Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Mo Fara Mọ́ Ohun Tí Ọlọ́run Sọ Nípa Ẹ̀jẹ̀

Mo Fara Mọ́ Ohun Tí Ọlọ́run Sọ Nípa Ẹ̀jẹ̀

Mo Fara Mọ́ Ohun Tí Ọlọ́run Sọ Nípa Ẹ̀jẹ̀

Oníṣègùn Kan Sọ Ìtàn Ara Rẹ̀

INÚ gbọ̀ngàn ilé ìwòsàn ni mo wà níbi tí mo ti ń sọ àbájáde àyẹ̀wò tá a ṣe lára òkú kan fún àwùjọ àwọn dókítà kan. Aláìsàn tó kú náà ní kókó ọlọ́yún tó lè ṣekú pani, mo sì sọ pé, “A lè ní ohun tó fa ikú aláìsàn yìí ni hemolysis [ìṣòro kí àwọn sẹ́ẹ̀lì pupa inú ẹ̀jẹ̀ bà jẹ́] àti bí kíndìnrín rẹ̀ ṣe kọṣẹ́ látàrí ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ ẹ̀jẹ̀ tí wọ́n fà sí i lára.”

Ni ọ̀jọ̀gbọ́n kan bá dìde fùú ó sì fìbínú kígbe pé, “Ṣé ohun tóò ń sọ ni pé ẹ̀jẹ̀ tí kò bá a lára mu la fà sí i lára?” Mo dáhùn pé, “Ohun tí mo ní lọ́kàn kọ́ nìyẹn.” Nípa pípe àfiyèsí wọn sí àwọn apá kéékèèké kan lára kíndìnrín ẹni náà nínú àwọn àwòrán kan lára ògiri, mo fi kún un pé: “A lè rí sẹ́ẹ̀lì ẹ̀jẹ̀ pupa tó bà jẹ́ nínú kíndìnrín náà, èyí sì lè mú wa gbà pé ohun tó mú kí kíndìnrín náà kọṣẹ́ nìyẹn.” a Ọ̀rọ̀ di wò-mí-n-wò-ọ́, ojora sì mú mi. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀dọ́mọdé dókítà ni mí tí òún sì jẹ́ ọ̀jọ̀gbọ́n, mo wò ó pé mi ò lè kó ọ̀rọ̀ mi jẹ.

Nígbà ìṣẹ̀lẹ̀ yìí, n kò tíì di ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ọdún 1943 ni wọ́n bí mi ní ìlú Sendai, ìlú kan lápá àríwá orílẹ̀-èdè Japan. Nítorí pé onímọ̀ nípa àrùn inú ara àti oníṣègùn ọpọlọ ni bàbá mi, mo pinnu pé màá kẹ́kọ̀ọ́ ìmọ̀ ìṣègùn. Lọ́dún 1970, nígbà tí mo wà ní ọdún kejì ní ilé ẹ̀kọ́ nípa ìṣègùn, mo gbé ọ̀dọ́mọbìnrin kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Masuko níyàwó.

Mo Tún Lọ Kẹ́kọ̀ọ́ Nípa Àrùn Inú Ara

Masuko ló ń ṣiṣẹ́ táwa méjèèjì fi ń gbọ́ bùkátà ara wa nígbà tí mò ń parí iléèwé mi lọ. Iṣẹ́ ìṣègùn wù mí gan-an. Àgbàyanu gbáà ni ọ̀nà tí a gbà ṣe ara èèyàn jẹ́ fún mi! Síbẹ̀, mi ò ronú rẹ̀ rí pé Ẹlẹ́dàá wà. Èrò mi ni pé ìwádìí nípa ìmọ̀ ìṣègùn lè fún ìgbésí ayé mi nítumọ̀. Nítorí náà, lẹ́yìn tí mo di oníṣègùn tán, mo pinnu láti lọ kẹ́kọ̀ọ́ síwájú sí i nípa àrùn inú ara, ìyẹn ẹ̀kọ́ nípa àwọn àmì àìsàn, ohun tó fà wọ́n àti ohun tó máa ń jẹ́ àbájáde wọn.

