Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ọ̀nà Tó Dára Jù Lọ Láti Rí Ìtẹ́lọ́rùn Tẹ̀mí

Ọ̀nà Tó Dára Jù Lọ Láti Rí Ìtẹ́lọ́rùn Tẹ̀mí

Ọ̀nà Tó Dára Jù Lọ Láti Rí Ìtẹ́lọ́rùn Tẹ̀mí

KÍ LÓ Ń MÚ ÀWỌN ÈÈYÀN ṣe ẹ̀sìn? Àwọn kan lè sọ pé nítorí pé àwọn èèyàn ń wá bí ọkàn wọn á ṣe balẹ̀ nínú ayé tó kún fún ewu yìí ló jẹ́ kí wọ́n máa yíjú sí ìsìn. Àmọ́ ohun tó wà nídìí ẹ̀ jùyẹn lọ. Àpilẹ̀kọ kan nínú ìwé ìròyìn àtìgbàdégbà náà American Sociological Review sọ pé: “Ìfọ̀kànbalẹ̀ nìkan kọ́ ló ń mú káwọn èèyàn nífẹ̀ẹ́ láti ṣe ẹ̀sìn. Ọjọ́ pẹ́ táwọn èèyàn ti ń wá ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè bí: Ibo ni ìwàláàyè ti ṣẹ̀ wá? Ibo là ń lọ? Kí la wà láàyè fún?”

Ó dájú pé wàá gbà pé àwọn ìbéèrè yìí kò ṣe é fọwọ́ rọ́ sẹ́yìn. Nígbà náà, ǹjẹ́ ìdáhùn tó ṣe é gbára lé kọ́ là ń wá? Àwọn ìbéèrè yìí ṣe pàtàkì gan-an wọ́n sì tóbi kọjá nǹkan tá a lè yanjú nípa wíwulẹ̀ máa mú èyí tó wù wá nínú àwọn ìgbàgbọ́ onírúurú ẹ̀sìn tó ti wà tipẹ́. Ká tó lè rí àwọn ìdáhùn tó dúró sán-ún tó sì ṣe é gbára lé sí àwọn ìbéèrè tó túbọ̀ ṣe pàtàkì nípa ìgbésí ayé, ó dájú pé à ń wá ìlànà kan tó dára ju wíwulẹ̀ gba ohunkóhun tó bá wù wá gbọ́.

Àmọ́ ṣé irú ohun bẹ́ẹ̀ wà? Ọ̀gbẹ́ni Ferrar Fenton, tó jẹ́ olùtumọ̀ Bíbélì sọ ohun kan tó ṣàrà ọ̀tọ̀ nípa Bíbélì. Ó pè é ní “kọ́kọ́rọ́ kan ṣoṣo tó ṣí Ìmọ̀ Ayé òun Ọ̀run payá fún Ènìyàn tó sì tún jẹ́ kí Ènìyàn Lóye Ara Rẹ̀.” Bẹ́ẹ̀ ni, Bíbélì dáhùn àwọn ìbéèrè nípa ohun tó ti ṣẹlẹ̀ kọjá, àwọn ohun tó ń ṣẹlẹ̀ lọ́wọ́lọ́wọ́, àtàwọn ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú. Ó sọ ibi tí ìwàláàyè ti wá fún wa, ó sọ ìtumọ̀ ìgbésí ayé, ó sọ bí a ṣe lè rí ayọ̀ àti ohun tá a máa gbádùn lọ́jọ́ iwájú. Kò síwèé kankan nínú ìtàn tó gbajúmọ̀ tó Bíbélì; bẹ́ẹ̀ ni kò síwèé náà bíi Bíbélì, táwọn èèyàn fẹ́ pa run àmọ́ tí kò ṣeé ṣe fún wọn. Kí ló wá dé tí ọ̀pọ̀ kì í ka ìwé tí kò lẹ́gbẹ́ yìí kún bí wọ́n ti ń wá ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè nípa ìgbésí ayé?

