Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

“Kò Ní Pẹ́ Rárá!” (Orin Àpéjọ Agbègbè 2023)

“Kò Ní Pẹ́ Rárá!” (Orin Àpéjọ Agbègbè 2023)

(Hábákúkù 2:3)

Wà á jáde:

  1. 1. Àwòyanu ni, iṣẹ́ rẹ Baba,

    Torí pó o fẹ́ wa, lo ṣe dá gbogbo wọn.

    Ṣụ̀gbọ́n ìṣòro ti pọ̀ jù láyé; a mọ̀ pé láìpẹ́,

    Wàá yanjú gbogbo rẹ̀.

    (ÈGBÈ)

    Jèhófà Baba wa, jọ̀wọ́ gbọ́ ẹ̀bẹ̀ wa.

    Jọ̀ọ́, má ṣe jẹ́ kó sú wa.

    À ń retí ọjọ́ náà, táyé tuntun máa dé.

    Jọ̀ọ́, jẹ́ ká lè ní sùúrù.

    Ká fìwà jọ ọ́.

  2. 2. Téèyàn wa bá kú, ó máa ń dùn wá gan-an.

    O ṣèlérí pé wàá jí òkú dìde.

    A mọ̀ dájú pé ọ̀rọ̀ rẹ máa ṣẹ.

    Alèwílèṣe, jọ̀ọ́ jẹ́ ká ní sùúrù.

    (ÈGBÈ)

    Jèhófà Baba wa, jọ̀wọ́ gbọ́ ẹ̀bẹ̀ wa.

    Jọ̀ọ́, má ṣe jẹ́ kó sú wa.

    À ń retí ọjọ́ náà, táyé tuntun máa dé.

    Jọ̀ọ́, jẹ́ ká lè ní sùúrù.

    Ká fìwà jọ ọ́.

  3. 3. Ikú ẹlẹ́ṣẹ̀ kò wù ọ́ Baba.

    O fẹ́ kí gbogbo èèyàn wá dọ̀rẹ̀ẹ́ rẹ.

    O rán wa jáde, ká wàásù fún wọn,

    Káwa àtàwọn lè wà láàyè láéláé.

    (ÈGBÈ)

    Jèhófà Baba wa, jọ̀wọ́ gbọ́ ẹ̀bẹ̀ wa.

    Jọ̀ọ́, má ṣe jẹ́ kó sú wa.

    À ń retí ọjọ́ náà, táyé tuntun máa dé.

    Jọ̀ọ́, jẹ́ ká lè ní sùúrù.

    Ká fìwà jọ ọ́.

    Jọ̀ọ́, jẹ́ ká lè ní sùúrù!

(Tún wo Kól. 1:11.)