Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Báwo Ni Màá Ṣe Fara Dà Á Ní Báyìí Tí Dádì Ti Já Wa Sílẹ̀?

Báwo Ni Màá Ṣe Fara Dà Á Ní Báyìí Tí Dádì Ti Já Wa Sílẹ̀?

Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . .

Báwo Ni Màá Ṣe Fara Dà Á Ní Báyìí Tí Dádì Ti Já Wa Sílẹ̀?

“Dídàgbà láìsí dádì mi nítòsí ṣòro fún mi. Mo ń fẹ́ àfiyèsí díẹ̀.”—Henry. a

ỌMỌ ọdún mẹ́tàlá péré ni Joan nígbà tí bàbá rẹ̀ fi ilé sílẹ̀. Níwọ̀n bí ọtí àmupara ti jàrábà rẹ̀, ó gbìyànjú díẹ̀ láti kàn sí àwọn ọmọ rẹ̀ lẹ́yìn tó filé sílẹ̀. Kì í ṣe Joan nìkan ló ní irú ìṣòro yìí; ó bani nínú jẹ́ pé ọ̀pọ̀ àwọn èwe ni àwọn bàbá wọn ti pa tì.

Tó bá ti ṣẹlẹ̀ bẹ́ẹ̀ sí ọ, ó lè ṣòro gan-an fún ọ láti fara dà á. Ìrora àti ìbínú lè máa bá ọ fínra lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. Nígbà míì, inú rẹ lè bà jẹ́ kí o sì sorí kọ́. Ó tiẹ̀ lè dà bí ẹni pé kóo ṣàìgbọràn pàápàá. Gẹ́gẹ́ bí ohun tí òǹkọ̀wé Bíbélì nì, Sólómọ́nì, sọ nígbà kan, “ìnilára pàápàá lè mú kí ọlọ́gbọ́n ṣe bí ayírí.”—Oníwàásù 7:7.

‘Ṣíṣe Bí Ayírí’

James ‘ṣe bí ayírí’ lẹ́yìn tí bàbá rẹ̀ fi ilé sílẹ̀. James sọ pé: “Kò tiẹ̀ sí ẹni tó lè bá mi sọ̀rọ̀ kí n gbọ́, títí kan mọ́mì mi pàápàá. Ńṣe ni mo kàn ń jà káàkiri. Gbogbo ìgbà ni mo máa ń parọ́ tí mo sì máa ń yọ́ jáde lóru nítorí pé kò sí ẹnì kankan tó máa bá mi wí. Mọ́mì gbìyànjú láti mú kí n jáwọ́, àmọ́ kò ṣeé ṣe fún un.” Ǹjẹ́ ṣíṣàìgbọràn mú kí ìgbésí ayé James túbọ̀ sunwọ̀n sí i ní ti gidi? Ó dájú pé kò rí bẹ́ẹ̀. James sọ pé kò pẹ́ tí òun fi bẹ̀rẹ̀ sí “dán oògùn líle wò, bẹ́ẹ̀ lóun tún ń pa ilé ìwé jẹ, tóun sì wá ń gba òdo ràbàtà ní ilé ìwé.” Kò sì pẹ́ tí àṣemáṣe rẹ̀ yìí fi légbá kan sí i. Ó jẹ́wọ́ pé: “Mo máa ń fẹ́wọ́ ní àwọn ibi ìtajà, mo sì máa ń dá àwọn ènìyàn lọ́nà pẹ̀lú. Ẹ̀ẹ̀mejì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni ọlọ́pàá mú mi tí wọ́n sì fi mí sẹ́wọ̀n fún ìgbà díẹ̀, àmọ́ ìyẹn ò ní kí ń jáwọ́.”

Nígbà tí wọ́n béèrè lọ́wọ́ James pé kí ló mú kó ya ìpáǹle, ó ní: “Nítorí pé bàbá mi ti fi ilé sílẹ̀, mi ò sì réèyàn bá mi wí. Mi ò tiẹ̀ ronú ní ti gidi nípa bí ohun tí mò ń ṣe ṣe ń dun màmá mi, àwọn àbúrò mi, àti èmi alára tó. Mo ń fẹ́ àfiyèsí àti ìbáwí dádì mi.”

Àmọ́ ńṣe ni ṣíṣàìgbọràn yóò túbọ̀ ba nǹkan jẹ́ sí i. (Jóòbù 36:18, 21) Bí àpẹẹrẹ, bí James ṣe ń kó ara rẹ̀ sínú ìṣòro ló tún ń kó àwọn àbúrò rẹ̀ àti màmá rẹ̀ pẹ̀lú sínú ìjàngbọ̀n, tó sì ń kó wọn sínú másùnmáwo àti wàhálà tí kò yẹ kí ó bá wọn. Èyí tó tiẹ̀ tún wá pabanbarì níbẹ̀ ni pé ṣíṣàìgbọràn lè mú kéèyàn kẹ̀yìn sí Ọlọ́run pàápàá. Ó ṣe tán, Jèhófà pàṣẹ fún àwọn ọmọ láti máa gbọ́ràn sí ìyá wọn lẹ́nu.—Òwe 1:8; 30:17.