Bí mo ṣe ń ṣe àyẹ̀wò òkú àwọn tí àrùn jẹjẹrẹ pa, mo bẹ̀rẹ̀ sí ṣiyèméjì nípa bí ìfàjẹ̀sínilára ṣe gbéṣẹ́ sí. Àwọn alárùn jẹjẹrẹ tí àìsàn wọn ti gogò lè má fi bẹ́ẹ̀ ní ẹ̀jẹ̀ lára mọ́ nítorí ẹ̀jẹ̀ tí wọ́n máa ń pàdánù. Nítorí pé ìtọ́jú oníkẹ́míkà tí wọ́n máa ń fún wọn sì túbọ̀ máa ń dín ẹ̀jẹ̀ inú ara kù, àwọn dókítà sábà máa ń dábàá ìfàjẹ̀sínilára. Àmọ́ ṣá, ara bẹ̀rẹ̀ sí í fu mí pé ìfàjẹ̀sínilára lè mú kí àrùn jẹjẹrẹ náà tàn lọ sí ibòmíràn nínú ara. Èyí ó wù kó jẹ́, wọ́n ti wá mọ̀ lónìí pé ìfàjẹ̀sínilára lè sọ àwọn èròjà agbóguntàrùn inú ara di aláìlágbára, èyí tó lè mú kí àwọn kókó ọlọ́yún tún padà wá tó sì lè mú kó ṣòro fún àwọn alárùn jẹjẹrẹ láti yè é. b

Ọdún 1975 ni ìṣẹ̀lẹ̀ tí mo mẹ́nu kàn lókè yẹn ṣẹlẹ̀. Ọ̀jọ̀gbọ́n náà ló ń bójú tó ọ̀ràn aláìsàn náà, ògbógi sì ni nínú ọ̀ràn nípa ẹ̀jẹ̀. Nítorí náà, kì í ṣe ohun ìyàlẹ́nu pé inú bí i gan-an nígbà tó gbọ́ tí mo sọ pé ẹ̀jẹ̀ tí wọ́n fà sí aláìsàn náà lára ló fa ikú rẹ̀! Àmọ́, mi ò dá ọ̀rọ̀ mi dúró, díẹ̀díẹ̀ inú rẹ̀ sì bẹ̀rẹ̀ sí wálẹ̀.

Kò Ní Sí Àìsàn Tàbí Ikú Mọ́

Àárín àkókò yìí ni obìnrin àgbàlagbà kan tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ ìyàwó mi. Nínú àlàyé rẹ̀, obìnrin náà lo ọ̀rọ̀ náà “Jèhófà,” ìyàwó mi sì bi í pé kí nìyẹn túmọ̀ sí. Ẹlẹ́rìí náà dáhùn pé, “Jèhófà ni orúkọ Ọlọ́run òtítọ́.” Àtikékeré ni Masuko ti máa ń ka Bíbélì, àmọ́ wọ́n ti fi “OLÚWA” rọ́pò orúkọ Ọlọ́run nínú Bíbélì tó ń lò. Báyìí, ó ti wá mọ̀ pé ẹni gidi kan ni Ọlọ́run àti pé ó ní orúkọ!

Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni Masuko bẹ̀rẹ̀ sí kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́dọ̀ Ẹlẹ́rìí tó jẹ́ àgbàlagbà náà. Nígbà tí mo dé láti ọsibítù ní nǹkan bí aago kan òru, tìdùnnú-tìdùnnú ni ìyàwó mi fi sọ fún mi pé, “Ó wà nínú Bíbélì pé àìsàn àti ikú kò ní sí mọ́!” Mo dáhùn pé, “Ìyẹn á mà ti lọ wà jù kẹ̀!” Ó wá ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ pé, “Níwọ̀n ìgbà tí ayé tuntun kò ní pẹ́ dé mọ́, mi ò fẹ́ kó o fi àkókò rẹ ṣòfò o.” Ohun tí mo rò pé ó ní lọ́kàn ni pé kí n má ṣiṣẹ́ dókítà mọ́, ni mo bá fa ìbínú yọ, àárín wa ò sì dán mọ́rán mọ́.