Ọ̀pọ̀ èèyàn ni kò tíì wá àkókò láti ṣàyẹ̀wò àwọn ìyàtọ̀ pàtàkì pàtàkì tó wà láàárín Bíbélì àtàwọn ṣọ́ọ̀ṣì tí wọ́n ti mọ̀ bí ẹní mowó. Wọ́n rí i tí àwọn tó fẹnu lásán pera wọn ní Kristẹni ń para wọn tí wọ́n sì ń sọ pé Ọlọ́run ló rán àwọn. Ọ̀pọ̀ sì ń ṣàròyé gẹ́gẹ́ bí ohun tí ìwé ìròyìn The Guardian sọ pé “lóde òní, bí àwọn àlùfáà ṣe máa rí owó kó jọ ni wọ́n gbájú mọ́ kì í ṣe fífúnni ní ìtọ́sọ́nà tẹ̀mí.” Èyí lè mú káwọn èèyàn yìí máa ronú pé, ó lè jẹ́ pé Bíbélì fọwọ́ sírú ìwà bẹ́ẹ̀ tàbí pé ó fàyè gba irú nǹkan bẹ́ẹ̀. Àmọ́ ní tòdodo, ńṣe ni Bíbélì pàṣẹ pé kí àwọn Kristẹni ‘nífẹ̀ẹ́ ara wọn’ ó sì sọ fún àwọn tó ń wàásù ọ̀rọ̀ náà pé, “Ọ̀fẹ́ ni ẹ̀yin gbà, ọ̀fẹ́ ni kí ẹ fúnni.” (Jòhánù 13:34; Mátíù 10:8) Ṣé ó wá dára nígbà náà ká máa fi ìwà àwọn èèyàn tó sọ pé àwọn bọ̀wọ̀ fún Bíbélì àmọ́ tí wọn ò tẹ̀ lé e díwọ̀n Bíbélì?

Ọ̀pọ̀ máa ń sọ pé Bíbélì kò bá sáyẹ́ǹsì mu, pé ó tako ara rẹ̀ àti pé kò bóde mu mọ́. Síbẹ̀ tá a bá yẹ Bíbélì wò fínnífínní, òdìkejì èyí lohun tá a máa rí níbẹ̀. Lóòótọ́, Bíbélì kì í ṣe ìwé sáyẹ́ǹsì. Àmọ́ nígbà tó bá sọ nípa àwọn nǹkan tó jẹ mọ́ sáyẹ́ǹsì, irú bí àwọn nǹkan ẹlẹ́mìí ṣe fara hàn lórí ilẹ̀ ayé ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀-lé, ìrísí ayé tàbí ọ̀nà tó tọ́ láti gbà wo àìsàn, ọ̀rọ̀ Bíbélì kò ṣe é kó dà nù. Kódà gan-an, ó sọ àwọn ohun tó jẹ́ pé ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún lẹ́yìn tó ti sọ wọ́n ni sáyẹ́ǹsì tó ó ṣẹ̀ṣẹ̀ mọ ohun tó ń jẹ́ bẹ́ẹ̀. Bákan náà, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìwé mẹ́rìndínláàádọ́rin ló para pọ̀ di Bíbélì tí kíkọ wọn sì gba ẹgbẹ̀jọ [1,600] ọdún, gbogbo wọn pátá ló ṣọ̀kan látòkè délẹ̀. Síwájú sí i, Bíbélì fi ọgbọ́n tó ga jù lọ hàn nínú bó ṣe ṣàlàyé ọ̀nà tí ẹ̀dá máa ń gbà hùwà èyí tó jẹ́ kó ṣì máa bágbà mu títí dọjọ́ òní.

