Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Kí Ló Ń Mú Káwọn Èèyàn Máa Ṣe Iṣẹ́ Olùkọ́?

Kí Ló Ń Mú Káwọn Èèyàn Máa Ṣe Iṣẹ́ Olùkọ́?

Kí Ló Ń Mú Káwọn Èèyàn Máa Ṣe Iṣẹ́ Olùkọ́?

“Nítorí pé iṣẹ́ olùkọ́ jẹ́ iṣẹ́ tó ń ran àwọn akẹ́kọ̀ọ́ lọ́wọ́ ló mú káwọn kan máa ṣe é. [Iṣẹ́ olùkọ́ jẹ́] iṣẹ́ tó ń tún ayé àwọn ọmọ ṣe.”—Ìwé Teachers, Schools, and Society.

ONÍRÚURÚ ìṣòro ló wà nídìí iṣẹ́ olùkọ́ o, bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn èèyàn kan ń mú kó dà bí iṣẹ́ tó rọrùn. Àwọn ìṣòro bíi káwọn akẹ́kọ̀ọ́ pọ̀ jù nínú kíláàsì kan, kí iṣẹ́ ìwé kíkọ pọ̀ lápọ̀jù, kí àwọn iṣẹ́ tó gba ọgbọ́n fẹ́rẹ̀ẹ́ pá olùkọ́ lórí, káwọn akẹ́kọ̀ọ́ kan má mọ̀wé àti kí owó oṣù olùkọ́ máà tó bó ṣe yẹ. Ẹ gbọ́ bí Pedro, tó jẹ́ olùkọ́ nílùú Madrid ní Sípéènì ṣe sọ ọ́: “Kò rọrùn rárá láti jẹ́ olùkọ́. Èèyàn gbọ́dọ̀ ní ẹ̀mí ìfara-ẹni-rúbọ ńláǹlà. Àmọ́ ṣá o, pẹ̀lú gbogbo ìṣòro tó wà níbẹ̀, mo ṣì gbà pé iṣẹ́ olùkọ́ lérè nínú ju iṣẹ́ okòwò lọ.”

Àwọn ìṣòro yìí lékenkà ní àwọn ilé ìwé tó wà ní ìlú ńláńlá ní ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn orílẹ̀-èdè. Oògùn olóró, ìwà ipá, ìwà pálapàla àti dídágunlá táwọn òbí ń dágunlá nígbà mìíràn máa ń sọ ilé ìwé dìdàkudà, ìwà tó dáa ò sì ní lè jọba níbẹ̀. Ẹ̀mí ìṣọ̀tẹ̀ náà wà dáadáa. Pẹ̀lú gbogbo èyí, kí ló fà á tó fi jẹ́ pé iṣẹ́ olùkọ́ làwọn ọ̀mọ̀wé kan ń ṣe?

Iṣẹ́ olùkọ́ ni Leemarys àti Diana ń ṣe ní Ìlú New York. Wọ́n máa ń kọ́ àwọn ọmọ ọlọ́dún márùn-ún sí ọlọ́dún mẹ́wàá. Àwọn méjèèjì gbọ́ èdè Gẹ̀ẹ́sì àti èdè Spanish dáadáa, ọmọ àwọn ará Sípéènì ni wọ́n sì ń kọ́. Ìbéèrè tá a bi wọ́n ni pé . . .

Kí Ló Ń Mú Àwọn Èèyàn Ṣe Iṣẹ́ Olùkọ́?

Leemarys sọ pé: “Ṣé ohun tó ń mú mi ṣiṣẹ́ olùkọ́ lẹ fẹ́ mọ̀? Ìfẹ́ tí mo ní fún àwọn ọmọdé ni. Mo mọ̀ pé àwọn ọmọ kan wà tó jẹ́ pé èmi nìkan ló ń gbárùkù tì wọ́n nínú gbogbo akitiyan wọn.”

Diana sọ pé: “Mo kọ́ ọmọ ẹ̀gbọ́n mi ọkùnrin tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́jọ tí kò mọ̀wé kà lẹ́kọ̀ọ́. Inú mi dùn gan-an nígbà tí orí òun àtàwọn mìíràn wá jí sí ìwé! Ni mo bá sọ pé mo fẹ́ ṣiṣẹ́ olùkọ́, mo sì fi iṣẹ́ báńkì tí mò ń ṣe sílẹ̀.”

Jí! béèrè irú ìbéèrè kan náà lọ́wọ́ àwọn olùkọ́ láwọn orílẹ̀-èdè mìíràn, lára àwọn ìdáhùn wọn ló wà nísàlẹ̀ yìí.

Ará Ítálì ni Giuliano, ó sì ti lé lẹ́ni ogójì ọdún. Ó sọ pé: “Ohun tó mú mi ṣiṣẹ́ olùkọ́ ni pé iṣẹ́ náà wù mí gan-an nígbà tí mo wà nílé ẹ̀kọ́ (lápá ọ̀tún). Mo kà á sí iṣẹ́ ọpọlọ tó sì ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ àǹfààní láti mú káwọn mìíràn ṣe dáadáa. Ìtara tí mo ní níbẹ̀rẹ̀ ló jẹ́ kí n lè borí àwọn ìṣòro tí mo dojú kọ nígbà tí mo ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ yìí.”

