Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Owó Orí Ṣé Òun Ló Mú Kí “Àwùjọ Ọ̀làjú” Ṣeé Ṣe?

Owó Orí Ṣé Òun Ló Mú Kí “Àwùjọ Ọ̀làjú” Ṣeé Ṣe?

Owó Orí Ṣé Òun Ló Mú Kí “Àwùjọ Ọ̀làjú” Ṣeé Ṣe?

“Láìsí owó orí kò lè sí àwùjọ ọ̀làjú.”—Àkọlé tó wà lára iléeṣẹ́ Ẹ̀ka Tó Ń Rí sí Owó Tó Ń Wọlé Sápò Ìjọba, ní ìpínlẹ̀ Washington, D.C.

ÀWỌN ìjọba gbà pé owó orí pọn dandan bí kò tiẹ̀ bára dé, nítorí pé òun lohun tó ń mú kí “àwùjọ ọ̀làjú” ṣeé ṣe. Yálà o fara mọ́ èrò yìí tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́, a ò lè sẹ́ ẹ pé owó kékeré kọ́ ló ń bá sísan owó orí lọ.

A lè pín owó orí sí ọ̀nà méjì: èyí táà ń san tààràtà àtèyí tá ò san tààràtà. Àpẹẹrẹ àwọn tó ṣe tààràtà ni owó orí téèyàn ń san lórí iye tó ń wọlé fún un, owó orí táwọn iléeṣẹ́ máa ń san àti owó orí lórí nǹkan ìní. Nínú àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta yìí, owó orí lórí iye tó ń wọlé fúnni ló dà bíi pé àwọn èèyàn ò nífẹ̀ẹ́ sí rárá. Èyí sì sábà máa ń rí bẹ́ẹ̀ láwọn orílẹ̀-èdè tó jẹ́ pé bí iye tó ń wọlé fúnni bá ṣe ń ròkè náà ni owó orí á máa ròkè. Àwọn tí kò fara mọ́ irú owó orí yìí sọ pé kì í jẹ́ kí wàhálà ẹni tó ń fi gbogbo ara ṣiṣẹ́ tó sì ń rí tajé ṣe yọ.

Ìwé OECD Observer, tí Àjọ Tó Wà fún Ìfọwọ́sowọ́pọ̀ àti Ìdàgbàsókè Ètò Ọrọ̀ Ajé ń tẹ̀ jáde rán wa létí pé, yàtọ̀ sí owó orí tí à ń san fún ìjọba àpapọ̀, “ó ṣeé ṣe kí àwọn òṣìṣẹ́ tún máa san àwọn owó orí tó jẹ́ ti ìbílẹ̀, ti àgbègbè àti ti ìpínlẹ̀ láfikún sí ti ìjọba àpapọ̀. Èyí lohun tó ń ṣẹlẹ̀ ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, Belgium, Iceland, Japan, Kánádà, Korea, àwọn orílẹ̀-èdè Scandinavia, Sípéènì àti Switzerland.”

Àwọn owó orí tí kò ṣe tààràtà ni owó orí lórí ọjà títà, lórí ọtí líle àti sìgá àti owó ibodè. Àwọn wọ̀nyí kì í fi bẹ́ẹ̀ hàn bí owó orí tá a san tààràtà, síbẹ̀ owó kékeré kọ́ ni wọ́n ń gbọ́n lọ, pàápàá lápò àwọn tálákà. Nínú ìwé ìròyìn ilẹ̀ Íńdíà tó ń jẹ́ Frontline, òǹkọ̀wé Jayali Ghosh sọ pé irọ́ pátápátá ni pé àwọn tó rí já jẹ díẹ̀ àtàwọn ọlọ́rọ̀ ló ń san èyí tó pọ̀ jù lára owó orí ilẹ̀ Íńdíà. Ghosh sọ pé: “Ní ti àwọn ìjọba Ìpínlẹ̀, owó orí tí wọ́n ń gbà lọ́nà tí kò ṣe tààràtà ju ìdá márùndínlọ́gọ́rùn-ún nínú ìdá ọgọ́rùn-ún gbogbo iye tí wọ́n ń gbà. . . . Ó ṣeé ṣe kó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn tálákà gan-an ló ń san èyí tó pọ̀ jù lára iye tó ń wọlé fún wọn gẹ́gẹ́ bí owó orí, ju àwọn ọlọ́rọ̀ lọ.” Ó hàn gbangba pé ohun tó mú ìyàtọ̀ yìí wá ni owó orí gegere tí wọ́n máa ń bù lé àwọn nǹkan tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn ń lò, irú bí ọṣẹ àti oúnjẹ.

