Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Jẹ́ Kí Èéfín Olóró Ríbi Gbà Jáde

Jẹ́ Kí Èéfín Olóró Ríbi Gbà Jáde

Jẹ́ Kí Èéfín Olóró Ríbi Gbà Jáde

ÈYÍ ò wa pàpọ̀jù? Kéèyàn mẹ́ta máa kú sílé níṣẹ̀ẹ́jú, ìṣẹ́jú lóòjọ́. Kí lohun tó ń pa wọ́n gan-an? Èéfín tó ń rú jáde látara àwọn nǹkan tí wọ́n ń lò nílò ògùṣọ̀ mà ni o.

Àwọn nǹkan wo ni wọ́n ń lò nílò ògùṣọ̀? Ó lè jẹ́ ìgbẹ́ ẹran tó ti gbẹ, igi gbígbẹ, ẹ̀ka igi, koríko, tàbí àwọn pàǹtírí irúgbìn tí wọ́n dà sí àkìtàn. Ìwé ìròyìn The Kathmandu Post ti orílẹ̀-èdè Nepal sọ pé, ìdá mẹ́ta àwọn èèyàn tó ń gbé láyé, èyí tó lé ní bílíọ̀nù méjì, ni wọ́n ń lo àwọn nǹkan wọ̀nyí láti dáná oúnjẹ tàbí láti fi mú ilé móoru. Òun sì ni àwọn tí òṣì mù dundun sábà máa ń rí fi dáná.

Àmọ́, ó ṣeni láàánú pé èéfín olóró làwọn pàǹtírí irúgbìn táwọn èèyàn fi ń dáná yìí ń tú dà sáfẹ́fẹ́. Èwo wá ni ṣíṣe báyìí o? Àjọ kan tó ń ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè láti mú káyé wọn túbọ̀ sunwọ̀n, ìyẹn Ẹgbẹ́ Tó Ń Rí sí Ìdàgbàsókè Ìmọ̀ Iṣẹ́ Ẹ̀rọ sọ pé: “Ìṣòro tó rọrùn láti yanjú ni ìṣòro kéèéfín máa ba àlàáfíà inú ilé jẹ́. Yálà kó o má ṣe jẹ́ kí èéfín wọnú ilé wá, tàbí kó o jẹ́ kí èéfín tó ti wọnú ilé ríbi gbà jáde.”

Àbá wọn àkọ́kọ́ ni pé kéèyàn máa dáná ní gbangba ìta. Béèyàn ò bá wá fẹ́ dáná níta tàbí tí ò bá ṣeé ṣe láti dáná níta ńkọ́ o? Ẹgbẹ́ náà dábàá pé kó o túbọ̀ jẹ́ kí afẹ́fẹ́ máa fẹ́ wọnú ilé dáadáa, kó sì máa ríbi gbà jáde. Ọ̀nà méjì lo sì lè gbà ṣèyẹn. O lè dáhò yíká apá òkè ògiri, (bó o bá fi nẹ́ẹ̀tì bo ojú ihò náà, àwọn ẹranko kéékèèké ò ní máa gbabẹ̀ wọlé) o sì lè ṣe wíńdò tí èéfín á máa gbà jáde (bí o kò bá fẹ́ káwọn èèyàn máa rí inú ilé, o lè fi igi pẹlẹbẹ mélòó kan dígàgá ẹ̀). Èyí á jẹ́ kí afẹ́fẹ́ máa ríbi wọlé, èéfín á sì máa ríbi gbà jáde. Àmọ́ ṣá o, kò ní bọ́gbọ́n mu láti dáhò yíká apá òkè ògiri bó bá jẹ́ nítorí kí ilé lè máa móoru lo ṣe ń dáná. Nítorí náà, ọgbọ́n míì wà tó o lè dá sí i.

Ẹgbẹ́ náà sọ pé ohun èlò tí wọ́n ń dáná lábẹ́ rẹ̀, tí èéfín ń gba inú ẹ̀ jáde jẹ́ ọ̀kan lára ohun tó dáa tó sì wúlò jù lọ téèyàn fi lè fa èéfín jáde. Wọ́n lè fi páànù pẹlẹbẹ tí kò wọ́nwó ṣe é, wọ́n sì tún lè fi bíríkì àti amọ̀ ṣe é. Ńṣe lèèyàn á gbé páànù tí wọ́n ká kóróbójó yìí sórí ààrò ìdáná, èéfín tó bá wọnú rẹ̀ á sì gba ibi tó ti yọrí lára òrùlé jáde. Àwọn ògbógi sọ pé béèyàn bá lè ṣe é kí afẹ́fẹ́ máa gba apá òkè ògiri wọlé kí èéfín sì máa gba inú ihò jáde, gbogbo èéfín olóró tó wà nínú ilé ló máa fẹ́rẹ̀ẹ́ wábi gbà. Àwọn tó ní ihò tí èéfín ń gbà jáde yìí sọ pé àwọn kì í fi bẹ́ẹ̀ ṣàìsàn, èéfín ò rùn mọ́ nínú ilé àwọn, àwọn lè ṣiṣẹ́ púpọ̀ sí i, káwọn sì gbádùn wíwà lábẹ́ ọ̀ọ̀dẹ̀ ju ti tẹ́lẹ̀ lọ. Èyí fi hàn pé ohun tí ò tó nǹkan lè máyé dẹrùn sí i.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]

Ilé ìdáná kan tí wọ́n kọ́ mọ́ ara ilé ní orílẹ̀-èdè Kẹ́ńyà, tó ní ibi tí èéfín ń bá jáde, kò sún mọ́ ara ilé jù, wọ́n sì ṣe wíńdò sí i

[Credit Line]

Dr. Nigel Bruce/www.itdg.org