Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ṣé Ìkórìíra fún Sísan Owó Orí—Túbọ̀ Ń Pọ̀ Sí I Ni?

Ṣé Ìkórìíra fún Sísan Owó Orí—Túbọ̀ Ń Pọ̀ Sí I Ni?

Ṣé Ìkórìíra fún Sísan Owó Orí—Túbọ̀ Ń Pọ̀ Sí I Ni?

“Bí mo tiẹ̀ ṣiṣẹ́ àṣefẹ́ẹ̀ẹ́kú, ibòmíràn ni èyí tó pọ̀ jù lára owó tí mo bá rí máa ń gbà lọ.”—Òwe àwọn ará Bábílónì, nǹkan bí ọdún 2300 ṣáájú Sànmánì Tiwa

“Nínú ayé yìí, àyàfi ikú àti owó orí ni ò ṣeé yẹ̀ sílẹ̀.”—Olóṣèlú ilẹ̀ Amẹ́ríkà, Benjamin Franklin, ọdún 1789.

ALÁGBÀTÀ ọjà ni Reuben. Ọdọọdún ni ìdá mẹ́ta lára owó tó ń fi òógùn ojú rẹ̀ rí ń bá owó orí lọ. Ó ṣàròyé pé: “Mi ò mọ ibi tí gbogbo owó tí ìjọba ń gbà yìí ń lọ. Pẹ̀lú bí wọ́n ṣe ń dín owó tí wọ́n ń ná fún ìlò aráàlú kù, ńṣe làwọn àǹfààní tí aráàlú ń jẹ lọ́dọ̀ ìjọba ń dín kù sí i.”

Àmọ́ ṣá o, yálà a fẹ́ tàbí a ò fẹ́, dandan lowó orí. Òǹkọ̀wé Charles Adams sọ pé: “Látìgbà tí ọ̀làjú ti bẹ̀rẹ̀, oríṣiríṣi ọgbọ́n ni ìjọba [ti] dá láti gba owó orí.” Ọ̀pọ̀ ìgbà ni owó orí ti fa ìkórìíra bẹ́ẹ̀ ló sì ti fa rúkèrúdò láwọn ìgbà mìíràn. Àwọn ará ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì ayé ìgbàanì máa ń bá àwọn ará Róòmù jà, wọ́n sì máa ń sọ pé: “Ì bá kúkú sàn kẹ́ ẹ pa wá ju kẹ́ ẹ máa bu owó orí lé wa lọ!” Nílẹ̀ Faransé, ìkórìíra fún owó orí kan tí wọ́n ní káwọn èèyàn máa san lórí iyọ̀ ló fa Ìyípadà Tegbòtigaga tó wáyé nílẹ̀ Faransé, èyí tó mú kí wọ́n máa bẹ́ orí àwọn agbowó orí nígbà náà. Rúkèrúdò nítorí owó orí náà tún wà lára ohun tó mú kí ilẹ̀ Amẹ́ríkà bá ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì jagun láti gbòmìnira.

Kò yani lẹ́nu nígbà náà pé, títí dòní olónìí ni ìkórìíra fún owó orí ṣì ń bá a nìṣó. Àwọn ọ̀mọ̀ràn sọ pé láwọn orílẹ̀-èdè tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà, ètò owó orí sísan kì í fi bẹ́ẹ̀ “gbéṣẹ́,” ó sì máa ń ní “ojúsàájú” nínú. Gẹ́gẹ́ bí olùṣèwádìí kan ṣe sọ, orílẹ̀-èdè akúṣẹ̀ẹ́ kan wà nílẹ̀ Áfíríkà tí onírúurú owó orí tí wọ́n ń san níbẹ̀ “lé ní ọ̀ọ́dúnrún, èyí tí kò ṣeé ṣe láti mójú tó, kódà ká tiẹ̀ ní àwọn òṣìṣẹ́ tó tóótun wà. Wọn ò mọ ọ̀nà tó tọ́ láti fi máa gbà á bẹ́ẹ̀ ni kò sí àmójútó gidi kan tàbí kí wọ́n má tiẹ̀ mú àwọn ọ̀nà náà lò, . . . èyí tó ṣí àǹfààní sílẹ̀ fún ṣíṣe é báṣubàṣu.” Iléeṣẹ́ Ìròyìn BBC ròyìn pé, ní orílẹ̀-èdè kan nílẹ̀ Éṣíà, “àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba bu ọ̀pọ̀ . . . owó orí tí kò bófin mu fún àwọn èèyàn—látorí owó gbígbin ọ̀gẹ̀dẹ̀ títí lọ dorí owó orí fún pípa ẹlẹ́dẹ̀—yálà láti mú owó [pọ̀] sí i lápò ìjọba ìbílẹ̀ tàbí láti mú àpò tiwọn wú sí i.”