Àmọ́, ìyàwó mi kò jáwọ́ lọ́rọ̀ mi o. Ó máa ń gbàdúrà láti rí àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó bá ipò mi mu, ó sì máa ń fi wọ́n hàn mí. Ọ̀rọ̀ inú ìwé Oníwàásù 2:22, 23 ló wọ̀ mí lọ́kàn jù, èyí tó sọ pé: “Kí ni ènìyàn wá ní nítorí gbogbo iṣẹ́ àṣekára rẹ̀ àti nítorí ìlàkàkà ọkàn-àyà rẹ̀ èyí tí ó fi ń ṣiṣẹ́ kárakára lábẹ́ oòrùn? . . . Ọkàn-àyà rẹ̀ kò jẹ́ sùn ní òru. Asán gbáà ni èyí pẹ̀lú.” Èyí bá ohun tí mò ń ṣe mu—gbogbo ara ni mo fi jin ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ ìṣègùn, tọ̀sán-tòru sì ni, láìrí ayọ̀ gidi kan.

Ní òwúrọ̀ Sunday kan ní July 1975, lẹ́yìn tí ìyàwó mi ti lọ sí Gbọ̀ngàn Ìjọba Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tán, mo pinnu lọ́kàn mi pé èmi náà á lọ. Ẹnu ya ìyàwó mi gan-an nígbà tó rí mi níbẹ̀, tọ̀yàyàtọ̀yàyà làwọn Ẹlẹ́rìí náà sì fi kí mi káàbọ̀. Látìgbà náà, mi ò pa ìpàdé Sunday kankan jẹ. Ní nǹkan bí oṣù kan lẹ́yìn náà, Ẹlẹ́rìí kan bẹ̀rẹ̀ sí kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú mi. Oṣù mẹ́ta lẹ́yìn tí àwọn Ẹlẹ́rìí ṣèbẹ̀wò àkọ́kọ́ sọ́dọ̀ ìyàwó mi ló ṣèrìbọmi.

Fífara Mọ́ Ohun Tí Ọlọ́run Sọ Nípa Ẹ̀jẹ̀

Kò pẹ́ tí mo fi kẹ́kọ̀ọ́ pé Bíbélì sọ fún àwọn Kristẹni láti ‘ta kété sí ẹ̀jẹ̀.’ (Ìṣe 15:28, 29; Jẹ́nẹ́sísì 9:4) Níwọ̀n bí mo kúkú ti ń ṣiyèméjì tẹ́lẹ̀ nípa bí ìfàjẹ̀sínilára ṣe gbéṣẹ́ sí, kò ṣòro fún mi rárá láti tẹ́wọ́ gba ojú ìwòye Ọlọ́run nípa ẹ̀jẹ̀. c Mo ronú pé, ‘Bí Ẹlẹ́dàá kan bá wà, bó bá sì jẹ́ ohun tó sọ nìyẹn, ó ní láti jẹ́ ohun tó tọ̀nà nígbà náà.’

Mo tún kẹ́kọ̀ọ́ pé ohun tó ń fa àìsàn àti ikú ni ẹ̀ṣẹ̀ Ádámù. (Róòmù 5:12) Lákòókò yẹn, mò ń ṣe ìwádìí kan lórí àìsàn tó máa ń jẹ́ kí òpójẹ̀ tó ń gbé ẹ̀jẹ̀ kiri nínú ara le tantan. Bá a ti ń dàgbà sí i, àwọn òpójẹ̀ wa máa ń le tantan wọ́n á sì tín-ín-rín, èyí sì máa ń fa àwọn àìsàn bí àrùn ọkàn, àìsàn tó ń ṣàkóbá fún iṣan tó ń gbé ẹ̀jẹ̀ lọ sínú ọpọlọ àti àrùn kíndìnrín. Ó bọ́gbọ́n mu fún mi láti gbà pé àìpé tá a ti jogún ló ń fà á. Lẹ́yìn èyí, ìtara tí mo ní fún ìmọ̀ ìṣègùn bẹ̀rẹ̀ sí dín kù. Àyàfi Jèhófà Ọlọ́run nìkan ṣoṣo ló lè mú àìsàn àti ikú kúrò!

Ní March 1976, oṣù méje lẹ́yìn tí mo bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, mo pa ẹ̀kọ́ mi ní ilé ìwòsàn tó wà ní yunifásítì náà tì. Ẹ̀rù kọ́kọ́ ń bà mí pé mi ò ní ríṣẹ́ gẹ́gẹ́ bíi dókítà mọ́, àmọ́ mo ríṣẹ́ sí ọsibítù mìíràn. Mo ṣèrìbọmi ní May 1976. Mo pinnu pé ọ̀nà tó dára jù lọ fún mi láti lo ìgbésí ayé mi ni pé kí n sìn gẹ́gẹ́ bí ajíhìnrere alákòókò kíkún tàbí aṣáájú ọ̀nà, èyí tí mo bẹ̀rẹ̀ ní July 1977.