Kí tiẹ̀ làwọn ìjọba máa ń fi gbogbo owó tí wọ́n ń gbà ṣe?

Ibi Tí Owó Náà Ń Gbà Lọ

Ká sòótọ́, kì í ṣe owó kékeré làwọn ìjọba ń ná láti ṣèjọba àti láti pèsè àwọn ohun pàtàkì táwọn èèyàn nílò. Bí àpẹẹrẹ, nílẹ̀ Faransé, èèyàn kan nínú mẹ́rin ló ń ṣiṣẹ́ lábẹ́ ìjọba. Lára wọn ni àwọn olùkọ́, àwọn òṣìṣẹ́ iléeṣẹ́ ìfìwéránṣẹ́, àwọn tó ń ṣiṣẹ́ láwọn ibi ìkóhun-ìṣẹ̀ǹbáyé-sí àti nílé ìwòsàn, àwọn ọlọ́pàá àtàwọn òṣìṣẹ́ ọba mìíràn. Ìjọba nílò owó orí láti lè san owó oṣù wọn. Látinú owó orí yìí náà ni wọ́n ti ń rí owó ná sórí àwọn títì, àwọn iléèwé àtàwọn ilé ìwòsàn, tí wọ́n sì ti ń rí owó san fún àwọn iṣẹ́ bíi kíkó ìdọ̀tí àti ètò ìfìwéránṣẹ́.

Ìnáwó lórí ohun ìjà ogun tún jẹ́ kókó pàtàkì mìíràn fún sísanwó orí. Àwọn ọlọ́rọ̀ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì ni wọ́n kọ́kọ́ bu owó orí fún láti fi bójú tó ìnáwó tó wà nídìí ogun tí ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì bá ilẹ̀ Faransé jà lọ́dún 1799. Àmọ́, nígbà Ogun Àgbáyé Kejì, ìjọba ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì bẹ̀rẹ̀ sí í sọ pé kí àwọn òṣìṣẹ́ náà máa san owó orí lórí iye tó ń wọlé fún wọn. Títí dòní, owó táwọn orílẹ̀-èdè ń ná lórí ọ̀rọ̀ ológundé kì í ṣe kékeré rárá, àní lákòókò tí wàhálà kò bá sí pàápàá. Ilé Ẹ̀kọ́ Tó Ń Ṣèwádìí Nípa Àlàáfíà Àgbáyé ní Stockholm fojú bù ú pé owó tó lọ sórí nǹkan ìjà ogun lọ́dún 2000 tó ẹgbẹ̀rin ó dín méjì bílíọ̀nù [798,000,000,000] dọ́là.

Ọ̀nà Kan Láti Mú Kí Àwọn Èèyàn Ṣe Ohun Tó Tọ́

Owó orí tún jẹ́ ọ̀nà kan tí wọ́n ń lò láti mú kí àwọn èèyàn máa hu àwọn ìwà kan tàbí láti mú kí àwọn èèyàn jáwọ́ nínú híhu àwọn ìwà kan. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n gbà pé bíbu owó orí lé ọtí líle lè dín ọtí àmujù kù. Nípa bẹ́ẹ̀, ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè, ìdá márùndínlógójì nínú ọgọ́rùn-ún iye tí wọ́n ń ta ọtí bíà ló jẹ́ owó orí.