Ará New South Wales, ní Ọsirélíà ni Nick. Ó sọ pé: “Kò fi bẹ́ẹ̀ sí iṣẹ́ gidi kan ní ẹ̀ka ìwádìí nípa kẹ́míkà tí mo ti ń ṣiṣẹ́, àmọ́ iṣẹ́ wà dáadáa níbi iṣẹ́ olùkọ́. Àtìgbà tí mo sì ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ olùkọ́ ni mo ti ń gbádùn rẹ̀, ó sì dà bí ẹni pé àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà ń gbádùn bí mo ṣe ń kọ́ wọn.”

Àpẹẹrẹ àwọn òbí ló sábà máa ń jẹ́ káwọn tó ń ṣiṣẹ́ olùkọ́ ṣe iṣẹ́ náà. Ọmọ Kẹ́ńyà ni William, bó ṣe dáhùn ìbéèrè wa rèé: “Bàbá mi lẹni náà gan-an tó jẹ́ kí n nífẹ̀ẹ́ sí iṣẹ́ olùkọ́, nítorí iṣẹ́ olùkọ́ lòun náà ń ṣe lọ́dún 1952. Mímọ̀ tí mo mọ̀ pé mò ń gbin ohun tó dáa sọ́kàn àwọn ògo wẹẹrẹ ló jẹ́ kí n ṣì máa bá iṣẹ́ náà lọ.”

Ọmọ Kẹ́ńyà ni Rosemary náà, ó sọ fún wa pé: “Ó máa ń wù mí láti ran àwọn èèyàn tí nǹkan ò fi bẹ́ẹ̀ ṣẹnuure fún lọ́wọ́. Ó wá di pé kí n yan ọ̀kan nínú iṣẹ́ nọ́ọ̀sì àti iṣẹ́ olùkọ́. Iṣẹ́ olùkọ́ ló sì kọ́kọ́ wá sọ́kàn mi. Jíjẹ́ ti mo tún jẹ́ òbí mú kí n nífẹ̀ẹ́ sí iṣẹ́ náà.”

Ohun tó sún Berthold, ọmọ ìlú Düren ní Jámánì dédìí iṣẹ́ olùkọ́ yàtọ̀ sí tàwọn tó kù o. Ó sọ pé: “Ìyàwó mi fi yé mi pé mo màá lè ṣe iṣẹ́ olùkọ́ dáadáa.” Mo sì wá rí i pé òtítọ́ lohun tó sọ. Berthold fi kún un pé: “Iṣẹ́ náà ń fún mi ní ayọ̀ ńláǹlà ní báyìí. Bí olùkọ́ kan fúnra rẹ̀ kò bá mọ̀ pé ẹ̀kọ́ ṣe kókó, kò ní lè jẹ́ olùkọ́ tó múná dóko, kò ní lè jẹ́ olùkọ́ tó ń ṣàṣeyọrí, tó ń mú káwọn èèyàn fẹ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ kó sì jẹ́ olùkọ́ tó ní ìtẹ́lọ́rùn.”

Olùkọ́ kan tó ń jẹ́ Masahiro, ọmọ ìlú Nakatsu ní orílẹ̀-èdè Japan, sọ pé: “Olùkọ́ kan tó mòye tó kọ́ mi nígbà tí mo ṣẹ̀ṣẹ̀ wọ ilé ẹ̀kọ́ girama ló jẹ́ kí èmi náà bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ olùkọ́. Tinútinú ló fi kọ́ wa. Ohun tó sì jẹ́ kí n máa bá iṣẹ́ náà lọ ni pé mo fẹ́ràn àwọn ọmọdé.”

Ẹni ọdún mẹ́rìnléláàádọ́ta ni Yoshiya, ọmọ orílẹ̀-èdè Japan si lòun náà. Ilé iṣẹ́ kan ló ti n ṣiṣẹ́, owó tó jọjú sì ń wọlé fún un, àmọ́ ó sọ pé iṣẹ́ náà ti fẹ́ sọ òun di ẹrú, òun ò sì lè máa rìnrìn àjò káàkiri ní gbogbo ìgbà mọ́. “Lọ́jọ́ kan mo bẹ̀rẹ̀ sí ronú pé, ‘Ọjọ́ wo ni màá tó bọ́ nínú irú ìgbésí ayé tí mò ń gbé yìí?’ Mo pinnu pé iṣẹ́ tá á jẹ́ kí èmi àtàwọn èèyàn jọ máa fọ̀rọ̀ wérọ̀ ni màá bẹ̀rẹ̀ sí ṣe dípò èyí tí mo fi ń kó onírúurú nǹkan káàkiri. Kò sí iṣẹ́ mìíràn tó dà bí iṣẹ́ olùkọ́. Nítorí àwọn ọmọdé ni wàá máa bá ṣiṣẹ́. Iṣẹ́ ọmọlúwàbí sì ni.”

