Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Gbogbo Wa Ló Yẹ Ká Máa Pawọ́ Pọ̀ Tún Ilé Ṣe

Gbogbo Wa Ló Yẹ Ká Máa Pawọ́ Pọ̀ Tún Ilé Ṣe

Gbogbo Wa Ló Yẹ Ká Máa Pawọ́ Pọ̀ Tún Ilé Ṣe

Látọwọ́ òǹkọ̀wé Jí! ní Mẹ́síkò

KÒ MÀ sí ohun tó dáa bíi kéèyàn máa gbé níbi tó mọ́ tí kò lẹ́gbin kankan o! Àmọ́, léyìí tí ìdọ̀tí àti pàǹtírí ń pọ̀ sí i káàkiri ìlú yìí, ńṣe ló túbọ̀ ń ṣòro sí i láti mú kí àyíká wà ní mímọ́ àti létòlétò.

Àwọn ìjọba ìbílẹ̀ ń sapá láti mú kí àwọn òpópónà wà ní mímọ́ nípa gbígbé ìdọ̀tí táwọn èèyàn bá dá jọ, síbẹ̀ ńṣe làwọn ìdọ̀tí ga gègèrè láwọn àgbègbè kan, gbogbo ibẹ̀ kì í ṣeé rí, ó sì ń kó àìsàn bá aráàlú. Bí ìdọ̀tí bá ga gègèrè láìrí ẹni kó o, ó lè mú kí àwọn eku, aáyán àtàwọn nǹkan míì tó lè kó àrùn ranni máa pọ̀ sí i. Ǹjẹ́ ohun kan wà tó o lè ṣe nípa ọ̀ràn yìí? Bẹ́ẹ̀ ni, jẹ́ kí ilé àti àyíká rẹ máa wà ní mímọ́ tónítóní.

Èrò Tó Tọ́ Kí Gbogbo Wa Ní

Àwọn èèyàn kan gbà pé ipò òṣì ló máa ń fa kí àyíká tàbí inú ilé dọ̀tí. Àmọ́, kò fi gbogbo ara rí bẹ́ẹ̀. Ná, bí owó kò bá sí lọ́wọ́, ó máa ṣòro láti mú kí àyíká wa wà ní mímọ́. Ṣùgbọ́n bí òwe àwọn ará Sípéènì kan ṣe sọ, “kò sí aáwọ̀ kankan láàárín òṣì àti ìmọ́tótó.” Ẹ̀wẹ̀, bí ẹnì kan bá lówó lọ́wọ́ dáadáa, ìyẹn ò sọ pé àyíká rẹ̀ á máa mọ́ tónítóní.

Ohun tó lè mú kí ilé àti àyíká máa wà ní mímọ́ ni pé kéèyàn ní èrò tó tọ́ nípa ṣíṣe bẹ́ẹ̀ kó sì máa tún ilé ṣe. Kódà, mímú kí ilé wà ní mímọ́ sinmi lórí ohun tí olúkúlùkù nínú ìdílé bá ń rò nípa ọ̀ràn náà. Nítorí èyí, ó dára láti wo ohun tí gbogbo wa lè ṣe ká lè rí sí i pé ilé wa àti àyíká ibi tá à ń gbé wà ní mímọ́.

Ètò fún Mímú Kí Ilé Wà ní Mímọ́

Ó dà bí ẹni pé iṣẹ́ abiyamọ kì í tán nínú ilé. Òun láá gbọ́únjẹ, táá múra ilé ìwé fáwọn ọmọ, òun kan náà láá tún gbálé gbáta kí gbogbo rẹ̀ lè wà ní mímọ́. Ǹjẹ́ o ti kíyè sí i pé, lọ́pọ̀ ìgbà, ìyá ló máa ń palẹ̀ aṣọ tàbí àwọn nǹkan ìṣeré táwọn ọmọ rẹ̀ bá dà sílẹ̀ mọ́? Bẹ́ ẹ bá ní ètò fún mímú kí ilé wà ní mímọ́, tẹ́ ẹ sì yan ipa ti ẹnì kọ̀ọ̀kan nínú ìdílé fún un, ìyẹn lè dín iṣẹ́ tí ìyá ń ṣe kù.

