Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Báwo ni Mo Ṣe Lè Yan Àwọn Fídíò Orin Tó Bójú Mu?

Báwo ni Mo Ṣe Lè Yan Àwọn Fídíò Orin Tó Bójú Mu?

Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . .

Báwo ni Mo Ṣe Lè Yan Àwọn Fídíò Orin Tó Bójú Mu?

“Bí mo bá ti rí orúkọ ẹgbẹ́ olórin kan tàbí orin kan tí kò fi bẹ́ẹ̀ bójú mu báyìí, ńṣe ni mo máa ń yí tẹlifíṣọ̀n sí ibòmíràn.”—Casey.

Ọ̀PỌ̀LỌPỌ̀ ọ̀dọ́ ló ń gbádùn wíwo fídíò orin gan-an. Àmọ́ gẹ́gẹ́ bí àpilẹ̀kọ tó ṣáájú èyí ṣe ṣàlàyé, ọ̀pọ̀ àwọn fídíò orin ló máa ń ní ìwà pálapàla àti ìwà ipá tó ń múni gbọ̀n rìrì nínú. a Kí a má ṣẹ̀ṣẹ̀ tún máa sọ ọ́, bí eré ìnàjú èyíkéyìí bá ń gbé àwọn ohun tí Ọlọ́run kò fẹ́ lárugẹ, Kristẹni kan ní láti yẹra fún wíwò ó. Àmọ́ o, kì í ṣe gbogbo fídíò orin ló fi bẹ́ẹ̀ ní ìwà pálapàla nínú. Àwọn kan lè bójú mu dé àyè kan. Ó sì lè dà bíi pé ìwà ipá inú àwọn kan kò burú jáì. Síbẹ̀, irú àwọn fídíò bẹ́ẹ̀ lè máa fi ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ gbin àwọn ohun tí kò bá Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run mu síni lọ́kàn.

Bí àwọn òbí rẹ bá gbà ọ́ láyè láti máa wo fídíò orin, ó gbọ́dọ̀ ní irú èyí tí wàá máa wò. Èyí á sì béèrè pé kó o máa lo “agbára ìwòye” rẹ tó o ti fi Bíbélì dá lẹ́kọ̀ọ́, kó bàa lè ṣeé ṣe fún ọ láti fi ìyàtọ̀ sáàárín ohun tó dára láti wò àti ohun tí kò dára. (Hébérù 5:14) Àwọn ìlànà Bíbélì wo ló lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti ṣe èyí? Àwọn ẹsẹ Bíbélì àti àlàyé tó wà nísàlẹ̀ wọ̀nyí lè ṣèrànwọ́ fún ọ.

Òwe 4:23: “Ju gbogbo ohun mìíràn tí a ní láti ṣọ́, fi ìṣọ́ ṣọ́ ọkàn-àyà rẹ, nítorí láti inú rẹ̀ ni àwọn orísun ìyè ti wá.” Ǹjẹ́ o ní ohun èlò eré ìdárayá kan tàbí ohun èlò orin kan tó o fẹ́ràn gan-an? Láìsí àní-àní, ńṣe ni wàá máa rí i dájú pé ó wà ní ipò tó dára, wàá sì máa tọ́jú rẹ̀ síbi tí nǹkan ò ti ní í ṣe é. Ó dájú pé, o ò ní gbé e sí ẹ̀bá ọ̀nà láìfi ẹnì kan ṣọ́ ọ, kódà fún ìṣẹ́jú kan pàápàá, nítorí wàá máa bẹ̀rù pé nǹkan kan lè bà á jẹ́ tàbí kí ẹnì kan jí i. Ní ti tòótọ́, ńṣe ni wàá máa ṣọ́ ọ. Lọ́nà kan náà, o ní láti pinnu pé wàá máa ṣọ́ ọkàn rẹ, o ò sì ní fi sínú ewu àní fún ìṣẹ́jú kan pàápàá, nípa wíwo àwọn eré ìnàjú tí kò bójú mu.

