Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwọn Ohun Arùfé-Ìṣekúṣe-Sókè—Ṣé Nǹkan Ṣeréṣeré Lásán ni Wọ́n?

Àwọn Ohun Arùfé-Ìṣekúṣe-Sókè—Ṣé Nǹkan Ṣeréṣeré Lásán ni Wọ́n?

Ojú Ìwòye Bíbélì

Àwọn Ohun Arùfé-Ìṣekúṣe-Sókè—Ṣé Nǹkan Ṣeréṣeré Lásán ni Wọ́n?

LÁKÒÓKÒ tí Ọbabìnrin Victoria ti ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì ń ṣàkóso, kò sí ìwà pálapàla bíi tòde ìwòyí, àmọ́ àwọn ohun táwọn awalẹ̀pìtàn ìgbà náà rí nígbà tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í hú àwọn àwókù láéláé ti ìlú Pompeii jáde yà wọ́n lẹ́nu gan-an. Nínú àwọn àwòrán àlẹ̀mógiri àti àwọn iṣẹ́ ọnà tó jojú ní gbèsè ni wọ́n ti rí àwọn ohun gbígbẹ́ àti àwòrán tó ń fi ìhòòhò goloto àti ìṣekúṣe hàn lọ́nà tó burú jáì. Àwọn àwòrán náà kóni nírìíra débi pé, ńṣe ni ìjọba ní kí wọ́n lọ kó wọn pa mọ́ sáwọn ilé ìkóhun-ìṣẹ̀ǹbáyé-sí tó wà ní kọ́lọ́fín. Látinú àwọn ọ̀rọ̀ èdè Gíríìkì méjì kan tó túmọ̀ sí “kíkọ̀wé nípa ìṣe àwọn aṣẹ́wó” ni wọ́n ti mú ọ̀rọ̀ náà, “arùfẹ́-ìṣekúṣe-sókè” jáde. Lóde òní, ìtumọ̀ tí wọ́n fún un ni “fífi àwòrán ìṣekúṣe hàn nínú ìwé, nínú àwòrán, lára ère gbígbẹ́, nínú sinimá, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ, pẹ̀lú ète láti ru ìfẹ́ ìbálòpọ̀ sókè.”

Lọ́jọ́ òní, àwọn nǹkan tó ń ru ìfẹ́ ìṣekúṣe sókè ti pọ̀ yamùrá, ó sì jọ pé ibi gbogbo ni wọ́n ti tẹ́wọ́ gbà á. Tẹ́lẹ̀ rí, ibi tí wọ́n ti máa ń rí wọn ni àwọn ilé sinimá tí kò bójú mu àti àwọn àdúgbò tí ilé aṣẹ́wó pọ̀ sí, àmọ́ ó ti wá di ohun tó wọ́pọ̀ gan-an báyìí níbi púpọ̀, wọn ò sì fi bò rárá. Ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà nìkan ṣoṣo, owó táwọn ohun arùfẹ́-ìṣekúṣe-sókè ń pa wọlé lọ́dọọdún lé ní bílíọ̀nù mẹ́wàá dọ́là!

Àwọn kan tí wọn ò róhun tó burú nínú rẹ̀ sọ pé ó máa ń jẹ́ kí ìgbéyàwó tí ìfẹ́ ti sọ nù nínú rẹ̀ tún máa dùn padà. Òǹkọ̀wé kan sọ pé: “Ó máa ń mú èèyàn lálàá ọ̀sán gangan. Ó ń fúnni ní ìtọ́ni lórí béèyàn ṣe lè gbádùn ìbálòpọ̀.” Àwọn mìíràn sọ pé ó máa ń lé ìtìjú dà nù nígbà ìbálòpọ̀. Òǹkọ̀wé Wendy McElroy ní tiẹ̀ sọ pé: “Ohun arùfẹ́-ìṣekúṣe-sókè máa ń ṣe àwọn obìnrin láǹfààní.”