Àwọn ìyàwó ilé kan ti fojú dá àwọn nǹkan tí wọ́n á máa kíyè sí tí wọ́n á sì máa sọ di mímọ́ lójoojúmọ́, àwọn ibòmíì sì wà tí wọ́n á máa yẹ̀ wò lẹ́ẹ̀kan lọ́sẹ̀ tàbí lẹ́ẹ̀kan lóṣù. Kódà, àwọn ohun kan wà téèyàn lè ṣètò pé òun á máa sọ di mímọ́ lẹ́ẹ̀kan lọ́dún. Bí àpẹẹrẹ, láwọn Ilé Bẹ́tẹ́lì tó wà ní ọ́fíìsì àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lórílẹ̀-èdè kọ̀ọ̀kan, wọ́n máa ń fọ yàrá kékeré tí wọ́n máa ń kó aṣọ sí lẹ́ẹ̀kan lọ́dún. Èyí máa ń fún wọn láǹfààní láti kó àwọn nǹkan tí kò bá wúlò dà nù, kí wọ́n sì tún inú yàrá kékeré náà tò. Ètò sì tún wà fún fífọ ara ògiri déédéé.

Àwọn ibì kan tún wà nínú ilé tó gbọ́dọ̀ máa wà ní mímọ́ tónítóní kí àìsàn má bàa máa ṣeni, irú ibẹ̀ ni ilé ìwẹ̀. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ojoojúmọ́ ló yẹ kéèyàn máa tún ilé ìwẹ̀ ṣe níwọ̀nba, béèyàn bá túbọ̀ ń tún un ṣe dáadáa, bóyá lẹ́ẹ̀kan lọ́sẹ̀, àwọn kòkòrò àrùn ò ní ríbi yé sí. Àwọn kan rò pé kò sí ohun téèyàn lè ṣe sí ìdọ̀tí tó máa ń gbára jọ sára ṣáláńgá aláwo àti pé kò sí béèyàn ṣe lè fọ̀ wọ́n kúrò. Síbẹ̀, àwọn ilé kan wà tí àwo ṣáláńgá wọn máa ń mọ́ tónítóní, tó sì máa ń dán gbinrin. Gbogbo ohun tó ń béèrè ò ju pé kéèyàn máa fọ̀ ọ́ déédéé, kéèyàn sì máa lo ọṣẹ àti kẹ́míkà tó bá yẹ.

Ó tún yẹ kéèyàn má fara balẹ̀ fọ ilé ìdáná kó sì tún máa gbá a mọ́ tónítóní. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé lójoojúmọ́ lo máa ń fọ abọ́ tó o sì máa ń nu sítóòfù àti orí ibi tó o máa ń kó àwọn ohun èlò sí nílé ìdáná, ó pọn dandan pé kó o túbọ̀ máa fọ àwọn ibi pàtó kan mọ́ tónítóní lẹ́ẹ̀kan lọ́gbọ̀n, tàbí bóyá ó kéré tán, lẹ́ẹ̀kan lóṣù, irú bí ẹ̀yìn kọ́bọ́ọ̀dù, fíríìjì àtàwọn pàlàpolo ibòmíì. Bó o bá ń gbá tinú tòde ibi tẹ́ ẹ̀ ń kó oúnjẹ sí tàbí kọ́bọ́ọ̀dù tó wà nílé ìdáná, àwọn aáyán àtàwọn kòkòrò mìíràn ò ní lè fi ibẹ̀ ṣelé.

Bí Olúkúlùkù Nínú Ìdílé Ṣe Lè Fọwọ́ Sowọ́ Pọ̀

Àwọn òbí kan gbé ìlànà táwọn ọmọ wọn á máa tẹ̀ lé kalẹ̀, wọ́n sì ti kọ́ wọn débi pé kí wọ́n tó lọ sílé ìwé láàárọ̀, wọ́n á tún bẹ́ẹ̀dì wọn tẹ́, wọ́n á palẹ̀ àwọn aṣọ wọn tó dọ̀tí mọ́, wọ́n á sì to àwọn nǹkan tó wà ní yàrá wọn nigínnigín. Ìlànà kan tó wúlò fún olúkúlùkù nìyí, “O gbọ́dọ̀ ní ibi tí wàá máa tọ́jú àwọn nǹkan sí, sì jẹ́ kí wọ́n máa wà níbẹ̀.”

