Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Kí Ló Dé Tí Àjọgbé Èmi àti Alábàágbé Mi Fi Nira?

Kí Ló Dé Tí Àjọgbé Èmi àti Alábàágbé Mi Fi Nira?

Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . .

Kí Ló Dé Tí Àjọgbé Èmi àti Alábàágbé Mi Fi Nira?

“Afínjú èèyàn ni mí, tẹnu kọ́. Àmọ́ tí mo bá délé, ńṣe ni màá bá alábàágbé mi tá á napá nasẹ̀ sílẹ̀ tá á máa wo tẹlifíṣọ̀n, tí oríṣiríṣi pépà àti àjẹkù gbúgbúrú á sì wà káàkiri inú yàrá. Gbogbo ìgbà tí mo bá ń bọ̀ nílé ló jẹ́ pé ohun tí màá délé bá ní mo máa ń rò. Màá sì máa sọ ọ́ lọ́kàn mi pé, ‘Kò sóhun tí mo fẹ́ lọ mú nínú yàrá yẹn o jàre.’”—David.

“Àkẹ́bàjẹ́ lọmọ tá a jọ ń gbé yàrá. Bóyá ó máa ń rò pé òún gba ọmọọ̀dọ̀ sílé ni. Nǹkan tó bá sì ti sọ ló máa ń fẹ́ kí abẹ gé.”—Renee. a

ÀPILẸ̀KỌ kan nínú ìwé ìròyìn U.S.News & World Report sọ pé: “Kíkọ́ láti fara da ìwà àti ìṣesí ẹnì kan téèyàn ò mọ̀ tẹ́lẹ̀ lè kọ́ni ní . . . bá a ti ń mú nǹkan mọ́ra àti bá a ti ń gbójú fo nǹkan dá. Àmọ́ kíkọ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀ kì í rọrùn rárá.” Àwọn tó ti bá ẹlòmíràn gbé yàrá rí lè jẹ́rìí sí ọ̀rọ̀ yìí.

Ọ̀pọ̀ ọmọ ilé ẹ̀kọ́ yunifásítì máa ń ní alábàágbé kí owó gegere tí wọ́n ná lórí ẹ̀kọ́ lè dín kù. Àwọn ọ̀dọ́ kan sì máa ń lọ gbé pẹ̀lú ẹlòmíràn nítorí pé wọ́n fẹ́ kúrò lákàtà àwọn òbí wọn. Láàárín àwọn ọ̀dọ́ tó jẹ́ Kristẹni, ọ̀pọ̀ di ẹni tó ń bá ẹlòmíràn gbé nítorí kí wọ́n lè lépa ire tẹ̀mí. (Mátíù 6:33) Wọ́n rí i pé níní ẹnì kan tí wọ́n á jọ máa pín owó ilé san á ràn wọ́n lọ́wọ́ láti sìn bí ajíhìnrere alákòókò kíkún. Nígbà míì, níní alábàágbéyàrá máa ń di apá kan ìgbésí ayé àwọn míṣọ́nnárì àtàwọn tó ń sìn ní oríṣiríṣi ọ́fíìsì ẹ̀ka àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. b

Jí! bá àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin àtàwọn ọ̀dọ́mọbìnrin díẹ̀ tí wọ́n ti bá èèyàn gbé yàrá rí sọ̀rọ̀. Gbogbo wọn ló sọ pé níní alábàágbéyàrá kọjá pé kéèyàn kàn rí ẹnì kan tí wọ́n á jọ máa pín owó ilé san. Wọ́n ní ẹni téèyàn ń bá gbé yàrá lè jẹ́ alábàákẹ́gbẹ́ ẹni, ẹni téèyàn lè bá sọ̀rọ̀ téèyàn sì lè jọ máa ṣe nǹkan pọ̀. Lynn sọ pé: “A kì í sùn bọ̀rọ̀, àwọn nǹkan táwọn ọmọbìnrin máa ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ la máa ń sọ tàbí ká máa wo tẹlifíṣọ̀n.” Renee sọ pé: “Alábàágbéyàrá tún lè jẹ́ ẹnì kan tó máa ń fúnni níṣìírí. Nígbà míì tó o bá ń ṣiṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́, tó ò ń wò ó pé báwo ni wàá ṣe san gbogbo owó tó yẹ ní sísan, tó o sì ń gbìyànjú láti wàásù, níní alábàágbé tó lè fún ọ níṣìírí dára lọ́pọ̀lọpọ̀.”