Gbígbèjà Ojú Ìwòye Ọlọ́run Nípa Ẹ̀jẹ̀

Ní November ọdún 1979, èmi àti Masuko ṣí lọ sí ìjọ kan ní Àgbègbè Chiba, níbi tí wọ́n ti nílò àwọn oníwàásù gan-an. Mo rí ọsibítù kan níbi tí mo ti lè máa ṣiṣẹ́ àbọ̀ọ̀ṣẹ́. Lọ́jọ́ àkọ́kọ́ mi níbi iṣẹ́, àwùjọ àwọn oníṣègùn iṣẹ́ abẹ kan yí mi ká. Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ń bi mí léraléra pé, “Bó o ṣe jẹ́ ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà yìí, kí ni wàá ṣe bí wọ́n bá gbé aláìsàn kan tó nílò ẹ̀jẹ̀ wá?”

Mo fi tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ ṣàlàyé fún wọn pé ohun tí Ọlọ́run sọ nípa ẹ̀jẹ̀ ni màá tẹ̀ lé. Mo ṣàlàyé pé àwọn ìtọ́jú mìíràn wà yàtọ̀ sí fífa ẹ̀jẹ̀ síni lára àti pé màá ṣe gbogbo ohun tí mo bá lè ṣe láti ran àwọn aláìsàn náà lọ́wọ́. Lẹ́yìn tá a ti jíròrò fún nǹkan bíi wákàtí kan, ẹni tó jẹ́ ọ̀gá oníṣẹ́ abẹ dáhùn pé, “Ọ̀rọ̀ rẹ yé mi. Àmọ́, bí wọ́n bá gbé ẹnì kan wá tó ti pàdánù ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀jẹ̀, àwa la máa bójú tó onítọ̀hún.” Ẹnì kan tó ṣòroó bá lò làwọn èèyàn mọ ọ̀gá oníṣẹ́ abẹ náà sí, àmọ́ lẹ́yìn ìjíròrò yẹn, a wá mọwọ́ ara wa gan-an, ó sì máa ń bọ̀wọ̀ fún ìgbàgbọ́ mi.

Kíkọ̀ Láti Gba Ẹ̀jẹ̀ Mú Ìdánwò Wá

Nígbà táà ń sìn ní Chiba, wọ́n ń kọ́ orílé iṣẹ́ tuntun ti àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Japan lọ́wọ́ nígbà yẹn ní ìlú Ebina. Èmi àti ìyàwó mi máa ń wakọ̀ lọ síbẹ̀ lẹ́ẹ̀kan lọ́sẹ̀ láti bójú tó ìlera àwọn Ẹlẹ́rìí tó jẹ́ olùyọ̀ǹda ara ẹni tí wọ́n ń kọ́ ilé yìí, tí à ń pè ní Bẹ́tẹ́lì. Lẹ́yìn oṣù díẹ̀, a gba ìkésíni pé ká wá máa sìn ní Bẹ́tẹ́lì Ebina. Nípa bẹ́ẹ̀, ní March ọdún 1981, a bẹ̀rẹ̀ sí gbé nínú àwọn ilé onígbà-kúkúrú tí wọ́n fi àwọn olùyọ̀ǹda ara ẹni tó lé ní ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta wọ̀ sí. Láàárọ̀, mo máa ń ṣèrànwọ́ láti mú kí àwọn ilé ìwẹ̀ àti ilé ìyàgbẹ́ tó wà níbi tá a ti ń ṣiṣẹ́ náà wà ní mímọ́ tónítóní, tó bá sì di ọ̀sán, mo máa ń bẹ àwọn tó nílò ìtọ́jú wò.