Bákan náà, ẹ lè yan iṣẹ́ tí olúkúlùkù nínú ìdílé á máa ṣe fún un, ó sì lè jẹ́ àwọn ibì kan nínú ilé ni wọ́n á máa bójú tó láti rí i pé ó wà ní mímọ́. Bí àpẹẹrẹ, ṣé bàbá ló ń palẹ̀ ibi tẹ́ ẹ̀ ń gbé mọ́tò sí mọ́ tó sì ń mú kí ibẹ̀ wà ní mímọ́ tónítóní, ó kéré tán, lẹ́ẹ̀kan lọ́dún? Ǹjẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọmọ kúkú lè máa ràn án lọ́wọ́? Ta ló ń tu igbó tó bá hù síwájú ilé, tàbí tó ń gé koríko? Báwo ló ṣe yẹ kó máa gé e lemọ́lemọ́ sí kí iwájú ilé bàa lè máa dùn ún wò? Ṣé yàrá tẹ́ ẹ kọ́ mọ́ ara òrùlé tàbí yàrá irinṣẹ́ wà tó yẹ kẹ́ ẹ máa yẹ̀ wò kẹ́ ẹ lè gbọn pàǹtírí tàbí ìdọ̀tí tó bá wà níbẹ̀, kí àyíká ibẹ̀ lè di mímọ́? Bó bá rí bẹ́ẹ̀, ta lẹ máa yàn án fún? Àwọn òbí kan máa ń yan irú iṣẹ́ wọ̀nyí fáwọn ọmọ, wọ́n sì máa ń pín in láàárín wọn.

Nítorí náà, ṣe ètò tó mọ́yán lórí fún títún ilé rẹ ṣe. Ì báà jẹ́ fúnra rẹ lò ń mú kí inú ilé wà ní mímọ́ tàbí kó jẹ́ pé ìwọ àti ìdílé rẹ lẹ jọ ń ṣe é, tàbí kó o tiẹ̀ gba ẹnì kan láti máa ràn ọ́ lọ́wọ́, ó pọn dandan pé kó o ní ètò gúnmọ́ tí wàá lè máa tẹ̀ lé. Ìyá kan tó máa ń mú kí ilé rẹ̀ wà ní mímọ́ tónítóní sọ fún wa pé gbogbo àwọn làwọn ń fọwọ́ sowọ́ pọ̀ láti mú kí ilé wà ní mímọ́ tónítóní. Ó sọ pé: “Èmi àtàwọn ọmọbìnrin mi mẹ́ta la jọ máa ń pín iṣẹ́ náà ṣe láàárín ara wa. Norma Adriana ló máa ń tún pálọ̀, yàrá méjì, àgbàlá àti iwájú ilé ṣe. Ana Joaquina ló ń tọ́jú ilé ìdáná. Èmi ni mo máa ń fọ aṣọ tí mo sì máa ń bójú tó àwọn nǹkan míì, María del Carmen ló sì ń fọ abọ́.”

Bí Iwájú Ilé Ṣe Lè Máa Fani Mọ́ra

Báwo ló ṣe yẹ kí iwájú ilé máa rí? Yálà ò ń gbé nínú ilé ràgàjì tàbí nínú ilé kẹ́jẹ́bú, ó ṣe pàtàkì pé kó o ṣètò bí iwájú ilé tó ò ń gbé á ṣe máa wà ní mímọ́. Bí àpẹẹrẹ, ọ̀kan lára irin tó gbé géètì dúró lè ti kán. Ìwọ náà mọ bó ṣe máa burú tó bí wọ́n bá fi géètì náà sílẹ̀ láìtún un ṣe títí táá fi já lulẹ̀. Bẹ́ẹ̀ náà ló máa jẹ́ ohun tó burú bá a bá jẹ́ kí ìdọ̀tí kóra jọ pelemọ síwájú ilé tàbí lójú ọ̀nà téèyàn ń gbà nítòsí ilé. Nígbà míì sì rèé, àwọn kan máa ń jẹ́ kí agolo, irinṣẹ́, àtàwọn ohun èèlò mìíràn kóra jọ pelemọ síwájú ilé, inú ìdọ̀tí bẹ́ẹ̀ sì làwọn eku àti kòkòrò àrùn fi máa ń ṣelé.

Àwọn ìdílé kan ti pinnu pé nígbàkigbà tí àyíká ilé àwọn, títí kan ojú ọ̀nà ẹlẹ́sẹ̀ àti ilẹ̀ iwájú ilé bá dọ̀tí, àwọn á máa gbá a, àwọn á sì máa jẹ́ kó wà ní mímọ́ lẹ́ẹ̀kan lóòjọ́ tàbí lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀. Òótọ́ ni pé láwọn ibì kan, ìjọba ní ètò tó mọ́yán lórí fún mímú kí àyíká wà ní mímọ́, ṣùgbọ́n láwọn ibòmíràn, ìjọba ìbílẹ̀ ò ní ètò tó jọ bẹ́ẹ̀. Kò sí iyè méjì níbẹ̀ pé àyíká ibi tá à ń gbé á dára sí i, a ò sì ní máa kó àrùn bí gbogbo wa bá ń ṣe ipa tiwa láti mú kó máa wà ní mímọ́.

