Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Iṣẹ́ Bọ́!

Iṣẹ́ Bọ́!

Iṣẹ́ Bọ́!

“Nígbà tíṣẹ́ bọ́ lọ́wọ́ mi, ṣe ló dà bíi pé orí mi fò lọ lọ́rùn mi. Ọ̀rọ̀ ayé mi ò wá yé mi mọ́.”—Tony, Jámánì.

“Ńṣe ló dà bíi pé wọ́n di òkúta sínú ẹ̀rù, tí wọ́n wá gbé e kà mí lórí. Èmi tó jẹ́ pé ṣe ni mò ń dá tọ́mọ, mo bẹ̀rẹ̀ sí ṣàníyàn lórí bí màá ṣe máa tọ́ àwọn ọmọ mi méjèèjì àti bí màá ṣe máa san owó tó bá yẹ ní sísan.”—Mary, Íńdíà.

“Ọkàn mi dàrú nígbà tíṣẹ́ bọ́ lọ́wọ́ mi, mò ń ṣàníyàn lórí bóyá màá rí òmíràn àbí mi ò ní rí.”—Jaime, Mẹ́síkò.

KÁÀKIRI àgbáyé, ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn ló ń fara gbá irú ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Tony, Mary àti Jaime. Ní ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rúndún tá a wà yìí, wọ́n ṣírò rẹ̀ pé ìdá mẹ́wàá àwọn tó wà lọ́jọ́ orí ẹni tó lè ṣiṣẹ́, ìyẹn nǹkan bíi mílíọ̀nù mẹ́tàlélógún èèyàn ló ń wáṣẹ́. Láwọn orílẹ̀-èdè tí kò tíì gòkè àgbà, ẹnì kan nínú mẹ́rin lára àwọn tó wà lọ́jọ́ orí ẹni tó lè ṣiṣẹ́ ni ò níṣẹ́ tó ń mówó wọlé fún wọn. Ìwé ìròyìn The New York Times sọ ní July ọdún 2003 pé nílẹ̀ Amẹ́ríkà, “ó lé ní mílíọ̀nù méjì àbọ̀ èèyàn tí iṣẹ́ bọ́ mọ́ lọ́wọ́ lójijì, láàárín ọdún méjì àti oṣù mẹ́rin tó kọjá.”

Ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè, iṣẹ́ wíwá ti dogun. Bí àpẹẹrẹ, ẹgbàágbèje ọ̀dọ́ tó jáde nílé ìwé gíga ló kún ìgboro tí wọ́n ń wáṣẹ́ kiri. Yàtọ̀ síyẹn, pé ẹnì kan ní ìwé ẹ̀rí nínú iṣẹ́ kan kò fi hàn pé ó máa rí iṣẹ́ tó yàn láàyò. Ìdí rèé tó fi jẹ́ pé ní báyìí, kì í ṣe tuntun mọ́ káwọn èèyàn máa pààrọ̀ iṣẹ́ láìmọye ìgbà láàárín ọdún tí wọ́n fi ṣiṣẹ́ lábẹ́ èèyàn. Àwọn kan tiẹ̀ ti pa iṣẹ́ tí wọ́n kọ́ tì pátápátá tí wọ́n sì ti mú òmíràn ṣe.

Tó bá di pé o ò níṣẹ́ lọ́wọ́, kí lo lè ṣe kó bàa lè túbọ̀ rọrùn fún ẹ láti ríṣẹ́? Tó o bá sì ti wá ríṣẹ́, báwo lo ṣe lè ṣe é tíṣẹ́ náà ò fi ní bọ́ mọ́ ẹ lọ́wọ́?