Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ǹjẹ́ Ìrètí Ńbẹ?

Ǹjẹ́ Ìrètí Ńbẹ?

Ǹjẹ́ Ìrètí Ńbẹ?

“Ìṣòro kan tó máa ń wà nínú àwọn ìgbéyàwó tó ní wàhálà nínú ni èrò tí wọ́n máa ń ní pé nǹkan kò lè dára. Irú èrò bẹ́ẹ̀ sì máa ń dojú àtúnṣe délẹ̀ ni nítorí pé kò ní jẹ́ kí ẹ lè ní ẹ̀mí láti gbìyànjú ohunkóhun tó lè mú nǹkan dára.”—Ọ̀MỌ̀WÉ AARON T. BECK.

KÁ SỌ pé o ń jẹ̀rora, o wá tọ dókítà lọ láti mọ ohun tó ń ṣe ọ́. Ọkàn rẹ ò balẹ̀—kò sì sọ́gbọ́n kó máà rí bẹ́ẹ̀. Ó ṣe tán, ìlera rẹ—kódà ẹ̀mí rẹ pàápàá lè wà nínú ewu. Ṣùgbọ́n ká ní lẹ́yìn àyẹ̀wò náà, dókítà wá sọ fún ọ pé bó tilẹ̀ jẹ́ pé ohun tó ń ṣe ẹ́ kò ṣeé fọwọ́ yẹpẹrẹ mú, ṣùgbọ́n ó ṣeé wò sàn. Dókítà tilẹ̀ sọ fún ọ pé bí o bá ṣọ́ bóo ṣe ń jẹun, tóo sì ń ṣeré ìmárale níwọ̀n tó yẹ, ara rẹ yóò yá pátápátá. Ó dájú pé ọkàn rẹ yóò balẹ̀ gan-an, tayọ̀tayọ̀ ni wàá si fi ìmọ̀ràn rẹ̀ sílò!

Fi ìṣẹ̀lẹ̀ àfinúrò yìí wéra pẹ̀lú ohun tí a ń jíròrò rẹ̀. O ha ń ní ìrora ọkàn nínú ìgbéyàwó rẹ bí? Lóòótọ́, kò sí ìgbéyàwó tí ìṣòro àti aáwọ̀ kì í bá fínra. Nítorí náà, bí àárín yín kò bá gún régé láwọn àkókò kan, ìyẹn kò túmọ̀ sí pé kò sí ìfẹ́ nínú ìgbéyàwó yín. Ṣùgbọ́n bí ohun tó ń fa ìrora ọkàn náà kò bá tán, tó ń bá a lọ fún ọ̀pọ̀ ọ̀sẹ̀, oṣù, tàbí ọdún pàápàá ńkọ́? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, ó yẹ kí ẹ̀rù bà ọ́ lóòótọ́, nítorí ọ̀ràn tó wà nílẹ̀ yìí kì í ṣe ọ̀ràn kékeré. Láìṣe àní-àní, ohun tó ń ṣẹlẹ̀ nínú ìgbéyàwó rẹ lè fẹ́rẹ̀ẹ́ nípa lórí gbogbo apá ìgbésí ayé rẹ—àti ti àwọn ọmọ rẹ. Fún àpẹẹrẹ, àwọn èèyàn gbà gbọ́ pé tí ìgbéyàwó ò bá fara rọ, ìyẹn lè fa àwọn ìṣòro bí ìsoríkọ́, àìjáfáfá lẹ́nu iṣẹ́, àti kí àwọn ọmọ máa fìdí rẹmi nílé ìwé. Ṣùgbọ́n kò tán síbẹ̀ o. Àwọn Kristẹni mọ̀ pé àjọṣe tó wà láàárín àwọn àti ẹni táwọn fẹ́ lè nípa lórí àjọṣe àwọn pẹ̀lú Ọlọ́run.—1 Pétérù 3:7.

Ti pé ìṣòro wà láàárín ìwọ àti ẹnì kejì rẹ kò túmọ̀ sí pé ọ̀ràn yín ti burú kọjá àtúnṣe. Mímọ òkodoro òtítọ́ náà nípa ìgbéyàwó—pé ìṣòro yóò máa wà—lè ran tọkọtaya kan lọ́wọ́ láti wo àwọn ìṣòro wọn láwòjinlẹ̀ kí wọ́n sì gbìyànjú láti wá ojútùú sí i. Ọkọ kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Isaac sọ pé: “Mi ò mọ̀ tẹ́lẹ̀ pé kì í ṣe ohun tójú ò rí rí kí tọkọtaya ní gbọ́nmi-si-omi-o-to nínú ìgbéyàwó wọn. Mo rò pé a níṣòro àrà ọ̀tọ̀ kan ni!”