Ohun tó mú kí Valentina, ọmọ ìlú St. Petersburg, ní Rọ́ṣíà náà fẹ́ràn iṣẹ́ olùkọ́ nìyẹn. Ó sọ pé: “Iṣẹ́ tó wù mí gan-an ni iṣẹ́ olùkọ́. Láti ọdún mẹ́tàdínlógójì báyìí ni mo ti ń kọ́ àwọn ọmọ ilé ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀. Mó fẹ́ràn láti máa wà pẹ̀lú àwọn ọmọdé, àgàgà àwọn tó ṣì kéré gan-an. Mo fẹ́ràn iṣẹ́ mi, ìdí rèé tí mi ò fi tíì fẹ̀yìn tì lẹ́nu iṣẹ́ ọ̀hún.”

William Ayers, tóun náà jẹ́ olùkọ́ kọ ọ́ pé: “Àwọn èèyàn ń ṣiṣẹ́ olùkọ́ nítorí pé wọ́n fẹ́ràn àwọn ọmọdé àtàwọn èwe, tàbí nítorí pé wọ́n fẹ́ láti máa wà pẹ̀lú àwọn ọmọdé, kí wọ́n máa rí wọn bí wọ́n ṣe ń dàgbà tí wọ́n á sì lè fúnra wọn ṣe àwọn nǹkan, tí wọ́n á fi dẹni tó mòye, tí wọ́n á sì dèèyàn ńlá láyé. . . . Àwọn èèyàn ń ṣiṣẹ́ olùkọ́ . . . bí ọ̀nà kan láti fi ara wọn fún àwọn ẹlòmíràn. Ohun tó ń mú mi ṣiṣẹ́ olùkọ́ ni láti sọ ilé ayé di ibi tó dára fún ọmọ èèyàn.”

Òdodo ọ̀rọ̀, láìka àwọn ìṣòro àtàwọn ìpalára tó wà nídìí iṣẹ́ olùkọ́ sí, ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn ọkùnrin àti obìnrin ni wọ́n wà tí wọ́n ń fi tọkàntọkàn ṣiṣẹ́ yìí. Kí ni díẹ̀ lára àwọn ìṣòro tó ń dojú kọ wọ́n? Àpilẹ̀kọ́ tó kàn á gbé ìbéèrè yìí yẹ̀ wò.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 6]

Àwọn Àbá Lórí Ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ Láàárín Àwọn Òbí Àtàwọn Olùkọ́

✔ Rí i pé o mọ òbí àwọn akẹ́kọ̀ọ́. Àkókò tó o fi ṣe bẹ́ẹ̀ kò ṣòfò o. Ẹ ṣì máa jèrè àkókò tẹ́yin méjèèjì jọ lò yìí lọ́jọ́ iwájú. Àǹfààní ló máa jẹ́ fún ẹ láti fèrò wérò pẹ̀lú àwọn tó ṣeé ṣe kẹ́ ẹ jọ mọwọ́ ara yín jù lọ.

✔ Rẹ ara rẹ sílẹ̀ sí ipò àwọn òbí náà, má sì ṣe hùwà ìgbéraga. Yẹra fún sísọ èdè tí kò lè yé àwọn òbí.

✔ Tó o bá ń bá àwọn òbí sọ̀rọ̀ nípa àwọn ọmọ wọn, tẹnu mọ́ apá ibi táwọn ọmọ náà ti ṣe dáadáa. Gbígbóríyìn fúnni máa ń jẹ́ kéèyàn fẹ́ láti jára mọ́ nǹkan. Sọ àwọn nǹkan táwọn òbí náà lè ṣe láti ran ọmọ náà lọ́wọ́ kó lè ṣe dáadáa.

✔ Fún àwọn òbí láyè láti sọ̀rọ̀, kó o sì tẹ́tí bẹ̀lẹ̀jẹ́ sí ọ̀rọ̀ wọn.

✔ Gbìyànjú láti mọ bí ibi tí ọmọ náà ń gbé ṣe rí. Bó bá tiẹ̀ ṣeé ṣe, lọ sí ilé rẹ̀.

✔ Yan ọjọ́ mìíràn tẹ́ ẹ tún máa jọ ríra. Rí i dájú pé o mú àdéhùn náà ṣẹ. Èyí á fi hàn pé lóòótọ́ lo nífẹ̀ẹ́ ọmọ náà dénú.—Látinú ìwé Teaching in America.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 6]

‘Bàbá mi náà ti ṣe iṣẹ́ olùkọ́ rí.’—WILLIAM, KẸ́ŃYÀ

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

“Mó fẹ́ràn láti máa wà pẹ̀lú àwọn ọmọdé.”—VALENTINA, RỌ́ṢÍÀ

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

“Kò sí iṣẹ́ mìíràn tó dà bí iṣẹ́ olùkọ́. Nítorí àwọn ọmọdé ni wàá máa bá ṣiṣẹ́.”—YOSHIYA, JAPAN