Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ọṣẹ—“Abẹ́rẹ́ Àjẹsára” Tó O Lè Gún Fúnra Rẹ

Ọṣẹ—“Abẹ́rẹ́ Àjẹsára” Tó O Lè Gún Fúnra Rẹ

Ọṣẹ—“Abẹ́rẹ́ Àjẹsára” Tó O Lè Gún Fúnra Rẹ

ÌWÉ ìròyìn The Economist sọ pé: “Ohun tó wọ́pọ̀ jù lọ ṣìkejì lágbàáyé tó ń pa àwọn ọmọdé kì í ṣe àrùn ibà, ikọ́ ẹ̀gbẹ tàbí àrùn éèdì o. Ìgbẹ́ gbuuru . . . ni.” Síbẹ̀, ọ̀pọ̀ lára àwọn ọmọ wọ̀nyí ni ì bá wà láàyè lónìí ká ní pé àwọn àtàwọn ìdílé wọn máa ń fi ọṣẹ fọ ọwọ́ wọn déédéé.

Ìwé ìròyìn The Economist sọ pé, àwọn olùṣèwádìí ní Ilé Ẹ̀kọ́ Nípa Ìmọ́tótó àti Àwọn Oògùn Ilẹ̀ Olóoru ní Ìlú London ti ṣàwárí pé “fífọ ọwọ́ ẹni mọ́ dáadáa lè fi ìdá mẹ́tàlélógójì nínú ọgọ́rùn-ún dín àìsàn ìgbẹ́ gbuuru kù. Bákan náà ló tún lè nípa gidigidi lórí àkóràn tó máa ń fa ìṣòro ní ọ̀nà èémí, èyí tó jẹ́ ohun tó ń pa àwọn ọmọdé jù lọ. Ìwádìí gbígbòòrò kan tí wọ́n ṣe nípa àwọn ọmọ ogun ilẹ̀ Amẹ́ríkà fi hàn pé nǹkan bí ìdá márùndínláàádọ́ta nínú ọgọ́rùn-ún ni sísúnmú àti wíwúkọ́ fi dín kù nígbà tí àwọn ọmọ ogun bẹ̀rẹ̀ sí fọ ọwọ́ wọn ní ìgbà márùn-ún lójúmọ́.” Kódà láwọn orílẹ̀-èdè tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà pàápàá, ọṣẹ kì í ṣe ohun tó ṣòro fún ọ̀pọ̀ ìdílé láti rí. Ìdí rèé tí wọ́n fi pe ọṣẹ ní “abẹ́rẹ́ àjẹsára tó o lè gún fúnra rẹ.” Kì í sì ṣe abẹ́rẹ́ tó ń dunni!

Bíbélì pẹ̀lú rọ̀ wá láti máa wà ní mímọ́ tónítóní. Ìwé 2 Kọ́ríńtì 7:1 sọ pé: “Ẹ́ jẹ́ kí a wẹ ara wa mọ́ kúrò nínú gbogbo ẹ̀gbin ti ẹran ara àti ti ẹ̀mí.” Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìmọ́tótó nípa tẹ̀mí ni Ọlọ́run kà sí pàtàkì jù, ó tún ka ìmọ́tótó ara sí pàtàkì bákan náà. (Léfítíkù, orí 12 sí 15) Lóòótọ́ o, kò retí pé ká ki àṣejù bọ̀ ọ́. Síbẹ̀, ó yẹ ká sọ ọ́ dàṣà láti máa fọ ọwọ́ wa lẹ́yìn tá a bá lo ilé ìtura, lẹ́yìn tá a bá ṣàndí fọ́mọ tàbí tá a pààrọ̀ ìtẹ́dìí rẹ̀, ká tó máa se oúnjẹ tàbí ká tó bẹ̀rẹ̀ sí jẹun àti láwọn àkókò mìíràn tá a mọ̀ pé ó ṣeé ṣe gan-an ká kó àrùn ran àwọn ẹlòmíràn. Nípa fífọ ọwọ́ wa déédéé, à ń fi ìfẹ́ Kristẹni hàn sí ìdílé wa àtàwọn mìíràn tá a lè bá pàdé.—Máàkù 12:31.