Bákan náà, owó orí kékeré kọ́ ni wọ́n ń gbà lórí tábà. Ní orílẹ̀-èdè Gúúsù Áfíríkà, owó orí kó nǹkan bí ìlàjì nínú iye tí wọ́n ń ta páálí sìgá kan. Àmọ́ ṣá o, ohun tó ń mú ìjọba kan máa bu irú àwọn owó orí bẹ́ẹ̀ lè máà jẹ́ pé ńṣe ni wọ́n kúkú ní ire aráàlú lọ́kàn lóòótọ́. Gẹ́gẹ́ bí òǹkọ̀wé Kenneth Warner ṣe sọ nínú ìwé ìròyìn Foreign Policy, tábà jẹ́ “ọjà pàtàkì kan tí kò ṣeé fọwọ́ rọ́ sẹ́yìn, tó ń mú ọgọ́rọ̀ọ̀rún bílíọ̀nù dọ́là wọlé nígbà tí wọ́n bá tà á, tó sì tún ń mú ọ̀pọ̀ bílíọ̀nù dọ́là wọlé látinú owó orí tí wọ́n ń gbà lórí rẹ̀.”

Ohun kan tó ṣẹlẹ̀ ní ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rúndún ogún jẹ́ àpẹẹrẹ pàtàkì kan nípa lílo owó orí gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà láti mú káwọn èèyàn ṣe ohun tó tọ́. Àwọn aṣòfin ilẹ̀ Amẹ́ríkà ń wá ọ̀nà láti fòpin sí bí àwọn ìdílé ọlọ́lá ṣe ń kó ọrọ̀ jọ kí orúkọ wọn má bàa pa run. Kí ni wọ́n ṣe? Wọ́n ṣòfin pé kí àwọn èèyàn máa sanwó orí lórí dúkìá. Nígbà tí ọlọ́lá kan bá kú, iye tí owó orí nìkan ń kó lọ nínú àwọn ọrọ̀ tó kó jọ kì í ṣe kékeré. Àwọn tó gbé àbá náà kalẹ̀ sọ pé owó orí náà “ń darí díẹ̀ lára ọrọ̀ náà kúrò lọ́dọ̀ àwọn ọ̀tọ̀kùlú ó sì ń jẹ́ kí wọ́n rí owó náà lò fún àwọn aráàlú.” Èyí lè jẹ́ òótọ́, àmọ́ àwọn ọlọ́rọ̀ tó ń san owó orí yìí ti jágbọ́n oríṣiríṣi ọ̀nà láti dín sísan owó orí náà kù.

Wọn ò tíì dáwọ́ dúró láti máa lo owó orí gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà láti bójú tó àwọn ọ̀ràn tó lè ṣe aráàlú láǹfààní, irú bí ọ̀ràn nípa àyíká. Ìwé ìròyìn The Environmental Magazine sọ pé: “Àwọn orílẹ̀-èdè Ìwọ̀ Oòrùn ilẹ̀ Yúróòpù mẹ́sàn-án ló ti dá ìlànà gbígba owó orí ìmọ́tótó àyíká sílẹ̀ láìpẹ́ yìí, ní pàtàkì jù lọ gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà láti dín ẹ̀gbin inú afẹ́fẹ́ kù.” Owó orí tó máa ń ròkè bí iye tó ń wọlé fún ẹnì kan ṣe ń ròkè, tá a mẹ́nu kàn níṣàájú, tún jẹ́ ọ̀nà mìíràn tí wọ́n ń lò láti mú káwọn aráàlú ṣe ohun tó tọ́, èyí sì jẹ́ láti dín àlàfo tó wà láàárín àwọn ọlọ́rọ̀ àtàwọn tálákà kù. Àwọn ìjọba kan tún máa ń pèsè àǹfààní ẹ̀dínwó owó orí fún àwọn tó ń fowó ṣèrànwọ́ àti fún àwọn tọkọtaya tí wọ́n ní àwọn ọmọ.

Kí Ló Dé Tí Àwọn Òfin Owó Orí Fi Máa Ń Díjú Gan-an?