Kódà bí ìgbéyàwó rẹ bá ti burú débi pé kò sí ìfẹ́ láàárín yín mọ́, ẹ ṣì ṣe é kí ó má forí ṣánpọ́n. Òótọ́ ni pé àwọn ìrora ọkàn tí àjọṣe tí kò gún régé ń fà lè dunni gan-an, ní pàtàkì tí àwọn ìṣòro náà bá ti ń ṣẹlẹ̀ fún ọ̀pọ̀ ọdún. Ṣùgbọ́n a ṣì lè fọkàn sí pé nǹkan á dára. Gbígbégbèésẹ̀ jẹ́ kókó pàtàkì kan nínú rẹ̀. Kódà, àwọn èèyàn méjì tí wọ́n ní ìṣòro tó le gan-an nínú ìgbéyàwó wọn ṣì lè ṣàtúnṣe tó bá jẹ wọ́n lógún. a

Nítorí náà, bi ara rẹ léèrè pé, ‘Báwo ni mo ṣe fẹ́ láti ní àjọṣe tó gún régé tó?’ Ǹjẹ́ ìwọ àti ẹni tí o fẹ́ ní in lọ́kàn láti sapá láti mú kí ìgbéyàwó yín túbọ̀ tòrò sí i? Ọ̀mọ̀wé Beck, tí a fa ọ̀rọ̀ rẹ̀ yọ níbẹ̀rẹ̀, sọ pé: “Lọ́pọ̀ ìgbà ló máa ń yà mí lẹ́nu láti rí i pé bí tọkọtaya bá pawọ́ pọ̀ láti yanjú ìṣòro wọn, tí wọ́n sì fi àwọn ànímọ́ rere inú ìgbéyàwó wọn sílò, ó máa ń ṣeé ṣe fún wọn láti mú àjọṣe wọn tó hàn gbangba pé kò gún régé padà bọ̀ sípò.” Ṣùgbọ́n bí ẹnì kejì rẹ kò bá fẹ́ fọwọ́ sowọ́ pọ̀ láti mú kí àjọṣe náà túbọ̀ gún régé ńkọ́? Tàbí tó bá jọ pé kò fẹ́ gbà pé ìṣòro wà ńkọ́? Ṣé asán ló já sí ni bí ìwọ nìkan bá dá fàyà rán yíyanjú ìṣòro inú ìgbéyàwó yín? Rárá o! Ọ̀mọ̀wé Beck sọ pé: “Bí ìw bá ṣe àwọn àtúnṣe kan, ìyẹn gan-an lè mú kí ẹnì kejì rẹ ṣe àwọn àtúnṣe pẹ̀lú—ohun tó sì sábà máa ń ṣẹlẹ̀ nìyẹn.”

Má ṣe yára parí èrò sí pé èyí kò lè ṣẹlẹ̀ nínú ọ̀ràn tiyín. Irú èrò tó ń dojú ìsapá délẹ̀ bẹ́ẹ̀ lè jẹ́ ewu ńlá nínú ìgbéyàwó yín! Ìkan nínú yín ni yóò kọ́kọ́ gbégbèésẹ̀. Ṣé ìwọ lè ṣe bẹ́ẹ̀? Tóo bá ti gbégbèésẹ̀ náà, ẹnì kejì rẹ lè wá rí àǹfààní tó wà nínú fífọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú rẹ láti mú kí ìgbéyàwó yín túbọ̀ láyọ̀ sí i.

Nítorí náà, kí ni ẹ lè ṣe, yálà lẹ́nì kọ̀ọ̀kan tàbí lẹ́yin méjèèjì gẹ́gẹ́ bíi tọkọtaya, kí ìgbéyàwó yín má bàa forí ṣánpọ́n? Bíbélì ṣèrànwọ́ tó lágbára nípa dídáhùn ìbéèrè yìí. Ẹ jẹ́ ká wo bó ṣe dáhùn rẹ̀.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Lóòótọ́, nínú àwọn ọ̀ràn kan tó burú jáì, ìdí pàtàkì lè wà tí yóò mú kí ọkọ àti aya pínyà. (1 Kọ́ríńtì 7:10, 11) Ní àfikún sí i, Bíbélì gba ìkọ̀sílẹ̀ láyè lórí ìpìlẹ̀ àgbèrè. (Mátíù 19:9) Yálà ó yẹ kéèyàn kọ ẹnì kejì rẹ̀ tó jẹ́ aláìṣòótọ́ sílẹ̀ tàbí kò yẹ jẹ́ ìpinnu ara ẹni, kò sì yẹ kí àwọn ẹlòmíràn máa ti ẹni tó ṣe olóòótọ́ náà láti pinnu yálà láti kọ ẹnì kejì rẹ̀ sílẹ̀ tàbí kó má kọ̀ ọ́.—Wo ìwé Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé, ojú ìwé 158 sí 161, tí Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc., ṣe.