Àmọ́ kì í ṣe gbogbo èèyàn ló gbà bẹ́ẹ̀. Ọ̀pọ̀ ìgbà ni wọ́n ti sọ pé, wíwo àwòrán ìṣekúṣe ló máa ń fa ìwàkiwà lóríṣiríṣi, ó sì máa ń ní àwọn àbájáde burúkú. Àwọn kan tiẹ̀ sọ pé, fífipá báni lòpọ̀ àti híhùwà ipá oríṣiríṣi sáwọn obìnrin àtàwọn ọmọdé kò ṣẹ̀yìn àwọn ohun arùfẹ́-ìṣekúṣe-sókè. Ted Bundy, ẹni tí òkìkí rẹ̀ kàn fún bó ṣe gbẹ̀mí àwọn èèyàn lọ bí ilẹ̀ bí ẹní, jẹ́wọ́ pé, “ńṣe ló máa ń ṣe òun bíi pé kóun kàn máa wo àwọn ohun arùfẹ́-ìṣekúṣe-sókè tó ní ìwà ipá ṣáá ni.” Ó sọ pé: “Ẹni tó bá ní ìṣòro yìí kì í tètè mọ̀ pé òun ní ìṣòro ńlá kan. . . . Tó bá wá yá . . . á wá máa ṣe onítọ̀hún bíi pé kó máa ní ìbálòpọ̀ lọ́nà tó mú ìwà ipá dání. Mo fẹ́ ẹ́ fi dá a yín lójú pé, díẹ̀díẹ̀ ni ìfẹ́ láti wo ìṣekúṣe oníwà ipá yìí máa ń wọ èèyàn lára. Kì í bẹ̀rẹ̀ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀.”

Pẹ̀lú bí àríyànjiyàn lórí àwọn ohun arùfẹ́-ìṣekúṣe-sókè ṣe ń bá a lọ láìdáwọ́dúró yìí, tó sì tún ti di ohun tó wọ́pọ̀ rẹpẹtẹ lónìí, o lè wá máa wò ó pé, ‘Ǹjẹ́ Bíbélì tiẹ̀ pèsè ìtọ́sọ́nà kankan lórí ọ̀ràn yìí?’

Bíbélì Kò Fọ̀rọ̀ Sábẹ́ Ahọ́n Sọ Nípa Ìbálòpọ̀ Takọtabo

Nígbà tí Bíbélì bá ń sọ̀rọ̀ tó ní í ṣe pẹ̀lú ìbálòpọ̀, kì í fọ̀rọ̀ bọpobọyọ̀ bẹ́ẹ̀ ni kì í sì sọ ọ́ bí ohun ìtìjú. (Diutarónómì 24:5; 1 Kọ́ríńtì 7:3, 4) Sólómọ́nì gbani nímọ̀ràn pé: “Máa yọ̀ pẹ̀lú aya ìgbà èwe rẹ . . . Jẹ́ kí ọmú tirẹ̀ máa pa ọ́ bí ọtí ní gbogbo ìgbà.” (Òwe 5:18, 19) Bíbélì pèsè ìmọ̀ràn àti ìtọ́sọ́nà tó ṣe kedere nípa ìbálòpọ̀, títí kan ibi téèyàn gbọ́dọ̀ fi mọ sí. Ó ka níní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú ẹni tí kì í ṣe aya tàbí ọkọ ẹni léèwọ̀. Bẹ́ẹ̀ ló sì tún ka gbogbo àṣà ìbálòpọ̀ tí kò bójú mu léèwọ̀.—Léfítíkù 18:22, 23; 1 Kọ́ríńtì 6:9; Gálátíà 5:19.

Síbẹ̀, láàárín àwọn tí Bíbélì tiẹ̀ fi ìbálòpọ̀ mọ sí pàápàá, a tún retí pé kí wọ́n lo ìkóra-ẹni-níjàánu àti ọ̀wọ̀. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Kí ìgbéyàwó ní ọlá láàárín gbogbo ènìyàn, kí ibùsùn ìgbéyàwó sì wà láìní ẹ̀gbin.” (Hébérù 13:4) Òdìkejì pátápátá ni ìmọ̀ràn yìí jẹ́ sí ète tí àwọn ohun arùfẹ́-ìṣekúṣe-sókè wà fún àtàwọn ohun tó ń fi kọ́ni.

Àwọn Ohun Arùfẹ́-Ìṣekúṣe-Sókè Ń Yí Ète Ìbálòpọ̀ Padà

Dípò tí àwọn ohun tó ń ru ìfẹ́ ìṣekúṣe sókè ì bá fi fi ìbálòpọ̀ hàn gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà tó dára fún ọkùnrin kan àti obìnrin kan tí wọ́n jọ ṣe ìgbéyàwó tó níyì láti gbà fi ìfẹ́ jíjinlẹ̀ hàn síra wọn, ńṣe ló ń tàbùkù sí ìbálòpọ̀ takọtabo tó sì ń yí ète tó wà fún padà. Ó máa ń fi níní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú ẹnikẹ́ni àti níní ìbálòpọ̀ lọ́nà òdì hàn bí ohun tó gbádùn mọ́ni tó sì bójú mu. Títẹ́ ara ẹni lọ́rùn nìkan ni olórí ète rẹ̀ láìbìkítà nípa ẹnì kejì.

