ó máa ràn mí lọ́wọ́.
Ó máa ràn mí lọ́wọ́.
(ÈGBÈ)
Màá ṣọ́ ohun tí mò ń rò lọ́kàn mi;
Màá yẹra fún èròkerò,
Màá sì ṣohun táá fún mi láyọ̀.
Yóò jẹ́ kí n lè máa ṣe ohun tó tọ́.