Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Bá A Ṣe Lè Fòpin Sí Ṣíṣàfọwọ́rá

Bá A Ṣe Lè Fòpin Sí Ṣíṣàfọwọ́rá

Bá A Ṣe Lè Fòpin Sí Ṣíṣàfọwọ́rá

“Bí ṣíṣàfọwọ́rá ṣe máa dín kù kì í ṣe ìṣòro tìẹ nìkan, ìṣòro gbogbo ará àdúgbò ni, ó ṣe tán, gbogbo wa la máa jàǹfààní ẹ̀ tí ò bá sí olè mọ́.”—ÌWÉ “EVERY RETAILER’S GUIDE TO LOSS PREVENTION.”

BÍI tàwọn ìwà burúkú mìíràn, ṣíṣàfọwọ́rá máa ń mú kéèyàn ronú pé ohun tó tọ́ lòun ń ṣe. Nítorí náà, gẹ́lẹ́ báwọn olùtọ́jú inú ọgbà ṣe máa ń fa koríko tu tigbòǹgbò tigbòǹgbò làwọn tó fẹ́ ṣíwọ́ àfọwọ́rá gbọ́dọ̀ fa ìrònú burúkú yẹn tu kúrò nínú ọpọlọ wọn. Róòmù 12:2 rọ̀ wá pé ká ‘yí èrò inú wa padà.’ Bákan náà, 1 Pétérù 1:14 gbà wá níyànjú pé ká ‘jáwọ́ nínú dídáṣà ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ìfẹ́-ọkàn tí a ti ní tẹ́lẹ̀ rí.’ Àwọn kókó márùn-ún kan rèé tó lè ran ẹni tó ń ṣàfọwọ́rá lọ́wọ́ láti ṣíwọ́.

Ohun Tó Yẹ Kó Sún Èèyàn Láti Yí Ìrònú Rẹ̀ Padà

◼ Èkíní, títẹ òfin lójú ni ṣíṣàfọwọ́rá jẹ́. Ó lè jẹ́ pé tàgbà tọmọdé ló ń ṣàfọwọ́rá tó sì ń mú un jẹ ládùúgbò tẹ́ni tó ń ṣàfọwọ́rá ń gbé o, síbẹ̀ ẹni tó ń ṣàfọwọ́rá ṣì ń rúfin.—Róòmù 13:1.

Kí ló máa ṣẹlẹ̀ bí ọ̀pọ̀ èèyàn bá ń tẹ òfin lójú? Ohun tí Bíbélì sọ ni pé “òfin [máa] kú tipiri.” (Hábákúkù 1:3, 4) Ìyẹn ni pé, kò ní sí pé òfin ń kó ẹnikẹ́ni níjàánu láti má ṣe ohun tó burú, èyí sì máa ń jẹ́ kíwà ìbàjẹ́ gbòde kan. Gbogbo ìgbà tẹ́nì kan bá ti ṣàfọwọ́rá, ṣe lẹni yẹn ń jin àlàáfíà àwùjọ lẹ́sẹ̀. Bí ìyẹn bá sì ṣẹlẹ̀, kò sẹ́ni tí kò ní kàn.

◼ Ìkejì, ṣíṣàfọwọ́rá kì í jẹ́ kéèyàn lè fọkàn tán ẹlòmíì. Irú ìwà àìṣòótọ́ bẹ́ẹ̀ máa ń ba ìbágbépọ̀ ẹ̀dá jẹ́ díẹ̀díẹ̀, èyí tó máa ń mú kó nira féèyàn láti lóye ẹlòmíì kó sì fọkàn tán an.—Òwe 16:28.

Obìnrin oníṣòwò aṣọ kan táwọn olè dá ní gbèsè sọ pé: “Àṣìṣe mi tó burú jù ni bí mo ṣe máa ń gbára lé gbogbo èèyàn.” Ìdí ni pé ó ti gbọ́kàn lé àwọn oníbàárà ẹ̀ àtàwọn tó ń bá a ṣiṣẹ́ débi tó fi rò pé wọn ò lè ja òun lólè. Àmọ́, ní báyìí, ó ti wá rí i pé igi à bá fẹ̀yìn tì, kìkì ẹ̀gún ni.

Ẹnì kan lè parọ́ fún ẹnì kejì kó sì fi bẹ́ẹ̀ dẹni àbùkù lójú ẹni tó parọ́ fún náà. Ṣùgbọ́n ṣe ni aláfọwọ́rá á mú kí wọ́n máa fura sí gbogbo oníbàárà tó bá ti wọlé lẹ́yìn wọn. Á wá di pé kí wọ́n máa fojú olè wo ẹni tó jẹ́ olóòótọ́ pàápàá. Ṣó yẹ kéèyàn ṣe irú ìyẹn?

◼ Ìkẹta, àfọwọ́rá lè sún aláfọwọ́rá dédìí àwọn ìwà ọ̀daràn míì. Ó lè máà pẹ́ tí aláfọwọ́rá á fi máa tẹ̀ síwájú látinú búburú sínú búburú.—2 Tímótì 3:13.

Ìgbà Kan Ń Bọ̀ Tá A Ò Ní Gbúròó Àfọwọ́rá Mọ́

◼ Ìkẹrin, tó sì ṣe pàtàkì jù, ni pé Ọlọ́run Olódùmarè kì í fi ojúure wo aláfọwọ́rá. Ọ̀rọ̀ Rẹ̀ sọ pé kí olè “má jalè mọ́,” ó sì kìlọ̀ nípa ìdájọ́ tó wà nílẹ̀ fẹ́ni tó bá tàpá sí Ọ̀rọ̀ Òun. (Éfésù 4:28; Sáàmù 37:9, 17, 20) Ṣùgbọ́n, Jèhófà máa dárí ji àwọn olè tó bá yí padà. Wọ́n á lè wà ní àlàáfíà pẹ̀lú Ọlọ́run.—Òwe 1:33.