Àwọn ohun arùfẹ́-ìṣekúṣe-sókè máa ń fi obìnrin, ọkùnrin, àtàwọn ọmọdé hàn bíi pé ohun èlò ìbálòpọ̀ lásán ni wọ́n jẹ́. Ìròyìn kan sọ pé: “Ohun tí wọ́n máa ń fi díwọ̀n ẹwà ni bí ìrísí ẹnì kan ṣe rí, tí wọ́n á máa retí ohun tí kò ṣeé ṣe.” Ìròyìn mìíràn sọ pé: “Fífi àwọn obìnrin hàn bí ẹni tí kò já mọ́ nǹkankan, bí ẹni tó máa ń fìgbà gbogbo retí ìfà, bí ohun èlò ìbálòpọ̀ lásánlàsàn lọ́wọ́ ọkùnrin, àti jíjẹ́ kí wọ́n máa túra síhòòhò kí wọ́n sì máa ṣí ara síta nítorí owó àti láti dá àwọn èèyàn lára yá kò bọ́ sí i rárá. Ṣíṣe èyí kò fi àwọn obìnrin hàn bí ẹni iyì ẹni ẹ̀yẹ, tó yẹ láti kà sí, ká sì ní ìgbatẹnirò fún.”

Ní ìdàkejì, Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé ìfẹ́ “kì í hùwà lọ́nà tí kò bójú mu, kì í wá àwọn ire tirẹ̀ nìkan.” (1 Kọ́ríńtì 13:5) Bíbélì gba àwọn ọkùnrin níyànjú láti “nífẹ̀ẹ́ àwọn aya wọn gẹ́gẹ́ bí ara àwọn fúnra wọn” kí wọ́n sì “máa fi ọlá fún wọn,” kì í ṣe pé kí wọ́n máa wò wọ́n bí ohun èlò tó kàn wà fún títẹ́ ìfẹ́ ìbálòpọ̀ wọn lọ́rùn. (Éfésù 5:28; 1 Pétérù 3:7) Ṣé ẹnì kan, ì báà jẹ́ ọkùnrin tàbí obìnrin, tó ń fìgbà gbogbo wo àwòrán àwọn mìíràn tí wọ́n ń ní ìbálòpọ̀ lè sọ lóòótọ́ pé òun ń hùwà lọ́nà tó bójú mu? Ṣé ẹni yẹn sì ń fi ọlá àti ọ̀wọ̀ hàn lóòótọ́? Dípò tí àwọn ohun arùfẹ́-ìṣekúṣe-sókè ì bá fi fi ìfẹ́ kọ́ni, ńṣe ló máa ń sọni di anìkànjọpọ́n àti onífẹ̀ẹ́kúfẹ̀ẹ́.

Kókó mìíràn tún wà tó yẹ láti gbé yẹ̀ wò. Bíi ti ohunkóhun mìíràn tó máa ń ru èrò tí kò tọ́ sókè nínú ẹnì kan, láìpẹ́, ohun tó ti kọ́kọ́ ń rùfẹ́ ìṣekúṣe sókè lè máà tún jẹ́ nǹkankan sí ẹni náà mọ́. Òǹkọ̀wé kan sọ pé: “Bópẹ́ bóyá, [àwọn tó ń wo ìwòkuwò] á tún máa wá èyí tó túbọ̀ bà jẹ́ bàlùmọ̀ ju èyí tí wọ́n ti ń wò tẹ́lẹ̀ lọ . . . Wọ́n lè bẹ̀rẹ̀ sí í rọ ọkọ wọn tàbí aya wọn ṣáá láti máa ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú wọn lọ́nà tí kò bójú mu rárá . . . , èyí kò sì ní í jẹ́ kí àwọn [gan-an] lè fi ìfẹ́ tòótọ́ hàn mọ́.” Ǹjẹ́ ọ̀rọ̀ òǹkọ̀wé yìí fi hàn pé ohun ṣeréṣeré kan tí kò léwu nínú ni àwọn ohun arùfẹ́-ìṣekúṣe-sókè? Síbẹ̀, ìdí mìíràn kan tó ṣe pàtàkì wà, tó fi yẹ kéèyàn yẹra fún àwọn ohun tó ń ru ìfẹ́ ìṣekúṣe sókè.