Ṣíṣàkóso Ìbínú Náà

Báwo lo ṣe máa wá ṣe ti inú tó ń bí ọ sí bàbá rẹ àti ìkórìíra tóo ní sí i? Lákọ̀ọ́kọ́ ná, ó yẹ kóo rántí pé fífi tí bàbá rẹ filé sílẹ̀ kì í ṣe ẹjọ́ ẹ. Bẹ́ẹ̀ sì ni kò fi dandan túmọ̀ sí pé kò nífẹ̀ẹ́ rẹ mọ́ tàbí pé kò bìkítà nípa rẹ. Ká sọ tòótọ́, ó máa ń dun èèyàn gan-an nígbà tí bàbá ẹni ò bá bìkítà láti bẹni wò. Àmọ́ gẹ́gẹ́ bí àpilẹ̀kọ tó ṣáájú nínú ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ yìí ti fi hàn, b ohun tó mú kí àìmọye àwọn bàbá tó filé sílẹ̀ kọ̀ láti kàn sí àwọn ọmọ wọn kì í ṣe nítorí pé wọn ò fẹ́ràn wọn, ṣùgbọ́n ó jẹ́ nítorí pé ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ àti ìtìjú ìwà àìtọ́ tí wọ́n hù ń yọ wọ́n lẹ́nu. Gẹ́gẹ́ bọ́ràn bàbá Joan ṣe rí, àwọn mìíràn wà tó jẹ́ pé oògùn líle àti ọtí líle ti di bárakú fún wọn, tí èyí ò sì jẹ́ kí wọ́n lè hùwà bí ọmọlúwàbí mọ́.

Bó ti wù kí ọ̀ràn náà rí, gbìyànjú láti rántí pé aláìpé ni àwọn òbí rẹ. Bíbélì sọ pé: “Gbogbo ènìyàn ti ṣẹ̀, wọ́n sì ti kùnà láti kúnjú ìwọ̀n ògo Ọlọ́run.” (Róòmù 3:23; 5:12) Lóòótọ́, èyí kì í ṣe àwíjàre fún híhu ìwà tí ń ṣe ìpalára fún àwọn ẹlòmíràn tàbí tí ń fi ọ́ hàn bí ẹni tí kò wúlò. Àmọ́ mímọ̀ pé gbogbo wa la jẹ́ ẹ̀dá aláìpé yóò mú kó rọrùn fún ọ láti fi ìbínú tí ń pani run àti ìkórìíra sílẹ̀.

Ohun tó wà nínú ìwé Oníwàásù 7:10 lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti kápá ìbínú àti ìkórìíra tóo ní sí àwọn òbí rẹ. Wo bó ṣe kìlọ̀ nípa pípe àfiyèsí sí àwọn ohun tó ti kọjá, ó ní: “Má sọ pé: ‘Èé ṣe tí ó fi jẹ́ pé àwọn ọjọ́ àtijọ́ sàn ju ìwọ̀nyí lọ?’ nítorí pé ọgbọ́n kọ́ ni ìwọ fi béèrè nípa èyí.” Nítorí náà, dípò kóo máa ronú lórí báwọn nǹkan ṣe wà tẹ́lẹ̀, yóò dára kóo máa ronú nípa bóo ṣe lè lo ipò tóo bá ara rẹ lọ́nà tó dára.

Lo Ìdánúṣe Láti Kàn Sí I

Bí àpẹẹrẹ, o lè ronú nípa lílo ìdánúṣe láti kàn sí bàbá rẹ. Òótọ́ ni pé òun ló já ọ sílẹ̀, èyí sì lè jẹ́ kóo wá máa ronú pé òun ló yẹ kó kọ́kọ́ wá ọ wá. Àmọ́ bí kò bá ṣe bẹ́ẹ̀ tí àìgbúròó rẹ̀ sì ń bà ọ́ nínú jẹ́, ṣé o ò ronú pé yóò dára bí ìwọ alára bá wá a lọ? Ronú nípa ohun tí Jésù Kristi ṣe nígbà táwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ kan ṣe ohun tó dùn ún. Ní òru ọjọ́ tó kẹ́yìn ìgbésí ayé rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé, àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ fi í sílẹ̀. Pétérù ti fọ́nnu tẹ́lẹ̀ pé èkùrọ́ ni alábàákú ẹ̀wà, pé ohun yòówù ó ṣẹlẹ̀ ńṣe lòun máa wà lẹ́yìn Jésù gbágbáágbá. Àmọ́, ìgbà mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni Pétérù sẹ́ Jésù!—Mátíù 26:31-35; Lúùkù 22:54-62.