◼ Ìkarùn-ún, bíi tàwọn ìwà ọ̀daràn míì, ìwà àfọwọ́rá máa tó ròkun ìgbàgbé. Nígbà tí Ìjọba Ọlọ́run bá gba àkóso ayé bí Bíbélì ti ṣèlérí, àwọn èèyàn á máa fòótọ́ inú bára wọn lò. Èyí ni pé kò ní sí pé èèyàn tún ń kàgbákò àfọwọ́rá mọ́.—Òwe 2:21, 22; Míkà 4:4.

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 22]

ÀWỌN Ọ̀NÀ TÍ KÒ WỌ́NWÓ LÁTI DÈNÀ ÀFỌWỌ́RÁ

Àwọn oníṣòwò alábọ́dé kan lè máà rówó ra ohun èèlò olówó ńlá tó ń táṣìírí ọ̀daràn. Ṣùgbọ́n, èyí ò ní kí wọ́n má lè bọ́ lọ́wọ́ àwọn aláfọwọ́rá. Lọ́pọ̀ ìgbà, àwọn oníṣòwò lè dáàbò bo ọjà wọn nípa ṣíṣe àwọn nǹkan tí kò fi bẹ́ẹ̀ nira pàápàá.

Ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ ni Michael Brough àti Derek Brown. Àwọn méjèèjì tẹnu mọ́ bó ṣe yẹ káwọn oníṣòwò máa kíyè sí àwọn oníbàárà wọn nínú ìwé kan tí wọ́n pawọ́ pọ̀ ṣe. Wọ́n ní: “Gbogbo èèyàn ni kẹ́ ẹ máa ṣọ́. . . . Ìwọ àtàwọn tó ń bá ẹ tajà ni kẹ́ ẹ jọ máa ṣọ́ wọn.” Wọ́n dábàá pé kẹ́ ẹ sún mọ́ ẹnì kan tẹ́ ẹ bá fura sí pé ó fẹ́ ṣàfọwọ́rá, kẹ́ ẹ sì bi í pé: “Ǹjẹ́ ẹ ti rí ọjà tẹ́ ẹ̀ ń wá? Ẹ jọ̀wọ́, ẹ gbé e síbi tí wọ́n ti ń sanwó kí n lè báa yín ro iye ẹ̀ pọ̀.” “Àbí, kí n báa yín fi bébà wé ìyẹn?” “Ṣé súwẹ́tà yẹn bá yín mu?” Ṣé kí n bá yín wá apẹ̀rẹ̀ tẹ́ ẹ máa kó o sí? Àwọn ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ náà ní: “Èyí ló máa jẹ́ káwọn ojúlówó oníbàárà títí kan àwọn aláfọwọ́rá pàápàá mọ̀ pé ojú wà lára àwọn àti pé ẹ nífẹ̀ẹ́ àwọn.”

Wọ́n tún sọ̀rọ̀ nípa wíwà létòlétò, wọ́n ní: “Jẹ́ káwọn ọjà náà wà létòlétò kó sì mọ́ tónítóní. Bó o bá ń jẹ́ kó wà létòlétò ní gbogbo ìgbà, wàá lè mọ ọjà tó o ní lórí igbá dunjú. Bó bá sì ṣe mọ́ tónítóní tó ló ṣe máa rọrùn fún ẹ tó láti mọ̀ bí ẹnì kan bá ti fọwọ́ kan nǹkan kan tàbí tó ti mú un lọ.”Ìwé Every Retailer’s Guide to Loss Prevention.

Russell Bintliff tó jẹ́ olùwádìí dábàá pé: “Ó yẹ kí ibi tó dà bí ọ̀nà tí wọ́n máa gbà dédìí ọjà tí wọ́n fẹ́ rà náà fẹ̀ tó, báwọn ọjà náà bá sì sún mọ́ra, ojú á lè máa tó àwọn oníbàárà. Bí ẹni tí wọ́n gbà láti máa bá wọn tajà bá lè máa pasẹ̀ lọ pasẹ̀ bọ̀ nítosí ibi tí ẹni tí wọ́n fura sí bí aláfọwọ́rá bá dúró sí, ó máa rọrùn fún un láti mọ̀ bí ọjà kan bá ti pòórá. Bí ìgbà tó bá ń yẹ ọjà tó wà lórí igbá wò ló máa ṣe táá fi máa yẹ ọjà tó ti wà nínú apẹ̀rẹ̀ tẹ́ni náà fà lọ́wọ́ wò. . . . Ó máa tètè yé ẹni tó fẹ́ ṣàfọwọ́rá pé àṣírí ti fẹ́ tú, nígbà táwọn ojúlówó oníbàárà ò tiẹ̀ ní mọ̀ pé ẹnì kan ń wo àwọn.” Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ nípa bó ṣe yẹ kí wọ́n to inú ṣọ́ọ̀bù, Russell Bintliff ní: “Bí wọ́n ṣe to ọjà náà gbọ́dọ̀ lè láàyè débi tójú [ẹni tó ni ṣọ́ọ̀bù] àtàwọn tí wọ́n gbà síbẹ̀ á fi lè máa tó àwọn oníbàárà.”—Ìwé Crimeproofing Your Business—301 Low-Cost, No-Cost Ways to Protect Your Office, Store, or Business.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 21]

Òótọ́ inú máa ń jẹ́ káwọn èèyàn lè fọkàn tán ara wọn, kí wọ́n sì bá ara wọn lò tinútinú