Ojú Tí Bíbélì Fi Ń Wo Ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ èèyàn lónìí lè máa rò pé kò sóhun tó burú nínú ríru ìfẹ́ ìbálòpọ̀ sókè tàbí pé kò léwu, Bíbélì kò fara mọ́ èyí. Ó ṣàlàyé ní kedere pé, kò sọ́gbọ́n kí àwọn ohun tá à ń kó sí ọpọlọ máà nípa lórí ìṣesí wa. Kristẹni ọmọ ẹ̀yìn náà, Jákọ́bù sọ pé: “Olúkúlùkù ni a ń dán wò nípa fífà á jáde àti ríré e lọ nípasẹ̀ ìfẹ́-ọkàn òun fúnra rẹ̀. Lẹ́yìn náà, ìfẹ́-ọkàn náà, nígbà tí ó bá lóyún, a bí ẹ̀ṣẹ̀.” (Jákọ́bù 1:14, 15) Jésù sọ pé: “Olúkúlùkù ẹni tí ń bá a nìṣó ní wíwo obìnrin kan láti ní ìfẹ́ onígbòónára sí i, ti ṣe panṣágà pẹ̀lú rẹ̀ ná nínú ọkàn-àyà rẹ̀.”—Mátíù 5:28.

Gẹ́gẹ́ bí Jákọ́bù àti Jésù ti sọ, ohun tó bá wà lọ́kàn ẹ̀dá èèyàn ni wọ́n máa ń fi hùwà. Tí wọ́n bá wá túbọ̀ ń ṣe àwọn ohun tó máa fínná mọ́ ìfẹ́ ọkàn yìí, bí àkókò ti ń lọ, ó lè di ohun tí wọ́n á máa ronú nípa rẹ̀ ṣáá. Bẹ́ẹ̀ sì rèé, ohun téèyàn bá ń ronú nípa rẹ̀ nígbà gbogbo máa ń ṣòro láti kápá ó sì lè ti èèyàn hùwà. Nípa bẹ́ẹ̀, àwọn ohun tá à ń kó sí ọpọlọ máa ń nípa lílágbára lórí ohun tá a máa ṣe lẹ́yìn-ò-rẹyìn.

Fífọkàn yàwòrán ìbálòpọ̀ lè ba ìjọsìn wa sí Ọlọ́run jẹ́. Ìdí nìyẹn tí Pọ́ọ̀lù fi kọ̀wé pé: “Nítorí náà, ẹ sọ àwọn ẹ̀yà ara yín . . . di òkú ní ti àgbèrè, ìwà àìmọ́, ìdálọ́rùn fún ìbálòpọ̀ takọtabo, ìfẹ́-ọkàn tí ń ṣeni lọ́ṣẹ́, àti ojúkòkòrò, tí í ṣe ìbọ̀rìṣà.”—Kólósè 3:5.

Níbẹ̀, Pọ́ọ̀lù so níní ìdálọ́rùn fún ìbálòpọ̀ takọtabo mọ́ ojúkòkòrò, èyí tó jẹ́ níní ìfẹ́ àìníjàánu fún ohun tí kì í ṣe tẹni. a Ojúkòkòrò jẹ́ oríṣi ìbọ̀rìṣà kan. Kí nìdí? Nítorí pé olójú kòkòrò èèyàn máa ń fi ohun tó ń fẹ́ yẹn ṣáájú ohunkóhun mìíràn, títí kan Ọlọ́run. Àwọn ohun arùfẹ́-ìṣekúṣe-sókè máa ń mú kéèyàn ní ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ sí ohun téèyàn ò ní. Òǹkọ̀wé kan nípa ìsìn sọ pé: “Wàá fẹ́ láti mọ̀ nípa ọ̀nà táwọn ẹlòmíràn ń gbà ní ìbálòpọ̀. . . . Kò sóhun mìíràn tá á máa gbà ẹ́ lọ́kàn ju ìfẹ́ ọkàn àìníjàánu láti gbádùn ohun tí kì í ṣe tìẹ. . . . Ohun téèyàn bá ń nífẹ̀ẹ́ sí lójú méjèèjì ló máa di ọlọ́run tí onítọ̀hún ń jọ́sìn.”