Éfésù 2:1, 2: “Ẹ̀yin ni Ọlọ́run sọ di ààyè bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ ti kú nínú àwọn àṣemáṣe àti àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín, nínú èyí tí ẹ ti rìn ní àkókò kan rí ní ìbámu pẹ̀lú ètò àwọn nǹkan ti ayé yìí, ní ìbámu pẹ̀lú olùṣàkóso ọlá àṣẹ afẹ́fẹ́, ẹ̀mí tí ń ṣiṣẹ́ nísinsìnyí nínú àwọn ọmọ àìgbọ́ràn.” Ẹ̀mí ayé ni afẹ́fẹ́ náà, ìyẹn ni ìrònú àti ẹ̀mí tó ń sún àwọn èèyàn láti hu àwọn ìwà tí kò bá ìfẹ́ Ọlọ́run mu. Ẹ̀mí yìí máa ń fara hàn gbangba nínú ọ̀pọ̀ àwọn fídíò orin, ó sì lòdì pátápátá sí ẹ̀mí Ọlọ́run, èyí tó máa ń jẹ́ kéèyàn ní àwọn ànímọ́ bí ìdùnnú, àlàáfíà, àti ìkóra-ẹni-níjàánu.—Gálátíà 5:22, 23.

2 Tímótì 2:22: “Sá fún àwọn ìfẹ́-ọkàn tí ó máa ń bá ìgbà èwe rìn.” Wíwo àwọn ìran tó ń fi ìbálòpọ̀ takọtabo hàn, kódà fún àkókò kúkúrú pàápàá, yóò wulẹ̀ jẹ́ kí ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ túbọ̀ máa gbilẹ̀ lọ́kàn rẹ ni. Ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀dọ́langba sọ pé kì í rọrùn fún àwọn láti gbàgbé irú àwọn ìran bẹ́ẹ̀; wọ́n tiẹ̀ lè máa fọkàn yàwòrán wọn léraléra. Ọ̀dọ́kùnrin kan tó ń jẹ́ Dave, tó wo fídíò kan tí kò fi bẹ́ẹ̀ bójú mu, jẹ́wọ́ pé: “Lẹ́yìn ìgbà náà, gbogbo ìgbà tí mo bá ti gbọ́ orin yẹn ni mo máa ń ronú nípa fídíò náà.” Nípa bẹ́ẹ̀, wíwo irú àwọn fídíò bẹ́ẹ̀ lè mú kí ìfẹ́ láti hu ìwà pálapàla máa gbilẹ̀ lọ́kàn ẹni.—1 Kọ́ríńtì 6:18; Kólósè 3:5.

Òwe 13:20: “Ẹni tí ó bá ń ní ìbálò pẹ̀lú àwọn arìndìn yóò rí láburú.” Béèrè lọ́wọ́ ara rẹ, ‘Ǹjẹ́ mo lè ké sí àwọn oníwà ipá, àwọn abẹ́mìílò, àwọn ọ̀mùtípara tàbí àwọn oníwà pálapàla wá sínú ilé mi?’ Bíbá irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ kẹ́gbẹ́ nípasẹ̀ tẹlifíṣọ̀n kò yàtọ̀ sí pípè wọ́n wá sínú ilé rẹ. Ǹjẹ́ ṣíṣe bẹ́ẹ̀ lè mú kó o “rí láburú”? Ọ̀dọ́ kan tó ń jẹ́ Kimberly sọ pé: “Láwọn àpèjẹ kan tí mo lọ, mo ti rí i tí àwọn ọ̀dọ́mọbìnrin kan ń fara wé ìwọṣọ tàbí ijó oníwà pálapàla tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ wò lórí tẹlifíṣọ̀n.” Ìwọ náà lè ti rí irú nǹkan bẹ́ẹ̀. Nípa fífarawé àwọn tí kò bọ̀wọ̀ fún àwọn ìlànà Ọlọ́run, àwọn ọ̀dọ́ wọ̀nyí ń fi hàn pé àwọn ti bẹ̀rẹ̀ sí “rí láburú.” Nítorí náà, yàgò fún “ẹgbẹ́ búburú” èyíkéyìí.—1 Kọ́ríńtì 15:33.

Sáàmù 11:5: “Jèhófà tìkára rẹ̀ ń ṣàyẹ̀wò olódodo àti ẹni burúkú, dájúdájú, ọkàn Rẹ̀ kórìíra ẹnikẹ́ni tí ó bá nífẹ̀ẹ́ ìwà ipá.” Bí a bá ń wo àwọn fídíò tó ń ṣe àfihàn ìwà ipá bíburú jáì, tí kò mọ́gbọ́n dání, ǹjẹ́ ìyẹn kò ní fi hàn pé a jẹ́ ‘olùfẹ́ ìwà ipá’?