Nígbàkigbà tí wọ́n bá fẹ́ gbé owó orí tuntun kalẹ̀, àwọn aṣòfin máa ń rí i dájú pé kò ní ṣeé yẹ̀ sílẹ̀ lọ́nàkọnà. Rántí o: Ọ̀pọ̀lọpọ̀ owó nìyẹn lè mú wọn pàdánù. Kí ni àbájáde èyí? Òfin owó orí sábà máa ń díjú gan-an ó sì máa ń ṣòro láti lóye. Àpilẹ̀kọ kan nínú ìwé ìròyìn Time ṣàlàyé pé ọ̀pọ̀ àwọn ohun tó díjú nínú òfin owó orí ilẹ̀ Amẹ́ríkà “máa ń ní í ṣe pẹ̀lú mímọ ohun tó yẹ kí wọ́n bu owó orí lé nínú iye tó ń wọlé fún ẹnì kan.” Ohun mìíràn tó tún díjú níbẹ̀ ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìlànà “tó so mọ́ ẹ̀dínwó owó orí tàbí tó lè mú kí ẹnì kan láǹfààní láti má ṣe san owó orí.” Àmọ́, kì í ṣe orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà nìkan ló ní àwọn òfin owó orí tó díjú o. Nílẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, ẹgbẹ̀rún mẹ́sàn-án, ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta àti ọ̀kànlélógún [9,521] ojú ìwé ni ẹ̀dà tuntun ìwé òfin owó orí wọ́n ní, èyí sì jẹ́ ìdìpọ̀ ìwé ńláńlá mẹ́wàá.

Iléeṣẹ́ Tó Ń Ṣèwádìí Nípa Ìlànà Owó Orí ní Yunifásítì Michigan ròyìn pé: “Lọ́dọọdún, ó lé ní bílíọ̀nù mẹ́ta wákàtí táwọn tó ń san owó orí nílẹ̀ Amẹ́ríkà ń lò láti fi kọ ọ̀rọ̀ sínú àwọn fọ́ọ̀mù owó orí. . . . Lápapọ̀, gbogbo àkókò àti owó tí àwọn tó ń san owó orí nílẹ̀ Amẹ́ríkà ń lò [láti kọ ọ̀rọ̀ sínú fọ́ọ̀mù owó orí] máa ń tó ọgọ́rùn-ún bílíọ̀nù dọ́là lọ́dọọdún, tàbí ìdá mẹ́wàá nínú ọgọ́rùn-ún owó orí tí wọ́n ń san. Ọ̀pọ̀ lára wàhálà tó kúrò ní kékeré yìí ló jẹ́ pé dídíjú tí òfin sísan owó orí díjú ló fà á.” Reuben tá a dárúkọ rẹ̀ níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ àkọ́kọ́ sọ pé: “Tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀, fúnra mi ni mo máa ń bójú tó àwọn fọ́ọ̀mù owó orí mi, àmọ́ èyí ti máa ń jẹ àkókò jù, ńṣe ló sì máa ń dà bíi pé mò ń san ju iye tó yẹ kí n san lọ. Nítorí náà, ńṣe ni mo wá ń sanwó fún olùṣirò owó kan nísinsìnyí láti máa bá mi kọ ọ̀rọ̀ sínú àwọn fọ́ọ̀mù owó orí mi.”—Wo àpótí náà, “Fífọwọ́ Sowọ́ Pọ̀ Pẹ̀lú Òfin Owó Orí,” lójú ìwé 8.