Pẹ̀lú gbogbo nǹkan tí Pétérù ṣe yìí, Jésù ṣì nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ síbẹ̀. Lẹ́yìn tí Jésù jíǹde, òun ló gbé ìgbésẹ̀ àkọ́kọ́ láti tún fìdí àjọṣe wọn múlẹ̀ nípa fífarahan Pétérù lọ́nà àkànṣe. (1 Kọ́ríńtì 15:5) Ó dùn mọ́ni nínú pé nígbà tí Jésù béèrè lọ́wọ́ Pétérù pé, “Ìwọ ha nífẹ̀ẹ́ mi?” Pétérù náà wá dá a lóhùn pé: “Bẹ́ẹ̀ ni, Olúwa, ìwọ mọ̀ pé mo ní ìfẹ́ni fún ọ.” Pẹ̀lú gbogbo ìwà tó ń tini lójú tí Pétérù hù, ó ṣì nífẹ̀ẹ́ Jésù síbẹ̀.—Jòhánù 21:15.

Gẹ́gẹ́ bó ṣe rí nínú ọ̀ràn Jésù àti Pétérù, ọ̀ràn ìwọ àti bàbá rẹ lè má burú tó bóo ṣe rò. Ó ṣeé ṣe kí bàbá rẹ dá ọ lóhùn bóo bá lo ìdánúṣe láti kàn sí i bóyá nípa títẹ̀ ẹ́ láago, tàbí kóo kọ lẹ́tà sí i, kódà o tiẹ̀ lè lọ bẹ̀ ẹ́ wò pàápàá. Henry, táa mẹ́nu kàn níbẹ̀rẹ̀ sọ pé: “Nígbà kan, mo kọ̀wé sí dádì mi, òun náà sí kọ lẹ́tà sí mi pé òun ń fi mí yangàn. Mo fi lẹ́tà yẹn sínú férémù kékeré, mo sì gbé e kọ́ sára ògiri fún ọ̀pọ̀ ọdún. Kódà, ó ṣì wà lọ́wọ́ mi dòní olónìí.”

Joan àti àwọn àbúrò rẹ̀ náà lo ìdánúṣe láti lọ bẹ bàbá wọn tó jẹ́ ọ̀mùtí wò. Joan sọ pé: “Ipò tó wà ò dùn mọ́ wa nínú, àmọ́ inú wa dùn pé a rí i.” Ó ṣeé ṣe kí nǹkan yọrí sí rere bóo bá lo ìdánúṣe. Bí kò bá sì dá ọ lóhùn lákọ̀ọ́kọ́, o lè jẹ́ kí ọjọ́ bíi mélòó kan kọjá kóo tún gbìyànjú lẹ́ẹ̀kan sí i.

Fífarada Ìrora tí Kíkọnisílẹ̀ Máa Ń Mú Wá

Sólómọ́nì rán wa létí pé “ìgbà wíwá àti ìgbà gbígbà pé ó ti sọnù” wà. (Oníwàásù 3:6) Nígbà mìíràn, èwe kan ní láti gba kámú pé bàbá òun kò tiẹ̀ fẹ́ ní àjọṣe kankan pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ̀. Bó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀ lọ̀ràn bàbá rẹ rí, ọjọ́ kan á jọ́kan tí yóò wá mọ̀ pé òun ti pàdánù ọ̀pọ̀ nǹkan nípa ṣíṣàìní àjọṣe pẹ̀lú rẹ.

Ní báyìí ná, jẹ́ kó dá ọ lójú pé kíkọ̀ tó kọ̀ ẹ́ sílẹ̀ kò túmọ̀ sí pé o kò wúlò. Onísáàmù inú Bíbélì náà, Dáfídì, sọ pé: “Bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé baba mi àti ìyá mi fi mí sílẹ̀, àní Jèhófà tìkára rẹ̀ yóò tẹ́wọ́ gbà mí.” (Sáàmù 27:10) Bó ṣe rí gan-an nìyẹn, o ṣì ṣeyebíye gan-an lójú Ọlọ́run.—Lúùkù 12:6, 7.

Nítorí náà, bóo bá rẹ̀wẹ̀sì tàbí tí o sorí kọ́, sún mọ́ Ọlọ́run dáadáa nínú àdúrà. (Sáàmù 62:8) Bó bá ṣe ń ṣe ọ́ gan-an ni kóo sọ fún un. Kóo sì jẹ́ kó dá ọ lójú pé yóò gbọ́ ọ, yóò sì tù ọ́ nínú. Onísáàmù mìíràn nínú Bíbélì tún sọ pé: “Nígbà tí ìrònú tí ń gbé mi lọ́kàn sókè di púpọ̀ nínú mi, ìtùnú tìrẹ ni ó bẹ̀rẹ̀ sí ṣìkẹ́ ọkàn mi.”—Sáàmù 94:19.