Síbẹ̀, bíbá èèyàn gbé lè mú ìṣòro ńlá lọ́wọ́, àgàgà tó bá jẹ́ ẹnì téèyàn ò mọ̀ tẹ́lẹ̀. Nígbà tí ìwé ìròyìn U.S.News & World Report ń sọ nípa ohun tó máa ń ṣẹlẹ̀ láwọn ilé ẹ̀kọ́ gíga, ó sọ pé: “Pẹ̀lú gbogbo akitiyan ńláǹlà tí ọ̀pọ̀ iléèwé máa ń ṣe láti pín àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tó mọwọ́ ara wọn díẹ̀ pọ̀ láti jọ máa gbé yàrá, wàhálà kò yéé ṣẹlẹ̀.” Àní sẹ́, gbọ́nmi-sí-i-omi-ò-to láàárín àwọn ọmọ ilé ẹ̀kọ́ gíga tí wọ́n wà ní yàrá kan náà máa ń dìjà rẹpẹtẹ lọ́pọ̀ ìgbà! Ìyẹn ló mú kí àwọn ibi tí wọ́n ń kọ ìsọfúnni sí lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì ti wà báyìí táwọn akẹ́kọ̀ọ́ lè kọ gbogbo ohun tó lè máa bí wọn nínú nípa àwọn alábàágbéyàrá wọn sí. Kí ló dé tí bíbá ẹlòmíràn gbé inú yàrá fi máa ń fa ìṣòro ná?

Bíbá Ẹni Téèyàn Ò Mọ̀ Rí Gbé

Mark sọ pé: “Nǹkan kékeré kọ́ ni kéèyàn lọ máa bá ẹni tí kò mọ̀ rí gbé o. O ò lè sọ pé irú ọwọ́ báyìí ló máa yọ.” Ká sòótọ́, ìrònú tí bíbá ẹnì kan tọ́rọ̀ yín lè má jọ wọ̀ gbé yàrá máa ń dá síni lára kì í ṣe kékeré. Lóòótọ́, ó yẹ kí ọ̀rọ̀ àwọn tó jẹ́ Kristẹni yéra wọn kí wọ́n sì ní ọ̀pọ̀ nǹkan láti máa bára wọn sọ. Síbẹ̀, David sọ pé: “Ẹ̀rù bíbá èèyàn gbé máa ń bà mí gan-an.”

Ó wá ṣẹlẹ̀ pé, irú àgbègbè kan náà ni David àtẹni tó ń bá gbé ti dàgbà. Àmọ́ kì í ṣe gbogbo àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tí wọ́n bá pín pa pọ̀ lọ̀rọ̀ wọn máa ń wọ̀ o. Mark sọ pé: “Béèyàn bu omi sẹ́nu ẹni tí mo kọ́kọ́ bá gbé yàrá, ibẹ̀ lonítọ̀hún máa bá a. Tíwọ àti ẹnì kan bá jọ ń gbé yàrá, ó ṣe pàtàkì pé kẹ́ ẹ jọ máa sọ̀rọ̀. Àmọ́ tiẹ̀ kò rí bẹ́ẹ̀ o, kò jẹ́ sọ̀rọ̀. Ìgbà tó yá ńṣe ni inú bẹ̀rẹ̀ sí í bí mi.”

Ibi ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tí kálukú ti wá tún máa ń fa àwọn ìṣòro mìíràn. Lynn sọ pé: “Nígbà tó o bá kọ́kọ́ kúrò nílé yín, wàá fẹ́ kó jẹ́ pé bó ṣe wù ẹ́ ni wàá máa ṣe gbogbo nǹkan rẹ. Àmọ́ kò ní pẹ́ tó fi máa yé ọ pé o gbọ́dọ̀ ro tàwọn ẹlòmíì mọ́ tìẹ.” Àní sẹ́, bó o ti ṣẹ̀ṣẹ̀ ń jáde látinú ààbò ìdílé yín, ó lè yà ọ́ lẹ́nu láti rí i pé ojú táwọn èèyàn fi ń wo nǹkan yàtọ̀ pátápátá gbáà.

Ilé Ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, Ìwà Ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀

Púpọ̀ sinmi lórí irú ẹ̀kọ́ tí ẹnì kan gbà lọ́dọ̀ àwọn òbí rẹ̀ tàbí bóyá kò tiẹ̀ gba ẹ̀kọ́ rárá. (Òwe 22:6) Fernando tó jẹ́ ọ̀dọ́ sọ pé: “Afínjú èèyàn ni mí, àmọ́ ọ̀bùn ṣìọ̀ṣìọ̀ lẹni tí mò ń bá gbé yàrá. Ká mú ibi ìkáṣọsí bí àpẹẹrẹ: Ó gbádùn kó máa ju aṣọ síbikíbi tó bá rí. Èmi sì máa ń fẹ́ kéèyàn máa fi aṣọ kọ́ síbi tó yẹ.” Nígbà míì, ìyàtọ̀ gbọ̀ọ̀rọ̀gbọọrọ máa ń wà nínú ohun tí kálukú nífẹ̀ẹ́ sí.