Àwọn Tó Ń San Án, Àwọn Tó Ń Yẹra fún Un, Àtàwọn Tí Kò Fẹ́ San Án Rárá

Ó kéré tán, ọ̀pọ̀ jù lọ èèyàn ni yóò gbà bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ pé owó orí ní àwọn àǹfààní tó ń ṣe fún àgbègbè wọn. Olùdarí Ẹ̀ka Tó Ń Rí sí Gbígba Owó Orí Nílẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì sọ nígbà kan pé: “Kò sẹ́ni tó gbádùn sísan owó orí, àmọ́ bóyá lẹnì kan wà tó lè sọ pé ipò nǹkan á túbọ̀ dára fún wa láìsí owó orí.” Àwọn kan fojú bù ú pé nǹkan bí ìdá mẹ́sàn-án nínú mẹ́wàá àwọn ará Amẹ́ríkà ló fara mọ́ ọn pé owó orí yẹ ní sísan. Ẹnì kan tó mọ tinú tòde owó orí sọ pé: “Ohun tó ń mú ọ̀pọ̀ máa yẹra fún sísan owó orí ni wàhálà tó so mọ́ àwọn òfin owó orí àtàwọn ìlànà tó jẹ mọ́ sísan án, kì í ṣe pé wọ́n ń mọ̀ọ́mọ̀ sá fún un.”

Síbẹ̀síbẹ̀, ọ̀pọ̀ máa ń wá ọ̀nà láti yẹra fún sísan àwọn owó orí kan. Bí àpẹẹrẹ, wo ohun tí àpilẹ̀kọ kan nínú ìwé ìròyìn U.S.News & World Report sọ nípa owó orí tó yẹ kí àwọn iléeṣẹ́ máa san: “Ọ̀pọ̀ àwọn iléeṣẹ́ ni kì í san púpọ̀ lára iye tó tọ́ sí wọn tàbí kí wọ́n má tiẹ̀ san ọ̀kankan nínú rẹ̀, nípa ṣíṣi ètò ẹ̀dínwó lò àti yíyí àwọn àkọsílẹ̀ owó wọn.” Àpilẹ̀kọ náà ń bá ọ̀rọ̀ lọ nípa mímú àpẹẹrẹ kan wá nípa ọgbọ́n tí iléeṣẹ́ kan dá, ó ní: “Iléeṣẹ́ kan nílẹ̀ Amẹ́ríkà lọ dá iléeṣẹ́ sílẹ̀ ní orílẹ̀-èdè kan tí owó orí tí wọ́n ń san níbẹ̀ kò tó nǹkan. Ó wá fi iléeṣẹ́ ti ilẹ̀ Amẹ́ríkà sí abẹ́ iléeṣẹ́ ilẹ̀ òkèèrè náà.” Nípa bẹ́ẹ̀, iléeṣẹ́ yìí kì í san owó orí ti ilẹ̀ Amẹ́ríkà, èyí tí ì bá máa lọ sí bí ìdá márùndínlógójì nínú ọgọ́rùn-ún owó tó ń wọlé fún un, kódà bí ohun tá a fi lè dá “orílé iṣẹ́ náà mọ̀ ò tiẹ̀ ju àdírẹ́sì, ibi tí wọ́n ń kó lẹ́tà àti fáìlì sí lọ.”

Bákan náà sì ni àwọn kan tún wà tí wọn kì í fẹ́ sanwó orí rárá. A gbọ́ pé ní orílẹ̀-èdè kan nílẹ̀ Yúróòpù, àwọn èèyàn jákèjádò orílẹ̀-èdè náà ti ka sísá fún owó orí sí “ohun tí kò burú.” Gẹ́gẹ́ bí ìwádìí kan ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ti fi hàn, kìkì ìdá méjìdínlọ́gọ́ta péré nínú ọgọ́rùn-ún àwọn ọkùnrin tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n sí mọ́kàndínlọ́gbọ̀n ló gbà pé ó burú láti má ṣe sọ gbogbo iye tó ń wọlé fúnni. Àwọn tó ṣe ìwádìí náà sọ pé: “Àbọ̀ ìwádìí náà fi hàn pé àwọn èèyàn tó wà láwùjọ wa kò ní ìwà ọmọlúwàbí.” Ní orílẹ̀-èdè Mẹ́síkò, wọ́n fojú bù ú pé nǹkan bí ìdá márùndínlógójì nínú ọgọ́rùn-ún èèyàn ló ń sá fún owó orí sísan.