Ọ̀kan lára àwọn tí mo tọ́jú ni Ilma Iszlaub, tó wá láti orílẹ̀-èdè Ọsirélíà sí Japan gẹ́gẹ́ bíi míṣọ́nnárì lọ́dún 1949. Ó ní àrùn leukemia, àwọn dókítà rẹ̀ sì sọ fún un pé kò lè lò ju oṣù díẹ̀ péré lọ tí yóò fi kú. Ilma kọ̀ láti gba ẹ̀jẹ̀ láti mú ẹ̀mí rẹ̀ gùn sí i, ó sì yàn láti lọ gbé ìwọ̀nba ọjọ́ rẹ̀ tó kù ní Bẹ́tẹ́lì. Nígbà yẹn, kò tíì sí àwọn oògùn bí erythropoietin, èyí tó máa ń jẹ́ kí ara lè túbọ̀ mú àwọn sẹ́ẹ̀lì pupa inú ẹ̀jẹ̀ jáde. Nípa bẹ́ẹ̀, àwọn ìgbà míì wà tí ìwọ̀n èròjà pupa inú ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ máa lọ sílẹ̀ gan-an sí gíráàmù mẹ́ta tàbí mẹ́rin! (Méjìlá sí mẹ́ẹ̀ẹ́dógún ló dára.) Àmọ́, mo ṣe gbogbo ohun tí mo lè ṣe láti tọ́jú rẹ̀. Ilma ń bá a nìṣó láti máa fi ìgbàgbọ́ tí kì í yẹ̀ hàn nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run títí tó fi wá kú ní January ọdún 1988, ìyẹn nǹkan bí ọdún méje lẹ́yìn ìgbà náà!

Bọ́dún ti ń gorí ọdún, wọ́n ṣiṣẹ́ abẹ fún àwọn olùyọ̀ǹda ara ẹni bíi mélòó kan ní ẹ̀ka iléeṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Japan. Ọpẹ́ ńlá ló yẹ àwọn dókítà tó wà ní àwọn ọsibítù tó wà nítòsí wa fọwọ́ sowọ́ pọ̀ nípa ṣíṣe àwọn iṣẹ́ abẹ náà láìlo ẹ̀jẹ̀. Ọ̀pọ̀ ìgbà ni wọ́n ti pè mí sínú yàrá iṣẹ́ abẹ láti máa wo ọ̀nà tí wọ́n ń gbà ṣe é, àwọn ìgbà míì sì wà tá a tiẹ̀ jọ ṣiṣẹ́ abẹ náà. Mo dúpẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn dókítà wọ̀nyẹn tí wọ́n bọ̀wọ̀ fún ojú ìwòye àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà nípa ọ̀ràn ẹ̀jẹ̀. Ṣíṣiṣẹ́ pẹ̀lú wọn ti fún mi ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ àǹfààní láti sọ fún wọn nípa ohun tí mo gbà gbọ́. Ọ̀kan nínú àwọn dókítà náà di Ẹlẹ́rìí tó ṣèrìbọmi láìpẹ́ yìí.

Ó jẹ́ ohun tó dùn mọ́ni láti mọ̀ pé ìsapá àwọn dókítà láti ṣètọ́jú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà láìlo ẹ̀jẹ̀ ti mú ìtẹ̀síwájú ńláǹlà bá ìmọ̀ ìṣègùn. Àwọn iṣẹ́ abẹ tí wọ́n ń ṣe láìlo ẹ̀jẹ̀ ti pèsè ẹ̀rí tó fi àwọn àǹfààní tó wà nínú ṣíṣàì gba ẹ̀jẹ̀ sára hàn. Àwọn ìwádìí fi hàn pé àwọn aláìsàn tètè máa ń gbádùn, wọn kì í sì fi bẹ́ẹ̀ níṣòro lẹ́yìn iṣẹ́ abẹ.

Bíbá A Nìṣó Láti Máa Kẹ́kọ̀ọ́ Lọ́dọ̀ Oníṣègùn Tó Ga Jù Lọ

Mo ṣì ń bá a lọ láti máa mọ̀ nípa àwọn ìtẹ̀síwájú tuntun tó ń dé bá ìmọ̀ ìṣègùn. Síbẹ̀, mo tún ń bá a nìṣó láti máa kẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ Jèhófà, Oníṣègùn tó ga jù lọ. Kì í ṣe ohun tó hàn sójú nìkan ló ń rí, àmọ́ ó tún ń rí wa bí a ṣe jẹ́ gan-an. (1 Sámúẹ́lì 16:7) Gẹ́gẹ́ bíi dókítà kan, mo máa ń gbìyànjú láti tọ́jú aláìsàn kọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí ẹnì kan fúnra rẹ̀, kì í ṣé àìsàn tó ń ṣe é nìkan ni mo máa ń wò. Èyí máa ń mú kí n lè fún aláìsàn kan ní ìtọ́jú tó péye.

