Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwọn Ọ̀dọ́langba Tó Máa Ń sùn Ṣáá—Ṣé Ọ̀ràn Wọn Ò Ń Fẹ́ Àmójútó Báyìí?

Àwọn Ọ̀dọ́langba Tó Máa Ń sùn Ṣáá—Ṣé Ọ̀ràn Wọn Ò Ń Fẹ́ Àmójútó Báyìí?

Àwọn Ọ̀dọ́langba Tó Máa Ń sùn Ṣáá—Ṣé Ọ̀ràn Wọn Ò Ń Fẹ́ Àmójútó Báyìí?

LÁTỌWỌ́ AKỌ̀RÒYÌN JÍ! NÍ KÁNÁDÀ

ÌWÉ ìròyìn The Globe and Mail ti ilẹ̀ Kánádà sọ pé, téèyàn ò bá sun oorun tó tó, onítọ̀hún ò ní lè ronú lọ́nà tó já gaara, á tún tètè máa gbàgbé nǹkan, àwọn ọ̀dọ́langba akẹ́kọ̀ọ́ ló sì dojú kọ ewu yìí jù lọ. “Bí àwọn ọmọdé àtàwọn ọ̀dọ́langba kò bá sùn tó, ó tún máa ń fa híhùwà lọ́nà òdì, kéèyàn máa ṣe bí ẹni tára ń kan, kí ara ẹni má sì balẹ̀.” Àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ fara balẹ̀ ṣèwádìí lórí bí àwọn ọmọ ilé ẹ̀kọ́ gíga tó tó nǹkan bí ẹgbẹ̀rún méjì ó lé igba [2,200] ṣe máa ń sùn sí, wọ́n sì rí i pé nǹkan bí ìdá mẹ́tàdínláàádọ́ta nínú ọgọ́rùn-ún wọn ni kì í sun oorun pé wákàtí mẹ́jọ lálaalẹ́, èyí tí wọ́n dámọ̀ràn fún gbogbo èèyàn.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé báwọn ọ̀dọ́ ṣe ń gbé ìgbésí ayé wọn kì í jẹ́ kí wọ́n sùn tó bí ara wọn ṣe nílò rẹ̀, síbẹ̀, ìwé ìròyìn The Globe and Mail sọ pé, “àwọn kan lára wọn tún lè ní àwọn àìlera kan tí kò tíì fojú hàn. Ìdá mẹ́rin nínú ọgọ́rùn-ún àwọn ọmọdé, láti ọmọ ọdún mẹ́rin sí méjìdínlógún ló ní ìṣòro kan tí wọ́n ń pè ní sleep apnea, èyí tí kì í jẹ́ kéèyàn sùn dáadáa lóru àmọ́ tí onítọ̀hún á máa sùn ṣáá lọ́sàn-án.” Nígbà téèyàn bá ń sùn lọ́wọ́, ibi tí afẹ́fẹ́ máa ń gbà kọjá lẹ́yìn ọ̀fun lè máà ṣí sílẹ̀ dáadáa tàbí kó tiẹ̀ pa dé pátápátá, èyí á sì ṣèdíwọ́ fún afẹ́fẹ́ oxygen láti ráyè kọjá dáadáa. Nípa báyìí, ọpọlọ ò ní í sinmi dáadáa, ńṣe ló sì máa rẹ àwọn ọmọdé nígbà tí wọ́n bá jí, tí wọ́n á sì tún máa kanra.

Lára àwọn àmì tó máa ń fi hàn pé ó ṣeé ṣe kí ọmọ kan ní ìṣòro sleep apnea ni, kó máa han-anrun tàbí kó máa mí pẹ̀lú agbára nígbà tó bá ń sùn lọ́wọ́, kí orí máa fọ́ ọ láràárọ̀, kó máa gbàgbé nǹkan kó má sì lè pọkàn pọ̀, bákan náà ni kó máa sùn ṣáá lójú mọmọ. Wọ́n rọ àwọn òbí láti máa tẹ́tí sí àwọn ọmọ wọn lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan nígbà tí wọ́n bá ti sùn wọra. Dókítà Robert Brouillette, tó jẹ́ onímọ̀ nípa ìṣòro oorun àwọn ọmọdé ní ilé ìwòsàn Montreal Children’s Hospital, sọ pé tí ọmọ kan bá ní àìsàn kan, ó lè máa dáwọ́ mímí dúró tó bá ń sùn, bó tilẹ̀ jẹ́ pé àyà rẹ̀ lè máa lọ sókè lọ sódò. “Ọmọ náà lè tún bẹ̀rẹ̀ sí í mí padà tó bá ṣèèṣì ta jí tó [sì] mí èémí díẹ̀ kó tó ó tún padà sùn lọ.” Èyí lè ṣẹlẹ̀ ní ọgọ́rọ̀ọ̀rún ìgbà kí ilẹ̀ tó ó mọ́, tá á sì wá rẹ ọmọ náà tẹnutẹnu nígbà tó bá jí.

Ẹgbẹ́ Tó Ń Rí Sí Ìṣòro Oorun ní Ilẹ̀ Amẹ́ríkà wá dámọ̀ràn sísùn nínú yàrá tí kò sí ooru, èyí tó ṣókùnkùn, tí kò sì ní àwọn nǹkan tó lè ṣèdíwọ́ bíi tẹlifíṣọ̀n tàbí ẹ̀rọ kọ̀ǹpútà. Lílọ sùn ní àkókò kan náà àti jíjí ní àkókò kan náà ní gbogbo ìgbà á tún ṣèrànwọ́ fún àwọn ọmọ kéékèèké àtàwọn ọ̀dọ́langba láti máa sùn dáadáa lóru. Àwọn kan tó ní ìṣòro sleep apnea ti lo ẹ̀rọ kan tó máa ń rọra fẹ́ atẹ́gùn sínú ihò imú àti ẹnu, láti mú kí apá ẹ̀yìn ọ̀nà ọ̀fun wọn wà ní ṣíṣí sílẹ̀ nígbà tí wọ́n bá ń sùn lọ́wọ́. Dókítà kan tó máa ń ṣètọ́jú àwọn ọmọ wẹ́wẹ́ sọ pé: “Oorun ṣe pàtàkì ju oúnjẹ tá à ń jẹ lọ. Ó ṣe pàtàkì ju eré ìmárale lọ. Òun ló ń ṣàkóso omi ara tó máa ń súnni ṣe nǹkan, ìmọ̀lára wa àti ètò ìdènà àrùn inú ara wa.”