Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Báwo Lo Ṣe Lè Yẹra fún Èrò Tí Kò Tọ́?

Báwo Lo Ṣe Lè Yẹra fún Èrò Tí Kò Tọ́?

Ojú Ìwòye Bíbélì

Báwo Lo Ṣe Lè Yẹra fún Èrò Tí Kò Tọ́?

“Nígbà tí mo bá fẹ́ láti ṣe ohun tí ó tọ́, ohun tí ó burú a máa wà pẹ̀lú mi.”—RÓÒMÙ 7:21.

BÓYÁ ni Pọ́ọ̀lù ò ta gbogbo àwọn àpọ́sítélì yòókù yọ nínú fífún àwọn mìíràn níṣìírí láti tẹ̀ lé àwọn ìlànà gíga ti ìsìn Kristẹni. (1 Kọ́ríńtì 15:9, 10) Síbẹ̀, kò fọ̀rọ̀ sábẹ́ ahọ́n sọ nígbà tó sọ ohun tó wà lókè yìí nípa ara rẹ̀. Ó máa ń ní ìdààmú ọkàn nítorí àwọn èrò tí kò tọ́ tó máa ń wá sọ́kàn rẹ̀ nígbà gbogbo. Ṣé ìwọ náà ti ní irú ìmọ̀lára tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ní yìí rí? Ká sòótọ́, níwọ̀n bá a ti jẹ́ ẹ̀dá aláìpé, ta ni nínú wa ni kò tíì ní irú ìdààmú ọkàn bẹ́ẹ̀ rí?

Fún ọ̀pọ̀, ogun tí wọ́n ń jà láti borí èròkérò kì í ṣe kékeré rárá. Àwọn kan máa ń yán hànhàn láti tẹ́ ìfẹ́ ìṣekúṣe tó ń dìde nínú ọkàn wọn lọ́rùn. Ní ti àwọn mìíràn sì rèé, wọ́n ti di ẹrú fún tẹ́tẹ́ títa, tábà, oògùn olóró tàbí ọtí líle tó ti di bárakú fún wọn. Nígbà tí àwọn èrò ọkàn tó léwu tó sì jẹ́ aláìmọ́ bá ń wá sí wa lọ́kàn gan-an, báwo la ṣe lè mú wọn kúrò? Ìrànlọ́wọ́ wo la ní? Ǹjẹ́ bíbá àwọn èrò tí kò tọ́ jìjàkadì tiẹ̀ máa wá sópin láé?

Ìfẹ́ Ló Lè Múni Yẹra fún Àwọn Èrò Tí Kò Tọ́

Jésù sọ̀rọ̀ nípa òfin méjì tó tóbi jù lọ nínú Òfin Mósè. Àkọ́kọ́ nìyí: “Kí ìwọ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run rẹ pẹ̀lú gbogbo ọkàn-àyà rẹ àti pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹ àti pẹ̀lú gbogbo èrò inú rẹ.” (Mátíù 22:37) Bá a bá nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run lọ́nà tí Jésù sọ pé ká gbà nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, ǹjẹ́ mímú inú Rẹ̀ dùn kọ́ ló yẹ kó jẹ́ olórí ìfẹ́ ọkàn wa? Bó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, ìfẹ́ fún èrò tó tọ́ yìí lè ràn wá lọ́wọ́ láti bá àwọn èrò àìtọ́ jà, títí kan àwọn tó ti mọ́ wa lára! Èyí kì í kàn ṣe àsọdùn lásán o. Àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn Kristẹni ló ń bá àwọn èrò tí kò tọ́ jà lójoojúmọ́ tí wọ́n sì ń kẹ́sẹ járí. Báwo lo ṣe lè dẹni tó nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run lọ́nà yẹn? Nípa fífi ẹ̀mí ìmọrírì ṣàṣàrò lójoojúmọ́ lórí oore rẹ̀ bí a ti rí i nínú ìṣẹ̀dá, nínú Bíbélì àti nínú ọ̀nà tó ń gbà bá wa lò lẹ́nì kọ̀ọ̀kan—Sáàmù 116:12, 14; 119:7, 9; Róòmù 1:20.

Òfin tó tóbi ṣìkejì tí Jésù mẹ́nu kàn ni: “Kí ìwọ nífẹ̀ẹ́ aládùúgbò rẹ gẹ́gẹ́ bí ara rẹ.” (Mátíù 22:39) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé ìfẹ́ “kì í hùwà lọ́nà tí kò bójú mu” bẹ́ẹ̀ ni “kì í wá àwọn ire tirẹ̀ nìkan.” Irú ìfẹ́ àìmọtara-ẹni-nìkan yìí ń tipa bẹ́ẹ̀ ràn wá lọ́wọ́ láti yẹra fún ìwà èyíkéyìí tó lè pa àwọn ẹlòmíràn lára. (1 Kọ́ríńtì 13:4-8) Báwo la ṣe lè ní irú ìfẹ́ yìí? Nípa fífi ara wa sí ipò àwọn ẹlòmíràn ni, àti jíjẹ́ kí bí nǹkan ṣe ń rí lára wọn àti ire ayérayé wọn máa jẹ wá lọ́kàn gidigidi.—Fílípì 2:4.

Ìrànlọ́wọ́ Wo La Ní?