Mo ṣì ń sìn ní Bẹ́tẹ́lì. Ọ̀kan lára ohun tó sì ń fún mi láyọ̀ jù lọ ni ríran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ láti mọ̀ nípa Jèhófà, títí kan ojú tó fi wo ẹ̀jẹ̀. Àdúrà mi ni pé, kí Oníṣègùn Gíga náà, Jèhófà Ọlọ́run, mú òpin dé bá gbogbo àìsàn àti ikú láìpẹ́.—Gẹ́gẹ́ bí Yasushi Aizawa ti sọ ọ́.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Gẹ́gẹ́ bí ìwé Modern Blood Banking and Transfusion Practices látọwọ́ ọ̀jọ̀gbọ́n Denise M. Harmening ti sọ, “ìfàjẹ̀sínilára lè ba àwọn sẹ́ẹ̀lì pupa inú ẹ̀jẹ̀ aláìsàn kan jẹ́ bí ara rẹ̀ bá ti di aláìlágbára nítorí ẹ̀jẹ̀ tó ti kọ́kọ́ gbà sára, nítorí pé ó lóyún tàbí nítorí pé wọ́n ti ṣe iṣẹ́ abẹ ìpààrọ̀ ẹ̀yà ara fún un.” Nínú irú àwọn ọ̀ràn bẹ́ẹ̀, “àwọn ìlànà pípegedé tí wọ́n ń lò ṣáájú ìfàjẹ̀sínilára kò lè ṣàwárí” ohun agbóguntàrùn inú ara tó ń mú kí ara aláìsàn kan kọ ẹ̀jẹ̀ tí wọ́n bá fà sí i lára. Gẹ́gẹ́ bí ìwé Dailey’s Notes on Blood ti sọ, àwọn sẹ́ẹ̀lì pupa inú ẹ̀jẹ̀ “lè” bà jẹ́ “kódà bó bá jẹ́ ìwọ̀nba ẹ̀jẹ̀ díẹ̀ tí kò bá aláìsàn kan lára mu . . . ni wọ́n fà sí i lára. Nígbà tí kíndìnrín kò bá ṣiṣẹ́ mọ́, ìdọ̀tí á bẹ̀rẹ̀ sí gbára jọ sínú ẹ̀jẹ̀ aláìsàn náà, yóò sì bẹ̀rẹ̀ sí kú díẹ̀díẹ̀ nítorí pé kíndìnrín rẹ̀ kò lè mú àwọn ìdọ̀tí náà kúrò.”

b Ìwé àtìgbàdégbà náà, Journal of Clinical Oncology, ti August 1988 sọ pé: “Àwọn aláìsàn tó gba ẹ̀jẹ̀ ṣáájú kí wọ́n tó lọ ṣiṣẹ́ abẹ àrùn jẹjẹrẹ kì í kọ́fẹ padà bọ̀rọ̀ bíi tàwọn tí wọn ò gba ẹ̀jẹ̀ ṣáájú iṣẹ́ abẹ náà.”

c Fún ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé lórí ohun tí Bíbélì fi kọ́ni nípa ẹ̀jẹ̀, wo ìwé pẹlẹbẹ náà, How Can Blood Save Your Life? tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tẹ̀ jáde.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 14]

“Mo ṣàlàyé pé àwọn ìtọ́jú mìíràn wà yàtọ̀ sí fífa ẹ̀jẹ̀ síni lára àti pé màá ṣe gbogbo ohun tí mo bá lè ṣe láti ran àwọn aláìsàn náà lọ́wọ́”

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 15]

“Àwọn iṣẹ́ abẹ tí wọ́n ń ṣe láìlo ẹ̀jẹ̀ ti pèsè ẹ̀rí tó fi àwọn àǹfààní tó wà nínú ṣíṣàì gba ẹ̀jẹ̀ sára hàn”

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]

Lókè: Mò ń sọ àsọyé Bíbélì

Apá Ọ̀tún: Èmi àti aya mi, Masuko, lónìí