Kò Rọrùn Láti Ṣàṣàyàn

Nítorí pé “gbogbo ayé wà lábẹ́ agbára ẹni burúkú náà,” ó ti wá ṣòro gidigidi láti rí eré ìnàjú tí kò ní ìrònú àti ìṣarasíhùwà ayé yìí nínú. (1 Jòhánù 5:19) Àwọn ìkànnì tẹlifíṣọ̀n kan tó máa ń fi fídíò orin hàn lè gbé ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ àwọn ohun tí kò bójú mu sórí afẹ́fẹ́. Àní, bí àwọn ètò orí tẹlifíṣọ̀n kan kò bá tiẹ̀ fi ìwà pálapàla tàbí ìwà ipá hàn ní kedere, lọ́pọ̀ ìgbà, wọ́n ṣì máa ń gbé ẹ̀mí ayé lárugẹ. Àgbà ọ̀jẹ̀ olórin kan sọ pé, ìkànnì tẹlifíṣọ̀n tó gbajúmọ̀ kan tó máa ń fi fídíò orin hàn “kì í ṣe ìkànnì tó ń fi orin hàn mọ́, kàkà bẹ́ẹ̀ ó ti yí padà di ‘ìkànnì tó ń gbé àwọn àṣà ìgbésí ayé kan lárugẹ.’”

Ó lè dà bíi pé kò ṣòro láti mọ ohun tó yẹ kó o ṣe: Ẹnu kó o yí tẹlifíṣọ̀n sí ibòmíràn ni bí ìran kan kò bá bójú mu. Àmọ́, ìṣòro ibẹ̀ ni pé, ó yẹ kó o tún wà lójúfò nígbà tó o bá ń wo àwọn eré tí wọ́n ń fi hàn ní ìkànnì tẹlifíṣọ̀n mìíràn. Ọ̀pọ̀ wọn máa ń ṣe àfihàn àwọn ètò tí ìwà ipá tàbí ìwà pálapàla inú wọn kò ṣeé fẹnu sọ rárá, tàbí àwọn ètò tó ń fi àwọn èèyàn tó wà nínú ipò tí kò yẹ ọmọlúwàbí hàn. Ká sòótọ́, kì í gbádùn mọ́ni rárá, àní ó tiẹ̀ lè múnú bíni gan-an pàápàá, kéèyàn máa wo ètò alárinrin kan, kó sì tún máa wà lójúfò láti yí tẹlifíṣọ̀n sí ibòmíràn lọ́wọ́ kan náà. Nígbà míì sì rèé, kó tó di pé o yí tẹlifíṣọ̀n sí ìkànnì mìíràn, ètò náà á ti gbin èròkerò sí ọ lọ́kàn. Àwọn àwòrán ìṣekúṣe á ti wọni lọ́kàn. Síbẹ̀síbẹ̀, jẹ́ kó dá ọ lójú pé Jèhófà Ọlọ́run yóò bù kún ìsapá àtọkànwá èyíkéyìí tó o bá ṣe láti pa ọkàn rẹ mọ́.—2 Sámúẹ́lì 22:21.

Àwọn ohun mìíràn tó lè ràn ọ́ lọ́wọ́ wà tó o lè ṣe. Casey, ọ̀dọ́ tá a mẹ́nu kàn lókè, ṣàlàyé ohun kan tó máa ń ràn án lọ́wọ́, ó ní: “Wọ́n sábà máa ń fi orúkọ ẹgbẹ́ olórin náà àti àkọlé orin wọn hàn kí fídíò náà tó bẹ̀rẹ̀. Ẹgbẹ́ kọ̀ọ̀kan ló ní ohun téèyàn fi ń dá wọn mọ̀, nípa bẹ́ẹ̀ lọ́pọ̀ ìgbà, ó máa ń ṣeé ṣe láti mọ àwọn ẹgbẹ́ olórin àti orin tó ṣeé ṣe kó máà bójú mu. Nítorí náà, bí mo bá ti rí orúkọ ẹgbẹ́ olórin kan tàbí orin kan tí kò fi bẹ́ẹ̀ bójú mu báyìí, ńṣe ni mo máa ń yí tẹlifíṣọ̀n sí ibòmíràn. Kí wọ́n tó bẹ̀rẹ̀ orin rárá ni mo ti máa ń ṣe èyí láìfi àkókò ṣòfò.”