Renee sọ pé: “Mo bá ẹnì kan gbélé nígbà kan tó jẹ́ pé jákujàku ni yàrá tó ń sùn rí! Mo sì tún bá àwọn kan gbé tó jẹ́ pé bí wọ́n bá jẹun tán wọn kì í palẹ̀ mọ́, wọ́n sì lè fi abọ́ tí wọ́n fi jẹun sílẹ̀ láìfọ̀ fún odindi ọjọ́ méjì tàbí mẹ́ta.” Bẹ́ẹ̀ ni, àwọn alábàágbé kan wà tó jẹ́ pé tó bá dọ̀rọ̀ kéèyàn ṣiṣẹ́ ilé, wọ́n ò fi ibì kankan yàtọ̀ sí ọ̀rọ̀ tí Òwe 26:14 sọ pé: “Ilẹ̀kùn ń yí lórí ìkọ́ rẹ̀ olóyìípo, àti ọ̀lẹ lórí àga ìrọ̀gbọ̀kú rẹ̀.”

Tá a bá gba ìdàkejì wò ó, bíbá ẹni tí ìmọ́tótó rẹ̀ légbá kan gbélé kì í gbádùn mọ́ni rárá. Ọ̀dọ́mọbìnrin kan tó ń jẹ́ Lee sọ nípa ẹnì kan tí wọ́n jọ gbé pé: “Lójú tiẹ̀, wákàtí wákàtí lèèyàn gbọ́dọ̀ máa túnlé ṣe. Kì í ṣe pé mo jẹ́ onídọ̀tí èèyàn, àmọ́ ìgbà míì wà tí máa fi àwọn nǹkan sílẹ̀ lórí bẹ́ẹ̀dì mi, irú bí ìwé. A wá máa rò pé gbogbo nǹkan ni òun gbọ́dọ̀ máa rí sí.”

Èrò àwọn méjì tó jọ ń gbé yàrá tún lè yàtọ̀ nípa ìmọ́tótó ara. Mark sọ pé: “Alábàágbé mi máa ń pẹ́ gan-an kó tó jí. Á wá sáré jùàjùà lọ sídìí omi, á fi omi díẹ̀ wọ́n orí rẹ̀, ó lọ nìyẹn.”

Ibi tí wọ́n ti tọ́ kálukú àti ìwà tó ti mọ́ kálukú lára tún lè fa ìyàtọ̀ nínú eré ìnàjú tàbí irú eré ìtura tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ sí. Mark sọ nípa alábàágbé rẹ̀ pé: “A ò nífẹ̀ẹ́ sí irú orin kan náà.” Àmọ́, tí ẹnì kìíní bá fi ọ̀wọ̀ tó yẹ wọ ẹnì kejì, irú àwọn ìyàtọ̀ bẹ́ẹ̀ lè ṣàǹfààní, ó tiẹ̀ lè mú káwọn tó jọ ń gbé yàrá túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ ọ̀pọ̀ orin sí i. Ṣùgbọ́n, lọ́pọ̀ ìgbà, ìjà ni èyí-wù-ẹ́-ò-wù-mí yìí nínú ọ̀rọ̀ orin máa ń dá sílẹ̀. Fernando sọ pé: “Mo fẹ́ràn láti máa gbọ́ orin àwọn ara Sípéènì, àmọ́ ńṣe ni alábàágbé mi máa ń bẹnu àtẹ́ lù ú.”

Lílò Tẹlifóònù Máa Ń Fa Wàhálà

Tẹlifóònù lílò lè jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ohun tó máa ń fa arukutu jù lọ. Mark sọ pé: “Màá fẹ́ẹ́ lọ sùn. Àmọ́ alábàágbé mi á ṣì wà nídìí tẹlifóònù di òrugànjọ́ tá a máa sọ̀rọ̀. Tó bá yá, èyí lè jẹ́ kí inú bẹ̀rẹ̀ sí í bí èèyàn.” Lynn náà sọ irú nǹkan tó jọ bẹ́ẹ̀, ó ní: “Nígbà mi, aago mẹ́ta tàbí mẹ́rin ìdájí làwọn ọ̀rẹ́ alábàágbé mi máa fóònù rẹ̀. Tí kò bá sí nítòsí, o di dandan kí n dìde lọ gbé fóònù náà.” Báwo ni wọ́n ṣe yanjú ẹ̀? “A rí sí i pé kálukú ní fóònù tiẹ̀.”