Ìyàtọ̀ tó wà láàárín àwọn olówó àtàwọn tálákà lohun tó túbọ̀ wá mú kí ìkórìíra náà pọ̀ sí i. Ìwé ìròyìn Africa Recovery tí àjọ UN ń mú jáde sọ pé: “Ọ̀kan lára àwọn ìyàtọ̀ tó wà nínú ipò ọrọ̀ ajé àwọn orílẹ̀-èdè tó ti gòkè àgbà àtàwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà ni pé àwọn orílẹ̀-èdè tó ti gòkè àgbà máa ń pèsè owó ìrànwọ́ fún àwọn àgbẹ̀, nígbà tó jẹ́ pé ńṣe làwọn orílẹ̀-èdè tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà máa ń bu owó orí fún àwọn àgbẹ̀. . . . Àwọn ìwádìí tí Báńkì Àgbáyé ṣe fi hàn pé owó ìrànwọ́ tí ìjọba ilẹ̀ Amẹ́ríkà ń san fún àwọn àgbẹ̀ wọn nìkan ń mú kí iye tí Ìwọ̀ Oòrùn Áfíríkà ń rí lọ́dún látinú òwú tí wọ́n ń kó lọ sílẹ̀ òkèèrè fi àádọ́ta lé rúgba [250] mílíọ̀nù dọ́là dín lọ́dọọdún.” Nípa bẹ́ẹ̀, èyí lè mú kí àwọn àgbẹ̀ láwọn orílẹ̀-èdè tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà fárígá nígbà tí ìjọba wọn bá tún yọ owó orí lára owó tí kò tíì tó wọn ná tẹ́lẹ̀. Àgbẹ̀ kan ní orílẹ̀-èdè kan nílẹ̀ Éṣíà sọ pé: “Ìgbàkígbà tí [àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba] bá ti wá síbí, ó ti dájú pé owó ni wọ́n ń bọ̀ wá béèrè yẹn.”

Irú ìkórìíra bẹ́ẹ̀ tún fara hàn láìpẹ́ yìí ní orílẹ̀-èdè Gúúsù Áfíríkà nígbà tí ìjọba ní kí àwọn àgbẹ̀ máa san owó orí lórí ilẹ̀. Làwọn àgbẹ̀ náà bá sọ pé àwọn máa gbé ọ̀rọ̀ náà lọ sílé ẹjọ́. Ẹnì kan tó jẹ́ agbẹnusọ fún àwọn àgbẹ̀ náà sọ pé ńṣe ni owó orí náà “máa kó àwọn àgbẹ̀ sí gbèsè ńlá tí yóò sì túbọ̀ fa àìríṣẹ́ṣe fún àwọn lébìrà tó ń ṣiṣẹ́ oko.” Nígbà míì, ìkórìíra fún owó orí sísan ṣì máa ń fa ìwà ipá. Iléeṣẹ́ ìròyìn BBC sọ pé: “Wọ́n pa àwọn àgbẹ̀ [ilẹ̀ Éṣíà] méjì lọ́dún tó kọjá nígbà táwọn ọlọ́pàá ya lu abúlé kan níbi táwọn mẹ̀kúnnù ibẹ̀ ti yarí pé owó orí tí wọ́n ní kí àwọn máa san ti pọ̀ jù.”

Àmọ́ o, kì í ṣe àwọn tálákà nìkan ló kórìíra owó orí sísan o. Ìwádìí kan tí wọ́n ṣe ní orílẹ̀-èdè Gúúsù Áfíríkà fi hàn pé ọ̀pọ̀ àwọn ọlọ́rọ̀ tó ń san owó orí ni “kò ṣe tán láti fi kún owó orí tí wọ́n ń san, kódà bí ìyẹn bá tiẹ̀ túmọ̀ sí pé ìjọba ò ní lè fi kún àwọn nǹkan tó ṣe pàtàkì fún wọn.” Àwọn gbajúgbajà tí àwọn èèyàn mọ̀ kárí ayé lágbo orin kíkọ, nínú sinimá, lágbo eré ìdárayá àti lágbo ìṣèlú ti dẹni tí wọ́n ń gbé ọ̀rọ̀ wọn jáde nínú àwọn ìwé ìròyìn fún bí wọ́n kì í ṣe fẹ́ san owó orí. Ìwé náà, The Decline (and Fall?) of the Income Tax sọ pé: “Ó bani nínú jẹ́ pé àwọn tó jẹ́ lọ́gàálọ́gàá lẹ́nu iṣẹ́ ọba àtàwọn olórí orílẹ̀-èdè wa náà pàápàá kò fi àpẹẹrẹ rere lélẹ̀ rárá nínú fífún àwọn aráàlú níṣìírí láti tẹ̀ lé òfin owó orí sísan.”

Bóyá ìwọ náà gbà pé owó orí ti máa ń pọ̀ jù, pé ó máa ń ní ojúsàájú nínú àti pé ó máa ń gani lára. Nígbà náà, ojú wo ló yẹ kó o máa fi wo sísan owó orí? Kí tiẹ̀ ni owó orí wà fún gan-an? Kí ló dé tí ètò owó orí sísan fi sábà máa ń díjú gan-an tó sì tún máa ń dà bí ohun tí kò tọ̀nà? Àwọn àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé èyí yóò tú iṣu àwọn ìbéèrè wọ̀nyí désàlẹ̀ ìkòkò.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 4]

Láwọn orílẹ̀-èdè tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà àwọn akúṣẹ̀ẹ́ lè máa san ju iye tó tọ́ sí wọn nínú owó orí tí ìjọba ń béèrè

[Credit Line]

Godo-Foto