Ju gbogbo rẹ̀ lọ, àwọn èèyàn gbà pé ó yẹ ká máa san owó orí, wọ́n ò sì kọ̀ láti san èyí tó bá tọ́ sí wọn. Àmọ́ ṣá, gbólóhùn gbígbajúmọ̀ kan tí wọ́n ní Tiberius Caesar ló sọ ọ́ dà bí òótọ́, ìyẹn ni pé: “Irun ara àgùntàn nìkan ló yẹ kí olùṣọ́ àgùntàn dáadáa rẹ́, kò yẹ kó rẹ́ awọ àgùntàn mọ́ ọn.” Bó bá jọ pé à ń rẹ́ ọ jẹ nípasẹ̀ ètò owó orí tó jọ pé ó ń nini lára, tó ní ojúsàájú nínú, tó sì díjú púpọ̀, ojú wo gan-an ló yẹ kó o fi wo sísan án?

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 7]

Rò Ó Re Kó O Tó Ṣí Lọ!

Ètò owó orí yàtọ̀ síra láti orílẹ̀-èdè kan sí òmíràn. Kódà, owó orí sísan lè yàtọ̀ síra gan-an láàárín orílẹ̀-èdè kan náà. Ǹjẹ́ ó tó ohun téèyàn ń ronú àtiṣí lọ sí àgbègbè mìíràn níbi tí owó orí tí wọ́n ń san ò ti fi bẹ́ẹ̀ pọ̀? Ó lè jẹ́ bẹ́ẹ̀, àmọ́, ó yẹ kó o rò ó re kó o tó ṣí lọ síbẹ̀.

Bí àpẹẹrẹ, àpilẹ̀kọ kan nínú ìwé ìròyìn OECD Observer rán àwọn òǹkàwé létí pé kì í ṣe owó orí nìkan lohun tó yẹ láti gbé yẹ̀ wò. Ó sọ pé: “Wọ́n ti máa ń yọ àwọn ẹ̀dínwó kan kúrò nínú iye tí wọ́n ń bù fún ẹnì kọ̀ọ̀kan gẹ́g̣ẹ́ bí owó orí.” Bí àpẹẹrẹ, owó orí tí wọ́n ń san láwọn orílẹ̀-èdè kan kì í fi bẹ́ẹ̀ pọ̀. Àmọ́, “wọn kì í fi bẹ́ẹ̀ fúnni ní àwọn àjẹmọ́nú, àti ẹ̀dínwó owó orí, tàbí kí wọ́n yọ̀ọ̀da fún àwọn kan láti má ṣe san owó orí.” Nípa bẹ́ẹ̀, iye tí wàá san níbẹ̀ lè pọ̀ ju ti àwọn orílẹ̀-èdè tí owó orí wọn ga àmọ́ tí wọ́n ń fúnni ní àwọn àjẹmọ́nú àti ẹ̀dínwó owó orí tó túbọ̀ pọ̀ sí i.

Ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, àwọn kan máa ń ronú àtiṣí lọ sí àwọn ìpínlẹ̀ tí wọn kì í san owó orí ìjọba ìpínlẹ̀. Àmọ́, ṣé èyí wá ní kí owó pọ̀ sí i lọ́wọ́ ẹni ni? Rárá o, nítorí pé ìwé ìròyìn Kiplinger’s Personal Finance sọ pé: “Nínú àwọn ipò kan, ìwádìí wa fi hàn pé àwọn ìpínlẹ̀ tí kì í gba owó orí lórí iye tó ń wọlé fúnni máa ń gba owó orí tó ga lórí dúkìá, lórí ọjà àtàwọn owó orí mìíràn.”

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 8]

Fífọwọ́ Sowọ́ Pọ̀ Pẹ̀lú Òfin Owó Orí

Fún ọ̀pọ̀ lára wa, sísan owó orí kì í ṣe ohun tó rọrùn rárá, ó sì jẹ́ ohun tó nira. Èyí ló mú kí Jí! béèrè àwọn àbá díẹ̀ tó lè ṣèrànwọ́ lọ́wọ́ ẹnì kan tó jẹ́ onímọ̀ nípa owó orí.