Àmọ́ gbogbo ọ̀dọ́ kọ́ ló lówó àtigba fóònù tara wọn, ó sì di dandan káwọn kan máa pín ẹyọ kan lò. Èyí lè fa aáwọ̀ tí kì í ṣe kékeré. Renee sọ pé: “Ọ̀kan lára àwọn tá a jọ ń gbé ní ọ̀rẹ́kùnrin kan, gbogbo ìgbà ni wọ́n jọ máa ń sọ̀rọ̀ lórí fóònù fún ọ̀pọ̀ wákàtí. Oṣù kan wà tó jẹ gbèsè àádọ́rùn-ún dọ́là. Ó wá ń retí pé kí àwa tó kù san lára rẹ̀ nítorí pé a ti jọ ṣàdéhùn pé ńṣe ni a óò máa pín owó fóònù san lọ́gbọọgba.”

Rírí fóònù lò tún lè jẹ́ ìṣòro mìíràn. Lee sọ pé: “Mo bá ẹnì kan gbé tó dàgbà jù mí lọ, fóònù kan ṣoṣo la sì ní. Gbogbo ìgbà ni mo máa ń lo fóònù torí mo lọ́rẹ̀ẹ́ tó pọ̀. Àmọ́ kò jẹ́ sọ nǹkankan. Èrò tèmi ni pé, tó bá fẹ́ lo fóònù á jẹ́ kí n mọ̀. Ìsinsìnyí ni mo ṣẹ̀ṣẹ̀ wá mọ̀ pé ohun tí mò ń ṣe nígbà yẹn kò dáa.”

Kéèyàn Má Lè Wà Lóun Nìkan

David sọ pé: “Kò sẹ́ni tí kì í fẹ́ láti dá wà láwọn àkókò kan. Nígbà míì, á kàn wù mí kí n fẹ̀yìn lélẹ̀ láìṣe nǹkan kan.” Àmọ́, rírí àkókò láti dá wà ní ìwọ nìkan lè máà rọrùn tó o bá ń bá èèyàn gbé yàrá. Mark sọ pé: “Ó máa ń wù mí kí n wà lémi nìkan. Ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ pé ìṣòro mi tó tóbi jù lọ ni rírí àkókò tí mo lè fi dá wà. Ìgbà kan náà ni ìgbòkègbodò èmi àti alábàágbé mi bọ́ sí. Nítorí náà, ó máa ń nira láti rí àkókò láti wà lémi nìkan.”

Àwọn ìgbà kan wà tí Jésù Kristi alára fẹ́ láti wà lóun nìkan. (Mátíù 14:13) Tó bá ṣòro tàbí tí kò ṣeé ṣe rárá láti kàwé, láti kẹ́kọ̀ọ́ tàbí láti ṣàṣàrò nítorí pé ẹni tẹ́ ẹ jọ ń gbé wà nítòsí, èyí lè mú kí inú bẹ̀rẹ̀ sí í bí èèyàn. Mark sọ pé: “Kì í rọrùn fún mi láti kẹ́kọ̀ọ́ nítorí pé kò sígbà kan tí yàrá wa ń pa rọ́rọ́. Alábàágbé mi lè kó àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ wálé, ó lè máa lo tẹlifóònù, ó sì lè máa wo tẹlifíṣọ̀n tàbí kó máa gbọ́ rédíò.”

Síbẹ̀síbẹ̀, bó ti wù kó ṣòro láti fara da ìwà alábàágbé ẹni tó, ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọ̀dọ́ ti ṣàṣeyọrí nínú ṣíṣe bẹ́ẹ̀. Àwọn àpilẹ̀kọ tó ń bọ̀ lọ́nà nínú ọ̀wọ́ yìí yóò jíròrò àwọn ọ̀nà díẹ̀ tó fi lè ṣeé ṣe láti rí adùn tó pọ̀ nínú gbígbé pẹ̀lú ẹnì kan.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a A ti yí àwọn orúkọ kan padà

b Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ọ̀dọ́ la torí ẹ̀ kọ àpilẹ̀kọ yìí, ó tún lè wúlò fún àwọn àgbàlagbà tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í bá ẹlòmíràn gbé pẹ̀lú lẹ́yìn tí ipò ìgbésí ayé wọn yí padà, bóyá lẹ́yìn tí ọkọ wọn tàbí aya wọn ṣaláìsí.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10, 11]

Ṣíṣàì nífẹ̀ẹ́ irú orin tí ẹnì kejì nífẹ̀ẹ́ sí lè fa arukutu

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12]

Àìkì í gba tẹlòmíràn rò lè fa ìṣòro