Ìbákẹ́gbẹ́pọ̀ ọlọ́yàyà pẹ̀lú àwọn Kristẹni bíi tìrẹ tún lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti fara da jíjá tí bàbá rẹ já ọ sílẹ̀. Ìwé Òwe 17:17 sọ pé: “Alábàákẹ́gbẹ́ tòótọ́ a máa nífẹ̀ẹ́ ẹni ní gbogbo ìgbà, ó sì jẹ́ arákùnrin tí a bí fún ìgbà tí wàhálà bá wà.” O lè rí irú ìbákẹ́gbẹ́ bẹ́ẹ̀ nínú ìjọ Kristẹni ti àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ní pàtàkì, ó tiẹ̀ tún lè ràn ọ́ lọ́wọ́ bóo bá mọ díẹ̀ lára àwọn alàgbà ìjọ. Àbúrò Joan tó ń jẹ́ Peter dámọ̀ràn pé: “Bá àwọn àgbààgbà inú ìjọ sọ̀rọ̀, wọ́n á sì ràn ọ́ lọ́wọ́ gidigidi. Bí bàbá rẹ bá ti pa ọ́ tì, jẹ́ kí wọ́n mọ bó ṣe rí lára rẹ.” Àwọn alábòójútó nínú ìjọ pàápàá tún lè fún ọ ní àwọn àbá tó gbéṣẹ́ lórí bóo ṣe lè bójú tó díẹ̀ lára àwọn ẹrù iṣẹ́ tí bàbá rẹ máa ń bójú tó tẹ́lẹ̀, bí i ṣíṣe àwọn àtúnṣe pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ nínú ilé.

Màmá rẹ pàápàá tún lè jẹ́ orísun ìtìlẹ́yìn fún ọ. Òtítọ́ ni pé òun alára lè ní ìdààmú ọkàn. Àmọ́, bóo bá fi tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ ṣàlàyé bí ọ̀ràn náà ṣe rí lára rẹ fún un, ó dájú pé yóò sa gbogbo ipá rẹ̀ láti gbọ́ tìrẹ.

Ti Ìdílé Rẹ Lẹ́yìn!

Oríṣiríṣi ọ̀nà ní àìsínílé bàbá rẹ fi lè nípa lórí ìdílé rẹ. Ó lè di dandan pé kí ìyá rẹ bẹ̀rẹ̀ sí ṣiṣẹ́ àṣelàágùn kí awọ ba lè kájú ìlù. Kó sì wá di dandan pé kí ìwọ àtàwọn àbúrò rẹ wá máa bójú tó àwọn ẹrù iṣẹ́ púpọ̀ sí i nínú ilé. Àmọ́, bóo bá ní ìfẹ́ aláìmọtara-ẹni-nìkan tí Kristẹni ní, yóò mú kó ṣeé ṣe fún ọ láti fara da irú àwọn ìyípadà bẹ́ẹ̀. (Kólósè 3:14) Èyí yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti ní ẹ̀mí pé nǹkan á dára, tí yóò sì mú kóo paná ìkórìíra tó ń jó nínú rẹ. (1 Kọ́ríńtì 13:4-7) Peter sọ pé: “Mo mọ̀ pé ojúṣe mi ni láti ran ìdílé mi lọ́wọ́, mo sì máa ń ní ìtẹ́lọ́rùn nítorí mo mọ̀ pé mo ń ran mọ́mì àti àwọn ẹ̀gbọ́n mi obìnrin lọ́wọ́.”

Láìsí àní-àní, ó máa ń dunni gan-an, ó sì tún máa ń ba èèyàn nínú jẹ́ bí bàbá bá fi ilé sílẹ̀. Àmọ́ o, jẹ́ kó dá ọ lójú pé pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Ọlọ́run àti ti àwọn ará àti ẹbí tí wọ́n jẹ́ Kristẹni, ìwọ àti ìdílé rẹ lè fara dà á. c

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a A ti yí àwọn orúkọ padà.

b Wo àpilẹ̀kọ náà “Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . . Èé Ṣe Tí Dádì Fi Já Wa Sílẹ̀?” tó wà nínú ìtẹ̀jáde wa ti December 8, 2000.

c Fún ìsọfúnni síwájú sí i nípa gbígbé nínú ìdílé olóbìí kan, wo àwọn àpilẹ̀kọ “Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . . ” tó wà nínú ìtẹ̀jáde ti October 22, 1991, àti January 22, 1992.

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 30]

Àwọn ọ̀dọ́ kan ti lo ìdánúṣe láti kàn sí bàbá wọn