“Gba ìmọ̀ràn tó pójú owó. Èyí ṣe pàtàkì, nítorí pé òfin owó orí máa ń díjú, wọn kì í sì sábà gbà pé àìlóye òfin náà jẹ́ ìdí tó níláárí fún kíkọ̀ láti tẹ̀ lé e. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹni tó ń san owó orí lè máa wo àwọn òṣìṣẹ́ olówó orí bí ọ̀tá, lọ́pọ̀ ìgbà wọ́n lè pèsè àwọn àlàyé pípé pérépéré tó sì rọrùn láti lóye nípa béèyàn ṣe lè bójú tó àwọn ohun tó jẹ mọ́ owó orí. Àwọn aláṣẹ owó orí á fẹ́ kó o kọ ọ̀rọ̀ sínú àwọn fọ́ọ̀mù owó orí rẹ láìsí àṣìṣe kankan nígbà àkọ́kọ́ tó o bá kọ ọ́. Wọn ò fẹ́ fìyà jẹ ọ́ fún ṣíṣàì fọwọ́ sowọ́ pọ̀.

“Bí àwọn ìnáwó rẹ bá díjú, gba ìmọ̀ràn lọ́dọ̀ amọṣẹ́dunjú kan tó ń báni ṣe ìwé owó orí. Àmọ́ ṣọ́ra o! Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ àwọn amọṣẹ́dunjú ló wà tó ń báni ṣe ìwé owó orí tí wọ́n sì fẹ́ láti ranni lọ́wọ́, àìmọye ló jẹ́ gbájú ẹ̀. Ní kí ọ̀rẹ́ kan tó o fọkàn tán tàbí alábàáṣiṣẹ́ rẹ kan bá ọ wá ẹnì kan tó mọ̀ nípa ọ̀rọ̀ owó orí dáadáa kó o sì yẹ àwọn ẹ̀rí tí ẹni náà ní wò.

“Ṣe é kánmọ́kánmọ́. Ìjìyà tó wà fún àwọn tí kò bá tètè lọ fi ìwé owó orí wọn sílẹ̀ kì í ṣe kékeré.

“Jẹ́ kí àwọn àkọsílẹ̀ rẹ wà létòlétò. Ọ̀nà yòówù tó o lè máa gbà ṣe àkọsílẹ̀ àwọn ohun tó ń wọlé fún ọ, jẹ́ kó máa bá àkókò mu. Lọ́nà yẹn, iṣẹ́ tí wàá ṣe nígbà tí àkókò bá tó láti kọ ọ̀rọ̀ sínú àwọn fọ́ọ̀mù owó orí kò ní fi bẹ́ẹ̀ pọ̀ rárá. Bákan náà ni wàá ti wà ní sẹpẹ́ bí wọ́n bá fẹ́ ṣe àyẹ̀wò àkọsílẹ̀ owó rẹ.

“Jẹ́ olóòótọ́. Ó lè máa ṣe ọ́ bíi pé kó o ṣe màgòmágó tàbí kó o ṣe awúrúju díẹ̀ nínú àwọn òfin owó orí. Àmọ́, àwọn òṣìṣẹ́ owó orí mọ oríṣiríṣi ọ̀nà tí wọ́n fi ń mọ̀ táwọn èèyàn bá parọ́ láti lè gba àwọn ẹ̀dínwó kan. Sísọ òótọ́ nígbà gbogbo lóhun tó dára jù.

“Má ṣe dá ẹni yẹn dá a. Bí ẹni tó o sanwó fún láti bá ọ ṣe àwọn fọ́ọ̀mù owó orí rẹ bá lọ fi ìsọfúnni tí kò pé sílẹ̀, ìwọ ni wàá ṣì dáhùn fún un. Nítorí náà, rí i dájú pé ohun tó o sọ fún ẹni tó ń ṣojú rẹ náà ló ṣe.”

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

Ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè, owó orí kékeré kọ́ ni wọ́n ń gbà lórí tábà àti ọtí líle

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8, 9]

Owó orí ni ìjọba ń lò láti fi gbọ́ bùkátà ọ̀pọ̀ àwọn nǹkan tá a lè má kà sí