Ta Ni Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà?
A wá látinú onírúurú ẹ̀yà àti èdè, síbẹ̀ àwọn ohun kan náà ló jẹ gbogbo wa lógún. Olórí gbogbo ẹ̀ ni pé, a fẹ́ bọlá fún Jèhófà, Ọlọ́run tó ni Bíbélì tó sì jẹ́ Ẹlẹ́dàá ohun gbogbo. A ń ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù Kristi, inú wa sì ń dùn pé a jẹ́ Kristẹni. Ẹnì kọ̀ọ̀kan wa máa ń fi àkókò rẹ̀ ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ kí wọ́n lè kẹ́kọ̀ọ́ nípa Bíbélì àti Ìjọba Ọlọ́run. Àwọn èèyàn mọ̀ wá sí Ẹlẹ́rìí Jèhófà torí pé a máa ń jẹ́rìí nípa Jèhófà Ọlọ́run àti Ìjọba rẹ̀.
Oríṣiríṣi nǹkan lo máa rí lórí ìkànnì yìí. Ka Bíbélì lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì. Mọ púpọ̀ sí i nípa wa àtàwọn ohun tá a gbà gbọ́.