Àwọn Ohun Arùfẹ́-Ìṣekúṣe-Sókè Ń Sọni Dìdàkudà

Bíbélì gbà wá níyànjú pé: “Ohun yòówù tí ó jẹ́ mímọ́ níwà, ohun yòówù tí ó dára ní fífẹ́, ohun yòówù tí a ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ dáadáa, ìwà funfun yòówù tí ó bá wà . . . , ẹ máa bá a lọ ní gbígba nǹkan wọ̀nyí rò.” (Fílípì 4:8) Ńṣe ni ẹnì kan tó bá ń fìgbà gbogbo wo àwọn ohun arùfẹ́-ìṣekúṣe-sókè ń kọ ìmọ̀ràn Pọ́ọ̀lù sílẹ̀. Àwọn ohun arùfẹ́-ìṣekúṣe-sókè kò bójú mu rárá nítorí pé wọ́n máa ń fi àjọṣe àárín ẹ̀dá méjì han síta láìtijú rárá. Ohun ìríra gbáà ló jẹ́ nítorí pé ó ń rẹni wálẹ̀, kò sì fi ọ̀wọ̀ àti ìgbatẹnirò hàn fún àwọn ẹlòmíràn. Kò fi ìfẹ́ hàn nítorí pé kì í fi ẹ̀mí ìbánikẹ́dùn àti aájò kọ́ni. Ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ lásán ló ń gbé lárugẹ.

Bí àwọn ohun arùfẹ́-ìṣekúṣe-sókè ṣe ń fi ìwà pálapàla hàn lọ́nà bíburú jáì ń ṣàkóbá fún àwọn ìsapá Kristẹni kan láti “kórìíra ohun búburú.” (Ámósì 5:15) Ó máa ń gbé ẹ̀ṣẹ̀ lárugẹ, òdìkejì pátápátá ló sì jẹ́ sí ọ̀rọ̀ ìṣírí tí Pọ́ọ̀lù fún àwọn ará Éfésù, pé “kí a má tilẹ̀ mẹ́nu kan àgbèrè àti ìwà àìmọ́ onírúurú gbogbo tàbí ìwà ìwọra láàárín yín, gẹ́gẹ́ bí ó ti yẹ àwọn ènìyàn mímọ́; bẹ́ẹ̀ náà ni ìwà tí ń tini lójú . . . tàbí ìṣẹ̀fẹ̀ rírùn, àwọn ohun tí kò yẹ.”—Éfésù 5:3, 4.

Àwọn ohun arùfẹ́-ìṣekúṣe-sókè léwu gan-an ni. Ó máa ń sọni dìdàkudà ó sì ń ba tẹni jẹ́. Ó lè ba àjọṣe jẹ́ pàápàá, nítorí pé ó máa ń jẹ́ kí oníwòkuwò ẹ̀dá máa fojú tí kò yẹ wo ìbálòpọ̀. Ó máa ń ba ìrònú àti ipò tẹ̀mí ẹni tó ń wo ìwòkuwò náà jẹ́. Ó máa ń sọni di onímọtara-ẹni-nìkan àti olójúkòkòrò, ó sì ń kọ́ àwọn èèyàn láti máa wo àwọn ẹlòmíràn bí ohun èlò kan ṣá láti tẹ́ ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ wọn lọ́rùn. Kì í jẹ́ kí èèyàn lè hùwà tó dára kéèyàn sì ní ẹ̀rí ọkàn tó mọ́. Èyí tó wá ṣe kókó jù lọ ni pé, ó lè ṣàkóbá fún ipò tẹ̀mí ẹni tàbí kó ba àjọṣe èèyàn pẹ̀lú Ọlọ́run jẹ́ ráúráú. (Éfésù 4:17-19) Ní ti tòótọ́, àrùn tó yẹ kéèyàn sá fún pátápátá ni àwọn ohun arùfẹ́-ìṣekúṣe-sókè jẹ́.—Òwe 4:14, 15.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Ìdálọ́rùn fún ìbálòpọ̀ tó bójú mu kọ́ ni Pọ́ọ̀lù ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ níbí, ìyẹn ìfẹ́ láti ní ìbálòpọ̀ tó bójú mu pẹ̀lú ọkọ ẹni tàbí aya ẹni.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]

Àwọn ohun arùfẹ́-ìṣekúṣe-sókè máa ń jẹ́ kí ẹnì kan máa wo ẹ̀yà kejì gẹ́gẹ́ bí ohun èlò ìbálòpọ̀ lásán