Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

“Ká Láwọn Ọ̀dọ́ Mọ̀ Pé Bọ́rọ̀ Ṣe Rí Nìyẹn Ni!”

“Ká Láwọn Ọ̀dọ́ Mọ̀ Pé Bọ́rọ̀ Ṣe Rí Nìyẹn Ni!”

“Ká Láwọn Ọ̀dọ́ Mọ̀ Pé Bọ́rọ̀ Ṣe Rí Nìyẹn Ni!”

LẸ́YÌN tí David jáde ilé ìwé gíga, dípò tí ì bá fi máa ronú bó ṣe máa kó àwọn nǹkan tara jọ bíi tàwọn akẹgbẹ́ rẹ̀, èrò míì ló wà lọ́kàn ẹ̀. Lóṣù September, ọdún 2003, òun àti ọ̀rẹ́ ẹ̀ kan kó kúrò ní ìpínlẹ̀ Illinois, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, wọ́n sì lọ sí orílẹ̀-èdè Dominican Republic. a Nígbà tí wọ́n débẹ̀, David tí tẹbí tọ̀rẹ́ kúndùn àtimáa pè ní Davey, pinnu pé òun á kọ́ èdè Spanish òun á sì máa dara pọ̀ mọ́ Ìjọ Navas kóun àtàwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà níbẹ̀ lè jọ máa kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Àwọn ará ìjọ náà gbà á tọwọ́tẹsẹ̀. Juan, tó jẹ́ alàgbà kan ṣoṣo tó wà nínú ìjọ náà sọ pé: “Davey kì í rojú iṣẹ́ rárá. Ńṣe lo fira ẹ̀ jìn fáwọn ẹlòmíràn, àwọn ará sì fẹ́ràn rẹ̀ dénú.”

Ibi tí Davey ti ń wàásù yìí wù ú gan-an ni. Nínú lẹ́tà tó kọ sí ọ̀rẹ́ ẹ̀ kan tó wà níbi tó ti wá lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, ó sọ fún un pé: “Mò ń gbádùn ara mi gan-an níbi tí mo wà yìí o. Bíi kéèyàn má padà sílé mọ́ ni tó bá ti lọ sóde ẹ̀rí! A máa ń lò tó ogún ìṣẹ́jú nílé tá a bá ti wàásù nítorí pé àwọn èèyàn máa ń fẹ́ gbọ́ gbogbo ohun tá a bá ní í sọ. Mò ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì mẹ́fà báyìí, síbẹ̀ à ń fẹ́ àwọn oníwàásù púpọ̀ sí i. Akéde ọgbọ̀n ló wà nínú ìjọ wa, ṣùgbọ́n a ti ṣe ìpàdé kan rí tó jẹ́ pé èèyàn mẹ́tàlélọ́gọ́rùn-ún ló wá sípàdé náà!”

Ó bani nínú jẹ́ pé lọ́jọ́ kẹrìnlélógún oṣù April, ọdún 2004, ìjàǹbá mọ́tò pa Davey àti ọ̀dọ́kùnrin mìíràn kan tí wọ́n jọ wà nínú ìjọ. Kí Davey tó kú, ńṣe ni iná ìtara ẹ̀ máa ń jó fún iṣẹ́ ìwàásù tó ń ṣe, ó sì máa ń gba àwọn ọ̀dọ́ bíi tiẹ̀ tó kù nílé níyànjú pé kí wọ́n jẹ́ káwọn jọ máa ṣe é. Ó tiẹ̀ sọ fún Ẹlẹ́rìí kan tó jẹ́ ọ̀dọ́ pé: “Iṣẹ́ náà á yí ojú tó o fi ń wo nǹkan padà.”

Ojú tí Davey pàápàá fi n wo nǹkan tara yí padà. Bàbá Davey sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ kan báyìí tí Davey wá sílé. Wọ́n ní kó jẹ́ káwọn rìnrìn-àjò lọ gbafẹ́. Davey béèrè iye tó máa ná wọn. Nígbà tó gbọ́ iye tó máa ná wọn, ó lóun ò lè ná adúrú owó yẹn sórí ìrìn àjò afẹ́ lásán nítorí pé bóun bá rówó tó tóyẹn, òun á ṣì lè wàásù fún ọ̀pọ̀ oṣù sí i ní orílẹ̀-èdè Dominican Republic!

Àwọn míì rí ẹ̀kọ́ kọ́ látinú ìtara Davey. Ọ̀dọ́ kan tó wà lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà sọ pé: “Nígbà tí mo gbọ́ bí Davey ṣe ń ṣe bẹbẹ tó àti bó ṣe láyọ̀ tó, mo wá mọ̀ pé èmi náà ì bá ti máa wàásù bíi tiẹ̀. Ikú Davey ti mú kí n máa ronú nípa nǹkan tàwọn èèyàn á máa sọ nípa mi bí mo bá kú, àti bóyá wọ́n á lè rí ẹ̀kọ́ kọ́ nínú ohun tí mo gbélé ayé ṣe.”

Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà làwọn òbí Davey àtàwọn tẹ̀gbọ́n tàbúrò ẹ̀, ó dá wọn lójú hán-únhán-ún pé Ọlọ́run á jí Davey dìde nínú ayé tuntun tí òdodo yóò máa gbé. (Jòhánù 5:28, 29; Ìṣípayá 21:1-4) Kó tó dìgbà yẹn, ohun tó ń tù wọ́n nínú ni pé Davey ò lo ìgbésí ayé ẹ̀ nílòkulò, ńṣe ló fi sin Ẹlẹ́dàá rẹ̀. (Oníwàásù 12:1) Nígbà tí Davey ṣì wà láàyè, ó sọ bó ṣe wu òun tó láti lọ máa wàásù níbi tí wọ́n ti ń fẹ́ àwọn oníwàásù púpọ̀ sí i. Ó ní: “Ì bá mà wù mí o, ká ní gbogbo ọ̀dọ́ ló lè lọ síbi tí wọ́n ti ń fẹ́ àwọn oníwàásù púpọ̀ sí i, káwọn náà sì rí bí iṣẹ́ náà ṣe lárinrin tó. Kò sí ohun tó dà bíi kéèyàn sin Jèhófà tọkàntara. Ì bá ti dára tó ká láwọn ọ̀dọ́ mọ̀ pé bọ́rọ̀ ṣe rí nìyẹn ni!”

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Ọ̀pọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti yọ̀ọ̀da ara wọn, bíi ti David, láti lọ máa gbé níbi tí wọ́n ti ń fẹ́ àwọn oníwàásù púpọ̀ sí i, kódà àwọn kan tiẹ̀ kọ́ èdè míì kí wọ́n bàa lè máa fi òtítọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kọ́ àwọn èèyàn. Àwọn èèyàn tó lé nírínwó, tí wọ́n yọ̀ǹda ara wọn bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ń ṣiṣẹ́ ìwàásù ní orílẹ̀-èdè Dominican Republic báyìí.