Nítorí pé Ọlọ́run lóye bó ṣe nira tó fún wa láti ṣe ohun tó tọ́, ó ti ṣètò láti ràn wá lọ́wọ́ lóríṣiríṣi ọ̀nà. Nípasẹ̀ Ọ̀rọ̀ rẹ̀ tá a kọ sílẹ̀, ìyẹn Bíbélì, ó ń kọ́ wa láti kórìíra ohun tó burú ká sì ní ọ̀wọ̀ yíyẹ fún Òun. (Sáàmù 86:11; 97:10) Nínú Bíbélì, a lè rí àkọsílẹ̀ nípa ohun tó ṣẹlẹ̀ sí àwọn èèyàn, èyí tó fi àbájáde búburú tó máa ń wá látinú jíjuwọ́ sílẹ̀ fún àwọn èrò tí kò tọ́ hàn. Láfikún sí ìyẹn, Jésù sọ pé Ọlọ́run yóò fún wa ní ẹ̀mí mímọ́ Rẹ̀, tó jẹ́ ipá tó lágbára jù lọ ní gbogbo àgbáyé, bí a bá béèrè fún un. (Lúùkù 11:13) Ó lè sọ ìpinnu wa láti ṣe ohun tí ó tọ́ di èyí tó lágbára sí i. Ìrànlọ́wọ́ mìíràn tá a tún ní ni ìtìlẹ́yìn àti ìṣírí tọ̀tún-tòsì tá a lè rí gbà látọ̀dọ̀ àwọn Kristẹni mìíràn táwọn náà ń yẹra fún àwọn èrò tí kò tọ́. (Hébérù 10:24, 25) Bí àwọn ohun tó ń nípa rere lórí ẹni wọ̀nyí ti ń rọ́pò àwọn èrò tí kò tọ́ lọ́kàn wa, à ń rí ìrànlọ́wọ́ gbà nínú ìjàkadì wa láti ṣe ohun tó tọ́. (Fílípì 4:8) Ǹjẹ́ ìlànà yìí ń ṣiṣẹ́ lóòótọ́?

Ronú nípa Fidel, tí gbogbo àwọn ará àdúgbò rẹ̀ mọ̀ sí ọ̀mùtí paraku. Bó bá ti mutí yó tán, ó máa ń mu sìgá, ó máa ń ta tẹ́tẹ́, ó sì máa ń bá àwọn èèyàn jà. Ẹ̀kọ́ Bíbélì tó ń kọ́ àti bíbá tó ń bá àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kẹ́gbẹ́ ràn án lọ́wọ́ láti borí àwọn àṣà wọ̀nyẹn. Ní báyìí, ayé rẹ̀ ti wá dára sí i, ìyàwó rẹ̀ àtàwọn ọmọ wọn méjì sì ti ń gbádùn rẹ̀.

Ẹnì kan lè béèrè pé, ‘Àmọ́ ká ní mo tún wá ṣèèṣì padà sínú àṣà burúkú náà ńkọ́?’ Àpọ́sítélì Jòhánù sọ̀rọ̀ nípa èyí. Ó kọ̀wé pé: “Ẹ̀yin ọmọ mi kéékèèké, mo ń kọ̀wé nǹkan wọ̀nyí sí yín kí ẹ má bàa dá ẹ̀ṣẹ̀. Síbẹ̀síbẹ̀, bí ẹnikẹ́ni bá dá ẹ̀ṣẹ̀, àwa ní olùrànlọ́wọ́ lọ́dọ̀ Baba, Jésù Kristi, ẹni tí í ṣe olódodo. Òun sì ni ẹbọ ìpẹ̀tù fún àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa, síbẹ̀ kì í ṣe fún tiwa nìkan ṣùgbọ́n fún ti gbogbo ayé pẹ̀lú.” (1 Jòhánù 2:1, 2) Bẹ́ẹ̀ ni, ẹbọ Jésù kájú àwọn àṣìṣe ẹnì kan tó ronú pìwà dà tó sì ń sa gbogbo ipá rẹ̀ láti ṣe àtúnṣe kó bàa lè múnú Ọlọ́run dùn. Pẹ̀lú ìpèsè yìí, ìdí pàtàkì wo lẹnì kan lè ní fún jíjuwọ́ sílẹ̀ nínú ìjàkadì láti ṣe ohun tó tọ́?

Àwọn Èrò Tí Kò Tọ́ Máa Di Ohun Tí A Ṣẹ́gun

Bá a bá mú kí ìfẹ́ wa fún Ọlọ́run àti aládùúgbò pọ̀ sí i tá a sì ṣàmúlò ìrànlọ́wọ́ tí Ọlọ́run pèsè, kódà nísinsìnyí a lè kẹ́sẹ járí nínú ìsapá wa láti yẹra fún àwọn èrò tí kò tọ́. Láfikún sí i, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fi dá wa lójú pé ìjàkadì yìí kò ní máa bá a lọ títí ayé. Láìpẹ́ sígbà tá a wà yìí, àwọn tó bá lo àwọn ìpèsè tẹ̀mí tí Ọlọ́run pèsè yóò di ẹni tá a wò sàn pátápátá nípa tara àti nípa tẹ̀mí. (Ìṣípayá 21:3-5; 22:1, 2) Wọ́n á dòmìnira kúrò lọ́wọ́ ìnira tí ẹṣẹ̀ ń mú wá àti ikú tó ń jẹ́ àbájáde rẹ̀. (Róòmù 6:23) Ní ìdàkejì, àwọn tó bá ń bá a lọ láìjáwọ́ láti máa fi àwọn èrò ẹlẹ́gbin àtàwọn èrò tó ń pani lára tó ń wá sọ́kàn wọn ṣèwà hù kò ní sí lára àwọn tí yóò gbádùn àwọn ìbùkún wọ̀nyí.—Ìṣípayá 22:15.

Ẹ ò ri pé ohun tó ń tuní lára gan-an ló jẹ́ láti mọ̀ pé a ò ní máa bà a lọ títí ayé láti máa jìjàkadì pẹ̀lú àwọn èrò tí kò tọ́. Wọ́n á di ohun tá a mú kúrò pátápátá àti títí láé. Ìtura ńlá gbáà nìyẹn á mà jẹ́ o!