Yàtọ̀ sí pé àwọn ìdílé kan ní ètò gbálé-gbáta bí irú èyí tá à ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ yìí, wọ́n tún kọ ọ́ sórí ìwé, wọ́n sì lẹ̀ ẹ́ mọ́ ibi tí gbogbo wọn ti lè rí i, kí wọ́n bàa lè máa tẹ̀ lé e. Irú ètò bẹ́ẹ̀ máa ń ṣèrànwọ́ gan-an ni. Àmọ́ ṣá o, kì í ṣe gbogbo ohun tó yẹ kéèyàn mọ̀ nípa mímú kí ilé wà ní mímọ́ la tíì mẹ́nu bà o. Bí àpẹẹrẹ, ó yẹ kó o pinnu irú ọṣẹ tàbí kẹ́míkà téèyàn fi ń tún ilé ṣe tó máa wúlò jù lọ ní àdúgbò rẹ, àtàwọn ohun èlò míì tó jẹ mọ́ ọn, èyí tí owó rẹ lè ká.

Ó dájú pé àwọn àbá ṣókí yìí á jẹ́ kí olúkúlùkù nínú ìdílé mọ bó ti ṣe pàtàkì tó láti mú kí inú ilé àti àyíká ilé máa wà ní mímọ́ tónítóní. Má ṣe gbàgbé pé mímú kí ilé àti àyíká rẹ̀ wà ní mímọ́ kò sinmi lórí bó o ṣe rí já jẹ tó, níní èrò tó tọ́ nípa rẹ̀ ló jà jù.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 20, 21]

Ètò Gbálé Gbáta Tó Wúlò Gan-an

Lo àlàfo tá a fi sílẹ̀ láti fi àwọn kókó tìẹ kún ìṣètò yìí

Kókó pàtàkì: Ọ̀pọ̀ ewu ló wà nínú dída àwọn èròjà olómi tí wọ́n fi ń fọ nǹkan pọ̀ mọ́ra, pàápàá jù lọ bílíìṣì àti èròjà àmóníà

Ojoojúmọ́

❏ Yàrá: Tẹ́ bẹ́ẹ̀dì kó o sì to àwọn nǹkan tó wà níbẹ̀ nigín-nigín

❏ Ilé ìdáná: Fọ abọ́ àti ibi tó o ti ń dáná. Palẹ̀ orí tábìlì àti àyíká ibi tó o ti ń dáná mọ́ kó o sì to àwọn nǹkan bó ṣe yẹ. Bí ilẹ̀ ilé ìdáná bá dọ̀tí, gbá a tàbí kó o fọ̀ ọ́

❏ Ilé ìwẹ̀: Fọ ibi tẹ́ ẹ ti ń fọwọ́ àti ṣáláńgá aláwo. To àwọn nǹkan síbi tó bá yẹ kí wọ́n wà

❏ Pálọ̀ àtàwọn yàrá míì: To àwọn nǹkan síbi tó bá yẹ kí wọ́n wà. Nu àwọn ohun èlò tẹ́ ẹ tò sínú ilé fẹ́ẹ́rẹ́fẹ́. Bí ilẹ̀ bá dọ̀tí, gbá a, fomi fọ̀ ọ́, tàbí kó o gbá rọ́ọ̀gì, o sì lè fi ẹ̀rọ fa ìdọ̀tí inú rẹ̀

❏ Gbogbo ilé: Máa da ilẹ̀ nù déédéé

Ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀

❏ Yàrá: Pààrọ̀ aṣọ bẹ́ẹ̀dì. Gbálẹ̀, fomi fọ̀ ọ́, tàbí kó o gbá rọ́ọ̀gì, o sì lè fi ẹ̀rọ fa ìdọ̀tí inú rẹ̀, tó bá yẹ bẹ́ẹ̀. Faṣọ nu eruku tó wà lára àwọn ohun èlò tẹ́ ẹ tò sílé

