Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Pípèsè Oúnjẹ Látinú Oko Rẹ

Pípèsè Oúnjẹ Látinú Oko Rẹ

Pípèsè Oúnjẹ Látinú Oko Rẹ

LÁTỌWỌ́ AKỌ̀RÒYÌN JÍ! NÍ CENTRAL AFRICAN REPUBLIC

NÍ Ọ̀PỌ̀ orílẹ̀-èdè, ohun kan tí àwọn èèyàn máa ń ṣàníyàn nípa rẹ̀ lójoojúmọ́ ni bí wọ́n á ṣe pèsè oúnjẹ fún ìdílé wọn. Owó gegere tí wọ́n ń dá lé ewébẹ̀ sábà máa ń mú kí ṣíṣe èyí nira gan-an. Síbẹ̀síbẹ̀, àwọn kan ti rí ọ̀nà kan tó rọrùn láti gbà kojú ìṣòro yìí, ìyẹn ni gbígbin díẹ̀ lára oúnjẹ wọn!

Ó ṣeé ṣe kí ìwọ náà fẹ́ láti gbìyànjú dídáko kékeré kan. Lóòótọ́ o, ó lè má fi bẹ́ẹ̀ sí ilẹ̀ láyìíká ilé rẹ, àmọ́ ó ṣeé ṣe kí ilẹ̀ díẹ̀ wà nítòsí tó o lè lò láti fi dáko. Ronú nípa iye tó o lè fi pa mọ́ nípa ṣíṣọ̀gbìn àwọn oúnjẹ aládùn, oúnjẹ aṣaralóore! Àní, oko dídá lè jẹ́ ọ̀nà kan tó o lè gbà máa ṣe eré ìmárale, èyí tó ṣe kókó fún ìlera rẹ. Iṣẹ́ oko tún lè jẹ́ iṣẹ́ kan tí gbogbo ìdílé lápapọ̀ á jọ máa ṣe, èyí tí àwọn ọmọ rẹ yóò gbádùn. Láìsí àní-àní, dídáko ewébẹ̀ jẹ́ ohun tó ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́. Ó lè kọ́ni láwọn ànímọ́ bíi sùúrù. (Jákọ́bù 5:7) Láfikún sí i, wíwo bí àwọn irúgbìn ṣe ń dàgbà sókè lè túbọ̀ fà ọ́ sún mọ́ Ẹlẹ́dàá gbogbo ohun rere.—Sáàmù 104:14.

Àmọ́ o, má ṣe ronú pé gbígbin oúnjẹ rẹ kò ní gba ìsapá kankan tàbí pé kò ní pẹ́ tí wàá fi rí àbájáde akitiyan rẹ. Síbẹ̀síbẹ̀, bó o bá pinnu láti ṣiṣẹ́ àgbẹ̀, tó o sì ní òye díẹ̀ nípa rẹ̀, o lè ṣe é láṣeyọrí!

Bí Ìdílé Kan Ṣe Ń Pèsè Oúnjẹ Fúnra Wọn

Bí àpẹẹrẹ, ronú nípa Timothée àti Lucie—tọkọtaya Kristẹni kan tí wọ́n lọ́mọ méjì, tí wọ́n ń gbé ní ìlú Bangui, olú ìlú orílẹ̀-èdè Central African Republic. Wọ́n rí i pé dídá oko tiwọn jẹ́ ọ̀nà gbígbéṣẹ́ tó sì ń gbádùn mọ́ni láti ṣàlékún ìwọ̀nba owó tó ń wọlé fún wọn.

Nígbà tí Lucie wà lọ́mọ ọdún mẹ́tàlá, ó ń dá oko kékeré kan nítòsí ilé wọn, ó sì máa ń lọ ṣiṣẹ́ níbẹ̀ lẹ́yìn tó bá dé láti iléèwé àti ní òpin ọ̀sẹ̀. Ó fẹ́ràn láti máa wo bí àwọn ohun tó gbìn ṣe ń dàgbà. Àmọ́ o, ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn náà ni èrò dídáko nítorí ti ìdílé rẹ̀ tó ṣẹ̀ṣẹ̀ wá sí i lọ́kàn. Ó ṣètò láti lo ilẹ̀ kan nítòsí ilé wọn, èyí tí wọ́n fi ń da pàǹtírí sí. Lucie rí i pé ilẹ̀ náà ṣì lè wúlò gan-an. Dípò tí pàǹtírí ì bá fi ba ilẹ̀ náà jẹ́, ńṣe ni jíjẹrà tí wọ́n jẹrà mọ́lẹ̀ bí ọdún ti ń gorí ọdún mú kí ilẹ̀ náà dára fún iṣẹ́ ọ̀gbìn. Bí Lucie àti Timothée ṣe pinnu láti sọ ilẹ̀ náà di oko tó ń méso jáde lọ́pọ̀ yanturu nìyẹn.

Bí Wọ́n Ṣe Bẹ̀rẹ̀

Àmọ́ o, wọ́n gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ ṣèwádìí díẹ̀ ná. Wọ́n lọ bá àwọn tó mọ̀ nípa ọ̀gbìn ewébẹ̀ sọ̀rọ̀, wọ́n sì fetí sílẹ̀ dáadáa sí àlàyé wọn. Níwọ̀n bó ti yẹ kí wọ́n bomi rin ilẹ̀ náà, wọ́n tún kọ́ nípa bí wọ́n ṣe lè gbẹ́ kànga tiwọn pàápàá. Kíka àwọn ìwé tó sọ nípa oko dídá tún ràn wọ́n lọ́wọ́ gan-an ni.