Ìwé tí kò lẹ́gbẹ́ yìí sọ ohun kan tó ṣe kókó nípa ọ̀nà tó yẹ ká gbà jọ́sìn Ọlọ́run. Ó sọ pé a ò gbọ́dọ̀ gbé e ka ìlànà èèyàn àmọ́ pé ó gbọ́dọ̀ dá lórí àwọn ìlànà Ọlọ́run. (Jòhánù 5:30; Jákọ́bù 4:13-15; 2 Pétérù 1:21) Ṣùgbọ́n ìwọ̀nba èèyàn díẹ̀ péré ló ń fi tinútinú tẹ̀ lé ìlànà yẹn. Àtìgbà ìwáṣẹ̀ làwọn èèyàn ti ń ṣe ìsìn lọ́nà tó máa fi bá ohun tí ọkàn wọn fẹ́ mu. Ohun tó ń ṣẹlẹ̀ nìyẹn nígbà táwọn èèyàn bá fi igi gbẹ́ ọlọ́run wọn tí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í sìn wọ́n. Ohun kan náà ló ń mú káwọn ètò ìsìn máa kọ́ àwọn èèyàn láwọn ẹ̀kọ́ táwọn fúnra wọn hùmọ̀ rẹ̀. Ṣé kì í ṣe òun náà ló ń mú káwọn èèyàn kan máa ṣe àdábọwọ́ ìsìn tiwọn lọ́nà tó fi máa bá ohun tó wù wọ́n mu?

Wo ohun mìíràn tó yàtọ̀. Kí ló dé tó ò ṣe bíi tí adájọ́ àgbà kan ní Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà? Ó lo ọ̀nà kan náà tó máa ń gbà ṣàyẹ̀wò ẹjọ́ ní kóòtù. Láìlo ẹ̀tanú kankan, ó gbé àwọn ẹ̀rí yẹ̀ wò láti mọ̀ bóyá òótọ́ tàbí irọ́ làwọn ohun tó wà nínú Bíbélì. Kí ni àbájáde àyẹ̀wò rẹ̀? Ó sọ pé: “Mo ti wá rí i pé Bíbélì kì í ṣe ìwé lásán, pé ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ló ti wá.”

Báwo ni ìwọ náà ṣe lè ṣe irú àyẹ̀wò yìí fúnra rẹ? Àbá kan rèé, o lè bẹ̀rẹ̀ sí í ka Bíbélì pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ kó o sì máa ṣe bẹ́ẹ̀ déédéé, kó o wá máa wo bó ṣe dáhùn àwọn ìbéèrè tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí. Ó lé ní mílíọ̀nù mẹ́fà àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní igba ó lé márùndínlógójì [235] ilẹ̀ tí wọ́n ti ṣe irú ìwádìí yẹn. Wọ́n ń yọ̀ọ̀da àkókò wọn láti sọ àwọn ohun tí wọ́n ti kọ́ fún àwọn ẹlòmíràn. Ẹ̀kọ́ Bíbélì tí wọ́n ń kọ́ àwọn èèyàn nínú ilé wọn láìgba kọ́bọ̀ ti ran ọ̀pọ̀ mílíọ̀nù èèyàn lọ́wọ́ láti rí ìgbàgbọ́ tó kọjá ohun tó kàn jẹ́ àṣà lásán tàbí pé nǹkan báyìí ló wù mí. Ẹ̀sìn Kristẹni tòótọ́, tí kò lábààwọ́n tá a rí nínú Bíbélì kì í ṣe ẹ̀sìn tuntun kan lásán o. Ó jẹ́ òtítọ́ nípa Ọlọ́run àtàwọn ohun tó pinnu láti ṣe. Kí ló wá dé tí wàá gbé páńda ìsìn lọ́wọ́ tí wàá máa pè é ní ìsìn tòótọ́?—Jòhánù17:17.

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 20]

Ọ̀nà tó dára jù lọ láti rí ìtẹ́lọ́rùn tẹ̀mí ni pé kó o kẹ́kọ̀ọ́ nípa Ọlọ́run látinú Bíbélì kó o sì máa kẹ́gbẹ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn olùjọsìn tòótọ́