‘Sísọ Òtítọ́ Nínú Ọkàn-Àyà Rẹ’

Kódà bó o bá mọ àwọn ìlànà Bíbélì dáadáa pàápàá, ó ṣeé ṣe láti bẹ̀rẹ̀ sí fàyè gba àwọn ohun tí kò tọ́. Lọ́nà wo? Ó jẹ́ nípa wíwí àwíjàre. (Jákọ́bù 1:22) Bíbélì sọ fún wa pé ẹni tó bá ń “sọ òtítọ́ nínú ọkàn-àyà rẹ̀” ni ọ̀rẹ́ Jèhófà. (Sáàmù 15:2) Nítorí náà, jẹ́ olóòótọ́. Má tan ara rẹ jẹ. Bó bá jẹ́ pé ò ń dá ara rẹ láre lórí wíwo ohun kan tí kò bójú mu, béèrè lọ́wọ́ ara rẹ pé, ‘Ǹjẹ́ lóòótọ́-lóòótọ́ ni inú Jèhófà dùn sí ohun tí mò ń wò yìí?’ Rántí pé, lọ́pọ̀ ìgbà, kì í ṣe wíwulẹ̀ mọ ohun tó tọ́ tàbí ohun tí kò tọ́ ló ṣòro, àmọ́ ìṣòro ibẹ̀ ni pípinnu pé wàá ṣe ohun tó tọ́! O ní láti wo àjọṣe rẹ pẹ̀lú Jèhófà bí ohun tó ṣeyebíye ju eré ìnàjú èyíkéyìí lọ.—2 Kọ́ríńtì 6:17, 18.

Kò tó láti wulẹ̀ ṣe ìpinnu oréfèé tí kò dénú pé wàá máa ṣàṣàyàn. Ìpinnu rẹ lè tètè yẹsẹ̀ bí kò bá dìídì ti ọkàn rẹ wá. Bíbélì sọ fún wa nípa bí ọkùnrin olùbẹ̀rù Ọlọ́run kan tó ń jẹ́ Jóòbù ṣe pinnu láti jẹ́ olóòótọ́ sí aya rẹ̀. Ó sọ pé: “Èmi ti bá ojú mi dá májẹ̀mú. Nítorí náà, èmi yóò ha ṣe tẹjú mọ́ wúńdíá?” (Jóòbù 31:1) Ronú nípa ìyẹn ná! Jóòbù ṣe ìpinnu, tàbí àdéhùn kan tó gba ìrònújinlẹ̀, láti fi ààlà sí ohun tí yóò máa jẹ́ kí ojú rẹ̀ rí. Ìwọ náà lè gbìyànjú láti ṣe ohun kan náà. Ṣe ìpinnu tí kò lè yẹ̀, ìyẹn ni pé kó o bá ara rẹ dá májẹ̀mú, pé o ò ní wo àwọn ohun tí kò dára. Fi àwọn ààlà pàtó lélẹ̀. Fi í ṣe ọ̀ràn àdúrà. Kó o sì rí i pé o dúró lórí àdéhùn rẹ, kódà o lè kọ ọ́ sílẹ̀ bí ìyẹn bá máa ṣèrànwọ́. Bó o bá nílò ìtìlẹyìn, o ò ṣe jíròrò ọ̀ràn yìí pẹ̀lú àgbàlagbà kan tó o fọkàn tán, bóyá àwọn òbí rẹ?

Lójú àwọn ewu tó wà nínú wíwo fídíò orin, àwọn ọ̀dọ́ Kristẹni kan ti pinnu pé àwọn ò ní wo fídíò orin mọ́ rárá. Ohun yòówù kó jẹ́ ìpinnu rẹ nípa èyí, máa lo agbára ìwòye rẹ. Rí i dájú pé o ní ẹ̀rí ọkàn mímọ́. Nípa wíwo kìkì àwọn ohun tó bójú mu tó sì ń tuni lára, o ò ní ṣe ìpalára fún ara rẹ, wàá sì máa ní àjọṣe tó gún régé pẹ̀lú Jèhófà.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 20]

Àwọn fídíò orin kan tí kò fi bẹ́ẹ̀ ní ìwà pálapàla nínú ṣì máa ń gbé àwọn ohun tí Ọlọ́run kò fẹ́ lárugẹ

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 21]

Pinnu pé o ò ní wo àwọn ohun tí kò dùn mọ́ Ọlọ́run nínú