❏ Ilé ìdáná: Fọ sítóòfù tàbí àwọn ẹ̀rọ tó ò ń lò nílé ìdáná, àtàwọn páìpù tó wà níbẹ̀. Nu ilẹ̀ tàbí kó o fọ̀ ọ́

❏ Ilé ìwẹ̀: Fọ ògiri ilé ìwẹ̀, ara ẹ̀rọ alásẹ́ àti gbogbo páìpù àti ọrùn ẹ̀rọ. Fi omi tó o da oògùn apakòkòrò sí fọ ilé ìgbọ̀nsẹ̀, àwọn kọ́bọ́ọ̀dù ìkó-nǹkan-sí àtàwọn ibòmíì tó bá dọ̀tí. Pààrọ̀ aṣọ ìnura. Gbálẹ̀ tàbí kó o fọ̀ ọ́

Oṣooṣù

❏ Ilé ìwẹ̀: Fọ gbogbo ara ògiri mọ́ tónítóní

❏ Gbogbo ilé: Nu férémù gbogbo ilẹ̀kùn. Fi ẹ̀rọ fa ìdọ̀tí ara àga onítìmùtìmù tàbí kó o gbọ̀n ọ́n, kó o sì nù ún

❏ Ọgbà, àgbàlá, ibi ìgbọ́kọ̀sí: Bí wọn bá dọ̀tí gbá wọn tàbí kó o fomi fọ̀ wọ́n. Má ṣe jẹ́ kí ìdọ̀tí tàbí àwọn nǹkan tí kò wúlò gbára jọ

Oṣù Mẹ́fà-Mẹ́fà

❏ Yàrá: Fọ àwọn aṣọ bẹ́ẹ̀dì, kó o sì tẹ̀ lé ìtọ́ni àwọn tó ṣe aṣọ náà

❏ Ilé ìdáná: Kó ohun tó wà nínú fíríìjì kúrò kó o sì fọ̀ ọ́ mọ́ tónítóní

❏ Ilé ìwẹ̀: Nu kọ́bọ́ọ̀dù tó wà níbẹ̀ tinú tẹ̀yìn. Kó àwọn nǹkan tí kò wúlò bí oògùn, ìpara, tàbí àwọn kẹ́míkà ìfọlé tọ́jọ́ ti kọjá lórí wọn kúrò níbẹ̀

❏ Gbogbo ilé: Nu gílóòbù, fáànù àti ibi tó bá dọ̀tí lára wáyà àti ohun tẹ́ ẹ fi ń tan iná. Nu àwọn ilẹ̀kùn tó wà nínú ilé. Nu wíńdò, gíláàsì ara wíńdò àtàwọn férémù

Ọdọọdún

❏ Yàrá: Palẹ̀ yàrá kékeré tẹ́ ẹ̀ ń kó aṣọ sí mọ́ kó o gbá a, kó o sì nù ún dáadáa. Kó àwọn nǹkan tí kò wúlò dà nù. Fọ bùláńkẹ́ẹ̀tì. Fi ẹ̀rọ fa ìdọ̀tí inú tìmùtìmù bẹ́ẹ̀dì tàbí kó o gbọn tìmùtìmù náà. Fọ ìrọ̀rí, kó o tẹ̀ lé ìtọ́ni àwọn tó ṣe é

❏ Ilé ìdáná: Nu kọ́bọ́ọ̀dù àtàwọn àpótí míì tẹ́ ẹ̀ ń kó nǹkan sí tinú tẹ̀yìn. Kó àwọn nǹkan tó ò bá lò mọ́ dà nù. Sún àwọn ohun èlò tó fara ti ògiri kó o lè nu ẹ̀yìn wọn tàbí kó o fọ ilẹ̀ ibi tí wọ́n wà

❏ Gbogbo ilé: Fọ gbogbo ara ògiri. Nu àwọn àga onítìmùtìmù àti kọ́tìnì, kó o tẹ̀ lé ìtọ́ni àwọn tó ṣe é

❏ Ibi ìgbọ́kọ̀sí tàbí ibi ìkẹ́rùsí: Gbá a mọ́ tónítóní. To ibẹ̀ dáadáa tàbí kó o kó àwọn nǹkan tí kò wúlò níbẹ̀ dà nù

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 22]

“O gbọ́dọ̀ ní ibi tí wàá máa tọ́jú àwọn nǹkan sí, sì jẹ́ kí wọ́n máa wà níbẹ̀”

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 22]

Ì bá sàn jù kó o fún àwọn ẹlòmíì ní ohun tó ò bá lò mọ́