Wọ́n kà nípa bí àwọn irúgbìn ṣe máa ń nípa lórí ara wọn, wọ́n sì rí i pé àwọn irúgbìn kan máa ń ran ara wọn lọ́wọ́ láti dàgbà dáadáa. Àmọ́, àwọn irúgbìn kan kì í tiẹ̀ jẹ́ kí àwọn mìíràn gbérí rárá. Àwọn kan sọ pé kárọ́ọ̀tì àti tòmátì jọ máa ń dàgbà pọ̀ dáadáa nínú oko ewébẹ̀. Lọ́nà kan náà, gbígbin ewébẹ̀ celery àti cauliflower pọ̀ máa ń ṣe àwọn ewébẹ̀ méjèèjì láǹfààní. Irúgbìn dílì ní tirẹ̀ máa ń ṣe àwọn irúgbìn bí ẹ̀wà pòpòǹdó, apálá, ewébẹ̀ lettuce àti àlùbọ́sà láǹfààní. Àmọ́, ewébẹ̀ lettuce àti parsley kì í hù dáadáa bí a bá gbìn wọ́n pọ̀. Àlùbọ́sà sì máa ń pa ẹ̀wà aláwọ̀ ewé àti ẹ̀wà pòpòǹdó lára. Bí àwọn irúgbìn bá ń ṣàkóbá fún ara wọn, wọn ò ní lágbára mọ́, àwọn kòkòrò tó ń ba irúgbìn jẹ́ á sì lè tètè rí wọn gbé ṣe.

Timothée àti Lucie tún kẹ́kọ̀ọ́ pé kò bọ́gbọ́n mu láti máa gbin oríṣi irúgbìn kan ṣoṣo sórí ilẹ̀ téèyàn fi ń dáko. Bí àwọn kòkòrò tàbí àrùn kan bá kọ lu irúgbìn náà, wọ́n lè pàdánù gbogbo ohun tí wọ́n gbìn. Gbígbin onírúurú irúgbìn tó máa ń ṣe dáadáa bí a bá gbìn wọ́n pa pọ̀ ràn wọ́n lọ́wọ́ láti dín ewu pípàdánù irè oko wọn kù. Àwọn ewéko olóòórùn dídùn àti òdòdó mú kí oko ewébẹ̀ wọn ní àwọ̀ oríṣiríṣi, kó máa fani mọ́ra, kó sì lẹ́wà. Wọ́n sì tún ń fa àwọn oyin àtàwọn kòkòrò wíwúlò mìíràn tí wọ́n ń mú kí oko ọ̀gbìn máa ṣe dáadáa wá sínú oko náà.

Tọkọtaya yìí tún mọ àwọn ohun tí wọ́n lè ṣe láti yẹra fún fífọ́n àwọn oògùn apakòkòrò onímájèlé sára irè oko wọn. Wọ́n kẹ́kọ̀ọ́ pé gbígbin aáyù nìkan ti tó láti lé àwọn kòkòrò kan tó lè ba irúgbìn jẹ́ kúrò.

Ọ̀pọ̀ iṣẹ́ àṣekára àti sùúrù ló ná Timothée àti Lucie láti ṣọ̀gbìn oúnjẹ, àmọ́ ní báyìí wọ́n ti ní oko kan tó ń mú nǹkan jáde dáadáa. Oko wọn máa ń pèsè àwọn nǹkan bí ewébẹ̀ cabbage, parsley, tòmátì, kárọ́ọ̀tì, apálá àti ìgbá—ìwọ̀nyí sì máa ń pọ̀ gan-an nígbà míì ju ohun tí ìdílé wọn lè jẹ tán lọ!

Ìwọ Náà Dá Oko Tìrẹ!

Àmọ́ o, kì í ṣe nílẹ̀ Áfíríkà nìkan làwọn èèyàn ti rí i pé ó ṣàǹfààní láti ní oko tiwọn. Bí àpẹẹrẹ, nílẹ̀ Jámánì, ohun tó lé ní mílíọ̀nù kan ọgbà tí àwọn èèyàn lè fi dáko ló wà láàárín ìlú tàbí nítòsí ìlú. Nígbà míì, wọ́n máa ń pe àwọn oko àdáni wọ̀nyí ní Schrebergaerten (ní ìrántí oníṣègùn ará ilẹ̀ Jámánì náà, Daniel Schreber). Àwọn ọgbà tí àwọn èèyàn lè fi dáko láàárín ìlú yìí jẹ́ àwọn ilẹ̀ (bí igba sí irínwó mítà níbùú lóròó) tí wọ́n pín kéékèèké fún àwọn aráàlú tó bá fẹ́ yá wọn lò. Gẹ́gẹ́ bí ohun tí olùṣèwádìí kan sọ, àwọn oko kéékèèké wọ̀nyí “ń kópa tí kì í ṣe kékeré nínú ìmújáde àwọn èso àti ewébẹ̀.” Àwọn oko wọ̀nyí tún lè jẹ́ “párádísè” kékeré kan fún àwọn tó ń fi wọ́n dáko, ìyẹn ni ibi tí wọ́n ti lè ṣiṣẹ́ kí wọ́n sì sinmi.

Bíbélì ṣèlérí pé lọ́jọ́ kan láìpẹ́, gbogbo ayé yóò di ọgbà ọ̀gbìn kan tó kárí ayé, ìyẹn ni ojúlówó párádísè. (Lúùkù 23:43) Àmọ́, ní báyìí ná, o lè gbìyànjú láti wá ilẹ̀ kékeré kan, inú rẹ á sì dùn pé ò ń rí oúnjẹ látinú oko kékeré tó o dá.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]

Timothée àti Lucie ń fa omi tí wọ́n fẹ́ lò fún oko ìdílé wọn

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]

Ilẹ̀ kan tí wọ́n fún àwọn aráàlú láti fi dáko ní ìlú Munich, ní orílẹ̀-èdè Jámánì